Ẹwà Ìṣẹ̀dá Jèhófà
“Kí Àwọn Odò Pàápàá Pàtẹ́wọ́”
ÌWỌ wo àwòrán ojú ilẹ̀ ayé kan, wàá rí àwọn ìlà tó lọ kọ́lọkọ̀lọ káàkiri ojú ilẹ̀. Àwọn ìlà kọ́lọkọ̀lọ yìí kọjá láwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, aṣálẹ̀ àti láwọn pápá. Wọ́n kọjá láwọn àfonífojì, láàárín àwọn òkè àtàwọn igbó kìjikìji. (Hábákúkù 3:9) Odò làwọn ìlà wọ̀nyí dúró fún, ohun ìgbẹ́mìíró sì ni wọ́n jẹ́ fún àwọn ẹ̀dá alààyè. Ńṣe ni irú àwọn ipa odò bẹ́ẹ̀ ń fi ọgbọ́n àti agbára Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ayé, hàn. Bá a ti ń kíyè sí wọn, àwa náà fara mọ́ ohun tí onísáàmù náà wí, ẹni tó kọrin pé: “Kí àwọn odò pàápàá pàtẹ́wọ́; àní kí gbogbo àwọn òkè ńlá lápapọ̀ fi ìdùnnú ké jáde níwájú Jèhófà.”—Sáàmù 98:8, 9.a
Kò sí bá ó ṣe sọ nípa ìtàn ẹ̀dá èèyàn tá ò ní mẹ́nu kan àwọn odò. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn odò ńlá mẹ́rin tí wọ́n ya láti ara odò ńlá kan tó ń ṣàn jáde látinú ọgbà Édẹ́nì. (Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14) Nígbà tí ọ̀làjú kọ́kọ́ dé, àwọn àfonífojì tí ilẹ̀ wọn lọ́ràá létí odò Tígírísì àti Yúfírétì ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ló ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn odò bí Odò Hwang nílẹ̀ Ṣáínà, Ganges àti Íńdọ́sì ní Gúúsù Éṣíà àti Náílì nílẹ̀ Íjíbítì ló mú kí ọ̀làjú ìgbà àtijọ́ ṣeé ṣe.
Abájọ tó fi jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni agbára táwọn odò ní, pípọ̀ tómi wọn máa ń pọ̀ yanturu àti ẹwà wọn máa ń jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún ẹ̀dá èèyàn. Odò Náílì nílẹ̀ Íjíbítì ṣàn tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje àti àádọ́rin lé lẹ́gbẹ̀ta [6,670] kìlómítà kó tó wọnú òkun. Àmọ́ tá a bá ń sọ nípa odò tó fẹ̀ jù lọ, odò Amazon tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn odò kan máa ń jọni lójú gan-an nítorí títóbi wọn, àwọn odò tí kò tóbi náà máa ń wuni gan-an, irú bí Odò Tone nílẹ̀ Japan tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi àmọ́ tó máa ń ṣàn gbùúgbùú.
Kí ló máa ń mú kí odò ṣàn? Ní kúkúrú, òòfà ni. Òòfà yìí ló máa ń fa omi tó bá wà lókè wá sísàlẹ̀. Òun náà ló ń mú kí omi máa tàkìtì sísàlẹ̀ látorí àwọn òkè tòun ti ariwo ńlá. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe bí agbára àti ọlá ńlá wọn ṣe tó, ó sọ pé: “Àwọn odò gbé e sókè, Jèhófà, àwọn odò gbé ìró wọn sókè; àwọn odò ń gbé ìró ìbìlù wọn sókè ṣáá.”—Sáàmù 93:3.
Jèhófà béèrè lọ́wọ́ Jóòbù tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run pé: “Ta ní la ipa ojú ọ̀nà fún ìkún omi?” (Jóòbù 38:25) Bẹ́ẹ̀ ni, ibo ni gbogbo àwọn omi yẹn ti ń wá? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ní í ṣe pẹ̀lú ètò dídíjú kan tá a mọ̀ sí ìyípoyípo omi. Kò sígbà kan tí àwọn omi tó wà láyé kì í sí nínú ètò ìyípoyípo yìí, èyí tí agbára látinú oòrùn àti òòfà ń mú kó ṣeé ṣe. Oòrùn máa ń fa omi lọ sókè sojú òfuurufú. Omi náà yóò wá di kùrukùru. Bí àkókò ti ń lọ, omi tó di kùrukùru náà yóò wá rọ̀ padà sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì tàbí òjò. Inú àwọn agbami òkun, adágún, odò, ìṣàn òkìtì yìnyín, àwọn omi dídì tó wà ní ìpẹ̀kun ayé àti abẹ́ ilẹ̀ ni ọ̀pọ̀ jù lọ omi yìí máa ń gbára jọ sí.
Nígbà tí Bíbélì ń sọ nípa ètò ìyípoyípo omi pípabanbarì yìí, ó sọ pé: “Gbogbo ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ti ń ṣàn jáde lọ, ibẹ̀ ni wọ́n ń padà sí, kí wọ́n bàa lè ṣàn jáde lọ.” (Oníwàásù 1:7) Àyàfi Jèhófà nìkan ṣoṣo, Ọlọ́run tí ọgbọ́n rẹ̀ kò lópin tó tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́jú wa, ló lè ṣe irú ìyípoyípo bẹ́ẹ̀. Kí sì ni iṣẹ́ ọnà olóye yìí ń sọ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́? Pé ó jẹ́ Ọlọ́run ọlọ́gbọ́n gíga àti onífẹ̀ẹ́.—Sáàmù 104:13-15, 24, 25; Òwe 3:19, 20.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òdo máa ń tóbi tí wọ́n sì pọ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ lára wọn lomi wọn ṣeé mu. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè. Ìwé náà Water [Omi] sọ pé: “Bí kò bá sí omi, tá ò sì lágbára lórí omi dé ìwọ̀n àyè kan, kò sí ohunkóhun tí ẹ̀dá èèyàn yóò lè gbé ṣe. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkọsílẹ̀ ìtàn bí ọ̀làjú ṣe bẹ̀rẹ̀ fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.”
Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún wá làwọn òdo ti ń pa òǹgbẹ ẹ̀dá èèyàn tó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí omi lò fún oko wọn. Àwọn ilẹ̀ ọlọ́ràá tó máa ń wà lẹ́bàá ọ̀pọ̀ odò dára gan-an fún iṣẹ́ ọ̀gbìn. Kíyè sí bí kókó yìí ṣe fara hàn nínú ìbùkún kan tá a ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà: “Ẹ wo bí àwọn àgọ́ rẹ ti dára tó ní ìrísí, ìwọ Jékọ́bù, àwọn ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì! Bí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, wọ́n nasẹ̀ dé ọ̀nà jíjìn, bí àwọn ọgbà lẹ́bàá odò. Bí àwọn ọ̀gbìn álóè tí Jèhófà gbìn, bí àwọn kédárì lẹ́bàá omi.” (Númérì 24:5, 6) Odò tún ń jẹ́ kí àwọn ẹranko bí akátá àti pẹ́pẹ́yẹ inú àwòrán yìí máa rí ohun tí wọ́n nílò láti wà láàyè. Ká sòótọ́, bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ̀ nípa àwọn odò sí i, bẹ́ẹ̀ la ó máa rí ìdí tó fi yẹ ká yin Jèhófà sí i.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù May àti June nínú 2004 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìtàkìtì omi tí wọ́n ń pè ní Iguaçú Falls tó wà ní ààlà àárín orílẹ̀-èdè Ajẹntínà àti Brazil wà lára àwọn ìtàkìtì omi tó fẹ̀ jù lọ. Fífẹ̀ rẹ̀ lé ní kìlómítà mẹ́ta láti ẹ̀gbẹ́ kan síkejì. Ó wà láàárín igbó ilẹ̀ olóoru mímọ́ tónítóní, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún ìtàkìtì omi kéékèèké tó pín sí. Lákòókò òjò, omi tó máa ń ya lulẹ̀ wìì-wìì-wìì ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan kúrò ní kékeré.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Odò Tone, orílẹ̀-èdè Japan