“Ṣàṣeparí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Ní Kíkún”
“Ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ kúnnákúnná.”—2 TÍMÓTÌ 4:5, Byington.
1, 2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo Kristẹni ni ajíhìnrere, kí ni Ìwé Mímọ́ sọ pé káwọn alàgbà ṣe?
ṢÉ OLÙPÒKÌKÍ Ìjọba Ọlọ́run ni ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run fún àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ yìí. Ṣé alàgbà nínú ìjọ ni ẹ́? Àfikún àǹfààní látọ̀dọ̀ Jèhófà nìyẹn. Àmọ́, a kò ní gbàgbé láé pé kì í ṣe ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ayé tàbí bí ọ̀rọ̀ ṣe yọ̀ mọ́ni lẹ́nu la fi ń tóótun fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, kì í sì í ṣèyẹn la fi ń di alábòójútó nínú ìjọ. Jèhófà ló ń mú wa tóótun, tìtorí pé àwọn ọkùnrin kan láàárín wa kún ojú ìwọ̀n pàtó kan tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ ni wọ́n fi láǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ alábòójútó.—2 Kọ́ríńtì 3:5, 6; 1 Tímótì 3:1-7.
2 Gbogbo àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ló ń ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere, àmọ́ àwọn alábòójútó tàbí àwọn alàgbà ní pàtàkì ní láti fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ọlọ́run àti Kristi ń kíyè sí àwọn alàgbà “tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà náà ń kíyè sí ohun tí wọ́n ń ṣe. (1 Tímótì 5:17; Éfésù 5:23; Hébérù 6:10-12) Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ̀kọ́ tí alàgbà kan fi ń kọ́ni gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó gbéni ró nípa tẹ̀mí, nítorí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì tó jẹ́ alábòójútó pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké. Àmọ́ ṣá o, ìwọ, máa pa agbára ìmòye rẹ mọ́ nínú ohun gbogbo, jìyà ibi, ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere, ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ní kíkún.”—2 Tímótì 4:3-5.
3. Kí ló yẹ ní ṣíṣe kí àwọn ẹ̀kọ́ èké má bàa fi ipò tẹ̀mí ìjọ sínú ewu?
3 Láti rí i dájú pé ẹ̀kọ èké kò fi ipò tẹ̀mí ìjọ sínú ewu, alábòójútó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Ṣe gírí ní gbogbo ọ̀nà, . . . ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ kúnnákúnná.” (2 Tímótì 4:5, Byington) Bẹ́ẹ̀ ni o, alàgbà kan ní láti ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní kíkún.’ Ó gbọ́dọ̀ ṣe é pé, kó ṣe é kúnnákúnná, tàbí dé ojú ìwọ̀n. Alàgbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láṣepé máa ń bójú tó gbogbo ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ dáadáa, kì í fi ohunkóhun sílẹ̀ láìṣe tàbí kí ó máà ṣe é dójú ìwọ̀n. Irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun kékeré pàápàá.—Lúùkù 12:48; 16:10.
4. Kí lo lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún?
4 Ṣíṣe àṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kì í sábà gbà àkókò tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àmọ́ ó gba pé kéèyàn lo àkókò rẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ṣíṣe iṣẹ́ náà lọ láìdáwọ́dúró lè ran gbogbo Kristẹni lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ohun púpọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Bí alàgbà kan bá fẹ́ láti máa lo àkókò tó túbọ̀ pọ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó ní láti ṣètò ara rẹ̀ lọ́nà tó dáa láti lè mú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òun wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kí ó sì mọ iṣẹ́ tó yẹ kí òun gbé lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọ̀nà tó máa gbà ṣe bẹ́ẹ̀. (Hébérù 13:17) Gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí, alàgbà kan tó fi ara rẹ̀ sípò ọ̀wọ̀ tún máa ń ṣe ipa tirẹ̀, bíi Nehemáyà tó kópa nínú títún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́. (Nehemáyà 5:16) Ó yẹ kí gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà déédéé.—1 Kọ́ríńtì 9:16-18.
5. Báwo ló ṣe yẹ kí ọ̀ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà rí lára wa?
5 Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ aláyọ̀ gan-an la gbé lé wa lọ́wọ́ yìí, láti máa pòkìkí Ìjọba ọ̀run tó ti fìdí múlẹ̀! Ó dájú pé a mọyì àǹfààní wíwàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé kí òpin tó dé. (Mátíù 24:14) Bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, síbẹ̀ a lè rí ìṣírí gbà látinú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ní ìṣúra [iṣẹ́ òjíṣẹ́] yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Bẹ́ẹ̀ ni o, a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, àmọ́ okun àti ọgbọ́n tí Ọlọ́run ń fúnni nìkan la lè fi ṣe é.—1 Kọ́ríńtì 1:26-31.
Gbígbé Ògo Ọlọ́run Yọ
6. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Ísírẹ́lì ti ara àti Ísírẹ́lì tẹ̀mí?
6 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó sọ pé Ọlọ́run ti “mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn ní tòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́ májẹ̀mú tuntun kan.” Àpọ́sítélì náà sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín májẹ̀mú tuntun tí Ọlọ́run bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí dá nípasẹ̀ Jésù Kristi àti májẹ̀mú Òfin tó bá Ísírẹ́lì ti ara dá nípasẹ̀ Mósè. Pọ́ọ̀lù fi kún un pé nígbà tí Mósè gbé ọpọ́n tá a kọ Òfin Mẹ́wàá sí náà sọ̀ kalẹ̀ láti Òkè Sínáì, ojú rẹ̀ tàn yòò débi pé àwọn èèyàn ò lè tẹ́jú mọ́ ọn. Àmọ́ ṣá o, nígbà tó yá, ohun kan tó lágbára ju ìyẹn lọ ṣẹlẹ̀ nítorí pé “a mú agbára èrò orí wọn pòkúdu,” ìbòjú kan sì bo ọkàn wọn. Àmọ́ ìgbàkígbà tí wọ́n bá sin Jèhófà tọkàntọkàn ni ìbòjú náà máa ń ṣí kúrò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù tún ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a gbé lé àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun náà lọ́wọ́, ó sọ pé: ‘Gbogbo wa ń fi ojú tí a kò fi ìbòjú bò ṣe àgbéyọ ògo Jèhófà bí i dígí.’ (2 Kọ́ríńtì 3:6-8, 14-18; Ẹ́kísódù 34:29-35) “Àwọn àgùntàn mìíràn” tí Jésù ní lóde òní tún ní àǹfààní láti gbé ògo Jèhófà yọ̀.—Jòhánù 10:16.
7. Báwo làwọn èèyàn ṣe lè gbé ògo Ọlọ́run yọ?
7 Báwo ni ẹ̀dà èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè gbé ògo Ọlọ́run yọ, nígbà tó jẹ́ pé kò sẹ́ni tó lè rí Ọlọ́run kí ó sì yè? (Ẹ́kísódù 33:20) Ó yẹ ká mọ̀ pé yàtọ̀ sí ògo Jèhófà fúnra rẹ̀, ète rẹ̀ ológo láti dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ láre nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Òtítọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba náà ló para pọ̀ jẹ́ ara “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” tí àwọn tá a tú ẹ̀mí mímọ́ dà lé lórí ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa bẹ̀rẹ̀ sí kéde rẹ̀. (Ìṣe 2:11) Ẹ̀mí mímọ́ tó ń darí wọn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣàṣeparí ìṣẹ́ òjíṣẹ́ tá a gbé lé wọn lọ́wọ́.—Ìṣe 1:8.
8. Kí ni Pọ́ọ̀lù pinnu láti ṣe nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
8 Pọ́ọ̀lù pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ nínú ṣíṣe àṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun ní kíkún. Ó kọ̀wé pé: “Níwọ̀n bí a ti ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ní ìbámu pẹ̀lú àánú tí a fi hàn sí wa, tí àwa kò fi juwọ́ sílẹ̀; ṣùgbọ́n àwa ti kọ àwọn ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ tí ń tini lójú sílẹ̀ ní àkọ̀tán, a kò rin ìrìn àlùmọ̀kọ́rọ́yí, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ fífi òtítọ́ hàn kedere, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà olúkúlùkù ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá ènìyàn níwájú Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 4:1, 2) Ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí” mú kí òtítọ́ hàn kedere, ó sì mú kí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tàn dé ibi gbogbo.
9, 10. Báwo làwa èèyàn ṣe lè gbé ògo Jèhófà yọ?
9 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa Orísun ìmọ́lẹ̀ ti ara àti ti ẹ̀mí, ó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé: ‘Kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn,’ ó sì ti tàn sí ọkàn-àyà wa láti fi ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run tànmọ́lẹ̀ sí i nípasẹ̀ ojú Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 4:6; Jẹ́nẹ́sísì 1:2-5) Níwọ̀n bí a ti fún wa ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ti jíjẹ́ òjíṣẹ́ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́ tónítóní kí a lè máa gbé ògo Jèhófà yọ bíi dígí.
10 Àwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí kò lè rí ògo Jèhófà bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè rí ọ̀nà tí Jésù Kristi tó jẹ́ Mósè títóbi jù lọ gbà gbé ògo náà yọ. Àmọ́ àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà rí ìmọ́lẹ̀ ológo gbà látinú Ìwé Mímọ́, a sì ń tàn án dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Bí àwọn tó wà nínú òkùnkùn tẹ̀mí nísinsìnyí ò bá fẹ pa run, wọ́n ní láti gba ìmọ́lẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tá a fi ń fi ayọ̀ ńláǹlà àti ìtara ṣègbọràn sí àṣẹ àtọ̀runwá náà pé ká jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn látinú òkùnkùn fún ògo Jèhófà.
Jẹ̀ Kí Ìmọ́lẹ̀ Rẹ Tàn Nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú Ilé
11. Kí ni Jésù sọ nípa jíjẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn, kí sì ni ọ̀nà kan láti ṣe èyí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
11 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá. Àwọn ènìyàn a tan fìtílà, wọn a sì gbé e kalẹ̀, kì í ṣe sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, a sì tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:14-16) Ìwà rere wa lè mú kí àwọn ẹlòmíràn fi ògo fún Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:12) Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tá à ń ṣe pín sí onírúurú ẹ̀ka tó ń fún wa ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa tàn. Ọ̀kan lára ohun tó wà lórí ẹ̀mí wa jù lọ ni pé ká gbé ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yọ nípa dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́nà tó gbéṣẹ́. Èyí jẹ́ ọ̀nà tó ṣe pàtàkì gan-an láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Àwọn ìmọ̀ràn wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí yóò wọ àwọn tó ń wá òtítọ́ lọ́kàn ṣinṣin?
12. Báwo ni àdúrà ṣe wé mọ́ iṣẹ́ dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé?
12 Gbígbàdúrà sí Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí fi hàn pé ó wù wá láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó tún fi hàn pé a rí ìjẹ́pàtàkì ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ Ọlọ́run. (Ìsíkíẹ́lì 33:7-9) Ó dájú pé Jèhófà yóò dáhùn àdúrà wa, yóò sì bù kún akitiyan tá a ń ṣe tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. (1 Jòhánù 5:14, 15) Àmọ́ kì í ṣe kìkì pé ká kàn ri ẹni tá a ò kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan là ń gbàdúrà fún. Lẹ́yìn tá a bá ti rí ẹni tá a ò kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà àti àṣàrò lórí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà nílò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tó gbéṣẹ́ ní gbogbo ìgbà tá a bá ń ṣe é.—Róòmù 12:12.
13. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́nà tó gbéṣẹ́?
13 Tá a bá fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó múná dóko, a gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa ní gbogbo ìgbà tá a bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tó bá ń ṣe wá bí ẹni pé a ò tóótun, ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká kíyè sí ọ̀nà tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa gbà ń darí àwọn ibi tá a ń kà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè tẹ̀ lé àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n ti kẹ́sẹ járí nínú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Àmọ́ ṣá o, ó ṣe pàtàkì gan-an láti gbé irú ìṣarasíhùwà tí Jésù Kristi ní àti ọ̀nà tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yẹ̀ wò.
14. Báwo la ṣe lè dénú ọkàn ẹni tá a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
14 Inú Jésù máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ àti láti máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. (Sáàmù 40:8) Ó jẹ́ onínú tútù ó sì kẹ́sẹ járí nínú dídé inú ọkàn àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mátíù 11:28-30) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti dé inú ọkàn àwọn tá a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tá a bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, a ní láti máa múra gbogbo ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a bá fẹ́ ṣe sílẹ̀ dáadáa ká sì fi ipò akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ibi tí wọn ò ti gba Bíbélì gbọ́ rárá ni ẹni náà ti dàgbà, a ní láti kọ́kọ́ mú un dá a lójú pé Bíbélì jẹ́ òtítọ́. Ìyẹn sì gba pé kí á ka ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún un ká sì ṣàlàyé wọn.
Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Lọ́wọ́ Láti Lóye Àpèjúwe
15, 16. (a) Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ kan tí kò lóye àpèjúwe kan tí Bíbélì lò? (b) Kí la lè ṣe tí ọ̀kan nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa bá lo àpèjúwe kan tí ẹni tá a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò tètè lóye?
15 Àpèjúwe pàtó kan tí Ìwé Mímọ́ lò lè ṣàjèjì sí ẹni tí a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó lè má lóye ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ nípa gbígbé fìtílà sórí ọ̀pá fìtílà. (Máàkù 4:21, 22) Jésù ń tọ́ka sí fìtílà elépo kan láyé ìgbàanì tó ní òwú àtùpà tó ń jó. Orí ọ̀pá kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni wọ́n máa ń gbé irú fìtílà bẹ́ẹ̀ lé, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ tan ìmọ́lẹ̀ sí apá ibì kan nínú ilé náà. Ṣíṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà “Lamp” (Fìtílà) àti “Lampstand” (Ọ̀pá fìtílà) nínú irú ìtẹ̀jáde bí ìwé Insight on the Scriptures lè jẹ́ ohun tá a nílò láti jẹ́ kí àpèjúwe tí Jésù ṣe yẹn yé e yékéyéké.a Á mà dára gan-an o, kéèyàn múrà sílẹ̀ dáadáa kó sì ṣe àlàyé tí akẹ́kọ̀ọ́ náà máa lóye tá a sì mọrírì rẹ̀!
16 Ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè lo àpèjúwe tó ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti lóye. Rí i pé o ṣàlàyé rẹ̀ dáadáa, tàbí kó o lo àpèjúwe mìíràn tó máa mú kókó kan náà yẹn jáde. Ìtẹ̀jáde kan lè máa ṣàlàyé pé níní ọkọ tàbí aya rere àti ìsapá táwọn méjèèjì pawọ́ pọ̀ ṣe jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì gan-an nínú ìgbéyàwó. Láti ṣàpèjúwe èyí, a lè tọ́ka sí ọkùnrin kan tó jáwọ́ kúrò lára okùn tó dìrọ̀ mọ́, tó sì retí pé kí ẹni tí wọ́n jọ ń ṣe eré ìdárayá náà di òun mú kí òun má bàa já bọ́. Lọ́nà mìíràn, a tún lè ṣàpèjúwe bí ẹnì kejì rere àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ti ṣe pàtàkì tó nípa wíwo ọ̀nà tí òṣìṣẹ́ kan ń gbà ju ẹrù sí ẹnì kejì rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń já ẹrù látinú ọkọ̀ ojú omi.
17. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látọ̀dọ̀ Jésù tó bá kan ọ̀ràn àpèjúwe?
17 Lílo àpèjúwe mìíràn lè gba pé ká múra sílẹ̀ dáadáa. Síbẹ̀ ìyẹn jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a ní ire ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ́kàn. Jésù lo àwọn àpèjúwe tó rọrùn láti jẹ́ káwọn èèyàn lóye àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó le. Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè fì àwọn àpẹẹrẹ èyí hàn, Bíbélì sì fi hàn pe àwọn ohun tó fi kọ́ni ní ipa tó dára lórí àwọn olùgbọ́ rẹ̀. (Mátíù 5:1–7:29) Jésù fi sùúrù ṣàlàyé àwọn nǹkan nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn.—Mátíù 16:5-12.
18. Kí ni a gbà wà níyànjú láti ṣe nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa?
18 Ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ẹlòmíràn yóò sún wa láti bá àwọn èèyàn “fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́.” (Ìṣe 17:2, 3) Èyí gba pé kéèyàn máa kẹ́kọ̀ọ́ tàdúràtàdúrà kó sì fi ọgbọ́n lo àwọn ìtẹ̀jáde tí “olùṣòtítọ́ ìríjú” náà pèsè. (Lúùkù 12:42-44) Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó pọ̀ gan-an.b Ńṣe la wulẹ̀ tọ́ka sí àwọn kan lára wọn kí ìwé náà má bàa kún jù. Ó ṣe pàtàkì láti ka díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí wọ̀nyí nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì ṣàlàyé wọn. Ó ṣe tán, orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn dá lé, ó sì ní agbára púpọ̀. (Hébérù 4:12) Tọ́ka sí Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, kó o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àwọn ìpínrọ̀ náà. Ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti rí ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó kan tàbí nípa ìwà kan. Gbìyànjú láti jẹ́ kó mọ bó ṣe máa jàǹfààní látinú ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run.—Aísáyà 48:17, 18.
Béèrè Àwọn Ìbéèrè Amúnironújinlẹ̀
19, 20. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká lo àwọn ìbéèrè tá a fi ń mọ èrò ẹni nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan? (b) Kí la lè ṣe bí kókó kan pàtó bá wà tó yẹ ká túbọ̀ gbé yẹ̀ wò?
19 Ọ̀nà tí Jésù gbà lo àwọn ìbéèrè mú kí àwọn èèyàn ronú jinlẹ̀ gan-an. (Mátíù 17:24-27) Tá a bá béèrè àwọn ìbéèrè tá a fi ń mọ èrò ẹni, èyí tí kò kó ìtìjú bá ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, àwọn ìdáhùn rẹ̀ lè jẹ́ ká mọ èrò rẹ̀ nípa kókó kan pàtó. A lè wá rí i pé ó ṣì gba àwọn ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu gbọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó lè gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́. Orí kẹta ìwé Ìmọ̀ fi hàn kedere pé ọ̀rọ̀ náà “Mẹ́talọ́kan” kò sí nínú Bíbélì. Ìwé náà fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, ó sì tọ́ka sí àwọn ẹsẹ kan tó fi hàn pé Jèhófà yàtọ̀ sí Jésù àti pé agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni ẹ̀mí mímọ́, kì í ṣe ènìyàn. Kíka àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí àti ṣíṣe àlàyé wọn lè yanjú ìṣòro náà. Àmọ́ tó bá gba pé ká ṣe àlàyé jù bẹ́ẹ̀ lọ ńkọ́? Bóyá lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá parí ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ máa ṣe tẹ̀ lé èyí, ó lè fi àkókò díẹ̀ jíròrò kókó yìí bó ṣe wà nínú ìtẹ̀jáde mìíràn tó jẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, irú bí ìwé pẹlẹbẹ Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? Lẹ́yìn ìyẹn, a lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ nínú ìwé Ìmọ̀.
20 Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá dáhùn ìbéèrè kan tá a fẹ́ fi mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ lọ́nà tó yà wá lẹ́nu tàbí kó tiẹ̀ sọ nǹkan tá ò ronú pé ó yẹ kó sọ. Bí ó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹlẹgẹ́ bíi sìgá mímu tàbí kókó mìíràn, a lè dábàá pé ká máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ ná ká sì jíròrò ọ̀ràn náà nígbà tó bá yá. Mímọ̀ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣì ń mu sìgá yóò ràn wá lọ́wọ́ láti wá àwọn ìsọfúnni tá a ti tẹ̀ jáde tó lè ràn án lọ́wọ́ láti tẹ́ síwájú nípa tẹ̀mí. Bá a ṣe ń sapá láti dé inú ọkàn akẹ́kọ̀ọ́ náà, a lè máa gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí.
21. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá mú ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ bá ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nílò mu?
21 Pẹ̀lú ìmúrasílẹ̀ dáadáa àti ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó dájú pé yóò ṣeé ṣe fún wa láti mú ọ̀nà tá a gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ bá ohun tí ẹni tá a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílò mú. Bí àkókò ti ń lọ, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ràn án lọ́wọ́ kí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run lè túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. A tún lè ṣàṣeyọrí nínú jíjẹ́ kó máa bọ̀wọ̀ fún ètò àjọ Jèhófà kó sì mọrírì rẹ̀. Ẹ sì wo bó ṣe máa ń mórí ẹni wú tó nígbà tí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá gbà pé ‘Ọlọ́run wà láàárín wa ní ti tòótọ́’! (1 Kọ́ríńtì 14:24, 25) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́, ká sì ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.
Ìṣúra Kan Tá A Gbọ́dọ̀ Ṣìkẹ́
22, 23. Kí ni ohun tá a nílò tá a bá fẹ́ ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún?
22 Tá a bá fẹ́ ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún, a gbọ́dọ̀ gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ ẹni àmì òróró bíi tirẹ̀ pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe, kí agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má sì jẹ́ èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.”—2 Kọ́ríńtì 4:7.
23 Yálà a jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí a wà lára “àwọn àgùntàn mìíràn,” ńṣe la dà bí ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe. (Jòhánù 10:16) Síbẹ̀, Jèhófà lè fún wa ní okun tá a nílò láti ṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ láìfi ìṣòro tá a lè ní pè. (Jòhánù 16:13; Fílípì 4:13) Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tọkàntọkàn, ká mọrírì ìṣúra ìṣẹ́ ìsìn wa, ká sì ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún?
• Báwo lá ṣe lè mú kí ọ̀nà gbígbésẹ́ tá a gbà ń dárí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé sunwọ̀n sí i?
• Kí lo máa ṣe bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan kò bá lóye àpèjúwe kan tàbí tó bá nílò ìsọfúnni síwájú sí i lórí kókó kan pàtó?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn Kristẹni alàgbà ń kọ́ni nínú ìjọ, wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́nà tó gbéṣẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà mú kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn