ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 7/15 ojú ìwé 26-27
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ló Ń Fúnni Ní Òmìnira
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ọdún Júbílì Ṣàpẹẹrẹ Òmìnira Ọjọ́ Iwájú
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 7/15 ojú ìwé 26-27

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni ọdún Júbílì tí Ọlọ́run pa láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú Léfítíkù orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ṣàpẹẹrẹ?

Òfin Mósè là á kalẹ̀ pé “ní ọdún keje kí sábáàtì ìsinmi pátápátá wà fún ilẹ̀ náà.” Nípa ọdún náà, a pa á láṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí pápá rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ rẹ́wọ́ ọgbà àjàrà rẹ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kárúgbìn èéhù láti inú àwọn kóró dídàálẹ̀ lára ìkórè rẹ, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àkójọ èso àjàrà rẹ ti inú àjàrà tí a kò rẹ́wọ́ rẹ̀. Kí ọdún kan tí ó jẹ́ ti ìsinmi pátápátá wà fún ilẹ̀ náà.” (Léfítíkù 25:4, 5) Látàrí èyí, gbogbo ọdún keje gbọ́dọ̀ jẹ́ ọdún Sábáàtì fún ilẹ̀ náà. Gbogbo ọdún àádọ́ta, tó bá tẹ̀ lé ọdún Sábáàtì ẹlẹ́ẹ̀keje ni yóò jẹ́ Júbílì. Kí ni yóò wá ṣẹlẹ̀ lọ́dún yẹn?

Jèhófà tipasẹ̀ Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ sì sọ ọdún àádọ́ta di mímọ́, kí ẹ sì pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira ní gbogbo ilẹ̀ náà fún àwọn olùgbé rẹ̀. Yóò di Júbílì fún yín, kí ẹ sì padà, olúkúlùkù sí ohun ìní rẹ̀, kí ẹ sì padà, olúkúlùkù sínú ìdílé rẹ̀. Júbílì ni ohun tí ọdún àádọ́ta yóò dà fún yín. Ẹ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn tàbí kí ẹ kárúgbìn èéhù láti inú àwọn kóró dídàálẹ̀ tàbí kí ẹ ṣe àkójọ èso àjàrà tí ó jẹ́ ti àjàrà rẹ̀ tí a kò rẹ́wọ́ rẹ̀.” (Léfítíkù 25:10, 11) Ọdún tó bá tẹ̀ lé ọdún Sábáàtì keje ló ń jẹ́ ọdún Júbílì. Àmọ́, ọdún òmìnira ló máa ń já sí fáwọn olùgbé ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn Júù tí wọ́n bá ti tà sóko ẹrú ni wọ́n gbọ́dọ̀ dá sílẹ̀ lómìnira. Wọ́n gbọ́dọ̀ dá ohun ìní àjogúnbá tó ṣeé ṣe kí ipò nǹkan sún ẹnì kan láti tà padà fún ìdílé rẹ̀. Ọdún ìmúbọ̀sípò àti ìdáǹdè ni Ọlọ́run fẹ́ kí ọdún Júbílì jẹ́ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Àpẹẹrẹ kí ni ọdún náà jẹ́ fáwọn Kristẹni?

Ìwà ọ̀tẹ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, sọ aráyé dẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Ètò tí Ọlọ́run ṣe láti dá aráyé nídè kúrò lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni pípèsè tó pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.a (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 2:1, 2) Nígbà wo la dá àwọn Kristẹni nídè kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀? Nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù darí rẹ̀ sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó ní: “Òfin ẹ̀mí yẹn, èyí tí ń fúnni ní ìyè ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù ti dá ọ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ti ikú.” (Róòmù 8:2) Àwọn tí wọ́n ní ìrètí ìyè lókè ọ̀run gba òmìnira yìí nígbà tá a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n tí wọ́n sì jẹ́ aláìpé, Ọlọ́run polongo wọn ní olódodo ó sì sọ wọ́n di ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí. (Róòmù 3:24; 8:16, 17) Ní ti àwọn ẹni àmì òróró, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, Júbílì ti Kristẹni bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Tiwa.

Àwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? (Jòhánù 10:16) Ní ti àwọn àgùntàn mìíràn, Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi á jẹ́ ìgbà ìmúbọ̀sípò àti ìdáǹdè. Lákòókò Júbílì Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún yìí, Jésù á lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà rẹ̀ fún gbogbo aráyé tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run yóò sì mú ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ ń ní lórí aráyé kúrò. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ní ìparí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, aráyé á ti di ẹ̀dá pípé a ó sì ti dá wọn nídè pátápátá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá àti ikú. (Róòmù 8:21) Lẹ́yìn tí èyí bá ti rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Júbílì Kristẹni ti parí nìyẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jésù ni Jèhófà rán jáde “láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè.” (Aísáyà 61:1-7; Lúùkù 4:16-21) Ó kéde ìdáǹdè tẹ̀mí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àkókò ìmúbọ̀sípò àti ìdáǹdè ni Júbílì Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún yóò jẹ́ fáwọn “àgùntàn mìíràn”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́