“Olúwa Kì Yóò Ṣá Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Tì”
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣùgbọ́n Olúwa gbà á nínú wọn gbogbo.”—ORIN DÁFÍDÌ 34:19.
1, 2. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ lónìí? (b) Kí ni ọ̀pọ̀ Kristẹni dojú kọ, àwọn ìbéèrè wo sì ni ó dìde?
NÍ ÌMÚṢẸ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àwọn olùjọ́sìn Jèhófà ń gbé nínú párádísè tẹ̀mí. (Kọ́ríńtì Kejì 12:1-4) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ kan tí ó kárí ayé, tí a fi ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan dá mọ̀. (Jòhánù 13:35) Wọ́n ń gbádùn ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì tí ó jinlẹ̀, tí ó sì gbòòrò. (Aísáyà 54:13) Ẹ wo bí wọ́n ti kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà tó pé ó fún wọn ní àǹfààní láti jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ̀ nípa tẹ̀mí!—Orin Dáfídì 15:1.
2 Bí gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ètò àjọ Jèhófà tilẹ̀ ń gbádùn aásìkí tẹ̀mí, ó dà bíi pé àwọn kan ń gbé ní àlàáfíà, dé àyè kan wọ́n sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn, nígbà tí a sì ń pọ́n àwọn mìíràn lójú lọ́nà kan tàbí òmíràn. Fún àkókò gígùn, ọ̀pọ̀ Kristẹni ń rí ara wọn nínú ipò tí ń ṣeni láàánú, tí kò sì sí ìrètí kankan fún ìtura nítòsí. Ìrẹ̀wẹ̀sì kì í ṣe nǹkan àjèjì lábẹ́ irú àyíká ipò bẹ́ẹ̀. (Òwe 13:12) Àjálù ha jẹ́ ẹ̀rí pé inú Ọlọ́run kò dùn sí ẹnì kan bí? Jèhófà ha ń pèsè ààbò àrà ọ̀tọ̀ fún àwọn Kristẹni kan, tí ó sì ń ṣá àwọn mìíràn tì bí?
3. (a) Jèhófà ha ni ó fa làásìgbò tí ó dé bá àwọn ènìyàn rẹ̀ bí? (b) Èé ṣe tí ìyà fi ń jẹ àwọn olùṣòtítọ́ olùjọsìn Jèhófà pàápàá?
3 Bíbélì dáhùn pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe wí pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Jèhófà ni Aláàbò àti Olùmúdúró àwọn ènìyàn rẹ̀. (Orin Dáfídì 91:2-6) “Olúwa kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì.” (Orin Dáfídì 94:14) Èyí kò túmọ̀ sí pé ìyà kò lè jẹ àwọn olùṣòtítọ́ olùjọsìn. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ti jogún àìpé ni wọ́n ń ṣàkóso ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ayé ìsinsìnyí. Ọ̀pọ̀ jẹ́ oníwà ìbàjẹ́, àwọn kan sì jẹ́ olubi ẹ̀dá gbáà. Kò sí èyíkéyìí nínú wọn tí ń wo Jèhófà fún ọgbọ́n. Èyí ń yọrí sí ọ̀pọ̀ ìyà tí ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn. Bíbélì mú un ṣe kedere pé àwọn ènìyàn Jèhófà kò lè fìgbà gbogbo yẹra fún àbájáde bíbani nínú jẹ́ tí àìpé ẹ̀dá ènìyàn àti ìwà ibi ń mú wá.—Ìṣe 14:22.
A Retí Kí Àwọn Kristẹni Adúróṣinṣin Jìyà
4. Kí ni gbogbo Kristẹni lè máa retí níwọ̀n bí wọ́n bá ṣì ń gbé nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí, èé sì ti ṣe?
4 Bí wọn kì í tilẹ̀ ṣe apá kan ayé, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń gbé nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Jòhánù 17:15, 16) A tú Sátánì fó nínú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ipá ajẹgàba tí ń bẹ lẹ́yìn ayé yìí. (Jòhánù Kíní 5:19) Nítorí náà, gbogbo Kristẹni lè retí pé bó pẹ́ bó yá, àwọn yóò dojú kọ ìṣòro líle koko. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ pa àwọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pa ẹnì kan jẹ. Ṣùgbọ́n ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan naa ní ọ̀nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí nínú gbogbo ẹgbẹ́ àwọn arákùnrin yín nínú ayé.” (Pétérù Kíní 5:8, 9) Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ẹgbẹ́ àwọn Kristẹni lè retí ìyà.
5. Báwo ni Jésù ṣe mú un ṣe kedere pé àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ yóò nírìírí ohun bíbani nínú jẹ́ nínú ìgbésí ayé?
5 Bí a tilẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà jinlẹ̀, tí a sì jẹ́ adúróṣinṣin ti àwọn ìlànà rẹ̀, àwọn ohun bíbani nínú jẹ́ yóò ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ìgbésí ayé. Jésù mú èyí ṣe kedere nínú àkàwé rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú Mátíù 7:24-27, níbi tí ó ti ṣe ìfiwéra láàárín àwọn tí ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn tí kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ń ṣègbọràn wé ọkùnrin ọlọ́gbọ́n inú tí ó kọ́ ilé sórí àpáta ràbàtà tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in. Ò fi àwọn tí kì í ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wé òmùgọ̀ ọkùnrin tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Lẹ́yìn tí ẹ̀fúùfù líle kan fẹ́, ilé tí a kọ́ sórí àpáta ràbàtà nìkan ni kò wó. Ṣàkíyèsí pé ní ti ilé ọkùnrin ọlọ́gbọ́n inú náà, ‘òjò tú dà sílẹ̀ ìkún omi sì dé ẹ̀fúùfù sì fẹ́ wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀.’ Jésù kò ṣèlérí pé ọkùnrin ọlọ́gbọ́n inú náà yóò máa fìgbà gbogbo gbádùn àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọgbọ́n inú ọkùnrin náà yóò mú kí ó gbára dì láti la ẹ̀fúùfù náà já. Èrò kan náà ni àkàwé afúnrúngbìn gbìn síni lọ́kàn. Nínú rẹ̀, Jésù ṣàlàyé pé àwọn onígbọràn olùjọsìn pàápàá tí wọ́n ní “ọkàn àyà àtàtà àti rere” yóò “so èso pẹ̀lú ìfaradà.”—Lúùkù 8:4-15.
6. Nínú àkàwé Pọ́ọ̀lù nípa ohun èlò tí kò lè gbiná, ta ni a fi iná dán wò?
6 Nígbà tí ó ń kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ láti ṣàkàwé ìjẹ́pàtàkì níní àwọn ànímọ́ tí ó lè wà pẹ́ títí tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àdánwò. Irú àwọn ohun èlò tí kò lè gbiná bíi wúrà, fàdákà, àti òkúta iyebíye bá àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run mu. (Fi wé Òwe 3:13-15; Pétérù Kíní 1:6, 7.) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a fi àwọn ìwà ti ara wé ohun èlò tí ó lè gbiná. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Iṣẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò fara hàn kedere, nítorí ọjọ́ náà yóò fi í hàn, nítorí a óò ṣí i payá nípasẹ̀ iná; iná náà fúnra rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀rí ìdánilójú irú ohun tí iṣẹ́ ẹni kọ̀ọ̀kan jẹ́ hàn. Bí iṣẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó ti kọ́ sórí rẹ̀ bá wà síbẹ̀, òun yóò gba èrè ẹ̀san.” (Kọ́ríńtì Kíní 3:10-14) Níhìn-ín pẹ̀lú, Bíbélì ṣàlàyé pé gbogbo wa pátá yóò dojú kọ irú ìdánwò oníná tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.
7. Gẹ́gẹ́ bí Róòmù 15:4 ti sọ, báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò?
7 Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àkọsílẹ̀ ń bẹ nínú Bíbélì nípa àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ní láti fara da àjálù, nígbà míràn fún àkókò gígùn. Síbẹ̀, Jèhófà kò ṣá wọn tì. Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lọ́kàn nígbà tí ó wí pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́ kí àwa lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan, tí wọ́n gbádùn ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, síbẹ̀ tí àjálù dé bá wọn.
Ohun Tí A Rí Kọ́ Láti Inú Àkọsílẹ̀ Bíbélì
8. Kí ni Jèhófà fàyè gbà ní ti ọ̀ràn Jósẹ́fù, báwo sì ni ó ṣe pẹ́ tó?
8 Jèhófà ṣojú rere sí Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Jékọ́bù, láti ìgbà ọmọdé. Síbẹ̀, láìjẹ̀bi ọ̀ràn kankan, ọ̀wọ́ àjálù dé bá a. Àwọn arákùnrin rẹ̀ jí i gbé, wọ́n sì hùwà rírorò sí i. Wọ́n tà á lẹ́rú sí ilẹ̀ àjèjì níbi tí a ti parọ́ mọ́ ọn, tí a sì fi í sí “ihò túbú.” (Jẹ́nẹ́sísì 40:15) Níbẹ̀, “wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́, ọkàn rẹ̀ wá sínú àwọn irin.” (Orin Dáfídì 105:17, 18, NW) Nígbà tí ó wà ní oko ẹrú àti nínú túbú, kò sí àní-àní pé Jósẹ́fù bẹ Jèhófà léraléra fún ìdásílẹ̀. Síbẹ̀, fún nǹkan bí ọdún 13, bí Jèhófà tilẹ̀ fún un lókun ní onírúurú ọ̀nà, ó ń jí lóròòwúrọ̀ bí ẹrú tàbí ẹlẹ́wọ̀n.—Jẹ́nẹ́sísì 37:2; 41:46.
9. Kí ni Dáfídì ní láti fara dà fún ọ̀pọ̀ ọdún?
9 Ọ̀ràn Dáfídì tún fara jọ ọ́. Nígbà tí Jèhófà ń yan ọkùnrin tí ó tóótun láti ṣàkóso Ísírẹ́lì, ó wí pé: “Mo ti rí Dáfídì ọmọkùnrin Jésè, ọkùnrin tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún ọkàn àyà mi.” (Ìṣe 13:22) Láìka ojú rere tí ó ní lọ́dọ̀ Jèhófà sí, ìyà jẹ Dáfídì gidigidi. Nínú ewu tí ó lè yọrí sí ikú, ó fara pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún sínú aginjù, sínú hòrò, sínú ẹ̀là àpáta, àti sí ilẹ̀ àjèjì. A ṣọdẹ rẹ̀ bí ẹranko ẹhànnà, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a, ìbẹ̀rùbojo sì mú un. Síbẹ̀síbẹ̀, ó lo ìfaradà nínú okun Jèhófà. Ẹnu Dáfídì gbà á láti sọ̀rọ̀ láti inú ìrírí ara rẹ̀ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣùgbọ́n Olúwa gbà á nínú wọn gbogbo.”—Orin Dáfídì 34:19.
10. Àjálù ńlá wo ni ó dé bá Nábótì àti ìdílé rẹ̀?
10 Ní ọjọ́ wòlíì Èlíjà, 7,000 ènìyàn péré ní ń bẹ ní Ísírẹ́lì tí kò tí ì forí balẹ̀ fún Báálì ọlọ́run èké. (Àwọn Ọba Kìíní 19:18; Róòmù 11:4) A hùwà àìṣèdájọ́ òdodo lọ́nà búburú jáì sí Nábótì, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọ̀kan lára wọn. A dójú tì í, ní fífẹ̀sùn sísọ̀rọ̀ òdì kàn án. Ní rírí i pé ó jẹ̀bi, a dá a lẹ́bi, a sì fi òfin ọba dájọ́ ikú fún un pé kí a sọ ọ́ ní òkúta pa, ajá sì lá ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kódà a pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pàápàá! Àmọ́, kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ẹ̀sùn tí a fi kàn án rárá. Òpùrọ́ ni àwọn tí wọ́n jẹ́rìí mọ́ ọn lẹ́sẹ̀. Ayaba Jésébélì ni ó pilẹ̀ gbogbo rìkíṣí náà kí ọba baà lè gba ọgbà àjàrà Nábótì.—Àwọn Ọba Kìíní 21:1-19; Àwọn Ọba Kejì 9:26.
11. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ inú ìtàn Bíbélì?
11 Jósẹ́fù, Dáfídì, àti Nábótì wulẹ̀ jẹ́ mẹ́ta péré nínú ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin àti obìnrin olùṣòtítọ́ tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì, tí àjálù dé bá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àgbéyẹ̀wò ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jálẹ̀ ọ̀pọ̀ sànmánì. Nínú rẹ̀, ó sọ nípa àwọn tí wọ́n “rí àdánwò wọn gbà nípa ìfiṣẹlẹ́yà àti ìnàlọ́rẹ́, ní tòótọ́, ju èyíinì lọ, nípa àwọn ìdè àti ẹ̀wọ̀n. A sọ wọ́n ní òkúta, a dán wọn wò, a fi ayùn rẹ́ wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kú nípa fífi idà pa wọ́n, wọ́n lọ káàkiri nínú awọ àgùntàn, nínú awọ ewúrẹ́, nígbà tí wọ́n wà ninu àìní, nínú ìpọ́njú, lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́; ayé kò sì yẹ wọ́n. Wọ́n rìn káàkiri nínú àwọn aṣálẹ̀ àti àwọn òkè ńlá àti àwọn hòrò àti àwọn ihò ibùgbé ilẹ̀ ayé.” (Hébérù 11:36-38) Ṣùgbọ́n Jèhófà kò ṣá wọn tì.
Jèhófà Ń Bìkítà fún Àwọn Tí Ìyà Ń Jẹ
12. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìpọ́njú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ní lónìí?
12 Àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ètò àjọ kan, a lè gbára lé ààbò àtọ̀runwá, àti líla àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àti ìpọ́njú ńlá já. (Aísáyà 54:17; Ìṣípayá 7:9-17) Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, a mọ̀ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. (Oníwàásù 9:11, NW) Lónìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni olùṣòtítọ́ ń bẹ tí àjálù ń dé bá. Àwọn kan ń fara da ipò òṣì paraku. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ‘ọmọ òrukàn àti opó’ tí wọ́n ní ìpọ́njú. (Jákọ́bù 1:27) Ìyà ń jẹ àwọn mìíràn nítorí àbájáde ìjábá ti ìṣẹ̀dá, ogun, ìwà ọ̀daràn, ṣíṣi agbára lò, àìsàn, àti ikú.
13. Àwọn ìrírí líle koko wo ni a ròyìn rẹ̀ láìpẹ́ yìí?
13 Fún àpẹẹrẹ, nínú ìròyìn ọdún 1996 tí wọ́n kọ ránṣẹ́ sí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower sọ pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ipò tí ń múni káàánú, nítorí pé, wọ́n rọ̀ mọ́ ìlànà Bíbélì. A tú ìjọ mẹ́ta ká ní orílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù America nígbà tí àwùjọ agbábẹ́lẹ̀ jagun fipá mú ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Ẹlẹ́rìí láti fi àgbègbè náà sílẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, a pa Àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí ogun abẹ́lé kékeré ká mọ́. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn America, ipò ìṣúnná owó líle koko tí àwọn ará wa ń dojú kọ, túbọ̀ burú sí i nítorí ìjì líle tí ó ṣe jàǹbá ńláǹlà. Ní àwọn ibòmíràn tí òṣì àti àìtó oúnjẹ lè máà jẹ́ ìṣòro tó bẹ́ẹ̀, àwọn agbára ìdarí búburú lè bá ayọ̀ àwọn kan jẹ́. Pákáǹleke ìgbésí ayé òde òní ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ẹlòmíràn. Nítorí ẹ̀mí ìdágunlá tí àwọn ènìyàn ní, àwọn mìíràn lè rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí wọ́n bá ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà.
14. (a) Kí ni a rí kọ́ láti inú àpẹẹrẹ Jóòbù? (b) Dípò tí a óò fi ronú lọ́nà òdì, kí ni ó yẹ kí a ṣe nígbà tí làásìgbò bá dé bá wa?
14 Kò yẹ kí a ṣi àwọn ipò wọ̀nyí lóye gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé inú Ọlọ́run kò dùn sí wa. Rántí ọ̀ràn Jóòbù àti ọ̀pọ̀ làásìgbò tí ó dé bá a. Ó jẹ́ “ọkùnrin tí í ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin.” (Jóòbù 1:8) Ẹ wo bí inú Jóòbù ti gbọ́dọ̀ bà jẹ́ tó nígbà tí Élífásì fẹ̀sùn ìwà àìtọ́ kàn án! (Jóòbù, orí 4, 5, 22) A kò fẹ́ tètè dórí ìparí èrò pé àjálù ń dé bá wa nítorí pé a ti já Jèhófà kulẹ̀ ní ọ̀nà kan tàbí nítorí pé Jèhófà ti fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn. Èrò òdì nígbà ìpọ́njú lè bomi paná ìgbàgbọ́ wa. (Tẹsalóníkà Kíní 3:1-3, 5) Nígbà tí a bá ní ìrora ọkàn, ohun tí ó dára jù lọ ni láti ṣàṣàrò lórí òkodoro òtítọ́ náà pé Jèhófà àti Jésù wà gbágbágbá létí ọ̀dọ̀ àwọn olódodo láìka ohunkóhun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí.
15. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà bìkítà púpọ̀ nípa àjálù tí ó dé bá àwọn ènìyàn rẹ̀?
15 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù túbọ̀ fọkàn wa balẹ̀ nígbà tí ó sọ pé: “Ta ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ṣé ìpọ́njú ni tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ebi tàbí ìhòòhò tàbí ewu tàbí idà? . . . Mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba àkóso tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:35, 38, 39) Jèhófà ń ṣàníyàn gidigidi nípa wa, ó sì mọ̀ pé ìyà ń jẹ wá. Nígbà tí ó ṣì ń sá kiri, Dáfídì kọ̀wé pé: “Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn. Olúwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn tí í ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn.” (Orin Dáfídì 34:15, 18; Mátíù 18:6, 14) Bàbá wa ọ̀run ń bìkítà fún wa, àánú àwọn tí ìyà ń jẹ sì ń ṣe é. (Pétérù Kíní 5:6, 7) Ó ń pèsè ohun tí a nílò láti lè lo ìfaradà, láìka ìyà èyíkéyìí tí ó lè jẹ wá sí.
Ẹ̀bùn Jèhófà Ń Mú Wa Dúró
16. Ìpèsè wo láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfaradà, lọ́nà wo sì ni?
16 Bí a kò tilẹ̀ lè retí ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ògbólógbòó yìí, a “kò fi” wa “sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:8, 9) Jésù ṣèlérí láti pèsè olùrànlọ́wọ́ kan fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó wí pé: “Èmi yóò sì fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè lọ́wọ́ Bàbá òun yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́ náà.” (Jòhánù 14:16, 17) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé wọn yóò gba “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” (Ìṣe 2:38) Ẹ̀mí mímọ́ náà ha ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà ń fún wa ní èso àgbàyanu: “Ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ànímọ́ ṣíṣeyebíye tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfaradà.
17. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn òtítọ́ Bíbélì tí ń fún ìgbàgbọ́ àti ìpinnu wa lókun láti fi sùúrù dúró de Jèhófà?
17 Ẹ̀mí mímọ́ tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìpọ́njú lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́ “fún ìgbà díẹ̀ tí ó sì fúyẹ́,” nígbà tí a bá fi wé èrè ìyè àìnípẹ̀kun. (Kọ́ríńtì Kejì 4:16-18) Ó dá wa lójú pé Ọlọ́run kò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ tí a fi hàn fún un. (Hébérù 6:9-12) Ní kíka àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí a mí sí, a tù wá nínú nípasẹ̀ àwọn àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ ìgbàanì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́, tí wọ́n fara da ọ̀pọ̀ àjálù ṣùgbọ́n tí a pè wọ́n ní aláyọ̀. Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará, ẹ mú àwọn wòlíì, àwọn tí wọ́n sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwòṣe jíjìyà ibi àti mímú sùúrù. Wò ó! Àwọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀.” (Jákọ́bù 5:10, 11) Bíbélì ṣèlérí “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò. Jèhófà tún fi ìrètí àjíǹde bù kún wa. (Kọ́ríńtì Kejì 1:8-10; 4:7) Nípa kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ìlérí wọ̀nyí, a óò fún ìgbàgbọ́ àti ìpinnu wa lókun láti fi sùúrù dúró de Ọlọ́run.—Orin Dáfídì 42:5.
18. (a) Nínú Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4, kí ni a fún wa níṣìírí láti ṣe? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni alábòójútó ṣe jẹ́ orísun ìtùnú àti ìtura?
18 Ní àfikún sí i, Jèhófà ti fún wa ní párádísè tẹ̀mí níbi tí a ti lè gbádùn ojúlówó ìfẹ́ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa. Gbogbo wa ní ipa tí a ń kó nínú títu ara wa lẹ́nì kíní kejì nínú. (Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4) Ní pàtàkì, àwọn Kristẹni alábòójútó lè jẹ́ orísun pàtàkì ìtùnú àti ìtura. (Aísáyà 32:2) Gẹ́gẹ́ bí “àwọn ẹ̀bùn [nínú] ènìyàn,” a fàṣẹ yanṣẹ́ fún wọn láti gbé àwọn tí ìyà ń jẹ ró, láti “sọ̀rọ̀ ìrẹ̀lẹ́kún fún àwọn ọkàn tí ó sorí kọ́,” àti láti “máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn aláìlera.” (Éfésù 4:8, 11, 12; Tẹsalóníkà Kíní 5:14) A rọ àwọn alàgbà láti lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” pèsè dáradára. (Mátíù 24:45-47) Ìwọ̀nyí kún fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn tí a gbé ka Bíbélì, tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú—àní kí a tilẹ̀ dènà—àwọn ìṣòro kan tí ń jẹ́ kí a ṣàníyàn. Ǹjẹ́ kí a fara wé Jèhófà nípa títu ara wa lẹ́nì kíní kejì nínú, àti nípa fífún ara wa lẹ́nì kíní kejì níṣìírí ní àkókò ìṣòro!
19. (a) Kí ní ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn làásìgbò kan? (b) Paríparí rẹ̀, ta ni a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé, kí sì ni yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti kojú àdánwò?
19 Bí a ṣe túbọ̀ ń wọnú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, tí ipò nǹkan nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí sì ń burú sí i, àwọn Kristẹni ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti yẹra fún àjálù. (Òwe 22:3) Orí pípé, èrò inú tí ó yè kooro, àti mímọ àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu ọlọ́gbọ́n. (Òwe 3:21, 22) A ń tẹ́tí sí Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a sì ń ṣègbọràn sí i láti yẹra fún àwọn àṣìṣe tí kò yẹ kí a ṣe. (Orin Dáfídì 38:4) Síbẹ̀síbẹ̀, a mọ̀ pé kò sí bí ìsapá wa ti ṣe lè pọ̀ tó tí ó lè mú ìyà kúrò pátápátá nínú ìgbésí ayé wa. Nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀ olódodo ń dojú kọ làásìgbò ńláǹlà. Ṣùgbọ́n, a lè kojú àwọn àdánwò wa pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pátápátá pé “Olúwa kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì.” (Orin Dáfídì 94:14) A sì mọ̀ pé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí àti ìpọ́njú rẹ̀ yóò kọjá lọ láìpẹ́. Nítorí náà, ǹjẹ́ kí a pinnu láti má ṣe “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gálátíà 6:9.
Kí Ni A Rí Kọ́?
◻ Àdánwò wo ni gbogbo ẹgbẹ́ Kristẹni ń nírìírí rẹ̀?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ni ó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé àjálù kì í ṣe ẹ̀rí pé inú Jèhófà kò dùn sí wa?
◻ Kí ni ìmọ̀lára Jèhófà nípa làásìgbò tí ó ń dé bá àwọn ènìyàn rẹ̀?
◻ Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ẹ̀bùn tí ó ti ọwọ́ Jèhófà wá, tí ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Dáfídì, Nábótì, àti Jósẹ́fù jẹ́ àwọn mẹ́ta tí àjálù dé bá