ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 5/1 ojú ìwé 3-5
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Àlùfáà Máa Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Àlùfáà Máa Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Aṣáájú Ìsìn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ sí Lọ́wọ́ sí Ìṣèlú
  • Bí Ìṣèlú Ṣe Nípa Lórí Àwọn Oníwàásù
  • Ṣé Ó Yẹ Káwọn Ẹlẹ́sìn Lọ́wọ́ sí Òṣèlú?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ǹjẹ́ Àwọn Tó Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Martin Luther—Ogún Tó Fi Sílẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ǹjẹ́ Àìdá-sí-ìṣèlú Dí Ìfẹ́ Kristẹni Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 5/1 ojú ìwé 3-5

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Àlùfáà Máa Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?

“BÍṢỌ́Ọ̀BÙ àgbà kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà sọ fún àwọn arìnrìn-àjò ìsìn pé, kíkópa nínú ìṣèlú á jẹ́ ká lè ṣèrànwọ́ fáwọn tálákà . . . Kódà bó bá tiẹ̀ jọ pé ètò ìṣèlú ò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ‘ó yẹ ká lọ́wọ́ sí i láti lè bá àwọn tálákà kọ ìyà.’”—Catholic News.

Báwọn olórí ìsìn ṣe máa ń sọ pé kò sóhun tó burú nínú lílọ́wọ́ sí ìṣèlú kì í ṣohun tuntun; bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣohun àjèjì pé àwọn aṣáájú ìsìn ń tẹ́wọ́ gba ipò òṣèlú. Àwọn kan ti gbìyànjú láti fọ ìṣèlú mọ́. Bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ń kan sáárá sáwọn kan tí wọ́n sì ń rántí wọn fún ìpolongo tí wọ́n ṣe nípa pé ẹ̀yà kan ò ga jù kan lọ àti mímú ìfiniṣẹrú kúrò.

Àmọ́ ṣá o, inú ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ kì í dùn nígbà táwọn oníwàásù wọn bá ń dá sí ọ̀ràn ìṣèlú. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Christian Century, sọ pé: “Nígbà mìíràn, àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì gan-an ló ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn àlùfáà wọn pé wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ti ìlú. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìsìn gbà pé ohun mímọ́ ni ẹ̀sìn àti pé àwọn ẹlẹ́sìn kò gbọ́dọ̀ dá sí ìṣèlú.

Èyí wá gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì kan dìde, tó ń dààmú gbogbo ẹni tó fẹ́ kí ayé yìí dára ju bó ṣe wà yìí lọ. Ǹjẹ́ àwọn oníwàásù ẹ̀sìn Kristẹni lè fọ ìṣèlú mọ́?a Ǹjẹ́ kíkópa nínú ìṣèlú ni ọ̀nà tí Ọlọ́run á gbà mú ìjọba gidi àti ayé tó dára ju èyí lọ wá? Ṣé ìdí tí wọ́n fi dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ ni pé kí ó jẹ́ ọ̀nà tuntun tí wọ́n á máa gbà ṣe òṣèlú?

Bí Àwọn Aṣáájú Ìsìn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ sí Lọ́wọ́ sí Ìṣèlú

Òpìtàn Henry Chadwick sọ nínú ìwé rẹ̀, The Early Church pé, àwọn èèyàn mọ ìjọ Kristẹni ìjímìjí pé “kò sóhun tó kàn wọ́n nínú wíwá agbára nínú ayé yìí.” Wọ́n jẹ́ “àwùjọ èèyàn tí kì í dá sí ìṣèlú, tó máa ń lọ jẹ́jẹ́ wọn, tí wọn kì í sì í lọ́wọ́ sí ìjà tàbí ogun.” Ìwé kan tó ń jẹ́ A History of Christianity sọ pé: “Ohun kan wà tí gbogbo àwọn Kristẹni ìgbà yẹn gbà gbọ́, ohun náà ni pé kò sí ọ̀kankan lára wọn tó gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ipò òṣèlú . . . Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹta, ni Hippolytus ti sọ pé àṣà àwọn Kristẹni ìgbà láéláé ni pé ẹni tó bá jẹ́ adájọ́ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ kó tó lè di ọmọ ìjọ.” Àmọ́ kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí wọ́n ń fẹ́ ipò agbára bẹ̀rẹ̀ sí mú ipò iwájú nínú ọ̀pọ̀ ìjọ, wọ́n sì ń fún ara wọn láwọn oyè kàǹkà-kàǹkà. (Ìṣe 20:29, 30) Méjèèjì sì làwọn kan fẹ́ ṣe pọ̀, wọ́n fẹ́ jẹ́ olórí ìsìn wọ́n tún fẹ́ jẹ́ olóṣèlú. Ìyípadà kan tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba ilẹ̀ Róòmù túbọ̀ wá jẹ́ kí àǹfààní tí irú àwọn olórí ìsìn bẹ́ẹ̀ ń wá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́.

Lọ́dún 312 Sànmánì Tiwa, Kọnsitatáìnì tí í ṣe Olú Ọba Róòmù tó sì jẹ́ abọ̀rìṣà nífẹ̀ẹ́ láti di Kristẹni aláfẹnujẹ́. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn bíṣọ́ọ̀bù gbà láti juwọ́ sílẹ̀ fún olú ọba tó jẹ́ abọ̀rìṣà yìí nítorí àwọn àǹfààní tó gbé lé wọn lọ́wọ́. Henry Chadwick kọ̀wé pé: “Àwọn aṣáájú ìsìn túbọ̀ wá ń kópa gan-an nínú àwọn ìpinnu pàtàkì-pàtàkì tó jẹ́ ti ìṣèlú.” Ipa wo ni lílọ́wọ́ sí ìṣèlú ní lórí àwọn aṣáájú ìsìn?

Bí Ìṣèlú Ṣe Nípa Lórí Àwọn Oníwàásù

Augustine, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọmọ ìjọ Kátólíìkì kan tó gbajúmọ̀ gidi ní ọ̀rúndún karùn-ún ló ń tan èrò pé Ọlọ́run yóò lo àwọn aṣáájú ìsìn gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú kálẹ̀. Ó wòye pé lọ́jọ́ kan, ṣọ́ọ̀ṣì yóò ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè ayé yóò sì mú àlàáfíà wá fún aráyé. Àmọ́ òpìtàn H. G. Wells kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tí ìtàn ilẹ̀ Yúróòpù láti ọ̀rúndún kárùn-ún títí di ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún fi hàn ni bí gbogbo ìsapá láti rí i pé ìṣàkóso ayé ní ìtìlẹyìn Ọlọ́run ṣe já sí òtúbáńtẹ́.” Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò mú àlàáfíà wá sí ilẹ̀ Yúróòpù ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ gbogbo ayé. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀sìn Kristẹni táwọn èèyàn ti ń kà sí ohun gidi kò wá níyì kankan mọ́ lójú ọ̀pọ̀ èèyàn. Kí ló fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn ń kọ́ni ní ìsìn Kristẹni ló jẹ́ pé èrò tó dáa ni wọ́n ní lọ́kàn tí wọ́n fi ń kópa nínú ìṣèlú, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ibi. Martin Luther tó jẹ́ oníwàásù àti olùtumọ̀ Bíbélì gbajúmọ̀ gan-an nítorí ìsapá rẹ̀ láti ṣàtúnṣe sí ẹ̀sìn Kátólíìkì. Àmọ́ ṣá, bó ṣe ń fi ìgboyà ta ko àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì mú kó gbayì lọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ pé nítorí ọ̀ràn ìṣèlú làwọn ṣe ń dítẹ̀ ní tiwọn. Nígbà tí Luther náà wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ èrò tiẹ̀ jáde lórí ọ̀ràn ìṣèlú, ó tẹ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn mẹ̀kúnnù tó ń bá àwọn ọ̀tọ̀kùlú tó ń ni wọ́n lára jà ló ti kọ́kọ́ fara mọ́. Nígbà tí ìṣọ̀tẹ̀ náà wá di èyí tó mú ìwà ipá lọ́wọ́, ló bá fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú náà níṣìírí láti tẹ ọ̀tẹ̀ ọ̀hún rì. Àwọn yẹn ṣe bó ṣe sọ lóòótọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni wọ́n sì pa. Kò yani lẹ́nu pé èyí mú káwọn mẹ̀kúnnù náà kà á sí ọ̀dàlẹ̀ èèyàn. Àwòrán tí Holbein yà nígbà táwọn ọ̀tọ̀kùlú wọ̀nyẹn náà wá ń ṣọ̀tẹ̀ sí olú ọba tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, Luther tún tì wọ́n lẹ́yìn. Ká sòótọ́, àtìgbà táwọn Pùròtẹ́sítáǹtì, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wá mọ àwọn ọmọlẹ́yìn Luther sí, ti bẹ̀rẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ wọn ni wọ́n ti dá ẹgbẹ́ òṣèlú tiwọn sílẹ̀. Báwo ni agbára ṣe nípa lórí Luther? Ó sọ ọ́ dìdàkudà. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ ta ko fífipá yí àwọn oníyapa ìsìn padà, nígbà tó yá, ó sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ olóṣèlú pé kí wọ́n máa pa àwọn tí kò fara mọ́ ṣíṣe batisí fún ọmọ ọwọ́, ó ní kí wọ́n máa sun wọ́n nínú iná.

Àlùfáà John Calvin gbajúmọ̀ gan-an lórílẹ̀-èdè Geneva, àmọ́ nígbà tó yá, ó dẹni tẹ́nu ẹ̀ tólẹ̀ gan-an nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Nígbà tí Michael Servetus ṣàlàyé pé kì í ṣe inú Ìwé Mímọ́ ni ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan ti wá, Calvin lo agbára tó ní nínú ìṣèlú láti ṣètìlẹ́yìn fún pípa tí wọ́n pa Servetus, ẹni tí wọ́n dáná sun lórí òpó. Ẹ ò rí bí wọ́n ṣe yà kúrò nínú ẹ̀kọ́ Jésù lọ́nà tó burú jáì!

Bóyá àwọn èèyàn yìí gbà gbé ohun tí Bíbélì sọ ní 1 Jòhánù 5:19 pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Ṣé lóòótọ́ ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ fọ ètò ìṣèlú ayé ìgbà yẹn mọ́, àbí ìrètí kí ọwọ́ wọn lè tẹ agbára kí wọ́n sì lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tó wà nípò kàǹkà-kàǹkà ló fà wọ́n mọ́ra? Èyí ó wù ó jẹ́, ó yẹ kí wọ́n rántí ọ̀rọ̀ onímìísí tí Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Jákọ́bù mọ̀ pé ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.”—Jòhánù 17:14.

Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ gbà pé kò yẹ káwọn Kristẹni lọ́wọ́ sí ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, wọn ò fára mọ́ ṣíṣàì lọ́wọ́ sí òṣèlú, èyí tó jẹ́ ‘ṣíṣàì jẹ́ apá kan ayé’ ní ti gidi. Wọ́n ní ṣíṣàìdá sí ìṣèlú kì í jẹ́ káwọn Kristẹni lè fìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn bó ṣe yẹ. Wọ́n gbà pé ó yẹ káwọn aṣáájú ìsìn náà máa sọ èrò tiwọn jáde kí wọ́n sì máa kópa nínú gbígbógunti ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìrẹ́nijẹ. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni àìdá sí ìṣèlú tí Jésù fi kọ́ni ń ṣèdíwọ́ fún bíbìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe káwọn Kristẹni yẹra fún àwọn ọ̀ràn ìṣèlú tó ń fa ìpínyà síbẹ̀ kí wọ́n máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí tú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun tí wọ́n túmọ̀ ìṣèlú sí ni pé ó jẹ́ ìgbòkègbodò tó ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣàkóso orílẹ̀-èdè kan tàbí àgbègbè kan, pàápàá jù lọ àríyànjiyàn tàbí gbọ́nmi-si–omi-ò-to tó máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn tàbí àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú tó wà nípò tàbí àwọn tó fẹ́ kọ́wọ́ wọn tẹ ipò náà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn alákòóso, irú bí Olú Ọba Kọnsitatáìnì, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ipò ìṣèlú

[Credit Line]

Musée du Louvre, Paris

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Kí ló mú kí ìṣèlú wu àwọn aṣáájú ìsìn tó gbajúmọ̀ gan-an?

Augustine

Luther

Calvin

[Àwọn Credit Line]

Augustine: Fọ́tò ICCD; Calvin: Àwòrán tí Holbein yà, látinú ìwé The History of Protestantism (Vol. II)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́