Ìṣòro Tó Wà Nínú Ọmọ Títọ́ Lóde Òní
NÍ ALẸ́ ọjọ́ kan báyìí tí onílé oúnjẹ kan ń palẹ̀ mọ́ tó ń múra láti ti ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ kó sì máa lọ sílé ni àwọn obìnrin méjì àti ọmọ kékeré kan wọlé, wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ ra oúnjẹ. Nítorí pé ó ti rẹ olóúnjẹ yìí, ó kọ́kọ́ fẹ́ sọ fún wọn pé òun ti palẹ̀ mọ́, àmọ́ ó pinnu láti ṣe oúnjẹ fún wọn. Nígbà táwọn obìnrin méjèèjì ń sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì ń jẹun, ńṣe ni ọmọ náà ń sá káàkiri ilé oúnjẹ náà, tó ń dá bisikíìtì ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ tó sì ń fi ẹsẹ̀ rún wọn mọ́lẹ̀. Dípò kí ìyá ọmọ náà bá a wí, ẹ̀rín ló ń rín. Ìgbà táwọn oníbàárà yìí kúrò nílé oúnjẹ náà tán ni ẹni tó ní ilé oúnjẹ yìí, tó ti rẹ̀ tẹnutẹnu ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí nu ilẹ̀ tí ọmọ náà dọ̀tí.
Gẹ́gẹ́ bó ti ṣeé ṣe kó o mọ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé ní ọ̀pọ̀ ìdílé, àwọn èèyàn ò tọ́ ọmọ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ mọ́. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra. Àwọn òbí kan mọ̀ọ́mọ̀ fi àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ kí wọ́n máa ṣe ohun tó wù wọ́n, lérò pé ó yẹ káwọn ọmọ ní òmìnira. Tàbí kẹ̀, nítorí pé ọwọ́ àwọn òbí máa ń dí gan-an, wọ́n lè má rí àyè láti gbọ́ ti àwọn ọmọ wọn àti láti fún wọn ní ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n fún wọn. Àwọn òbí kan rò pé ilé ẹ̀kọ́ ọmọ wọn ló ṣe pàtàkì ju ohun gbogbo lọ, nítorí náà, wọ́n ń fún àwọn ọmọ wọn ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n tí wọ́n bá sáà ti gba máàkì tó dára nílé ìwé tí wọ́n sì rí kọ́lẹ́ẹ̀jì tó gbayì láwùjọ wọ̀.
Àmọ́, àwọn kan sọ pé ó yẹ kí àwọn òbí àti àwùjọ lápapọ̀ yí ojú tí wọ́n fi ń wo ọ̀ràn náà padà. Wọ́n sọ pé àwọn ọmọ ń lọ́wọ́ sí onírúurú ìwà ọ̀daràn àti pé ojoojúmọ́ ni ìwà ipá tó ń wáyé nílé ìwé túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Abájọ tí ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ girama kan ní Seoul, orílẹ̀-èdè olómìnira ti Kòríà fi sọ pé kíkọ́ àwọn ọmọ bí wọ́n ṣe máa jẹ́ ọmọlúwàbí ló yẹ kó ṣáájú. Ó sọ pé: “Ìwà rere ló yẹ kó o kọ́kọ́ kọ́ àwọn ọmọ rẹ kó o tó o fi ìmọ̀ kún un.”
Ọ̀pọ̀ òbí tó fẹ́ kí ọmọ wọn wọ kọ́lẹ́ẹ̀jì kí wọn sì ní láárí láyé ló máa ń kọ etí ikún sí ìkìlọ̀. Tó o bá jẹ́ òbí, irú èèyàn wo lo fẹ́ kí ọmọ rẹ jẹ́? Ṣé àgbà kan tó ní ìwà rere tó sì mọ ojúṣe rẹ̀ lo fẹ́ kó jẹ́? Ṣé ẹni tó ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò, tó mọ bá a ṣe ń yíwọ́ padà, tó sì ní ẹ̀mí nǹkan yóò dára lo fẹ́ kó jẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó kàn.