ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 5/1 ojú ìwé 5-7
  • Ǹjẹ́ Àìdá-sí-ìṣèlú Dí Ìfẹ́ Kristẹni Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Àìdá-sí-ìṣèlú Dí Ìfẹ́ Kristẹni Lọ́wọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwàásù Ohun Tó Dára Ju Ìṣèlú Lọ
  • Ṣé Ó Yẹ Káwọn Ẹlẹ́sìn Lọ́wọ́ sí Òṣèlú?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Kí Nìdí Tí Jésù Kò Fi Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • “Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Àlùfáà Máa Lọ́wọ́ Nínú Ìṣèlú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 5/1 ojú ìwé 5-7

Ǹjẹ́ Àìdá-sí-ìṣèlú Dí Ìfẹ́ Kristẹni Lọ́wọ́

JÍJẸ́ Kristẹni ju kéèyàn kàn máa ka Bíbélì, kó máa gbàdúrà, kó sì máa kọrin ìsìn lọ́jọọjọ́ Sunday. Kristẹni ní láti máa ṣe nǹkan fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòhánù 3:18) Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lógún, àwọn Kristẹni sì fẹ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n máa ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Àmọ́ kí ni iṣẹ́ Olúwa? Ṣé ó kan gbígbìyànjú láti yí ìlànà ìjọba padà fún àǹfààní àwọn tálákà àtàwọn tí à ń ni lára? Ṣé ohun tí Jésù ṣe nìyẹn?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn rọ Jésù láti dá sí ọ̀ràn ìṣèlú tàbí kó fara mọ́ ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn, ó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Sátánì fi agbára lórí gbogbo ìjọba ayé lọ̀ ọ́, ó kọ̀ ọ́. Kò gbà kí wọ́n fa òun wọnú àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ owó orí sísan, nígbà tí ẹgbẹ́ kan tó ń jà fún ìlú sì fẹ́ fi jẹ ọba, ńṣe ló kúrò láàárín wọn. (Mátíù 4:8-10; 22:17-21; Jòhánù 6:15) Àmọ́ àìdá-sí-ìṣèlú kò dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó máa ṣàwọn èèyàn láǹfààní.

Ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní ayérayé ni Jésù gbájú mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bíbọ́ tó bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún èèyàn tó sì tún wo àwọn aláìsàn sàn mú ìtura ìgbà díẹ̀ bá àwọn kan, àwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni ló mú kí gbogbo aráyé láǹfààní àtirí ìbùkún ayérayé gbà. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “Olùkọ́” làwọn èèyàn mọ Jésù sí, kì í ṣe olùdarí ètò afẹ́dàáfẹ́re. (Mátíù 26:18; Máàkù 5:35; Jòhánù 11:28) Ó sọ pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.”—Jòhánù 18:37.

Wíwàásù Ohun Tó Dára Ju Ìṣèlú Lọ

Òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ni kì í ṣe àbá èrò orí tó dá lórí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá lórí Ìjọba tí òun fúnra rẹ̀ máa jẹ́ Ọba rẹ̀. (Lúùkù 4:43) Ọ̀run ni Ìjọba yìí yóò wà, yóò sì rọ́pò gbogbo ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mú àlàáfíà ayérayé wá fún ìran èèyàn. (Aísáyà 9:6, 7; 11:9; Dáníẹ́lì 2:44) Nípa bẹ́ẹ̀, òun ni ìrètí gidi kan ṣoṣo tó wà fún aráyé. Ǹjẹ́ pípolongo pé káwọn èèyàn nírètí nínú ohun gidi tó ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la yìí kò fìfẹ́ hàn ju rírọ̀ wọ́n láti gbójú lé èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn láti mú ọjọ́ ọ̀la afinilọ́kànbalẹ̀ wá? Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.” (Sáàmù 146:3-5) Nítorí náà dípò kí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti lọ máa wàásù nípa ọ̀nà tó sàn jù láti gbà ṣètò ìjọba, ńṣe ló kọ́ wọn láti wàásù “ìhìn rere ìjọba [Ọlọ́run].”—Mátíù 10:6, 7; 24:14.

Nítorí náà, iṣẹ́ ìwàásù yìí ni “iṣẹ́ Olúwa” tá a gbé lé àwọn Kristẹni oníwàásù lọ́wọ́. Nítorí pé ara ohun tá a béèrè lọ́wọ́ àwọn tó máa jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, yóò ṣeé ṣe fún Ìjọba yẹn láti mú òṣì kúrò nípa pínpín àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé lọ́nà yíyẹ. (Sáàmù 72:8, 12, 13) Èyí gan-an ni ìhìn rere, dájúdájú ó sì yẹ ká wáàsù rẹ̀.

Lónìí, a ṣètò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ṣíṣe “iṣẹ́ Olúwa” ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀. Níbàámu pẹ̀lú aṣẹ Jésù, gbogbo ìjọba pátá ni wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún. (Mátíù 22:21) Àmọ́ wọ́n tún máa ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé.”—Jòhánù 15:19.

Àwọn kan tí wọ́n ń gbé ìṣèlú gẹ̀gẹ̀ nígbà kan rí ti jáwọ́ ńbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fára balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tó jẹ́ olóṣèlú tó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Ajagun Ìjọ Kátólíìkì, ìyẹn ẹgbẹ́ kan tí ṣọ́ọ̀ṣì ń darí, sọ pé: “Ohun tó mú mi kara bọ ìṣèlú ni pé, mo ronú pé ó yẹ kí kálukú kó ipa tiẹ̀ nínú ìdàgbàsókè ètò ìṣèlú àti àwùjọ.” Lẹ́yìn tó kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìlú láti lè wàásù Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣàlàyé ìdí tí àkitiyan àwọn tó ń fi tinútinú ṣòṣèlú kò fi yọrí sí rere. Ó ní: “Ohun tó mú kí ayé ṣì rí bó ṣe rí yìí kì í ṣe torí pé àwọn èèyàn tí ìwà wọn dára kò gbìyànjú láti mú ipò nǹkan dára sí i láwùjọ, àmọ́ ìwà burúkú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ni kò jẹ́ kí ìsapá dáadáa àwọn èèyàn díẹ̀ náà yọ.”

Ṣíṣàìlọ́wọ́ sí ìṣèlú nítorí àtiwàásù nípa ìrètí gidi kan ṣoṣo tó wà fáráyé kò dí àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn láwọn ọ̀nà pàtàkì. Àwọn tí wọ́n ń ràn lọ́wọ́ láti di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ń kẹ́kọ̀ọ́ láti yí ìwà abèṣe tí wọ́n ti ń hù padà, láti máa bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ, láti mú kí ìdílé wọn túbọ̀ láyọ̀, àti láti má ṣe ka ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Àwọn tó ń wáàsù nípa Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe àwùjọ tí wọ́n ń gbé láǹfààní. Àmọ́ ní pàtàkì, wọ́n ń tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà láti gbọ́kàn lé ìjọba kan tó dájú, èyí tí yóò mú àlàáfíà ayérayé wá fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Nítorí pé àwọn Kristẹni wọ̀nyí kì í dá sí ìṣèlú ló jẹ́ kí wọ́n lómìnira láti pèsè ìrànwọ́ gidi táwọn èèyàn lè rí gbà lónìí, èyí tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí ayé.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Olóṣèlú Tẹ́lẹ̀ Di Oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run

Nígbà tí Átila wà lọ́mọdé, ó kọ́ ẹ̀kọ́ ìsìn tó dá lórí ìjìjàgbara lọ́dọ̀ àlùfáà ìjọ rẹ̀ ní ìlú Belém, lórílẹ̀-èdè Brazil. Ó máa ń dùn mọ́ ọn láti gbọ́ pé lọ́jọ́ kan, ìran èèyàn máa bọ́ lọ́wọ́ ìnira. Èyí mú kó lọ di ara ẹgbẹ́ kan tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, níbi tó ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣètò ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn àti ọ̀nà láti ṣàtakò sí ìjọba.

Àmọ́ ó tún máa ń dùn mọ́ Átila láti máa kọ́ ọmọ àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ yìí lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé kan tí ẹnì kan fún un, ìyẹn Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na.a Ìwé yìí kọ́ni nípa híhùwà rere àti ṣíṣègbọràn sáwọn aláṣẹ. Èyí mú kó máa ya Átila lẹ́nu bí àwọn tó sọ pé àwọn ń ti ẹ̀kọ́ ìsìn tó dá lórí ìjìjàgbara lẹ́yìn ò ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà pàtàkì tí Jésù fi lélẹ̀ nípa ìwà híhù àti bí àwọn kan ṣe máa ń gbàgbé àwọn tíyà ń jẹ nígbà tí wọ́n bá dórí àlééfà. Bó ṣe kúrò nínú ẹgbẹ́ yẹn nìyẹn. Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn ilé rẹ̀ wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì mọ ohun náà gan-an tó máa fòpin sí ìnira ẹ̀dá.

Láàárín àkókò yẹn, Átila lọ sí àpérò kan tí ìjọ Kátólíìkì ṣe èyí tó dá lórí kókó náà, ìsìn àti ìṣèlú. Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ níbẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ọmọ ìyá kan náà ni ìsìn àti ìṣèlú jẹ́.” Ó tún lọ sí ìpàdé kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìyàtọ̀ kékeré kọ́ ló rí! Kò rí ẹnì kankan tó mu sìgá, ọtí tàbí ẹni tó ṣe àwàdàkáwàdà. Ló bá pinnu láti dára pọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi. Ní báyìí, ó ti wá rí ìdí tí ẹ̀kọ́ ìsìn tó dá lórí ìjìjàgbara kì í fi ṣe ojútùú gidi sáwọn ìṣòro tó ń bá àwọn tálákà fínra.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àìdá-sí-ìṣèlú kò di àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ láti ṣèrànwọ́ fún ọmọnìkejì wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́