Àṣeyẹ Kan Tí Ó Kàn Ọ́
NÍGBÀ tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó dá àṣeyẹ kan tó ń bọlá fún Ọlọ́run sílẹ̀. Èyí ni àṣeyẹ ìsìn kan ṣoṣo tí Jésù dìídì pa láṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe. Àṣeyẹ yìí ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, a sì tún mọ̀ ọ́n sí Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi.
Fojú inú wò ó pé o wà níbì kan tẹ́nikẹ́ni ò ti rí ọ, tó ò ń wo gbogbo ohun tó wáyé kí àṣeyẹ náà tó bẹ̀rẹ̀. Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń ṣayẹyẹ àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Júù ní yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ oúnjẹ Ìrékọjá tán ni, oúnjẹ ọ̀hún sì ni ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn sísun, ewébẹ̀ kíkorò, búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa. Wọ́n ní kí àpọ́sítélì Júdásì Ísíkáríótù tó jẹ́ aláìṣòótọ́ kúrò láàárín wọn, kò sì pẹ́ sígbà yẹn tó fi da Ọ̀gá rẹ̀. (Mátíù 26:17-25; Jòhánù 13:21, 26-30) Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ ni wọ́n jọ wà níbẹ̀. Mátíù jẹ́ ọ̀kan lára wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ Mátíù ẹni tí àṣeyẹ náà ṣojú rẹ̀, ọ̀nà tí Jésù gbà fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ rèé: “Jésù mú ìṣù búrẹ́dì [aláìwú] kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife [wáìnì] kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’”—Mátíù 26:26-28.
Kí nìdí tí Jésù fi fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀? Kí nìdí tó fi lo búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa nígbà tó ń fi í lọ́lẹ̀? Ṣé gbogbo ọmọlẹ́yìn Jésù ló ní láti máa jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ yìí? Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe àṣeyẹ yìí léraléra tó? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kàn ọ́?