ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 9/15 ojú ìwé 21-23
  • Àwọn Ọlọ Tó Ń Pilẹ̀ Oúnjẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọlọ Tó Ń Pilẹ̀ Oúnjẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Nìdí Tí Ọlọ Fi Ṣe Pàtàkì?
  • Àwọn Ọlọ Ọlọ́wọ́
  • Àwọn Ọlọ Ayíbírí Sọ Ohun Tó Le Dẹ̀rọ̀
  • Ẹ̀rọ Tí Omi Tàbí Ẹ̀fúùfù Ń Yí
  • “Oúnjẹ Wa fún Ọjọ́ Òní”
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ǹjẹ́ O ti Jẹ Búrẹ́dì Tí Ń Fúnni Ní Ìyè?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 9/15 ojú ìwé 21-23

Àwọn Ọlọ Tó Ń Pilẹ̀ Oúnjẹ

Ọ̀PỌ̀ orúkọ làwọn èèyàn ti fi pe búrẹ́dì rí. Àwọn kan ti pè é ní “ọ̀pá ìyè,” “ọba oúnjẹ,” “kòṣeémáàní oúnjẹ tí ń gbẹ́mìí ró látayébáyé.” Kò sírọ́ ńbẹ̀, ó pẹ́ tí búrẹ́dì ti jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú oúnjẹ táwọn èèyàn ń jẹ. Àní, ohun tó jẹ àwọn èèyàn lógún jù lọ ni bí wọ́n á ṣe rí oúnjẹ òòjọ́ wọn.

Èròjà pàtàkì tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì ni ìyẹ̀fun, irú èyí tí wọ́n ń rí lára kóró irúgbìn tí wọ́n gún tàbí tí wọ́n fi ọlọ lọ̀. Nítorí náà, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń fi ọlọ lọ nǹkan. Bí kò bá sí ti ẹ̀rọ tó sọ gbogbo nǹkan di ìrọ̀rùn báyìí, iṣẹ́ àṣelàágùn gbáà ni lílọ kóró kó tó kúnná ì bá ṣì jẹ́! Ní àwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ìró ọlọ ọlọ́wọ́ sábà máa ń dúró fún kí nǹkan máa lọ déédéé àti ipò àlàáfíà, àìsí rẹ̀ sì máa ń dúró fún ìsọdahoro.—Jeremáyà 25:10, 11.

Oríṣiríṣi ọ̀nà wo làwọn èèyàn ń gbà lọ nǹkan látọjọ́ táláyé ti dáyé? Kí ni díẹ̀ lára ọgbọ́n tí wọ́n ti dá, kí sì ni wọ́n fi ṣe àwọn ọlọ tí wọ́n ń lò? Irú àwọn ọlọ wo gan-an ni wọ́n fi ń lọ àwọn oúnjẹ lónìí?

Kí Nìdí Tí Ọlọ Fi Ṣe Pàtàkì?

Jèhófà sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Kíyè sí i, mo ti fi gbogbo ewéko tí ń mú irúgbìn jáde fún yín, èyí tí ó wà lórí gbogbo ilẹ̀ ayé, àti gbogbo igi lórí èyí tí èso igi tí ń mú irúgbìn jáde wà. Kí ó jẹ́ oúnjẹ fún yín.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:29) Lára àwọn oúnjẹ tí Jèhófà Ọlọ́run fún aráyé la ti rí àwọn irúgbìn oníkóró tó máa ń so wìnnìkìnkìn sára pòròpórò. Ọ̀kan pàtàkì làwọn irúgbìn oníkóró yìí jẹ́ lára àwọn oúnjẹ tó ń gbẹ́mìí ró, níwọ̀n bí tááṣì ti wà nínú gbogbo oúnjẹ oníkóró bí àlìkámà, ọkà báálì, ọkà rye, ọkà oat, ìrẹsì, ọkà bàbà, jéró àti àgbàdo. Tááṣì yìí ni ara máa ń sọ di ṣúgà gúlúkóòsì tó máa ń fára lókun.

Bí àwa èèyàn bá kó oúnjẹ oníkóró mì ní tútù láìlọ̀ ọ́, láìsè é, kò ní dà nínú wa. Ọ̀nà tá a fi lè gbádùn wọn jù lọ ni pé ká lọ̀ wọ́n kúnná ká sì sè wọ́n. Ọ̀nà tó rọrùn jù lọ láti ṣe èyí ni pé ká gún un lódó tàbí ká lọ̀ ọ́, tàbí ká kọ́kọ́ fi odó wó o ká tó wá lọ̀ ọ́.

Àwọn Ọlọ Ọlọ́wọ́

Àwọn ère kéékèèké tí wọ́n rí nínú àwọn ibojì ìgbàanì nílẹ̀ Íjíbítì mú ká mọ bí irú ọlọ kan tí wọ́n fi ń lọ kóró irúgbìn nígbà náà lọ́hùn-ún ṣe rí. Ọlọ gàárì ni wọ́n máa ń pè é. Ìdí tí wọ́n sì fi ń pè é bẹ́ẹ̀ ni pé ó fara jọ gàárì. Òkúta méjì ni wọ́n máa ń lò pa pọ̀. Òkúta tó jinnú díẹ̀ ló máa ń wà nísàlẹ̀, ọmọ ọlọ kékeré á wá wà lórí ẹ̀. Obìnrin ló sábà máa ń lo ọlọ yìí. Á kúnlẹ̀ ti ọlọ náà, á sì dáwọ́ rẹ̀ méjèèjì tẹ orí ọmọ ọlọ. Á rin orí ọmọ ọlọ náà mọ́lẹ̀, á wá máa tì í lọ̀ ọ́ síwá tì í lọ sẹ́yìn. Bó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni kóró tó dà sórí ìyá ọlọ a máa fọ́ pẹ̀ẹ́pẹ̀ẹ́ títí tá á fi kúnná. Ohun èlò tó rọrùn gbáà, tó sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa ni!

Àmọ́ ṣá o, kíkúnlẹ̀ ti ọlọ fún ọ̀pọ̀ wákàtí ní ìpalára tó ń ṣe fún ara o. Bí obìnrin náà ṣe ń ti ọmọ ọlọ síwá sẹ́yìn máa ń jẹ́ kí ẹ̀yìn, àwọn apá méjèèjì àti itan ro ó, á sì tún jẹ́ kí orúnkún àti àwọn ọmọkasẹ̀ rẹ̀ máa gbolẹ̀. Àwọn onímọ̀ nípa àkẹ̀kù egungun ṣe ìwádìí lórí ibi tó bà jẹ́ lára egungun àwọn òkú lórílẹ̀-èdè Síríà ìgbàanì. Ìwádìí tí wọ́n ṣe náà mú kí wọ́n gbà gbọ́ pé lílo irú ọlọ ọlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ló fà á táwọn obìnrin fi máa ń ṣèṣe lemọ́lemọ́, bíi kí orúnkún wọn tẹ̀ sínú, kí eegun ẹ̀yìn wọn yẹ̀, kí eegun àtàǹpàkò wọn sì rún sínú. Ní ilẹ̀ Íjíbítì ìgbàanì, ó dà bí ẹni pé àwọn ìránṣẹ́bìnrin ni wọ́n sábà máa ń lo ọlọ ọlọ́wọ́. (Ẹ́kísódù 11:5)a Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà gbọ́ pé nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, irú ọlọ yẹn gan-an ni wọ́n gbé dání.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ ìyá ọlọ àti ọmọ ọlọ lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa ṣiṣẹ́ dáradára sí i. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́hò tó dà bí àrọ sínú òkúta tí wọ́n fi ń ṣe ọmọ ọlọ, ló di pé kí ẹni tí ń lọ ọlọ máa da kóró irúgbìn tó bá fẹ́ lọ̀ sínú ihò náà, á sì gbabẹ̀ já bọ́ sẹ́nu ìyá ọlọ tó wà nísàlẹ̀. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹrin tàbí ìkarùn-ún ṣáájú Sànmánì Tiwa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹ̀rọ tí yóò máa lọ nǹkan ní ilẹ̀ Gíríìsì. Wọ́n de ọ̀pá gbọọrọ kan mọ́ ara ọmọ ọlọ. Wọ́n á wá di ọ̀pá gbọọrọ náà mú lókè kí wọ́n lè máa fi tì í lọ síwá sẹ́yìn. Bí wọ́n bá ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, á máa lọ ìyá ọlọ tó wà nísàlẹ̀, kóró tí wọ́n bá sì dá sínú ihò tí wọ́n gbẹ́ sínú ọmọ ọlọ tó wà lókè á máa já bọ́ sórí ìyá ọlọ nísàlẹ̀.

Àmọ́, ó níbi táwọn ọlọ tá a ti ṣàlàyé nípa wọn yìí lè ṣiṣẹ́ mọ o. Wọn ò lè ṣiṣẹ́ láìjẹ́ pé èèyàn ń tì wọ́n lọ síwà sẹ́yìn, kò sì sí ẹranko téèyàn lè kọ́ pé kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí abájọ nìyẹn téèyàn fi ní láti máa fọwọ́ yí àwọn ọlọ náà. Nígbà tó wá yá, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbé tuntun dé, ìyẹn ọlọ ayíbírí, téèyàn lè kọ́ ẹranko mọ̀ ọ́n lò.

Àwọn Ọlọ Ayíbírí Sọ Ohun Tó Le Dẹ̀rọ̀

Bóyá, ó lè jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àgbègbè Mẹditaréníà ni wọ́n ti kọ́kọ́ ṣe ọlọ ayíbírí tí wọ́n fi ń lọ kóró irúgbìn ní nǹkan bí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa. Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, àwọn Júù tó wà ní Palẹ́sìnì ti ń lo irú ọlọ ayíbírí ọ̀hún, nítorí pé Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ọlọ irúfẹ́ èyí tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí.”—Máàkù 9:42.

Wọ́n lo ọlọ tí ẹranko ń yí ní Róòmù àti ní apá ibi púpọ̀ ní Ilẹ̀ Ọba Róòmù. A ṣì lè rí ọ̀pọ̀ irú àwọn ọlọ bẹ́ẹ̀ ní ìlú Pompeii. Òkúta méjì náà ni wọ́n fi ṣe é. Ọmọ ọlọ tó wà lókè wúwo rinrin, ó sì dà bí ìgbà téèyàn bá fi ìdí òkòtó méjì kanra wọn, ọmọ ọlọ yìí ló máa ń jó lọ jó bọ̀ bí ọlọ bá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́. Bí òkòtó gan-an ni ìyá ọlọ tó wà nísàlẹ̀ rí. Bí ọmọ ọlọ tó wà lókè bá ti ń yí bíríbírí tó sì ń lọ ìyá ọlọ tó wà nísàlẹ̀, wọ́n á máa da kóró irúgbìn sẹ́nu àwọn òkúta méjèèjì, á sì máa rún wọn wómúwómú. Àwọn tó ṣì wà dòní olónìí lára irú ọmọ ọlọ tó máa ń wà lókè yìí tóbi jura lọ. Fífẹ̀ wọn tó nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà márùndínláàádọ́ta sí àádọ́rùn-ún sẹ̀ǹtímítà. Àwọn ọlọ náà sì ga tó ọgọ́sàn-án sẹ̀ǹtímítà, tàbí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà.

A ò lè sọ èyí tí wọ́n wò ṣe èkejì nínú ọlọ tí ẹranko ń fà àti ọlọ ayíbírí kékeré. Ṣùgbọ́n ohun tá a mọ̀ ni pé ọlọ ọlọ́wọ́ tó máa ń yí bírí rọrùn-ún gbé kiri, kò sì ṣòroó lò. Òkúta rìbìtì méjì ni wọ́n fi ṣe é. Fífẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan á sì tó ọgbọ̀n sí ọgọ́ta sẹ̀ǹtímítà. Orí òkúta tó wà nísàlẹ̀ rọra ṣe bí ẹní yọ gọnbu, òkúta tó wà lókè sì pánú díẹ̀, kó bàa lè ṣe rẹ́gí bí wọ́n bá dojú wọn déra. Wọ́n fi ohun kan mú òkúta tòkè mọ́lẹ̀ kó lè máa yí bíríbírí lójú kan, wọ́n wá ki igi kan bọ̀ ọ́ kí wọ́n lè máa fi yí i síwá sẹ́yìn. Àwọn obìnrin méjì sábà máa ń jòkòó dojú kọra, wọ́n á jọ́ fi ọwọ́ kọ̀ọ̀kan gbá igi orí òkúta tó wà lókè náà mú wọ́n á sì máa fi yí i. (Lúùkù 17:35) Ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà á máa fi ọwọ́ rẹ̀ kejì bu kóró irúgbìn díẹ̀díẹ̀ sínú ihò tí wọ́n gbẹ́ sórí òkúta tókè. Èyí èkejì á sì máa fọwọ́ gbá ìyẹ̀fùn tó ń dà sílẹ̀ láti abẹ́ àwọn okúta méjèèjì jọ sínú igbá tàbí aṣọ tó wà nísàlẹ̀. Irú ọlọ yìí gan-an ló dáa fáwọn jagunjagun, àwọn arìnrìn-àjò lójú òkun, tàbí àwọn ìdílé kéékèèké tí wọ́n ń gbé níbi tó jìnnà síbi tí wọ́n ti lè rí ẹ̀rọ lọ nǹkan.

Ẹ̀rọ Tí Omi Tàbí Ẹ̀fúùfù Ń Yí

Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹtàdínlọ́gbọ̀n ṣáájú Sànmánì Tiwa, onímọ̀ ẹ̀rọ kan ní Róòmù, Vitruvius, ṣàpèjúwe bí ọlọ tí wọ́n ń fi omi yí ṣe rí nígbà tiẹ̀. Wọ́n darí omi kan tó ń ya gbùúgbùú sára àgbá kẹ̀kẹ́ kan tí wọ́n jó mọ́ ara irin gbọọrọ. Omi yìí sì ń mú kí àgbá kẹ̀kẹ́ náà máa yí. Bó bá sì ṣe ń yí náà lá á máa yí ọ̀pá mìíràn tí wọ́n jó mọ́ ara irin gbọọrọ tó gbé àgbá kẹ̀kẹ́ náà ró. Ọ̀pá yìí náà á sì tún máa yí ọ̀pá ìrin gbọọrọ kan tí wọ́n jó mọ́ ara òkútà ńlá tó wà lókè ìyá ọlọ.

Báwo ni nǹkan tí ẹ̀rọ tí wọ́n ń fi omi yí yìí ń lọ̀ ṣe pọ̀ tó bá a bá fi wé ti àwọn ọlọ mìíràn? Wọ́n fojú bù ú pé àwọn ọlọ ọlọ́wọ́ máa ń lọ nǹkan tí kò pọ̀ tó kìlógíráàmù mẹ́wàá, ìyẹn nǹkan bí ìdámárùn-ún àpò ìrẹ̀sì kan, láàárín wákàtí kan, èyí tó sì dára jù lọ lára ọlọ tí wọ́n ń fi ẹranko fà, máa ń lọ ìwọ̀n tó pọ̀ tó àádọ́ta kìlógíráàmù, èyí tó tó ẹ̀kún àpò ìrẹ̀sì kan. Àmọ́, ẹrọ tí wọ́n ń fi omi yí tí Vitruvius ṣe, lè lọ nǹkan bí àádọ́jọ sí igba kìlógíráàmù, ìyẹn ẹ̀kún àpò ìrẹ̀sí mẹ́ta sí mẹ́rin, láàárín wákàtí kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ́kan-ò-jọ̀kan ẹ̀rọ ìlọ-nǹkan ló ti wá wà báyìí, tí ìyípadà lóríṣiríṣi sì ti bá ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe wọ́n, ìlànà kan náà tí Vitruvius ṣàpèjúwe rẹ̀ làwọn tó mọwọ́ ẹ̀rọ ṣíṣe ṣì ń tẹ̀ lé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà.

Kì í ṣe omi tó ń rọ́ yìí nìkan ni wọ́n fi ń pèsè agbára tó ń mú ọlọ ṣiṣẹ́ o. Bí wọ́n bá fi abẹ̀bẹ̀ ẹ̀rọ ayíbírí rọ́pò àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ tómi ń yí, ó ṣì máa ṣe iṣẹ́ tá a fẹ́ kó ṣe. Ó dà bí ẹni pé ní ọ̀rúndún kejìlá Sànmánì Tiwa ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo ẹ̀rọ tó n lo ẹ̀fúùfù nílẹ̀ Yúróòpù, wọ́n sì lò ó jákèjádò orílẹ̀-èdè Belgium, Jámánì, Holland àti láwọn ibòmíì. Àwọn ẹ̀rọ náà ò sì kúrò lọ́jà títí táwọn ẹ̀rọ tó ń lo ooru gbígbóná àtàwọn ohun àmúṣagbára mìíràn fi wá dọ́gbọ́n gbá gbogbo àwọn orísun agbára yòókù wọlé.

“Oúnjẹ Wa fún Ọjọ́ Òní”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú ti bá ọ̀nà tí wọ́n gbà ń lọ nǹkan, ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà lọ nǹkan látijọ́ làwọn míì ṣì ń lò láwọn ibì kan lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Àwọn kan nílẹ̀ Áfíríkà àti ní àgbègbè Oceania ṣì ń lo odó àti ọmọ odó títí dòní olónìí. Ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti ní Àárín Gbùngbùn ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ọlọ gàárì ni wọ́n fi ń lọ àgbàdo tí wọ́n fi ń ṣe àkàrà tortilla. Àwọn ibi kọ̀ọ̀kan sì wà tí wọ́n ti ń lo ẹ̀rọ tí wọ́n ń fi omi yí àtèyí tí wọ́n ń fi ẹ̀fúùfù yí.

Àmọ́ ṣá o, èyí tó pọ̀ jù lára ìyẹ̀fun tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lónìí ni wọ́n ń fi ẹ̀rọ ìgbàlódè lọ̀ láwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ti ń fi àwọn ẹ̀rọ tó ń dá ṣiṣẹ́ lọ nǹkan. Wọ́n máa ń da àwọn kóró irúgbìn sínú àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n ní irin pàlàbà méjì méjì, tójú wọn rí ṣágiṣàgi, tó sì mú hánránhánrán bí abẹ. Àwọn irin tá a lè mú kí wọ́n sáré tó bá a ṣe fẹ́ yìí á wá máa lọ àwọn kóró irúgbìn náà díẹ̀díẹ̀ títí tá á fi di lẹ́búlẹ́bú. Lílọ kóró irúgbìn lọ́nà yìí ti mú kó ṣeé ṣe láti pèse ìyẹ̀fun tó kúnná yàtọ̀ síra, láìnáni lówó gọbọi.

Rírí ìyẹ̀fun téèyàn lè fi ṣe ohun tẹ́nu ń jẹ kì í tún ṣe iṣẹ́ àṣelàágùn mọ́ bíi tìgbà kan. Síbẹ̀, ìdí ọpẹ́ wa pọ̀ lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá tó fún wa ní kóró irúgbìn àti ọgbọ́n tá a lè fi sọ ọ́ di “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.”—Mátíù 6:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láwọn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ìdí ọlọ ọlọ́wọ́ ni wọ́n ń fi àwọn ọ̀tá tọ́wọ́ bá tẹ̀ sí, irú bó ṣe ṣẹlẹ̀ sí Sámúsìnì àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì mìíràn. (Àwọn Onídàájọ́ 16:21; Ìdárò 5:13) Àwọn obìnrin tó wà lómìnira ara wọn, máa ń fi ọlọ lọ kóró irúgbìn lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ wọn.—Jóòbù 31:10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọlọ gàárì tí wọ́n ń lò ní Íjíbítì

[Credit Line]

Soprintendenza Archeologica per la Toscana, Firenze

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Wọ́n máa ń lo ọlọ tí wọ́n ń fi ẹranko fà bí wọ́n bá fẹ́ yọ òróró lára èso igi ólífì

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Látinú ìtumọ̀ Bíbélì Self-Pronouncing Edition of the Holy Bible, tó ní ìtumọ̀ King James Version àti Revised Standard Version nínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́