ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 2/15 ojú ìwé 15-20
  • Ṣọ́ra Fún Ẹ̀tàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra Fún Ẹ̀tàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ẹ̀tàn Fi Pọ̀ Lónìí?
  • Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn Àwọn Apẹ̀yìndà
  • Ṣọ́ra fún Títan Ara Rẹ Jẹ
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Irọ́ Sátánì
  • Yẹra fún Ẹ̀tàn
  • Ṣé Wàá Gbọ́ Ìkìlọ̀ Tó Ṣe Kedere Tí Jèhófà Ń fún wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Máa Sọ Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 2/15 ojú ìwé 15-20

Ṣọ́ra Fún Ẹ̀tàn

“Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ . . . ẹ̀tàn òfìfo.”—KÓLÓSÈ 2:8.

1-3. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé ẹ̀tàn ti wà nínú gbogbo apá ìgbésí ayé ojoojúmọ́? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹ̀tàn tó kún inú ayé yà wá lẹ́nu?

“MÉLÒÓ nínú yín ni ẹni tó mú ẹjọ́ wá ò parọ́ fún rí?” Ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó jẹ́ amòfin fi ìbéèrè yìí wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn agbẹjọ́rò. Kí wá ni ìdáhùn wọn? Ó sọ pé: “Nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn agbẹjọ́rò tí mo fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, ẹnì kan ṣoṣo péré ni àwọn tó máa ń mú ẹjọ́ wá kò tíì parọ́ fún.” Kí nìdí? “Agbẹjọ́rò yẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bá ilé iṣẹ́ ńlá kan ṣiṣẹ́ ni, kò sì tíì sí ẹni tó mú ẹjọ́ wá bá a.” Ìrírí yìí fìdí òtítọ́ kan tó bani nínú jẹ́ múlẹ̀ pé irọ́ àti ẹ̀tàn jẹ́ ohun tó gbòde kan láyé òde òní.

2 Onírúurú ọ̀nà ni ẹ̀tàn ń gbà wá, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé inú gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé ni ẹ̀tàn wà. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ìròyìn—àwọn olóṣèlú máa ń purọ́ nípa ohun tí wọ́n bá ṣe, àwọn tó ń ṣírò owó àtàwọn agbẹjọ́rò máa ń fẹnu bù mọ́ owó tó ń wọlé fún ilé iṣẹ́ wọn, àwọn tó ń polówó ọjà máa ń tan àwọn oníbàárà jẹ, àwọn tó ń pẹjọ́ máa ń rẹ́ àwọn ilé iṣẹ́ ìbánigbófò jẹ, ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára ẹ̀tàn tó wà. Ẹ̀tàn tún wà nínú ètò ẹ̀sìn pàápàá. Àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà máa ń ṣi àwọn ọmọ ìjọ lọ́nà nípa kíkọ́ wọn ní àwọn ẹ̀kọ́ èké, bí àìleèkú ọkàn, iná ọ̀run àpáàdì, àti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.—2 Tímótì 4:3, 4.

3 Ǹjẹ́ ó yẹ kí gbogbo ẹ̀tàn yìí yà wá lẹ́nu? Rárá o. Bíbélì ti kìlọ̀ fún wa nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù, wọn yóò máa ṣini lọ́nà, a ó sì máa ṣi àwọn pẹ̀lú lọ́nà.” (2 Tímótì 3:1, 13) Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ó yẹ ká wà lójúfò sí àwọn èrò tí ń ṣini lọ́nà, tó lè mú wa kúrò nínú òtítọ́. Àwọn ìbéèrè méjì ló sábà máa ń wáyé: Kí nìdí tí ẹ̀tàn fi gbòde kan lóde òní, àti báwo la ò ṣe ní jẹ́ káwọn èèyàn tàn wá jẹ?

Kí Nìdí Tí Ẹ̀tàn Fi Pọ̀ Lónìí?

4. Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ìdí tí ẹ̀tàn fi pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ayé?

4 Bíbélì ṣàlàyé tó yéni yéké nípa ìdí tí ẹ̀tàn fi gbòde kan nínú ayé yìí. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Sátánì Èṣù ni “ẹni burúkú” náà. Òun ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.” Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu nígbà náà pé ayé yìí ń gbé ẹ̀mí àti ìwà ẹ̀tàn alákòóso rẹ̀ yọ?—Jòhánù 8:44; 14:30; Éfésù 2:1-3.

5. Báwo ni Sátánì ṣe túbọ̀ tẹra mọ́ ipa tó ń sà láti tanni jẹ ní àkókò ìkẹyìn yìí, àwọn wo ló sì ń wá bóun ṣe máa rí mú?

5 Sátánì ti wá ń sa gbogbo ipá rẹ̀ gan-an báyìí lákòókò òpin tá a wà yìí. A ti fi sọ̀kò sórí ilẹ̀ ayé. Ó mọ̀ pé àkókò kúkúrú ni òun ní, ó sì ní “ìbínú ńlá.” Ó ti pinnu láti pa ọ̀pọ̀ èèyàn run bó bá ṣe lè ṣeé ṣe fún un tó, ìdí nìyí tó fi “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9, 12) Kì í ṣe pé ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni Sátánì máa ń tanni jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ìgbà ló ń wá bóun ṣe máa ṣi aráyé lọ́nà.a Gbogbo ọgbọ́n ẹ̀tàn tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ pátá ló ń lò, títí kan dídíbọ́n àti ṣíṣe àdàkàdekè láti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́ kó sì mú wọn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Àwọn tí ọ̀gá ẹlẹ́tàn yìí sì ń dọdẹ rẹ̀ jù lọ ni àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24; 1 Pétérù 5:8) Má ṣe gbàgbé pé Sátánì ti fi ẹnu ara rẹ̀ sọ pé: ‘Mo lè yí ẹnikẹ́ni padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run.’ (Jóòbù 1:9-12) Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára “àwọn ọgbọ́n ìtannijẹ” tí Sátánì ń lò àti bá a ṣe lè ṣọ́ra fún wọn.—Éfésù 6:11, Jewish New Testament.

Ṣọ́ra fún Ẹ̀tàn Àwọn Apẹ̀yìndà

6, 7. (a) Kí làwọn apẹ̀yìndà lè ṣe? (b) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi ohun tó wà lọ́kàn àwọn apẹ̀yìndà hàn kedere?

6 Ó pẹ́ tí Sátánì ti ń lo àwọn apẹ̀yìndà nínú ipa tó ń sà láti sún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run dẹ́ṣẹ̀. (Mátíù 13:36-39) Àwọn apẹ̀yìndà lè sọ pé Jèhófà làwọn ń sìn, pé àwọn sì gba Bíbélì gbọ́, àmọ́ wọ́n kọ ètò àjọ rẹ̀ tá a lè fojú rí sílẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ tún padà sínú àwọn ẹ̀kọ́ tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run, èyí tí “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé fi ń kọ́ni. (Ìṣípayá 17:5; 2 Pétérù 2:19-22) Ní abẹ́ ìmísí Ọlọ́run, àwọn tó kọ Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ kan tó lágbára láti tú àṣírí ohun tó wà lọ́kàn àwọn apẹ̀yìndà àti ọgbọ́n tí wọ́n ń dá.

7 Kí ni ohun táwọn apẹ̀yìndà ní lọ́kàn gan-an? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn apẹ̀yìndà ni kì í fẹ́ káwọn nìkan kúrò nínú ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti lè fìgbà kan sọ pé ó jẹ́ ọ̀nà òtítọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń fẹ́ káwọn ẹlòmíràn tẹ̀ lé wọn. Dípò kí ọ̀pọ̀ lára àwọn apẹ̀yìndà wọ̀nyí jáde lọ, kí wọ́n lọ wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn tiwọn, ńṣe ni wọ́n máa ń gbìyànjú láti “fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn [ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi] lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Nítorí àwọn olùkọ́ èké ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi fúnni ní ìkìlọ̀ kánjúkánjú tó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀.” (Kólósè 2:8) Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn apẹ̀yìndà máa ń gbìyànjú àtiṣe nìyẹn? Bíi gbọ́mọgbọ́mọ kan ṣe máa ń jí ẹni tí kò fura gbé kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀ náà ni àwọn apẹ̀yìndà ṣe máa ń fi àwọn tó fọkàn tán wọn nínú ìjọ ṣèjẹ, tí wọ́n á sì wá ọ̀nà tí wọ́n fi máa mú wọn kúrò nínú agbo.

8. Ọgbọ́n wo làwọn apẹ̀yìndà máa ń dá kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́?

8 Ọgbọ́n wo làwọn apẹ̀yìndà máa ń dá kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́? Wọ́n sábà máa ń ṣèrú, wọ́n máa ń firọ́ mọ́ òótọ́, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ dìídì purọ́ láìfi bò. Jésù mọ̀ pé ojú àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa rí màbo lọ́wọ́ àwọn tí yóò “pa gbogbo irọ́ burúkú mọ́” wọn. (Mátíù 5:11, Today’s English Version) Irú àwọn alátakò tí ń ba tẹni jẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò sọ ohun tí kì í ṣe òótọ́ kí wọ́n lè tan àwọn ẹlòmíràn jẹ. Àpọ́sítélì Pétérù kìlọ̀ nípa àwọn apẹ̀yìndà tí wọn yóò lo “ayédèrú ọ̀rọ̀,” tí wọ́n á tan “àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ” kálẹ̀, tí wọ́n á sì “lọ́ àwọn Ìwé Mímọ́” láti mú ète wọn ṣẹ. (2 Pétérù 2:3, 13; 3:16) Ó ṣeni láàánú pé àwọn apẹ̀yìndà ti “dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé.”—2 Tímótì 2:18.

9, 10. (a) Báwo la ṣe lè ṣọ́ra kí àwọn apẹ̀yìndà má bàa tàn wá jẹ? (b) Kí nìdí tá ò fi ń dààmú tá a bá rí i pé òye tá a ní nípa ète Ọlọ́run ṣì nílò àtúnṣe?

9 Báwo là ṣe lè ṣọ́ra ká má bàá di ẹni táwọn apẹ̀yìndà tàn jẹ? Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn tó wá látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tó sọ pé: “Máa ṣọ́ àwọn tí ń fa ìpínyà àti àwọn àyè fún ìkọ̀sẹ̀ lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́, ẹ sì yẹra fún wọn.” (Róòmù 16:17) A ń “yẹra fún wọn” nípa ṣíṣàì gba èrò wọn—yálà kí wọ́n bá wa sọ̀rọ̀ lójúkojú, tàbí ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé tàbí ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí nìdí tá a fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì dájú pé ohun tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ ni Jèhófà máa ń sọ pé ká ṣe.—Aísáyà 48:17, 18.

10 Ìkejì, a fẹ́ràn ètò àjọ tó kọ́ wa ní òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó yà wá sọ́tọ̀ gedegbe kúrò lára Bábílónì Ńlá. Lẹ́sẹ̀ kan náà, a gbà pé ìmọ̀ tá a ní nípa ète Ọlọ́run kì í ṣe èyí tó pé; bí ọdún sì ti ń gorí ọdún là ń ṣàtúnṣe òye wa. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin máa ń fara balẹ̀ dúró de ìgbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà láti ṣe gbogbo irú àtúnṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 4:18) Bá a sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní kúrò nínú ètò àjọ tí inú Ọlọ́run dùn sí, tó sì ń lò, nítorí pé a ti rí ẹ̀rí kedere tó fi hàn pé ìbùkún rẹ̀ wà lórí ètò àjọ yìí.—Ìṣe 6:7; 1 Kọ́ríńtì 3:6.

Ṣọ́ra fún Títan Ara Rẹ Jẹ

11. Kí nìdí tí ẹ̀dá aláìpé fi máa ń ní èrò láti tan ara rẹ̀ jẹ?

11 Ẹ̀dá aláìpé ní èrò kan tí Sátánì máa ń tètè rí lò, ìyẹn ní títan ara ẹni jẹ. Ìwé Jeremáyà 17:9 sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.” Jákọ́bù náà kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:14) Tí ọkàn wá bá di èyí tí a ré lọ, ó lè jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ máa wù wá, kó wá jẹ́ kó dà bí ohun tó ń fani mọ́ra tí kò sì lè pani lára. Irú èrò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀tàn, nítorí pé ìparun ni ẹ̀ṣẹ̀ dídá máa ń já sí nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Róòmù 8:6.

12. Àwọn ọ̀nà wo ni títan ara wa jẹ lè gbà jẹ́ ìdẹkùn fún wa?

12 Títan ara ẹni jẹ lè dẹkùn mú wa wẹ́rẹ́. Ọkàn tó ṣe àdàkàdekè lè mú ká fojú kéré ìkùdíẹ̀–káàtó kan tí kò dára rárá tàbí kó mú ká máa wí àwíjàre lórí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan. (1 Sámúẹ́lì 15:13-15, 20, 21) Ọkàn wa tó ti gbékútà tún lè mú ká máa wá ọ̀nà láti sọ pé kó sóhun tó burú nínú ìwà kan tó ń kọni lóminú. Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn eré ìnàjú yẹ̀ wò. Àwọn eré ìnàjú kan gbámúṣé, wọ́n sì gbádùn mọ́ni. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun tí ayé yìí ń gbé jáde nínú sinimá àtàwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n àti ti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló jẹ́ èyí tó ń kóni nírìíra tó sì kún fún ìṣekúṣe. Ó rọrùn láti mú un dá ara wa lójú pé a lè máa wo eré ìnàjú tó ń kọni lóminú kó má sì ṣe wá ní ohunkóhun. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé, “Kò ṣáà da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú, kí ló wá burú níbẹ̀ nígbà náà?” Àmọ́ ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń ‘fi èrò èké tan ara wọn jẹ.’—Jákọ́bù 1:22.

13, 14. (a) Àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé ẹ̀rí ọkàn wa kì í fìgbà gbogbo tọ́ wa sọ́nà láìséwu? (b) Báwo la ṣe lè ṣọ́ra fún títan ara wa jẹ?

13 Báwo la ṣe lè ṣọ́ra fún títan ara wa jẹ? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ní láti rántí pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ẹ̀rí ọkàn èèyàn ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Gbé ọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Kó tó di Kristẹni, ó ṣenúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìṣe 9:1, 2) Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ má dà á láàmú lákòókò yẹn. Àmọ́, ó hàn gbangba pé ó ti darí rẹ̀ sí ibi tí kò dára. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.” (1 Tímótì 1:13) Nítorí náà, bí eré ìnàjú kan kò bá da ẹ̀rí ọkàn wá láàmú, kò túmọ̀ sí pé ohun tá a ń ṣe yẹn tọ̀nà. Kìkì ẹ̀rí ọkàn rere tá a fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ dáadáa ló lè tọ́ wà sọ́nà láìséwu.

14 Tá a bá fẹ́ yẹra fún títan ara wa jẹ, àwọn ìmọ̀ràn kan tó lè ṣèrànwọ́ wà tá a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn. Yẹ ara rẹ wò tàdúràtàdúrà. (Sáàmù 26:2; 2 Kọ́ríńtì 13:5) Yíyẹ ara rẹ wò láìṣàbòsí lè jẹ́ kó o rí i kedere pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú bó o ṣe ń ronú àti nínú àwọn ọ̀nà tó o gbà ń ṣe nǹkan. Fetí sí àwọn ẹlòmíràn. (Jákọ́bù 1:19) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a kì í lè sọ bá a ṣe jẹ́ gan-an nígbà tá a bá yẹ ara wa wò, ó bọ́gbọ́n mu láti fetí sí òótọ́ ọ̀rọ̀ táwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó dàgbà dénú bá bá wa sọ. Tó o bá rí i pé àwọn ìpinnu tó ò ń ṣe tàbí àwọn ọ̀nà tó ò ń gbà hùwà ń kọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tó dàgbà dénú lóminú, o lè bi ara rẹ pé, ‘Ṣé kì í ṣe àìkọ́ ẹ̀rí ọkàn mi lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa ló fa èyí tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni ọkàn mi ń tàn mí jẹ?’ Máa fi Bíbélì àtàwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì bọ́ ara rẹ̀ déédéé. (Sáàmù 1:2) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí èrò rẹ, ìṣe rẹ, àti ìmọ̀lára rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run.

Ṣọ́ra fún Àwọn Irọ́ Sátánì

15, 16. (a) Àwọn irọ́ wo ni Sátánì ń pa láti tàn wá jẹ? (b) Báwo la ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tá a fi irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ tàn jẹ?

15 Onírúurú irọ́ ni Sátánì máa ń pa láti tàn wá jẹ. Ó ń gbìyànjú láti mú kí á gbà pé ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè fún wa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, àmọ́ ọ̀ràn kì í sábà rí bẹ́ẹ̀. (Oníwàásù 5:10-12) Ó fẹ́ ká gbà gbọ́ pé ayé burúkú yìí á máa bá a lọ títí láé, bẹ́ẹ̀ a ti rí ẹ̀rí tó fi hàn gbangba pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé báyìí. (2 Tímótì 3:1-5) Sátánì máa ń fẹ́ ká ronú pé kò séwu nínú gbígbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn jayéjayé nígbẹ̀yìn kì í dára. (Gálátíà 6:7) Báwo la ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tá a fi irú àwọn irọ́ bẹ́ẹ̀ tàn jẹ?

16 Jàǹfààní látinú àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Àpẹẹrẹ àwọn tí Sátánì fi irọ́ tàn jẹ wà nínú Bíbélì tí a lè fi ṣe ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, wọn ò fiyè sí àkókò tí wọ́n ń gbé, tàbí tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún ìṣekúṣe, àbájáde gbogbo rẹ̀ sì burú jáì. (Mátíù 19:16-22; 24:36-42; Lúùkù 16:14; 1 Kọ́ríńtì 10:8-11) Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn àpẹẹrẹ òde òní. Ó ṣeni láàánú pé, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan wà táwọn Kristẹni kan máa ń dẹra nù, wọ́n rò pé sísìn táwọn ń sin Ọlọ́run ti mú kí wọ́n pàdánù ohun kan tó dára. Wọ́n lè fi òtítọ́ sílẹ̀ kí wọ́n lọ máa lépa ohun tí wọ́n pè ní adùn. Àmọ́ ṣá o, “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wà, nítorí pé láìpẹ́ láìjìnnà wọ́n á ká èso ìwà búburú wọn. (Sáàmù 73:18, 19) Ó bọ́gbọ́n mu láti fi àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn kọ́gbọ́n.—Òwe 22:3.

17. Kí nìdí tí Sátánì fi ń purọ́ pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ wa àti pé kò ká wá sí?

17 Irọ́ mìíràn tún wà tí Sátánì ti rí lò dáadáa, irọ́ náà ni pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò kà wá sí. Sátánì ti fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wo àwa ẹ̀dá aláìpé. Ó mọ̀ pé ìrẹ̀wẹ̀sì lè kó àárẹ̀ bá wa. (Òwe 24:10) Ìdí nìyẹn tó fi ń tan irọ́ kálẹ̀ pé a ò já mọ́ ohunkóhun lójú Ọlọ́run. Tó bá “gbé wa ṣánlẹ̀,” tó sì jẹ́ ká gbà gbọ́ pé Jèhófà kò bìkítà nípa wa, ìyẹn lè mú ká fẹ́ juwọ́ sílẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:9) Ohun tí Ẹlẹ́tàn ńlá náà ń fẹ́ gan-an nìyẹn! Báwo la ṣe lè wá ṣọ́ra ká má bàá di ẹni tá a fi irọ́ Sátánì yìí tàn jẹ?

18. Báwo ni Bíbélì ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa?

18 Kí ìwọ fúnra rẹ ṣàṣàrò lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lo àwọn ọ̀rọ̀ àpèjúwe kan tó mú un dá wa lójú pé Jèhófà kà wá sí, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ó fi omijé rẹ “sínú ìgò awọ” rẹ̀, tó túmọ̀ sí pé ó rí ẹkún tó o sun nígbà tó ò ń sapá láti dúró gbọn-in bí olóòótọ́, kò sì gbàgbé ẹkún náà. (Sáàmù 56:8) Ó mọ ìgbà tó o jẹ́ “oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà” ó sì wà lọ́dọ̀ rẹ ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 34:18) Ó mọ bó o ṣe jẹ́ látòkèdélẹ̀, títí kan iye ‘irun orí rẹ’ pàápàá. (Mátíù 10:29-31) Lékè gbogbo rẹ̀, Ọlọ́run “fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo” lélẹ̀ nítorí rẹ. (Jòhánù 3:16; Gálátíà 2:20) Àwọn ìgbà kan wà tó lè ṣòro fún ọ láti gbà pé ìwọ gan-an ni irú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí èyí ń bá wí. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ gba ọ̀rọ̀ Jèhófà gbọ́. Ó fẹ́ ká gbà gbọ́ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, kì í ṣe pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lápapọ̀ nìkan, ó tún nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú.

19, 20. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti mọ irọ́ ti Sátánì ń pa pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ wa, kéèyàn sì sá fún un? (b) Ọ̀nà wo ni alábòójútó arìnrìn-àjò kan gbà ran àwọn tó ní ìròbìnújẹ́ ọkàn lọ́wọ́?

19 Mọ̀ pé irọ́ ni, kí o sì kọ̀ ọ́. Tó o bá mọ̀ pé irọ́ ni ẹnì kan ń pa, wàá mọ bó o ṣe máa ṣọ́ra tí onítọ̀hún kò fi ní rí ọ tàn jẹ. Bákan náà, tó o bá mọ̀ pé irọ́ ni Sátánì ń pa, tó fẹ́ kó o gbà pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ rẹ, ìyẹn lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Nígbà tí Kristẹni kan ń sọ èrò ọkàn rẹ̀ nípa àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ kan tó kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ètekéte Sátánì, ó sọ pé: “Mi ò mọ̀ rárá pé Sátánì máa ń wá bóun ṣe máa fi ẹ̀dùn ọkàn mi kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Mímọ̀ tí mo mọ èyí ti wá fún mi lókun láti kápá àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn mi.”

20 Kíyè sí ìrírí alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó wà ní orílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Amẹ́ríkà. Nígbà tó bá lọ ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó ní ìròbìnújẹ́ ọkàn, ó sábà máa ń bi wọ́n pé, ‘Ǹjẹ́ o gba Mẹ́talọ́kan gbọ́?’ Ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì náà á dáhùn pé, ‘Rárá o,’ nítorí ó mọ̀ pé èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn irọ́ Sátánì. Alàgbà arìnrìn-àjò yìí á tún béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ o gbà pé iná ọ̀run àpáàdì wà?’ Ẹni náà á tún dáhùn pé, ‘Rárá o!’ Alàgbà arìnrìn-àjò náà á wá sọ fún wọn pé irọ́ kan tún wà tí Sátánì ń tàn kálẹ̀, àmọ́ àwọn èèyàn kì í tètè mọ̀ pé bó ṣe jẹ́ nìyẹn. Ó ní kí wọ́n wo ojú ìwé 249, ìpínrọ̀ 21, nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà.b Ìpínrọ̀ náà fi hàn kedere pé irọ́ gbuu ló jẹ́ láti sọ pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Alábòójútó arìnrìn-àjò náà ròyìn àwọn àbájáde rere tó rí látinú ọ̀nà tó gbà ran àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì lọ́wọ́ láti mọ irọ́ tí Sátánì ń pa, kí wọ́n sì sá fún un.

Yẹra fún Ẹ̀tàn

21, 22. Kí nìdí tí àwọn ọgbọ́n àyínìke Sátánì kò fi ṣàjèjì sí wa, kí ló sì yẹ ká múra tán láti ṣe?

21 Ní apá ìparí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a gbọ́dọ̀ retí pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ irọ́ àti ẹ̀tàn ni Sátánì yóò dà sáyé. A dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ ká mọ gbogbo ọgbọ́n àyínìke tí Sátánì ń lò. Bíbélì àtàwọn ìwé tá a gbé ka Bíbélì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ jáde ń túdìí àṣírí àwọn ọgbọ́n burúkú tí Èṣù ń lò wọ̀nyí. (Mátíù 24:45) Ẹ sì mọ̀ pé ogun àgbọ́tẹ́lẹ̀ kì í pa arọ tó bá gbọ́n.—2 Kọ́ríńtì 2:11.

22 Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra fún èrò àwọn apẹ̀yìndà. Ẹ jẹ́ ká múra tán láti yẹra fún ìdẹkùn títan ara ẹni jẹ láìmọ̀. Ẹ sì jẹ́ ká mọ gbogbo irọ́ tí Sátánì ń pa, ká sì kọ̀ wọn sílẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe àárín àwa àti “Ọlọ́run òtítọ́” tó kórìíra ẹ̀tàn kò ní bà jẹ́.—Sáàmù 31:5; Òwe 3:32.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà tí ìwé kan tá a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìṣe náà ‘ń ṣì lọ́nà’ tó wà nínú Ìṣípayá 12:9, ó ní ìyẹn “fi hàn pé ohun kan tó ń bá a lọ láìdáwọ́dúró ni, ìyẹn èyí tó ti di bárakú síni lára.”

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí ẹ̀tàn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú ayé lónìí?

• Báwo la ṣe lè yẹra fún dídi ẹni táwọn apẹ̀yìndà máa tàn jẹ?

• Báwo la ṣe máa ṣọ́ra fún èrò èyíkéyìí tó lè mú ká tan ara wa jẹ?

• Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí Sátánì fi àwọn irọ́ rẹ̀ tàn wá jẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Má ṣe tan ara rẹ jẹ tó bá dọ̀ràn eré ìnàjú

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Tó o bá fẹ́ yẹra fún títan ara ẹni jẹ, ṣàyẹ̀wò ara rẹ tàdúràtàdúrà, fetí sí àwọn ẹlòmíràn, kó o sì máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ara rẹ déédéé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́