ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 8/15 ojú ìwé 27-29
  • Ọkùnrin Onígboyà “Tó Lọ Káàkiri Nítorí Ìhìn Rere”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkùnrin Onígboyà “Tó Lọ Káàkiri Nítorí Ìhìn Rere”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì ní Èdè Manchu
  • Wọ́n Rán An Lọ sí Rọ́ṣíà
  • Ó Lọ sí Ilẹ̀ Iberia Tí Omi Fẹ́rẹ̀ẹ́ Yí Po
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Yá Owó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ija-ogun Bibeli Ledee Spanish fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe dé Orílẹ̀ èdè Sípéènì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Bí Bíbélì Ṣe Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 8/15 ojú ìwé 27-29

Ọkùnrin Onígboyà “Tó Lọ Káàkiri Nítorí Ìhìn Rere”

ÌRÒYÌN sọ pé nígbà tí George Borrow fi máa pé ọmọ ọdún méjìdínlógún, ó ti lè sọ èdè méjìlá. Ní ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn, “tìrọ̀rùntìrọ̀rùn tòun ti ẹwà èdè” ló fi túmọ̀ ìwé sí èdè ogún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ní ọdún 1833, Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Ilẹ̀ Òkèèrè ní kí ọkùnrin tó lẹ́bùn àrà ọ̀tọ̀ yìí wá sí London ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni Borrow, kò sì lówó tó máa fi wọkọ̀ lọ, àmọ́ kò fẹ́ kí àǹfààní ńláǹlà yìí bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, ló bá fẹsẹ̀ rin ọgọ́sàn-án [180] kìlómítà láti ilé rẹ̀ ní Norwich lọ sí London ní wákàtí méjìdínlọ́gbọ̀n péré.

Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì gbé iṣẹ́ kan kà á láyà, wọ́n ní kó fi oṣù mẹ́fà péré kọ èdè Manchu tí wọ́n máa ń sọ láwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Ó ní kí wọ́n fóun níwèé gírámà, àmọ́ ìwé tí wọ́n rí fún un kò ju ẹ̀dà ìwé Ìhìn Rere Mátíù lédè Manchu àti ìwé atúmọ̀ èdè Manchu sí èdè Faransé. Láàárín oṣù mẹ́rin àti ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, ó kọ̀wé sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pé, “pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, mo ti gbọ́ èdè Manchu gan-an báyìí o.” Àṣeyọrí yìí tiẹ̀ tún wá kàmàmà, nítorí wọ́n ní bó ṣe ń kọ́ èdè ọ̀hún ló tún ń ṣe àtúnṣe sí ìwé Ìhìn Rere Lúùkù ní èdè Nahuatl tó jẹ́ ọ̀kan lára èdè ìbílẹ̀ Mẹ́síkò.

Bíbélì ní Èdè Manchu

Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, ìyẹn ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ èdè Manchu sórí ìwé nípa ṣíṣe àyálò ááfábẹ́ẹ̀tì èdè Mongolian Uighur láti fi kọ ọ́, ni èdè náà ti di èdè táwọn aláṣẹ ilẹ̀ Ṣáínà ń lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tó yá, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ lo èdè náà mọ́, síbẹ̀ Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Ilẹ̀ Òkèèrè hára gàgà láti tẹ Bíbélì jáde ní èdè Manchu kí wọ́n sì pín in fáwọn èèyàn. Nígbà tó fi máa di ọdún 1822, wọ́n ti náwó nára láti tẹ àádọ́tadínlẹ́gbẹ̀ta [550] ẹ̀dà ìwé Ìhìn Rere Mátíù tí Stepan V. Lipoftsoff túmọ̀. Stepan wà lára àwọn òṣìṣẹ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà Tó Wà fún Ilẹ̀ Òkèèrè, ó sì ti lo ogún ọdún ní Ṣáínà. Ìlú St. Petersburg ní wọ́n ti tẹ àwọn ìwé Ìhìn Rere Mátíù yìí, àmọ́ wọn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ pín ẹ̀dà púpọ̀ tí àgbàrá òjò fi ba ìyókù jẹ́.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì lódindi. Rírí tí wọ́n rí ìwé àfọwọ́kọ ayé ọjọ́un ní 1834, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù sì wà nínú rẹ̀ mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Ta ló máa wá ṣe kòkárí ṣíṣe àtúnṣe sí Bíbélì Manchu tó wà lọ́wọ́, tó sì máa wá parí ìtumọ̀ àwọn apá tó kù? Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Ilẹ̀ Òkèèrè ní kí George Borrow lọ bá wọn ṣe iṣẹ́ ọ̀hún.

Wọ́n Rán An Lọ sí Rọ́ṣíà

Nígbà tí Borrow dé ìlú St. Petersburg, ó wá gbájú mọ́ kíkọ́ èdè Manchu dáadáa kó bàa lè mọ àṣìṣe tó wà nínú Bíbélì náà nígbà tó bá ń kà á, kò sí ṣe àtúnṣe tó péye sí i. Iṣẹ́ ọ̀hún gbomi gan-an, ó sì máa ń fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́tàlá ṣiṣẹ́ lóòjọ́ láti ṣe àtúntò lẹ́tà ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé tí wọ́n máa fi tẹ Májẹ̀mú Tuntun náà táwọn èèyàn wá pé ní “ìwé rírẹwà kan tí wọ́n ṣe ní ìlà oòrùn ayé.” Ẹgbẹ̀rún kan ẹ̀dà Bíbélì yìí ni wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1835. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí Borrow ni pé kí ó kó àwọn ẹ̀dà Bíbélì náà lọ sí ilẹ̀ Ṣáínà kó lè pín in fáwọn èèyàn níbẹ̀, àmọ́ wọ́n dabarú ohun tó fẹ́ ṣe yìí. Ìjọba Rọ́ṣíà ń bẹ̀rù pé àwọn èèyàn lè lọ máa rò pé pípín Bíbélì Manchu ní Ṣáínà jẹ́ ohun kan táwọn míṣọ́nnárì fẹ́ ṣe láti fi bá àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n yìí jẹ́, nítorí èyí, wọ́n ò gbà kí Borrow lọ sẹ́nu bodè ilẹ̀ Ṣáínà tí “ẹyọ Bíbélì Manchu kan” bá wà lọ́wọ́ rẹ̀.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n pín ẹ̀dà mélòó kan fáwọn èèyàn, nígbà tó sì di ọdún 1859, wọ́n túmọ̀ ìwé Ìhìn Rere Mátíù àti ti Máàkù sí èdè Manchu àti Ṣáínà. Ìwé Ìhìn Rere méjèèjì wà ní òpó ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Àmọ́ lákòókò tá à ń wí yìí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó lè ka èdè Manchu ti wá fẹ́ràn kíka èdè Ṣáínà dípò èdè Manchu, nípa bẹ́ẹ̀ odindi Bíbélì Manchu tí àwọn èèyàn ṣì fọkàn sí pé ó máa jáde tẹ́lẹ̀ kò wá jọ pé ó máa ṣeé ṣe mọ́. Èdè Manchu wá di èdè táwọn èèyàn kì í sábà sọ mọ́, kò sì pẹ́ tí èdè Ṣáínà fi rọ́pò rẹ̀. Ó rọ́pò rẹ̀ pátápátá lọ́dún 1912, ìyẹn nígbà tí orílẹ̀-èdè Ṣáínà gbòmìnira.

Ó Lọ sí Ilẹ̀ Iberia Tí Omi Fẹ́rẹ̀ẹ́ Yí Po

Àwọn nǹkan tí George Borrow ṣe wù ú lórí gan-an, ló bá padà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tó di ọdún 1835, wọ́n rán an lọ sí ilẹ̀ Potogí àti Sípéènì. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó sọ lẹ́yìn ìgbà yẹn, ńṣe ni wọ́n rán an láti “lọ wò bóyá àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà ṣe tán láti tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti ẹ̀sìn Kristẹni.” Lákòókò tá à ń wí yìí, Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ti Ilẹ̀ Òkèèrè ò tíì ṣe iṣẹ́ débi púpọ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì wọ̀nyẹn nítorí wàhálà tí òṣèlú àti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà dá sílẹ̀. Inú Borrow dùn láti máa bá àwọn tó ń gbé láwọn ìgbèríko ilẹ̀ Potogí sọ̀rọ̀ Bíbélì, àmọ́ kò pẹ́ rárá tó fi rí i pé àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè yẹn kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ̀sìn sétí rárá, ìyẹn ló mú kó forí lé orílẹ̀-èdè Sípéènì.

Ọ̀tọ̀ ni ìṣòro tó bá pàdé nígbà tó dé Sípéènì, àgàgà láàárín àwọn ará Gypsy tí Borrow sọ dọ̀rẹ́ nítorí pé ó lè sọ èdè wọn. Kò pẹ́ tó débẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Bíbélì “Májẹ̀mú Tuntun” sí èdè àwọn ará Spanish ti Gypsy, ìyẹn èdè Gitano. Ó sọ fáwọn obìnrin Gypsy méjì pé kí wọ́n bá òun ṣe lára iṣẹ́ ìtumọ̀ náà. Borrow á ka Bíbélì Spanish sí wọ́n létí, lẹ́yìn náà, á wá ní kí wọ́n sọ fóun ìtumọ̀ ohun tóun kà. Báyìí ló ṣe kọ́ bá a ṣe ń lo òwe inú èdè Gypsy lọ́nà tó tọ́. Akitiyan rẹ̀ yìí ló mú kí wọ́n lè tẹ ìwé Ìhìn Rere Lúùkù jáde ní ìgbà ìrúwé ọdún 1838, èyí ló sì mú kí bíṣọ́ọ̀bù kan figbe bọnu, tó sọ pé: “Ọkùnrin yìí máa sọ gbogbo Sípéènì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa lílo èdè Gypsy.”

Wọ́n ní kí George Borrow lọ wá “èèyàn tó tóótun tó máa lè túmọ̀ Ìwé Mímọ́ sí èdè Basque.” Nínú ìwé tí Borrow kọ, ó sọ pé wọ́n gbé iṣẹ́ náà fún Dókítà Oteiza, oníṣègùn kan “tó gbọ́ èdè ọ̀hún dáadáa, tí èmi náà sì gbọ́ díẹ̀.” Ní ọdún 1838, ìwé Ìhìn Rere Lúùkù wá di ìwé Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n tẹ̀ sí èdè Spanish ti Basque.

Nítorí pé ó jẹ Borrow lọ́kàn gan-an láti la gbáàtúù èèyàn lóye, ìdí nìyí tó fi lọ sọ́nà jíjìn, tó sì tún fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu lọ́pọ̀ ìgbà láti pín àwọn ìwé Bíbélì fáwọn mẹ̀kúnnù tó ń gbé láwọn abúléko. Ó ronú nípa ohun tóun lè ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn wọ̀nyẹn bọ́ nínú àìmọ̀kan wọn nípa ìsìn àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ohun asán. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó fẹ́ fi yé wọn pé òtúbáńtẹ́ ni rírà tí wọ́n ń fowó ra ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ó bi wọ́n pé: “Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni rere fọwọ́ sí títa ẹ̀ṣẹ̀?” Àmọ́, Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì ń bẹ̀rù pé bí Borrow ṣe ń ta ko irú ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó ti fìdí múlẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú káwọn aláṣẹ fòfin dé iṣẹ́ àwọn, torí náà wọ́n sọ fún un pé pípín Ìwé Mímọ́ fáwọn èèyàn nìkan ni kó gbájú mọ́.

Ìjọba fẹnu sọ fún Borrow pé ó ti lómìnira láti tẹ El Nuevo Testamento, ìyẹn Májẹ̀mú Tuntun ní èdè Spanish, àmọ́ wọ́n ní kó má ṣe fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì sínú rẹ̀. Wọ́n pàpà fún un láyè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé olórí ìjọba kọ́kọ́ ta kò ó níbẹ̀rẹ̀, ó ń sọ pé ìtumọ̀ Bíbélì náà léwu ó tún pè é ní “ìwé tí kò tọ̀nà.” Borrow wá gba ṣọ́ọ̀bù kan sí ìlú Madrid tí yóò ti máa ta Bíbélì Májẹ̀mú Tuntun tó wà ní èdè Spanish, ohun tó sì ṣe yìí ló wá mú káwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn aláṣẹ fúngun mọ́ ọn. Wọ́n fi í sẹ́wọ̀n ọjọ́ méjìlá. Àmọ́ nígbà tí Borrow fàáké kọ́rí tó lóun ò gbà, wọ́n ní kó máa lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀. Nítorí pé ó dá a lójú hán-únhán-ún pé ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi òun sí kò tọ̀nà lábẹ́ òfin, ó tọ́ka sí àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sì takú pé òun ò ní lọ àyàfi bí wọ́n bá fi han àwọn èèyàn pé òun ò jẹ̀bí ẹ̀sùn kankan, tí àbààwọ́n kankan ò sì ní sí lára orúkọ òun.—Ìṣe 16:37.

Nígbà tí ọkùnrin onítara tí Ẹgbẹ́ Atúmọ̀ Bíbélì rán níṣẹ́ yìí, fi máa kúrò ní Sípéènì ní ọdún 1840, Ẹgbẹ́ náà ròyìn pé: “Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá [14,000] ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ la ti pín káàkiri ilẹ̀ Sípéènì láàárín ọdún márùn-ún tó ti kọjá yìí.” Nítorí pé Borrow kó ipa púpọ̀ nínú iṣẹ́ yìí, ó wá ṣe àkópọ̀ ìrírí tó ní nílẹ̀ Sípéènì lọ́nà yìí pé “àwọn ọdún tí mo tíì láyọ̀ jù lọ nìyẹn láyé mi.”

Ìwé The Bible in Spain, tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde lọ́dún 1842—tí wọ́n sì ń tẹ̀ jáde títí dòní olónìí—ni ìwé tó sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn nípa ìrìn àjò tí George Borrow rìn àtàwọn nǹkan tó gbéṣe. Nínú ìwé yẹn kan náà, táwọn èèyàn fẹ́ràn gan-an, Borrow pe ara rẹ̀ ní ọkùnrin onígboyà “tó lọ káàkiri nítorí Ìhìn Rere.” Ó kọ ọ́ pé: “Ohun tí mo ni lọ́kàn láti ṣe ni pé kí n lọ sáwọn ibi kọ́lọ́fín tó ṣòro dé ní àwọn òkè àti láàárín àwọn àpáta, kí n sì lọ sọ fáwọn èèyàn nípa Kristi ní ọ̀nà tèmi.”

Bí George Borrow ṣe fi ìtara pín Ìwé Mímọ́ káàkiri tó sì ń túmọ̀ rẹ̀ yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ táwọn ẹlòmíràn lè tẹ̀ lé—àǹfààní ńláǹlà sì ní lóòótọ́.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 29]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

George Borrow sapá láti túmọ̀ Bíbélì àti láti pín in fáwọn èèyàn, iṣẹ́ náà sì gbé e láti (1) Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ sí (2) Rọ́ṣíà, (3) ilẹ̀ Potogí, àti (4) Sípéènì

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Ìhìn Rere Jòhánù ní èdè Manchu, tí wọ́n tẹ̀ jáde lọ́dún 1835, tá a bá kà á láti òkè sísàlẹ̀ àti láti apá òsì sí apá ọ̀tún

[Credit Line]

Látinú ìwé The Bible of Every Land, 1860

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

Látinú ìwé The Life of George Borrow látọwọ́ Clement K. Shorter, 1919

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́