ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 4/1 ojú ìwé 9-14
  • Kọ Ẹ̀mí Ayé Tó Ń yí Padà Yìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ Ẹ̀mí Ayé Tó Ń yí Padà Yìí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwà Ọmọlúwàbí Ń Pòórá
  • ‘Má Ṣe Sú Lọ’
  • Ẹ̀mí Ayé Lágbára
  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Lágbára Ju Ẹ̀mí Ayé Lọ
  • Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Kó O Gbà, Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìwọ Ha Ń Gbéjàko Ẹ̀mí Ayé Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Má Ṣe Fàyè Gba “Ẹ̀mí Ayé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 4/1 ojú ìwé 9-14

Kọ Ẹ̀mí Ayé Tó Ń yí Padà Yìí

“Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”—1 Kọ́ríńtì 2:12.

1. Àwọn ọ̀nà wo la gbà tan Éfà jẹ?

“EJÒ—òun ni ó tàn mí.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:13) Pẹ̀lú gbólóhùn yẹn, Éfà, obìnrin àkọ́kọ́ náà gbìyànjú láti ṣàlàyé ohun tó mú kó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run. Òótọ́ ló sọ, àmọ́ ìyẹn ò dá ìwà àìtọ́ tó hù láre. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “[Éfà] ni a tàn jẹ pátápátá.” (1 Tím. 2:14) A tàn án jẹ́ pé ṣíṣàìgbọràn, ìyẹn jíjẹ èso tá a kà léèwọ̀, yóò ṣe é láǹfààní yóò sì mú kó dà bí Ọlọ́run. A tún tàn án jẹ ní ti pé kò mọ ẹni náà gan-an tó ṣi òun lọ́nà. Kò mọ̀ pé Sátánì kàn lo ejò náà bí agbẹnusọ ni.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.

2. (a) Ọ̀nà wo ni Sátánì ń gbà ṣi àwọn èèyàn lọ́nà lónìí? (b) Kí ni “ẹ̀mí ayé,” àwọn ìbéèrè wo la ó sì gbé yẹ̀ wò báyìí?

2 Láti ayé Ádámù àti Éfà, Sátánì kò tíì dáwọ́ dúró láti máa tan àwọn èèyàn jẹ. Ká sòótọ́, ‘gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá ló ń ṣì lọ́nà.’ (Ìṣípayá 12:9) Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tó ń lò kò sì tíì yí padà o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lo ejò gidi mọ́, ó ṣì ń bá a nìṣó láti máa fi irú ẹni tó jẹ́ gan-an pa mọ́. Sátánì ń lo eré ìnàjú, ilé iṣẹ́ ìròyìn àtàwọn ọ̀nà mìíràn láti fi mú kí àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé wọn ò nílò ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ tó ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti pé kò ṣe wọ́n láǹfààní kankan. Ìtànjẹ Èṣù tó ń bá a nìṣó yìí ti mú káwọn èèyàn níbi gbogbo dẹni tó ń ṣọ̀tẹ̀ sáwọn òfin Bíbélì àtàwọn ìlànà rẹ̀. Ẹ̀mí ìṣọ̀tẹ̀ yìí ni Bíbélì pè ní “ẹ̀mí ayé.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Ẹ̀mí yìí ń nípa gidigidi lórí ìgbàgbọ́, ìwà àti ìṣe àwọn tí kò mọ Ọlọ́run. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn ń gbà fi ẹ̀mí yìí hàn, báwo la sì ṣe lè yẹra fún un kó má ràn wá? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

Ìwà Ọmọlúwàbí Ń Pòórá

3. Kí ló mú kí “ẹ̀mí ayé” túbọ̀ fara hàn gan-an lóde òní?

3 Lóde òní, “ẹ̀mí ayé” ti túbọ̀ ń fara hàn gan-an. (2 Tímótì 3:1-5) Ó ṣeé ṣe kó o ti ṣàkíyèsí pé ìwà ọmọlúwàbí ń pòórá. Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tá a fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ lọ́dún 1914, ogun bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run. A ṣẹ́gun Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì a sì fi wọ́n sọ̀kò sí àgbègbè ilẹ̀ ayé. Sátánì wá fi ìbínú ńlá jára mọ́ ìsapá rẹ̀ láti máa tan àwọn èèyàn jẹ yíká ayé. (Ìṣípayá 12:1-9, 12, 17) Gbogbo ọ̀nà ló fi ń gbìyànjú “láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, bí ó bá ṣeé ṣe.” (Mátíù 24:24) Àwa tá a jẹ́ èèyàn Ọlọ́run gan-an ló dájú sọ. Ó ń gbìyànjú gidigidi láti ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́ ká lè pàdánù ojú rere Jèhófà àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.

4. Ojú wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà fi ń wo Bíbélì, ojú wo sì ni ayé fi ń wò ó?

4 Sátánì ń gbìyànjú láti sọ Bíbélì, ìwé ṣíṣeyebíye tó ń kọ́ wa nípa Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, di ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Bíbélì, ohun ìṣúra ni wọ́n sì kà á sí. A mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tóun fúnra rẹ̀ mí sí ni, kì í ṣe ọ̀rọ̀ èèyàn. (1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Tímótì 3:16) Àmọ́, ayé Sátánì kò ní fẹ́ ká ronú lọ́nà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ àkọ́sọ inú ìwé kan tó tako Bíbélì sọ pé: “Kò sí nǹkan kan tó jẹ́ ‘mímọ́’ nípa Bíbélì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ‘ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ Kì í ṣe àwọn ẹni mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí ló kọ ọ́, bí kò ṣe àwọn àlùfáà tó ń wá agbára.” Àwọn tó bá gba irú ọ̀rọ̀ yìí gbọ́ lè tètè dẹni tí a ṣì lọ́nà, kí wọ́n máa rò pé àwọn lè sin Ọlọ́run lọ́nàkọnà tó bá ṣáà ti wù wọ́n, tàbí kí àwọn má tiẹ̀ sìn ín rárá.—Òwe 14:12.

5. (a) Kí ni òǹkọ̀wé kan sọ nípa àwọn ìsìn tí wọ́n ń lo Bíbélì? (b) Báwo làwọn èrò kan tó wọ́pọ̀ nínú ayé ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ? (Fi ohun tó wà nínú àpótí lójú ìwé tó tẹ̀ lé e kún un.)

5 Ṣíṣàtakò Bíbélì ní tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, pa pọ̀ pẹ̀lú báwọn tó sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé e ṣe ń ṣàgàbàgebè, ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máà nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn mọ́ rárá, títí kan ìsìn èyíkéyìí tó bá ń lo Bíbélì. Báwọn iléeṣẹ́ tó ń gbéròyìn jáde ṣe ń bẹnu àtẹ́ lu ìsìn làwọn ọ̀mọ̀wé náà ń kógun tì í. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo ẹ̀sìn àwọn Júù àti ẹ̀sìn Kristẹni kò dára rárá. Wọ́n ní tá a bá ní ká tiẹ̀ wo ibi tí wọ́n dára sí, wọn ò bóde mu mọ́; tá a bá tún ní ká wo ibi tí wọ́n burú sí, wọ́n jẹ́ òkú ẹ̀kọ́ tí kì í jẹ́ kéèyàn lè lo làákàyè, wọ́n sì ń dènà ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn ò tiẹ̀ wá fi ìkórìíra wọn fún ẹ̀sìn bò mọ́, ńṣe ni wọ́n ń fi ṣẹ̀sín wọn ò sì fẹ́ gbọ́ nípa rẹ̀ rárá.” Àwọn tó sábà máa ń pilẹ̀ ìkóguntì yìí làwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà, tí wọ́n ti di “olórí òfìfo nínú èrò wọn.”—Róòmù 1:20-22.

6. Irú ojú wo layé fi ń wo ìbálòpọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé kò dára?

6 Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń jìnnà sí àwọn ìlànà tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ lórí ìwà híhù. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé “ohun ìbàjẹ́” ni ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ jẹ́. (Róòmù 1:26, 27) Ó tún sọ pé àwọn tí wọ́n ń ṣe àgbèrè àti panṣágà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 6:9) Síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kì í ṣe pé wọ́n ka irú àwọn ìbálòpọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ohun tó bójú mu nìkan ni, wọ́n tún máa ń pọ́n wọn lé nínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, orin, sinimá àti lórí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn tó bá wá sọ pé irú àṣà bẹ́ẹ̀ kò dára, ńṣe ni wọ́n máa kà wọ́n sí àwọn tí tiwọn ti le jù, tí wọ́n máa ń fúnka mọ́ nǹkan, tí wọn ò sì lajú. Dípò kí aráyé rí àwọn ìlànà Ọlọ́run pé ó jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ó bìkítà nípa wa, ojú pé àwọn ìlànà náà kò jẹ́ káwọn gbádùn òmìnira àwọn àti ìgbésí ayé àwọn ni wọ́n fi ń wò ó.—Òwe 17:15; Júdà 4.

7. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

7 Nínú ayé tí ṣíṣe àtakò sí Ọlọ́run túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i yìí, yóò dára ká máa gbé ìṣesí wa àtàwọn ìlànà tí à ń tẹ̀ lé yẹ̀ wò. Látìgbàdégbà, ó yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò ara wa tàdúràtàdúrà láìtan ara wa jẹ láti lè rí i dájú pé a kò bẹ̀rẹ̀ sí í sú lọ díẹ̀díẹ̀ kúrò nínú ìrònú àtàwọn ìlànà Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a lè bi ara wa pé: ‘Ṣé àwọn nǹkan tó jẹ́ pé lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn mi ò jẹ́ gbà láyè rárá ò ti máa gbádùn mọ́ mi nísinsìnyí? Ṣé mi ò ti máa ka àwọn àṣà tí Ọlọ́run dá lẹ́bi sóhun tí ò fi bẹ́ẹ̀ burú mọ́? Ṣé mi ò ti máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn nǹkan tẹ̀mí, èyí tí mi ò jẹ́ ṣe láwọn ìgbà kan? Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé ire Ìjọba Ọlọ́run ni mò ń fi sípò àkọ́kọ́?’ (Mátíù 6:33) Irú àwọn àyẹ̀wò báwọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dènà ẹ̀mí ayé.

‘Má Ṣe Sú Lọ’

8. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè sú lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà?

8 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó sọ pé: “Ó . . . pọndandan fún wa láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, kí a má bàa sú lọ láé.” (Hébérù 2:1) Ọkọ̀ òkun tó bá sú lọ kúrò ní ipa ọ̀nà rẹ̀ kò lè dé èbúté. Bí ọ̀gákọ̀ kan kò bá fiyè sí afẹ́fẹ́ àti ìgbì omi, díẹ̀díẹ̀, ọkọ̀ rẹ̀ lè sú lọ kúrò ní ọ̀nà èbúté tí kò léwu kó sì lọ rì sí etídò tó jẹ́ kìkì àpáta. Lọ́nà kan náà, bá ò bá fọkàn sí àwọn òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè sú lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà ká tó mọ̀, kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa sì rì. Ká má rò pé àfi tá a bá kọ òtítọ́ sílẹ̀ nìkan ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tó lè ṣẹlẹ̀ o. Ká sòótọ́, kò wọ́pọ̀ káwọn èèyàn kàn ṣàdéédéé kọ Jèhófà sílẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n máa ń tara bọ nǹkan tí kò ní jẹ́ kí wọ́n pọkàn pọ̀ mọ́ sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé láìfura ni wọ́n máa ń sú lọ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Bí ọ̀gákọ̀ tí oorun gbé lọ, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í ta jí títí dìgbà táá fi pẹ́ jù.

9. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bù kún Sólómọ́nì?

9 Gbé ìgbésí ayé Sólómọ́nì yẹ̀ wò. Òun ni Jèhófà gbé ìjọba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lé lọ́wọ́. Ọlọ́run fún Sólómọ́nì láyè láti kọ́ tẹ́ńpìlì ó sì darí rẹ̀ láti kọ àwọn apá kan nínú Bíbélì. Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà bá a sọ̀rọ̀ ó sì fún un ní ọlá àti ọlà, òkìkí àti ìṣàkóso alálàáfíà. Paríparí rẹ̀ wá ni pé, Jèhófà fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n tó ga. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run . . . ń bá a lọ láti fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi àti fífẹ̀ ọkàn-àyà, bí iyanrìn tí ó wà ní etíkun. Ọgbọ́n Sólómọ́nì sì pọ̀ jaburata ju ọgbọ́n gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn àti ju gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.” (1 Ọba 4:21, 29, 30; 11:9) Dájúdájú, àwọn kan lè rò pé, bí ẹnì kan bá wà tó yẹ kó jẹ́ adúró ṣinṣin sí Ọlọ́run láìyẹsẹ̀, Sólómọ́nì ni. Síbẹ̀, Sólómọ́nì sú lọ, o sí dì apẹ̀yìndà. Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀?

10. Ìtọ́sọ́nà wo ni Sólómọ́nì kọ̀ láti ṣègbọràn sí, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?

10 Sólómọ́nì mọ tinú-tòde Òfin Ọlọ́run ó sì yé e yékéyéké. Kò sí àní-àní pé yóò ti nífẹ̀ẹ́ gan-an sí àwọn ìtọ́ni tá a là lẹ́sẹẹsẹ fún àwọn tó bá di ọba ní Ísírẹ́lì. Ọ̀kan lára àwọn ìtọ́ni wọ̀nyẹn ni èyí tó sọ pé: “[Ọba] kò sì gbọ́dọ̀ sọ aya di púpọ̀ fún ara rẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa yà kúrò.” (Diutarónómì 17:14, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtọ́ni yìí ṣe kedere, Sólómọ́nì fẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ìyàwó àti ọ̀ọ́dúnrún wáhàrì. Ọlọ́run àjèjì lọ̀pọ̀ nínú àwọn obìnrin wọ̀nyí ń jọ́sìn. A ò mọ̀dí tí Sólómọ́nì fi kó ìyàwó tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ jọ, bẹ́ẹ̀ la ò sì mọ ohun tó fi ń dá ara rẹ̀ láre. Ohun tá a mọ̀ ni pé ó kọ̀ láti ṣègbọràn sí ìtọ́ni Ọlọ́run tó ṣe kedere. Ohun tí Jèhófà sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ ló sì ṣẹlẹ̀. A kà á pé: “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn aya [Sólómọ́nì] tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.” (1 Ọba 11:3, 4) Ní “kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀,” ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún un lọ tán pátápátá. Sólómọ́nì dẹni tó sú lọ. Bí àkókò ti ń lọ, ìfẹ́ ọkàn Sólómọ́nì láti tẹ́ àwọn aya rẹ̀ abọ̀rìṣà lọ́rùn gba ipò ìfẹ́ rẹ̀ láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti láti múnú rẹ̀ dùn. Ẹ ò rí i pé ohun ìbànújẹ́ gbáà lèyí, torí pé Sólómọ́nì yìí kan náà lẹ́ni tó kọ̀wé níṣàájú pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì!”—Òwe 27:11.

Ẹ̀mí Ayé Lágbára

11. Báwo ni ohun tí à ń gbà sínú ọpọlọ wa ṣe ń nípa lórí ìrònú wa?

11 Àpẹẹrẹ Sólómọ́nì kọ́ wa pé ó léwu láti máa rò pé àwọn ọ̀nà ayé kò lè nípa lórí ìrònú wa torí pé a ti mọ òtítọ́. Bí oúnjẹ tá a ń jẹ ṣe ń nípa lórí ara wa, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ohun tá à ń gbà sí ọpọlọ ṣe dà bí oúnjẹ tí wọ́n sì ń nípa lórí ìrònú wa. Ohun tá a ń gbà sínú ọpọlọ ń nípa lórí bá a ṣe ń ronú àti lórí ìṣesí wa. Àwọn ọlọ́jà mọ èyí, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ná ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó lọ́dọọdún láti polówó àwọn ohun tí wọ́n ń mú jáde. Ọ̀rọ̀ àti àwòrán tó máa fa àwọn òǹrajà mọ́ra ni wọ́n máa ń lò nínú àwọn ìpolówó ọjà tó gbéṣẹ́. Àwọn olùpolówó ọjà tún mọ̀ pé rírí ìpolówó ọjà lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì kì í fi bẹ́ẹ̀ sún àwọn èèyàn láti yára lọ ra nǹkan náà. Àmọ́, bí àwọn òǹrajà bá ti ń rí i léraléra, èyí sábà máa ń mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo nǹkan náà bí ohun tó dára. Ìpolówó ọjà máa ń ṣiṣẹ́—bíi bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sẹ́ni tí yóò máa da owó sórí rẹ̀. Ó máa ń nípa lórí ìrònú àti ìṣesí àwọn aráàlú gan-an.

12. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń nípa lórí ìrònú àwọn èèyàn? (b) Kí ló fi hàn pé ó tún lè nípa lórí àwọn Kristẹni pẹ̀lú?

12 Bíi ti olùpolówó ọjà kan, Sátánì máa ń gbé àwọn èrò rẹ̀ lárugẹ nípa jíjẹ́ kí wọ́n fara hàn lọ́nà tó máa fani mọ́ra, ní mímọ̀ pé nígbà tó bá yá òun lè yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà kí wọ́n máa ronú bí òun ṣe ń ronú. Nípasẹ̀ eré ìnàjú àtàwọn nǹkan mìíràn, Sátánì ń tan àwọn èèyàn láti mú wọn gbà gbọ́ pé ohun tó dára burú àti pé ohun tó burú dára. (Aísáyà 5:20) Kódà, àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ pàápàá ti jìn sọ́fìn ẹ̀tàn Sátánì, tó ń tàn kálẹ̀. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Àsọjáde onímìísí sọ ní pàtó pé ní ìkẹyìn àwọn sáà àkókò, àwọn kan yóò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù, nípasẹ̀ àgàbàgebè àwọn ènìyàn tí ń purọ́, àwọn tí a ti sàmì sí inú ẹ̀rí-ọkàn wọn gẹ́gẹ́ bí pé pẹ̀lú irin ìsàmì.”—1 Tímótì 4:1, 2; Jeremáyà 6:15.

13. Àwọn nǹkan wo ló lè jẹ́ ẹgbẹ́ búburú, báwo sì làwọn tí à ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe ń nípa lórí wa?

13 Kò sẹ́nì kankan nínú wa tí ẹ̀mí ayé ò lè ràn. Ipa tí ètò àwọn nǹkan Sátánì àti àrékérekè rẹ̀ ń ní lágbára. Bíbélì fún wa nímọ̀ràn ọlọ́gbọ́n pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ẹgbẹ́ búburú lè jẹ́ ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni tó ń fi ẹ̀mí ayé hàn—kódà nínú ìjọ pàápàá. Bá a bá ní láti rò pé ẹgbẹ́ búburú ò lè ṣe wá ní nǹkan kan, ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tá a wá ń sọ ni pé bíbá àwọn èèyàn rere kẹ́gbẹ́ ò lè ràn wá lọ́wọ́? Àṣìṣe gbáà nìyẹn á mà jẹ́ o! Bíbélì ṣàlàyé kókó yìí ní kedere nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.

14. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà dènà ẹ̀mí ayé?

14 Láti lè dènà ẹ̀mí ayé, a gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ọlọ́gbọ́n èèyàn kẹ́gbẹ́, ìyẹn àwọn tó ń sin Jèhófà. A gbọ́dọ̀ máa fi àwọn nǹkan tó máa gbé ìgbàgbọ́ wa ró kúnnú ọkàn wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” (Fílípì 4:8) Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ẹ̀dá tó lómìnira, a lè ṣàṣàyàn àwọn ohun tá o máa gbé yẹ̀ wò. Àwọn ohun tó máa mú wa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ni kẹ́ ẹ jẹ́ ká máa yàn nígbà gbogbo.

Ẹ̀mí Ọlọ́run Lágbára Ju Ẹ̀mí Ayé Lọ

15. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì ìgbàanì fi yàtọ̀ sáwọn èèyàn yòókù ní ìlú yẹn?

15 Àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sáwọn tí ẹ̀mí ayé ń darí, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń darí wọn. Ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì ni Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí nígbà tó sọ pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ayé ni àwa gbà, bí kò ṣe ẹ̀mí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, kí àwa bàa lè mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti fi fún wa pẹ̀lú inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 2:12) Ìlú tí ẹ̀mí ayé rin gbingbin ni ìlú Kọ́ríńtì ìgbàanì. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ibẹ̀ ya oníṣekúṣe débi pé, gbólóhùn náà, “láti ṣe ìṣe àwọn ará Kọ́ríńtì” wá di ohun tó túmọ̀ sí “láti jẹ́ oníṣekúṣe èèyàn.” Sátánì ti fọ́ èrò inú àwọn èèyàn náà lójú. Nípa bẹ́ẹ̀, òye wọn nípa Ọlọ́run òtítọ́ kò tó nǹkan tàbí kí wọ́n máa tiẹ̀ ní òye kankan nípa rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Síbẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Jèhófà la àwọn kan lára àwọn ará Kọ́ríńtì lójú, ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìmọ̀ òtítọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ sún wọn ó sì darí wọn láti ṣe àwọn ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé wọn kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ àti ìbùkún rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀mí ayé lágbára nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ẹ̀mí Jèhófà lágbára jù ú lọ.

16. Báwo la ṣe lè rí ẹ̀mí Ọlọ́run gbà kó má sì fi wá sílẹ̀?

16 Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lohun tó lágbára jù lọ láyé àti lọ́run, gbogbo àwọn tó bá sì fi ìgbàgbọ́ béèrè fún un ló ń fún lọ́fẹ̀ẹ́ àti lọ́pọ̀ yanturu. (Lúùkù 11:13) Ká tó lè ní ẹ̀mí Ọlọ́run, ohun tí a óò ṣe ju dídènà ẹ̀mí ayé lọ. A tún gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé ká sì máa fi sílò nínú ìgbésí ayé wa kí ẹ̀mí wa—ìyẹn ọ̀nà tí à ń gbà ronú—lè bá tirẹ̀ mu. Bá a bá ṣe èyí, Jèhófà yóò fún wa lókun láti lè dènà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ èyíkéyìí tí Sátánì bá fẹ́ lò láti fi ba ipò tẹ̀mí wa jẹ́.

17. Àwọn ọ̀nà wo ni ìrírí Lọ́ọ̀tì lè gbà fi wá lọ́kàn balẹ̀?

17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kì í ṣe apá kan ayé, inú ayé ni wọ́n ń gbé. (Jòhánù 17:11, 16) Kò sí bí ẹnikẹ́ni nínú wa ṣe lè sá fún ẹ̀mí ayé tán pátápátá, nítorí ó lè jẹ́ pé àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tàbí àwọn ọ̀nà rẹ̀ la jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí kó jẹ́ pé àwọn la tiẹ̀ ń bá gbé pàápàá. Ṣé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára Lọ́ọ̀tì ló rí lára àwa náà, ẹni tí ìwàkiwà àwọn èèyàn Sódómù tó ń gbé láàárín wọn ń “kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi”? (2 Pétérù 2:7, 8) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀. Jèhófà pa Lọ́ọ̀tì mọ́ ó sì gbà á, ó sì lè ṣe bákan náà fún wa. Baba wa onífẹ̀ẹ́ rí ipò wa ó sì mọ̀ ọ́n, ó sì lè fún wa ní ìrànlọ́wọ́ àti okun tá a nílò ká lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí. (Sáàmù 33:18, 19) Bá a bá gbára lé e, tá a fọkàn tán an, tá a tún ń ké pè é, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lè dènà ẹ̀mí ayé, bó ti wù kí ipò wa le tó.—Aísáyà 41:10.

18. Kí nídìí tó fi yẹ ká mọrírì àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà?

18 Nínú ayé tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tí Sátánì sì ti tàn jẹ yìí, a ti fi ìmọ̀ òtítọ́ bù kún àwa tá a jẹ́ èèyàn Jèhófà. Èyí ń jẹ́ ká ní ayọ̀ àti àlááfíà tí ayé kò ní. (Aísáyà 57:20, 21; Gálátíà 5:22) Ìrètí àgbàyanu ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè, níbi tí kò ti ní sí ẹ̀mí ayé tó ń kú lọ yìí mọ́, ń múnú wa dùn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká mọrírì àjọṣe ṣíṣeyebíye tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run ká sì wà lójúfò láti ṣàtúnṣe èrò èyíkéyìí tó bá lè mú wa sú lọ nípa tẹ̀mí. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà sí i, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti dènà ẹ̀mí ayé.—Jákọ́bù 4:7, 8.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Sátánì ti gbà tan àwọn èèyàn jẹ tó sì ti ṣì wọ́n lọ́nà?

• Báwo la ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tó sú lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà?

• Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí ayé lágbára?

• Báwo la ṣe lè rí ẹ̀mí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbà kó má sì fi wá sílẹ̀?

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 11]

ỌGBỌ́N AYÉ ÀTI ỌGBỌ́N ỌLỌ́RUN

Ohunkóhun lè jẹ́ òtítọ́, kálukú ló sì ní ohun tó kà sí òtítọ́.

“Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].”—Jòhánù 17:17.

Láti mọ ohun tó tọ́ tàbí ohun tí kò tọ́, ṣáà tẹ̀ lé ohun tọ́kàn rẹ bá ti sọ.

“Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè juohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.”—Jeremiah 17:9.

Ṣe ohunkóhun tó bá ti wù ọ́.

“Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremiah 10:23.

Ọrọ̀ ló ń fúnni láyọ̀.

“Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo.”—1 Timothy 6:10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Sólómọ́nì sú lọ kúrò nínú ìjọsin tòótọ́ ó sì lọ ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Bí olùpolówó ọjà kan, Sátánì ń gbé ẹ̀mí ayé lárugẹ. Ṣé ò ń yẹra fún ẹ̀mí yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́