ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 2/15 ojú ìwé 21-25
  • Wọ́n Pé Jọ sí “Agbedeméjì Ayé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Pé Jọ sí “Agbedeméjì Ayé”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ìgbà Àkọ́kọ́ Tá A Fúnrúgbìn Ìjọba Ọlọ́run sí Erékùṣù Náà
  • Wọ́n Múra Sílẹ̀ fún Àpéjọ Àyíká
  • Ẹni Tá Ò Rò Ló Ròyìn Wọn Fayé Gbọ́
  • Àpéjọ Náà Bẹ̀rẹ̀
  • Ìjẹ́rìí Òwúrọ̀
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tẹ̀mí Náà Ń Bá A Nìṣó
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 2/15 ojú ìwé 21-25

Wọ́n Pé Jọ sí “Agbedeméjì Ayé”

Ǹjẹ́ o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “Te Pito o Te Henua” rí? Ó túmọ̀ sí “Agbedeméjì Ayé” ní èdè Rapa Nui, ìyẹn èdè tí wọ́n ń sọ ní erékùṣù Easter Island. Kí ló mú kí àpéjọ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀?

IBI àdádó tó jìnnà réré, ibi àrímáleèlọ, ibi tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn wà lára ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi máa ń ṣàpèjúwe erékùṣù Easter Island, tàbí Rapa Nui gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ ṣe ń pè é. Ibi àdádó ni lóòótọ́, ó wà ní ibi tó jìnnà sí Gúúsù Òkun Pàsífíìkì, ó fi nǹkan bí ẹgbọ̀nkàndínlógún ó dín mẹ́wàá [3,790] kìlómítà jìn sí ìlú Santiago ní orílẹ̀-èdè Chile. Ó di ìpínlẹ̀ Chile ní September 9, 1888.

Òkè ńlá mẹ́ta tí kò yọ iná àtèéfín mọ́ ló para pọ̀ di erékùṣù onígun mẹ́ta yìí, fífẹ̀ àyè ilẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́jọ ó lé mẹ́fà [166] kìlómítà níbùú lóòró. Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn òkè ńlá tó yọ orí jáde lábẹ́ omi ló di erékùṣù yìí bíi ti ọ̀pọ̀ erékùṣù tó wà ní Òkun Pàsífíìkì. Wọ́n sọ pé erékùṣù yìí jẹ́ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé. Láìsí àní-àní ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ erékùṣù yìí nítorí àwọn àgbàyanu ère òkúta tó wà níbẹ̀ tí wọ́n ń pè ní moai.a

Yàtọ̀ sí ojú ilẹ̀ tó fani mọ́ra àtàwọn ibi tí nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé wà, erékùṣù Easter Island tún ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ aládùn lóríṣiríṣi. Àwọn èso ilẹ̀ ibẹ̀ nìwọ̀nyí: ọ̀pẹ̀yìnbó, píà, ìbẹ́pẹ, àti oríṣi ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ mẹ́sàn-án. Oríṣiríṣi ẹja àtàwọn oúnjẹ mìíràn ni wọ́n ń mú wá látinú òkun.

Ojú ọjọ́ máa ń tuni lára ní erékùṣù Easter Island, òjò máa ń rọ̀ déédéé, òṣùmàrè sì máa ń yọ, gbogbo èyí ló mú kí àwọn àlejò tó ń wá síbẹ̀ máa gbádùn afẹ́fẹ́ tó dáa tí wọ́n sì tún ń rí àwọn nǹkan àrà. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn tó ń gbé ibẹ̀ tó nǹkan bí ẹgbọ̀kàndínlógún [3,800] èèyàn. Àtọmọdọ́mọ àwọn tó kọ́kọ́ tẹ ibẹ̀ dó àti àwọn ará Yúróòpù, àwọn ará Chile, àtàwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè mìíràn ló ń gbé ibẹ̀ nísinsìnyí. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arìnrìn àjò afẹ́ láti Yúróòpù àti Éṣíà máa ń wá sí erékùṣù yìí, ìrìn àjò afẹ́ yìí sì ń mú owó wọlé gan-an fún wọn ní erékùṣù náà.

Ìgbà Àkọ́kọ́ Tá A Fúnrúgbìn Ìjọba Ọlọ́run sí Erékùṣù Náà

Ìwé 1982 Yearbook of Jehovah’s Witnesses ròyìn pé: “Fún àwọn àkókò kan, obìnrin kan ṣoṣo ni akéde tó wà ní erékùṣù Easter Island. Arábìnrin kan tó jẹ́ Míṣọ́nnárì ló ràn án lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, ó ń kọ̀wé sí i láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní [orílẹ̀-èdè Chile]. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin akéde yìí ti kúrò ní erékùṣù náà wá síbi tí kì í ṣe orí omi ní Chile, àwọn èèyàn tí wọ́n forúkọ sílẹ̀ fún gbígba Ilé Ìṣọ́ ṣì wà ní erékùṣù náà. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa ní April 1980 nígbà tí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì tẹ̀ wá láago, ó ní òun fẹ́ mọ ìgbà tá a fẹ́ ṣe Ìrántí ikú Jésù. Nígbà tó yá ní ọdún kan náà yẹn, tọkọtaya kan láti Valparaiso ṣí lọ síbẹ̀, wọ́n sì ń kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́. Ní April 1981 wọ́n ṣe Ìrántí ikú Jésù nígbà àkọ́kọ́ ní erékùṣù náà, èèyàn mẹ́tàlá ló wá. Inú wa mà dùn gan-an o pé ‘ìhìn rere’ ti ń dé ibi àdádó tó jìnnà réré yẹn!”

Nígbà tó yá, ní January 30, 1991, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa rán tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tó ń jẹ́ Dario àti Winny Fernandez, lọ sí erékùṣù náà. Arákùnrin Fernandez sọ pé: “Wákàtí márùn-ún ni ọkọ̀ òfuurufú fi gbé wa wá síbi tó dá dó jù lọ ní ayé yìí, ibi tí àṣà ìbílẹ̀ wọn ti kún fún àwọn ohun ìyanu.” Kíákíá ni wọ́n ṣètò àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì rí ìtìlẹ́yìn látọ̀dọ̀ arákùnrin kan tó ń gbé ibẹ̀ àti arábìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé síbẹ̀ pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ méjì. Pẹ̀lú ìṣòro kí ìdílé ẹni máa fúngun mọ́ni, ìtara ìsìn, àti irú ọ̀nà ìgbésí ayé kan pàtó tó wọ́pọ̀ nínú àṣà àwọn ará Polynesia, síbẹ̀ Jèhófà bù kún ìsapá wọn. Arákùnrin àti arábìnrin Fernandez kì í ṣe aṣáájú ọ̀nà àkànṣe mọ́ báyìí, àmọ́ wọ́n ṣì wà ní erékùṣù náà tí wọ́n ń tọ́ ọmọkùnrin tí wọ́n bí síbẹ̀. Lónìí, àwọn méjìlélọ́gbọ̀n akéde Ìjọba Ọlọ́run ló wà níbẹ̀. Lára wọn ni àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Rapa Nui àti àwọn tí wọ́n wá ń gbé níbẹ̀ tàbí àwọn tí wọ́n wá sìn níbẹ̀ nítorí pé wọ́n nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà púpọ̀ sí i.

Wọ́n Múra Sílẹ̀ fún Àpéjọ Àyíká

Nítorí pé erékùṣù náà jìnnà gan-an sí àwọn orílẹ̀-èdè Gúúsù Amẹ́ríkà, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni ìjọ tó wà níbẹ̀ máa ń gba àwọn kásẹ́ẹ̀tì fídíò tí ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè wà nínú rẹ̀. Àmọ́ ní ìparí ọdún 2000, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti orílẹ̀-èdè Chile rò ó pé á dára tí wọ́n bá lè ṣe àpéjọ àyíká tiwọn àkọ́kọ́ ní erékùṣù náà. Níkẹyìn wọ́n pinnu pé kí wọ́n ṣe àpéjọ àyíká náà ní November 2001, wọ́n sì pe díẹ̀ lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin láti ibi gbogbo ní orílẹ̀-èdè Chile wá sí àkànṣe ìpàdé yìí. Nítorí ọjọ́ tí iléeṣẹ́ tó ń bójú tó ìrìn àjò ọkọ̀ òfuurufú fi ìrìn àjò náà sí, wọ́n fi àpéjọ náà sí ọjọ́ Sunday àti Monday.

Gbogbo àwọn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n èèyàn tí wọ́n ní kí wọ́n lọ sí àpéjọ náà ni inú wọ́n dùn pé àwọn fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí erékùṣù yẹn láti lọ ṣe àpéjọ àyíká àkọ́kọ́ tí wọ́n fẹ ṣe níbi tó jìnnà réré yẹn. Lẹ́yìn tí ọkọ̀ òfuurufú àwọn tó ń lọ sí àpéjọ náà ti fò gba orí Òkun Pàsífíìkì fún àkókò gígùn, ọkàn wọn balẹ̀ nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ tí wọ́n ń dúró dè wọ́n ní pápá ọkọ̀ òfuurufú kí wọn káàbọ̀. Wọ́n fi ẹ̀gbà ọrùn tí wọ́n fi òdòdó ṣe kí àwọn tó wá náà káàbọ̀, ìyẹn sì ni ohun tí wọ́n máa ń fi tani lọ́rẹ ní erékùṣù náà. Wọ́n mú wọn lọ sílé ibi tí wọ́n fi wọ́n dé sí, lẹ́yìn náà wọ́n fi àkókò díẹ̀ wo erékùṣù náà káàkiri, ẹ̀yìn yẹn ni gbogbo àwọn tó máa kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà wá pàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ẹni Tá Ò Rò Ló Ròyìn Wọn Fayé Gbọ́

Nígbà tí ọkọ̀ ń gbé àwọn tó wá lọ sí àpéjọ náà, ẹnu yà wọ́n láti gbọ́ tí àlùfáà ibẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lórí rédíò nípa ìbẹ̀wò wọn. Ó sọ́rọ̀ nípa àwọn arìnrìn–àjò tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè Gúúsù Amẹ́ríkà tí wọ́n á máa lọ sí ilé àwọn èèyàn láti máa sọ̀rọ̀ nípa òpin ayé tí ń bọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rọ àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ láti má ṣe fetí sí àwọn àlejò náà, ìkéde tó ṣe mú kí àwọn èèyàn mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí erékùṣù náà. Èyí mú kí àwọn tí ń gbé ní erékùṣù náà máa fojú sọ́nà láti rí wọn. Láàárín àwọn ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, àwọn àlejò tó wá náà fi ọgbọ́n sọ ìhìn rere tó mórí yá fún àwọn èèyàn.

Àpéjọ Náà Bẹ̀rẹ̀

Ní òwúrọ̀ Sunday, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní erékùṣù náà dúró ní ẹnu ọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba láti kí àwọn tó wá sí àpéjọ náà káàbọ̀ bí wọ́n ti ń dé fún ọjọ́ kìíní àpéjọ. Wọ́n ń sọ pé, “Iorana Koe! Iorana Koe!” “Ẹ káàbọ̀!” Àwọn arábìnrin kan wọ aṣọ ìbílẹ̀, wọ́n si fi òdòdó ṣe irun wọn lọ́ṣọ̀ọ́ bíi tàwọn ará Polynesia.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi orin aládùn bíi mélòó kan ṣáájú, gbogbo wọn wá jùmọ̀ kọ orin tó ní àkọlé náà, “Ẹ Durogangan, Laiyẹsẹ!” wọ́n ò tíì gbọ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn kọrin bẹ́ẹ̀ rí ní erékùṣù náà. Àwọn ará tó ń gbé ní erékùṣù náà yọ omi ayọ̀ lójú nígbà tí alága kí àwọn èèyàn káàbọ̀ ní èdè ìbílẹ̀, ìyẹn èdè Rapa Nui. Ní àkókò ìsinmi ọ̀sán, àwọn mẹ́ta tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kìíní parí, ńṣe ló mú gbogbo wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.—1 Pétérù 5:9.

Ìjẹ́rìí Òwúrọ̀

Nítorí àwọn ipò nǹkan kan tó gba àfiyèsí ní erékùṣù náà, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kejì bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán. Nítorí ìdí yẹn, àwọn tó wá sí àpéjọ náà lo àǹfààní yìí láti fi òwúrọ̀ ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn ìrírí wo ni wọ́n ní?

Obìnrin àgbàlagbà kan tó ní ọmọkùnrin àtọmọ obìnrin tí gbogbo wọ́n jẹ́ mẹ́jọ sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé òun àtàwọn kò ní lè jọ sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì lòun. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ fún un pé àwọn fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó dojú kọ gbogbo wa, irú bí oògùn olóró àti wàhálà ìdílé, ó gbà láti fetí sí ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.

Inú obìnrin àgbàlagbà kan ládùúgbò náà kò dùn sí tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan. Ó sọ́ fún wọn pé kí wọ́n lọ bá àwọn èèyàn tí ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè Gúúsù Amẹ́ríkà sọ̀rọ̀ nítorí àwọn yẹn ni ìkà èèyàn. Tọkọtaya náà sọ fún un pé “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run wà fún gbogbo èèyàn àti pé ohun to mú káwọn wá sí erékùṣù náà ni àpéjọ kan tó máa ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́ láti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Ọlọ́run máa pọ̀ sí i. (Mátíù 24:14) Wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá á fẹ́ ẹ̀mí gígùn nínú àyíká Párádísè tó jọ ti erékùṣù yìí láìsí àìsàn àti ikú. Lẹ́yìn tí wọ́n ti bá a fèrò wérò nípa iye ọdún tí ihò òkè ayọnáyèéfín yẹn ti wà ní erékùṣù náà, ó ronú jinlẹ̀ lórí bí ìwàláàyè èèyàn ṣe kúrú tó, ó wá béèrè pé: “Kí ló dé tó fi jẹ́ pé àkókò tó kúrú là ń lò láyé?” Ẹnu yà á gan-an nígbà tó ka Sáàmù 90:10.

Ìgbà yẹn ni àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣàdédé gbọ́ ariwo ní ilé kejì sí ibi tí wọ́n wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lóye ohun tó fa ariwo náà, obìnrin náà sọ fún wọn pé àwọn ará àdúgbò ló ń bú àwọn èèyàn, wọ́n sì ń sọ pé àwọn ò fẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí wá sọ́dọ̀ àwọn. Ní agbo ilé obìnrin yìí, òun ni “nua,” ìyẹn ọmọbìnrin tó dàgbà jù lọ nínú ìdílé. Nítorí pé baba rẹ̀ ti kú, ojúṣe rẹ̀ ni láti pinnu ohun tó máa ṣe ìdílé rẹ̀ láǹfààní. Lójú gbogbo àwọn ìbátan rẹ̀, ó fi èdè ìbílẹ̀ gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí ó sì fi inú rere gba àwọn ìwé tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Ní ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, nígbà tí àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ń fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé e lọ, ó ní kó dá ọkọ̀ náà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú àbúrò rẹ̀ kò dùn, obìnrin náà kí àwọn Ẹlẹ́rìí pé ó dàbọ̀, ó ní iṣẹ́ ìwàásù wọn á yọrí sí rere o.

Ó hàn kedere sí àwọn àlejò náà pé àwọn èèyàn Rapa Nui nínúure, wọ́n sì lọ́yàyà bó tilẹ̀ jẹ́ pé níbẹ̀rẹ̀ ó jọ pé àwọn ará erékùṣù náà kò fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tí àwọn Ẹlẹ́rìí láti àwọn orílẹ̀-èdè Gúúsù Amẹ́ríkà ń sọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn fetí sí ìhìn rere náà tayọ̀tayọ̀. Àní mẹ́fà nínú Ẹlẹ́rìí ogún tó ṣèrìbọmi ní erékùṣù náà ló jẹ́ ọmọ ibẹ̀. Ọ̀nà tí ọ̀kan lára wọn kọ́kọ́ gbà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni pé ó fetí sílẹ̀ láti inú yàrá kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ti ń kọ́ aya rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi nísinsìnyí, ó sì ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tẹ̀mí Náà Ń Bá A Nìṣó

Lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kejì bẹ̀rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn tó fìfẹ́ hàn dára pọ̀ mọ́ arákùnrin àti arábìnrin méjìlélọ́gbọ̀n tó ń gbé ní erékùṣù náà àtàwọn àlejò mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tó wá. Àwọn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún ló fetí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà títí kan àsọyé fún gbogbo èèyàn tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Bí Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́ Ṣe Ṣẹ́gun Ayé.” Lóòótọ́, gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀ ló rí ìfẹ́ táwọn èèyàn Jèhófà fi hàn láàárín ara wọn, àní láàárín àwọn tó ní àṣà ìbílẹ̀ tí ó yàtọ̀ síra pàápàá.—Jòhánù 13:35.

Ní àpéjọ àyíká náà, alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè bá àwọn aṣáájú ọ̀nà ṣe ìpàdé pàtàkì kan. Àwọn àlejò tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe dára pọ̀ mọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé mẹ́ta tó wà ní erékùṣù náà. Gbogbo wọn sì rí ọ̀pọ̀ ìṣírí gbà.

Ní ọjọ́ kejì, àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n tún jẹ́ ẹni tó ń mú àwọn èèyàn wòran mú àwọn àlejò náà lọ wo erékùṣù náà káàkiri. Wọ́n lọ síbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta, níbi tí wọ́n ti gbẹ́ òkúta moai, wọ́n dé ibi tí àwọn òkè ayọnáyèéfín wà níbi táwọn ìdíje ìgbàanì ti máa ń wáyé, ó sì dájú pé wọ́n dé etíkun Anakena tó ní iyanrìn aláwọ̀ góòlù, níbi táwọn tó kọ́kọ́ tẹ̀ dó sí erékùṣù náà fi ọkọ̀ ojú omi wọn gúnlẹ̀ sí.b

Ibi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ni wọ́n ti láǹfààní láti wà pẹ̀lú àwọn ará kẹ́yìn. Lẹ́yìn ìpàdé náà, àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé ibẹ̀ ṣe ohun tó ya àwọn àlejò náà lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbé oúnjẹ pàtàkì kan tí wọ́n máa ń jẹ ní erékùṣù náà wá fún wọn. Nígbà tó yá, wọ́n wá fi aṣọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ jó fún wọn. Àwọn àlejò àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jẹ́ Rapa Nui wá rí i pé gbogbo akitiyan tí àwọn ṣe láti múra àpéjọ sílẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Ọkàn gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ náà fà mọ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ń gbé níbi àdádó yìí. Wọ́n lo ọ̀sẹ̀ kan gbáko lọ́dọ̀ wọn, ó sì lárinrin púpọ̀. Ojú ro wọ́n gan-an láti fi erékùṣù náà sílẹ̀. Wọ́n ò jẹ́ gbàgbé àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí wọ́n ní àti ìṣírí nípa tẹ̀mí tí wọ́n ti rí gbà. Ní pápá ọkọ̀ òfuurufú, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní erékùṣù náà fi ìkòtó òkun ṣe ọ̀ṣọ́ sọ́rùn àwọn tó wá sí àpéjọ náà.

Bí àwọn tó wá sí àpéjọ náà ṣe ń padà lọ, wọ́n ṣèlérí pé: “Iorana! Iau he hoki mai e Rapa Nui ee,” tí ó túmọ̀ sí: “Ó dìgbà kan ná! Rapa Nui, mo ṣì máa padà wá.” Lóòótọ́ ni, wọ́n ń fẹ́ láti tún padà wá sọ́dọ̀ àwọn ọrẹ́ wọn tuntun àti ìdílé wọ́n nípa tẹ̀mí tó ń gbé ní ibi àdádó tó jìnnà réré, tó jẹ́ àrímáleèlọ, tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, ìyẹn erékùṣù Easter Island tó kóni mọ́ra!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí! ti June 22, 2000 (èdè Gẹ̀ẹ́sì) tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

b Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n fọwọ́ kọ́ síbi ihò ayọnáyèéfín ti òkè Rano Raraku. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ìdíje tó máa ń wáyé láàárín àwọn tó bá fẹ́ di alákòóso erékùṣù náà. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ìdíje ọ̀hún ni pé, wọ́n á sọ̀ kalẹ̀ látorí àpáta gíga náà, wọ́n á wá lúwẹ̀ẹ́ lọ sí ọ̀kan lára àwọn erékùṣù kékeré, wọ́n á mú ẹyin ẹyẹ kan ní erékùṣù ọ̀hún, wọ́n á sì lúwẹ̀ẹ́ padà síbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n á wá gun àpáta náà lọ sókè pẹ̀lú ẹyin náà lọ́wọ́, ẹyin ọ̀hún ò sì gbọ́dọ̀ fọ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

Iṣẹ́ Ìwàásù ní Erékùṣù Easter Island

Ní nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú àpéjọ mánigbàgbé yìí, alábòójútó àyíká àti ìyàwó rẹ̀ ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù yìí wọ́n sì ní àwọn ìrírí alárinrin. Bí àpẹẹrẹ, wo irú ìyàlẹ́nu tó jẹ́ nígbà tí arábìnrin tó mú wọn lọ sí ilé tí wọ́n dé sí rán wọ́n létí pé wọ́n ti bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí ní gúúsù orílẹ̀-èdè Chile nígbà tóun wà ní ọ̀dọ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn. Irúgbìn yẹn ti wá so èso ní Rapa Nui báyìí.

Wọ́n tún ní ìrírí mìíràn tó ń pani lẹ́rìn-ín: Wọ́n fún ẹnì kan tó ń ta àwọn nǹkan àfiṣèrántí ní Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lá tẹ àwọn ìwé yẹn jáde. Nígbà tí wọ́n padà bẹ̀ ẹ́ wò, ó lóun kò lè ka Bíbélì náà. Àbí ẹ ò rí nǹkan, Bíbélì èdè Faransé ni wọ́n fún un dípò ti èdè Spanish tó ń fẹ́! Kò pẹ́ tí ìṣòro náà fi yanjú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ àti Bíbélì tó wà ní èdè rẹ̀, ó wá rí i pé ó tiẹ̀ rọrùn láti lóye Bíbélì.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 22]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ERÉKÙṢÙ EASTER ISLAND

ORÍLẸ̀-ÈDÈ CHILE

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Méjì lára àwọn tó ṣèrìbọmi ni àpéjọ àyíká náà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ayọnáyèéfín tó ń jẹ́ Rano Raraku; Àwòrán inú àkámọ́: Èso igbó tí wọ́n ń pè ní guayaba máa ń hù ní erékùṣù náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́