ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 2/15 ojú ìwé 10-15
  • Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nípa Dídáàbò Bo Ọkàn Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nípa Dídáàbò Bo Ọkàn Rẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ
  • Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè
  • Yẹra fún Ewu Títage
  • Kí Ló Burú Nínú Títage?
    Jí!—1998
  • Ṣé Ó Burú Kéèyàn Máa Tage?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ṣé Bí Ìfẹ́ Bá Ti Wà, Kò Sóhun Tó Burú Nínú Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?
    Jí!—2007
  • Pa Ọkàn-àyà Rẹ Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 2/15 ojú ìwé 10-15

Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nípa Dídáàbò Bo Ọkàn Rẹ

“Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.”—ÒWE 4:23.

1-3. (a) Báwo làwọn èèyàn ṣe sábà máa ń fi hàn pé àwọn ò fi ọwọ́ tó dáa mú ìwà mímọ́ wọn? Ṣàpèjúwe. (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣàyẹ̀wò bí ìwà mímọ́ ti ṣeyebíye tó?

ÀWÒRÁN náà dà bí èyí tí kò bá ìgbà mu mọ́. Ó ṣeé ṣe kó máà rí bí àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ mìíràn tó wà nínú ilé náà. Ohun yòówù tí ì báà jẹ́, ó dájú pé ẹni tó ni ín rò pé òun ò nílò rẹ̀ mọ́. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwòrán náà di èyí tí wọ́n gbé sí ibi tí wọ́n ti ń ta àwọn nǹkan àlòkù, wọ́n sì tà á ní dọ́là mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (ìyẹn owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà). Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n wá rí i pé àwòrán náà tó ohun téèyàn lè tà ní iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan dọ́là! Àní sẹ́, àwòrán náà wá di ohun àpéwò tí irú rẹ̀ ṣọ̀wọ́n. Fojú inú wo bí ọ̀ràn náà ṣe máa rí lára ẹni tó ni ín tẹ́lẹ̀, tó fojú kéré ohun iyebíye yìí!

2 Ohun kan náà ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí ìwà mímọ́, ìyẹn ìwà rere tàbí ìwà ọmọlúàbí tí ẹnì kan ní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lónìí ló fojú kéré ìwà mímọ́ tí wọ́n ní. Àwọn kan kà á sí àṣà àtijọ́ tí kò bá ọ̀nà ìgbésí ayé tòde òní mu. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ba ìwà ọmọlúàbí wọn jẹ́ nítorí ohun tí ò tó nǹkan. Àwọn kan ti tìtorí adùn ìbálòpọ̀ àárín ìṣẹ́jú díẹ̀ ba ìwà rere wọn jẹ́. Àwọn mìíràn ti fi ọmọlúàbí wọn tàfàlà lérò pé ìyẹn á jẹ́ káwọn ojúgbà wọn tàbí ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì kà wọ́n sí ẹni tó máyé jẹ.—Òwe 13:20.

3 Ìgbà tí ẹ̀pa ò bá bóró mọ́ ni ọ̀pọ̀ lára wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ bí jíjẹ́ táwọn jẹ́ oníwà mímọ́ tẹ́lẹ̀ ti ṣeyebíye tó. Ìbànújẹ́ gidi ni ohun tí wọ́n pàdánù yìí sì máa ń jẹ́ fún wọn. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ọ́, àbájáde ìṣekúṣe lè dà bíi májèlé, tó “korò bí iwọ.” (Òwe 5:3, 4) Pẹ̀lú bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbòde kan lónìí, báwo lo ṣe lè fọwọ́ tó dáa mú ìwà mímọ́ rẹ, kó o sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀? A ó jíròrò ìgbésẹ̀ mẹ́ta tá a lè gbé.

Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ

4. Kí ni ọkàn ìṣàpẹẹrẹ yìí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká dáàbò bò ó?

4 Ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ oníwà rere nìṣó ni pé ká máa dáàbò bo ọkàn wa. Bíbélì sọ pé: “Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ, nítorí láti inú rẹ̀ ni àwọn orísun ìyè ti wá.” (Òwe 4:23) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ọkàn-àyà rẹ,” ń tọ́ka sí níhìn-ín? Kì í ṣe ọkàn tó wà nínú ara rẹ là ń sọ níbí yìí o. Ọkàn ìṣàpẹẹrẹ là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó ń tọ́ka sí irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, títí kan èrò inú rẹ, bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára rẹ, àti ohun tó ń sún ọ ṣe nǹkan. Bíbélì sọ pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 6:5) Bíbélì sọ pé àṣẹ yìí ni ó tóbi jù lọ nínú gbogbo àṣẹ. (Máàkù 12:29, 30) Ó hàn gbangba pé ọkàn wa tá a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ṣeyebíye gan-an ni. Ó tó kéèyàn dáàbò bò ó.

5. Báwo ni ọkàn ṣe lè ṣeyebíye kó sì tún jẹ́ ewu?

5 Àmọ́ ṣa o, Bíbélì tún sọ pé “ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” (Jeremáyà 17:9) Báwo ni ọkàn ṣe lè ṣe àdàkàdekè kí ó sì jẹ́ ewu fún wa? Tóò, bí àpẹẹrẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ jẹ́ ohun èlò tó ṣeyebíye gan-an, kódà ó lè gba ẹ̀mí èèyàn là ní àkókò pàjáwìrì. Àmọ́ tí awakọ̀ náà kò bá fi àgbá ìtọ́kọ̀ darí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan náà yìí lè di ohun tó ń ṣekú pani. Bákan náà, tí o kò bá dáàbò bo ọkàn rẹ, wàá rí i pé ohun tó wù ọ́ àti ohun tí ọkàn rẹ fẹ́ ni yóò máa darí rẹ, ìyẹn sì lè kó ọ sí yọ́ọ́yọ́ọ́ níkẹyìn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.” (Òwe 28:26) Ó dájú pé o lè fi ọgbọ́n rìn kó o sì bọ́ lọ́wọ́ àgbákò tó o bá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí rẹ, gẹ́gẹ́ bó o ṣe máa wo ìwé àwòrán ọ̀nà kó o tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò.—Sáàmù 119:105.

6, 7. (a) Kí ni ìjẹ́mímọ́, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé ẹ̀dá aláìpé lè gbé ìjẹ́mímọ́ Jèhófà yọ?

6 Ọkàn wa kò ní fúnra rẹ̀ fẹ́ láti hu ìwà mímọ́. Àwa la máa darí rẹ̀ sí ọ̀nà yẹn. Ọ̀nà kan láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni ká ronú nípa bí ìwà mímọ́ ti ṣeyebíye tó. Ànímọ́ yìí wé mọ́ ìjẹ́mímọ́ gan-an ni, èyí tó túmọ̀ sí mímọ́ tónítóní, jíjẹ́ aláìlábààwọ́n, àti yíyàgò pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ànímọ́ tó níye lórí gan-an. Ó jẹ́ apá kan àwọn ohun tó fi bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe jẹ́ gan-an hàn. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹsẹ Bíbélì ló so ànímọ́ yìí mọ́ Jèhófà. Kódà, Bíbélì sọ pé “Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 28:36) Kí wá ni irú ànímọ́ gíga lọ́lá bẹ́ẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú àwa èèyàn tá a jẹ́ aláìpé?

7 Jèhófà sọ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.” (1 Pétérù 1:16) Bẹ́ẹ̀ ni o, a lè fara wé ìjẹ́mímọ́ Jèhófà; à lè wà ní mímọ́ tónítóní níwájú rẹ̀, ká sì jẹ́ oníwà mímọ́. Nítorí náà, nígbà tá a bá yẹra fún ìwà àìmọ́ àtàwọn ohun tó lè sọ wá di eléèérí, a jẹ́ pé à ń sapá láti jẹ àgbàyanu àǹfààní, ìyẹn àǹfààní láti ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ rere tí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ ní! (Éfésù 5:1 ) Ká má ṣe máa ronú pé ìyẹn kọjá agbára wa, nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọ̀gá tó gbọ́n tó ń gba tẹni rò, tí kì í sì í retí pé ka ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Sáàmù 103:13, 14; Jákọ́bù 3:17) Ká sòótọ́, ó gba ìsapá láti jẹ́ oníwà mímọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ . . . tọ́ sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 11:3) Ǹjẹ́ kò yẹ ká ro ti Jésù àti Baba rẹ̀, ká sa gbogbo ipá wa láti jẹ́ oníwà mímọ́? Ó ṣe tán, ìfẹ́ tí wọ́n ti fi hàn sí wa ga ju èyí tá a lè san padà lọ. (Jòhánù 3:16; 15:13) Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti fi hàn pé a moore nípa gbígbé ìgbésí ayé lọ́nà tó mọ́ tónítóní ká sì máa hu ìwà rere. Tá a bá ń rántí pé ìwà mímọ́ wa jẹ́ ọ̀nà tá a lè gbà fi ìmoore hàn, a ó mọrírì rẹ̀, a ó sì dáàbò bo ọkàn wa.

8. (a) Báwo la ṣe lè bọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ? (b) Kí ni ìjíròrò wa lè fi hàn nípa wa?

8 A tún ń dáàbò bo ara wa nípasẹ̀ ọ̀nà tá a gbà ń bọ́ ara wa. A gbọ́dọ̀ máa fi oúnjẹ tẹ̀mí tó dára bọ́ èrò inú àti ọkàn wa déédéé, ká sì jẹ́ kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run gbà wá lọ́kàn. (Kólósè 3:2) Kódà, ó yẹ kí ìjíròrò wa máa fi hàn pé ohun tó wà lọ́kàn wa nìyẹn. Táwọn èèyàn bá mọ̀ wá sí ẹni tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan ti ara àti àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe, a ń fi bí ọkàn wa ṣe rí hàn nìyẹn. (Lúùkù 6:45) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ wá sí ẹni tó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tẹ̀mí tó ń gbéni ró. (Éfésù 5:3) Tá a bá fẹ́ dáàbò bo ọkàn wa, àwọn ewu ńlá kan wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún. Ẹ jẹ́ ká jíròrò méjì lára wọn.

Ẹ Máa Sá fún Àgbèrè

9-11. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn tí kò gba ìmọ̀ràn inú 1 Kọ́ríńtì 6:18 ló ṣeé ṣe kó lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla tó burú jáì? Ṣàpèjúwe. (b) Tá a bá fẹ́ sá fún àgbèrè, kí là gbọ́dọ̀ yẹra fún? (d) Àpẹẹrẹ rere wo ni Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ nì fi lélẹ̀ fún wa?

9 Jèhófà mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìmọ̀ràn kan tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti dáàbò bo ọkàn wọn kí wọ́n sì máa hu ìwà mímọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ṣàkíyèsí pé ohun tó sọ kọjá wíwulẹ̀ sọ pé, “Ẹ yẹra fún àgbèrè.” Àwọn Kristẹni ní láti ṣe ju ìyẹn lọ. Wọ́n gbọ́dọ̀ sá fún irú ìwà ìṣekúṣe bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe máa sá fún ewu kan tó lè gba ẹ̀mí wọn. Tá ò bá gba ìmọ̀ràn yẹn, a jẹ́ pé ńṣe là ń rìn ní bèbè ìṣekúṣe, a sì lè pàdánù ojú rere Ọlọ́run.

10 Láti ṣàpèjúwe èyí: Ìyá kan ti wẹ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ó sì wọṣọ tó dáa si lọ́rùn nítorí pé wọ́n ń lọ síbi àṣeyẹ pàtàkì kan. Ọmọ náà béèrè bóyá òun lè máa ṣeré níta kó tó di àkókò tí wọ́n máa gbéra, ìyá náà gbà bẹ́ẹ̀, tí ọmọ náà bá lè pa àṣẹ kan mọ́. Ó wá sọ fún ọmọ rẹ̀ pé: “O ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ itòsí omi ìdọ̀tí tó wà níta yẹn o. Tó o bá kó ẹrọ̀fọ̀ yíra, wà á jìyà sí i o.” Àmọ́, láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ sí àkókò yẹn, ó rí ọmọkùnrin yìí tó ń fi ọmọ ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ gba etí bèbè omi ìdọ̀tí náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kó tíì kó ẹrọ̀fọ̀ yíra. Síbẹ̀ kò gba ìkìlọ̀ ìyá rẹ̀ pé kò gbọ́dọ̀ lọ sítòsí omi ìdọ̀tí náà, ó sì dájú pé ó máa jìyà. (Òwe 22:15) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbà tó yẹ kó máa ṣọ́ra gidigidi ló máa ń ṣe irú àṣìṣe kan náà yìí. Lọ́nà wo?

11 Ní àwọn àkókò yìí, tí ọ̀pọ̀ ti fi ara wọn “fún ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń dójú tini,” àwọn ilé iṣẹ́ ti wà tó jẹ́ pé ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ni wọ́n ń gbé lárugẹ. (Róòmù 1:26, 27) Àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè ti wà káàkiri báyìí nínú àwọn ìwé ìròyìn, àwọn ìwé, lórí fídíò àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó dájú pé àwọn tó yàn láti jẹ́ kí irú àwọn àwòrán bẹ́ẹ̀ gbà wọ́n lọ́kàn kò lè sọ pé àwọn ń sá fún àgbèrè. Ńṣe ni wọ́n ń gbé e ṣeré, tí wọ́n dúró sétí bèbè rẹ̀, tí wọ́n fojú di ìkìlọ̀ Bíbélì. Dípò kí wọ́n dáàbò bo ọkàn wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àwòrán búburú bà á jẹ́, èyí sì lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kó tó kúrò nínú ọpọlọ wọn. (Òwe 6:27) Ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ nì, ẹni tó bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú pé òun kò ní fi wo ohun tó lè sún òun hu ìwà búburú. (Jóòbù 31:1) Àpẹẹrẹ yẹn mà dára láti tẹ̀ lé lónìí o!

12. Báwo làwọn tọkọtaya Kristẹni ṣe lè “sá fún àgbèrè” lákòókò tí wọ́n ń fẹ́ ara wọn sọ́nà?

12 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ọkùnrin àti obìnrin tó ń fẹ́ ara wọn sọ́nà “sá fún àgbèrè.” Àkókò aláyọ̀, tó kún fún ìrètí àti ìháragàgà ló yẹ kí àkókò yẹn jẹ́, àmọ́ àwọn kan ti bà á jẹ́ nípa híhu ìwà pálapàla. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n fi ìpìlẹ̀ tó dára jù lọ fún ìgbéyàwó rere du ara wọn, ìyẹn àjọṣe tí ì bá dá lórí ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan, ìkóra-ẹni-níjàánu àti ìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn tọkọtaya Kristẹni kan bá ara wọn ṣèṣekúṣe nígbà tí wọ́n ń fẹ́ ara wọn sọ́nà. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, aya náà sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun ń da òun láàmú, kódà ó ba ayọ̀ ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ jẹ́. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo ti tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún méje ti kọjá lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹ̀rí ọkàn mi ṣì ń dá mi lẹ́bi.” Ó ṣe pàtàkì pé káwọn tó dá irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ gba ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà. (Jákọ́bù 5:14, 15) Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya Kristẹni ló hùwà ọlọ́gbọ́n tí wọn ò sì kó ara wọn sínú ewu yìí lákòókò tí wọ́n ń fẹ́ ara wọn sọ́nà. (Òwe 22:3) Wọn ò ki àṣejù bọ bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn. Wọ́n máa ń ṣètò pé kéèyàn wà pẹ̀lú wọn, wọ́n sì máa ń ṣọ́ra láti yẹra fún wíwà pà pọ̀ láwọn nìkan níbi kọ́lọ́fín.

13. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn Kristẹni fi ẹni tí kò sin Jèhófà ṣe àfẹ́sọ́nà?

13 Àwọn Kristẹni tó ń fi àwọn tí kò sin Jèhófà ṣe àfẹ́sọ́nà lè bára wọn nínú ìṣòro tó lékenkà. Bí àpẹẹrẹ, báwo lo ṣe lè so ara rẹ pọ̀ mọ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run? Ó ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni so ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ìlànà ìwà mímọ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?”—2 Kọ́ríńtì 6:14.

14, 15. (a) Àṣìṣe wo làwọn kan máa ń ṣe nípa ohun tí “àgbèrè” túmọ̀ sí? (b) Irú àwọn ìwà wo ló wé mọ́ “àgbèrè,” báwo sì ni àwọn Kristẹni ṣe lè “sá fún àgbèrè”?

14 Ìmọ̀ tún ṣe pàtàkì. A ò lè sá fún àgbèrè tá ò bá mọ ohun tó jẹ́ gan-an. Àwọn kan nínú ayé lónìí ní èrò òdì nípa ohun tí “àgbèrè” túmọ̀ sí. Wọ́n rò pé àwọn lè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn láìṣe ìgbéyàwó, táwọn bá ṣáá ti yẹra fún ìbálòpọ̀ gan-an fúnra ẹ̀. Kódà àwọn àjọ ìlera kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti dín oyún ẹ̀sín táwọn ọ̀dọ́ ń ní kù, gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú pé kí wọ́n máa ní ìbálòpọ̀ lọ́nà kan tó yàtọ̀ tí oyún kò fi ní dé. Ó bani nínú jẹ́ pé ìṣìnà pátápátá ni irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Yíyẹra fún oyún níní láìṣe ìgbéyàwó kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú jíjẹ́ oníwà mímọ́, ohun tí “àgbèrè túmọ̀” sí sì gbòòrò jù bẹ́ẹ̀ lọ.

15 Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà por·neiʹa, tá a túmọ̀ sí “àgbèrè,” ní ìtumọ̀ tó pọ̀. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò gbé ara wọn níyàwó àti ṣíṣi àwọn ẹ̀yà ìbímọ lò. Ohun mìíràn tá a tún ń pè ní por·neiʹa ni àṣà kéèyàn máa fi ẹnu kan ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíràn, ká máa ti ihò ìdí báni lò pọ̀, àti ká máa fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíràn, ìyẹn sì jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láwọn ilé aṣẹ́wó. Ńṣe làwọn tó rò pe irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í ṣe “àgbèrè” wulẹ̀ ń tan ara wọn jẹ, wọ́n sì ti kó sínú ọ̀kan lára àwọn pàkúté Sátánì. (2 Tímótì 2:26) Síwájú sí i, ohun tí jíjẹ́ oníwà mímọ́ túmọ̀ si kọjá wíwulẹ̀ sá fún ìwà èyíkéyìí tó para pọ̀ jẹ́ àgbèrè. Ká tó lè “sá fún àgbèrè,” a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo ohun tó jẹ́ mọ́ ìwà àìmọ́ takọtabo àti ìwà àìníjàánu tó lè súnni dórí dídá ẹ̀ṣẹ̀ por·neiʹa tó burú jáì. (Éfésù 4:19) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, oníwà mímọ́ ni wá.

Yẹra fún Ewu Títage

16. Àárín àwọn wo ni títage ti bójú mu, àpẹẹrẹ wo nínú Ìwé Mímọ́ ló sì fi èyí hàn?

16 Tá a bá fẹ́ jẹ́ oníwà mímọ́, ewu mìíràn tá a tún gbọ́dọ̀ yàgò fún ni pé ká ṣọ́ra fún àṣà bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa tage. Àwọn kan lè sọ pé kò sóhun tó burú nínú títage, kí wọ́n sọ pé eré tí kì í pani lára tó ń wáyé láàárín ọkùnrin àti obìnrin ni. Lóòótọ́, ó nígbà tí títage yẹni, ó sì láwọn tó yẹ kó máa bára wọn tage. Àwọn èèyàn rí Ísákì àti Rèbékà tí wọ́n ‘ń gbádùn ara wọn,’ àwọn tó rí wọn sì rí i kedere pé wọn kì í wulẹ̀ ṣe tẹ̀gbọ́n tàbúrò lásán. (Jẹ́nẹ́sísì 26:7-9) Wọ́n rí i pé tọkọtaya ni wọ́n. Bí wọ́n ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn yẹn bójú mu. Bíbá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni tage yàtọ̀ pátápátá síyẹn.

17. Kí ni bíbá ẹlòmíràn tage, báwo la sì ṣe lè kápá ìṣòro náà?

17 A lè túmọ̀ bíbá ẹlòmíràn tage lọ́nà yìí pé: ó jẹ́ ríru ìfẹ́ ẹnì kan sókè láìjẹ́ pé a ní in lọ́kàn láti bá ẹni náà ṣègbéyàwó. Èèyàn jẹ́ ẹ̀dá tí kò ṣeé tètè lóye, nítorí náà àìmọye ọ̀nà ni wọ́n lè gbà tage, àwọn kan lára wọn sì jẹ́ èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn síta. (Òwe 30:18, 19) Nítorí náà, kò sí òfin kan pàtó tá a lè gbé ọ̀ràn náà kà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun kan tó ju òfin lọ ló ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ni fífi òótọ́ inú yẹ ara ẹni wò àti fífi gbogbo ọkàn tẹ́ lé àwọn ìlànà Bíbélì.

18. Kí ló máa ń sún àwọn kan láti bá ẹlòmíràn tage, kí sì nìdí tí irú títage bẹ́ẹ̀ fi léwu?

18 Ká sòótọ́, a ó rí i pé ńṣe ni orí ọ̀pọ̀ jù lọ wa máa ń wú nígbà tí ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì bá ń fìfẹ́ hàn sí wa. Bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn. Àmọ́ ṣé àwa náà máa ń bá àwọn ẹlòmíràn tage kí wọ́n lè fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí wa, kí wọ́n lè mọ̀ pé àwa náà ò kẹ̀rẹ̀ tàbí ká lè mú orí àwọn ẹlòmíràn wú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ a ti ronú nípa ìpalára tá a lè máa ṣe fún ẹlòmíràn? Bí àpẹẹrẹ, Òwe 13:12 sọ pé: “Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn.” Bá a bá mọ̀ọ́mọ̀ ń ru ìfẹ́ ẹnì kan sókè, ó ṣeé ṣe ká má mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára onítọ̀hún. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa retí pé ká bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ ara wa sọ́nà, kódà kó tiẹ̀ máa rò pé a ó jọ ṣe ìgbéyàwó nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ìjákulẹ̀ tí ìyẹn máa fà lè burú jáì. (Òwe 18:14) Ìwà òǹrorò gbáà ló jẹ́ láti máa mọ̀ọ́mọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn ẹlòmíràn.

19. Báwo ni bíba ẹlòmíràn dọ́rẹ̀ẹ́ ṣe lè fi ìgbéyàwó àwọn Kristẹni sínú ewu?

19 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká yẹra fún bíbá àwọn to ti ṣègbéyàwó tage. Ká máa fi ìfẹ́ hàn sí ẹni tó ti lọ́kọ tàbí ẹni tó ti láya tàbí kí ẹni tó lọ́kọ tàbí ẹni tó láya máa fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn sí ẹlòmíràn tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀, kì í ṣe ohun tó dáa rárá. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan ti fi àṣìṣe rò pé ó bójú mú láti ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ẹnì kan tó jẹ́ ẹ̀yà kejì yàtọ̀ sí ọkọ tàbí aya wọn. Àwọn kan máa ń sọ ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wọn jù lọ fún irú “ọ̀rẹ́” bẹ́ẹ̀, kódà wọ́n máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí tí ọkọ tàbí aya wọn ò mọ̀ fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tí wọ́n ń fi hàn sí ara wọn ti wá ń lọ sórí fífi inú han ara wọn, ìyẹn sì lè jin ìgbéyàwó lẹ́sẹ̀ tàbí kó dà á rú pátápátá. Ó yẹ kí àwọn tọkọtaya Kristẹni máa rántí ìkìlọ̀ ọlọgbọ́n tí Jésù fúnni nípa panṣágà pé inú ọkàn ló ti ń bẹ̀rẹ̀. (Mátíù 5:28) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká dáàbò bo ọkàn wa, ká sì yẹra fún àwọn ipò tó lè mú irú àbájáde búburú bẹ́ẹ̀ wá.

20. Báwo la ṣe gbọ́dọ̀ máa wo ìwà mímọ́ wa?

20 Ká sòótọ́, kò rọrùn láti jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé oníwà pálapàla òde òní. Àmọ́ ṣá o, rántí pé ó rọrùn gan-an láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ oníwà mímọ́ jù kéèyàn tún fẹ́ padà jẹ́ oníwà mímọ́ lẹ́yìn tó bá ti ba ara rẹ̀ jẹ́. Lóòótọ́, Jèhófà lè “dárí jì lọ́nà títóbi” ó sì lè sọ àwọn tó bá fi gbogbo ọkàn ronú pìwà dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn di mímọ́ tónítóní. (Aísáyà 55:7) Àmọ́, Jèhófà kì í yọ àwọn tó hu ìwà pálapàla kúrò nínú ohun tó jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Àwọn àbájáde náà lè wà bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, kódà ó lè wà bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé onítọ̀hùn. (2 Sámúẹ́lì 12:9-12) Rí i dájú pé o jẹ́ oníwà mímọ́ nípa dídáàbò bo ọkàn rẹ. Máa wo ìdúró rere tó o ní àti ìwà mímọ́ rẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣeyebíye gan-an, kó o sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀!

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni ìwà mímọ́, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an?

• Báwo la ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa?

• Kí ni sísá fún àgbèrè wé mọ́?

• Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yẹra fún bíbá ẹlòmíràn tage?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan lè jẹ́ ewu tí a kò bá darí rẹ̀ dáadáa

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a ò bá gba ìkìlọ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìfẹ́sọ́nà tó jẹ́ mímọ́ máa ń kún fún ayọ̀, ó sì máa ń bọlá fún Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́