ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 10/1 ojú ìwé 4-7
  • ‘Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Jogún Ayé’—Lọ́nà Wo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Jogún Ayé’—Lọ́nà Wo?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Kí Ayé Yìí Wà Títí Láé
  • Ọlọ́run Tí Kò Yí Padà
  • Bá A Ṣe Lè Rí Ogún Tí Ọlọ́run Ṣèlérí Náà Gbà
  • ‘Bíi Ti Ọ̀run Bẹ́ẹ̀ Ni ní Ayé’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ṣé Ayé Yìí Ń Bọ̀ Wá Di Párádísè?
    Jí!—2008
  • Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Wa Yìí Yóò Pa Run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Igbesi-aye Ni Ète Ọlọ́láńlá Kan Ninu
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 10/1 ojú ìwé 4-7

‘Àwọn Ọlọ́kàn Tútù Ni Yóò Jogún Ayé’—Lọ́nà Wo?

“Ó ṢEÉ ṣe kó o mọ ọ̀rọ̀ amọ́kànyọ̀ tí Jésù sọ yẹn dáadáa pé, ‘àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé.’ Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo nǹkan táwọn èèyàn ń fojú ọmọnìkejì wọn rí àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ayé fúnra rẹ̀, kí lo rò pé ó máa ṣẹ́ kù fáwọn ọlọ́kàn tútù láti jogún?”—Mátíù 5:5; Sáàmù 37:11; Bibeli Mimọ.

Ìbéèrè yìí ni Myriam tó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan lórí Bíbélì. Èsì tí ọkùnrin tó ń bá sọ̀rọ̀ náà fún un ni pé tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jésù ṣe ìlérí yìí, a jẹ́ pé ayé tó ohun téèyàn lè jogún rẹ̀ nìyẹn, pé kì í ṣe ibì téèyàn ò ní lè gbénú rẹ̀ tó rí játijàti.

Ó dájú pé ìdáhùn tó fi ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára hàn nìyẹn. Àmọ́, ǹjẹ́ ìdí wà fún wa láti ní irú èrò bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí pé Bíbélì fún wa ní àwọn ìdí tí kò ṣeé já ní koro tó fi yẹ ká gbà gbọ́ pé ìlérí náà yóò ṣẹ. Ní ti gidi, ìmúṣẹ ìlérí yẹn ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ìran ènìyàn àti sí orí ilẹ̀ ayé. Ó sì dá wa lójú pé ohun tí Ọlọ́run bá ti sọ pé òun máa ṣe gbọ́dọ̀ ṣẹ ṣáá ni. (Aísáyà 55:11) Nítorí náà, kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ pé òun máa ṣe fún aráyé, báwo sì ni gbogbo rẹ̀ ṣe máa ṣẹ?

Bí Ọlọ́run Ṣe Fẹ́ Kí Ayé Yìí Wà Títí Láé

Ó ní ìdí kan pàtó tí Jèhófà Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ dá ilẹ̀ ayé yìí. “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run, Ẹni tí í ṣe Ọlọ́run tòótọ́, Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀, Òun tí í ṣe Ẹni tí ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, ẹni tí kò wulẹ̀ dá a lásán, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀: ‘Èmi ni Jèhófà, kò sì sí ẹlòmíràn.’” (Aísáyà 45:18) Nítorí náà, ìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé ni kí àwọn èèyàn lè máa gbé inú rẹ̀. Síwájú sí i, Ọlọ́run tún fẹ́ kí ilẹ̀ ayé jẹ́ ibi tí ìran ènìyàn yóò máa gbé títí láé. “Ó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.”—Sáàmù 104:5; 119:90.

Bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ayé rí tún hàn kedere nínú àṣẹ tó pa fún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Jèhófà sọ fún Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run fi síkàáwọ́ Ádámù àti Éfà yẹ kó jẹ́ ibi tí àwọn àtàwọn àtọmọdọ́mọ wọn yóò máa gbé títí láé. Onísáàmù náà sọ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Sáàmù 115:16.

Kí Ádámù àti Éfà títí kan àwọn àtọmọdọ́mọ wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan tó lè jàǹfààní ìrètí gíga lọ́lá yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá àti Olùfúnni-ní-ìyè ni ọba aláṣẹ àwọn, kí wọ́n sì múra tán láti ṣègbọràn sí i. Jèhófà fi èyí hàn kedere nígbà tó pàṣẹ yìí fún ọkùnrin náà pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Tí Ádámù àti Éfà bá fẹ́ máa gbé nínú ọgbà Édẹ́nì nìṣó, wọ́n ni láti pa àṣẹ tó ṣe kedere yẹn mọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò fi hàn pé wọ́n mọrírì gbogbo ohun tí Baba wọn ọ̀run ti ṣe fún wọn.

Nígbà tí Ádámù àti Éfà mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run nípa rírú òfin tó pa fún wọn, ohun tí wọ́n ṣe ní ti gidi ni pé wọ́n kẹ̀yìn sí ẹni tó fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n ní. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Nítorí ohun tí wọ́n ṣe yìí, wọ́n pàdánù Párádísè ilé wọn ẹlẹ́wà, wọn ò sì tún jẹ́ kí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn rí Párádísè ọ̀hún. (Róòmù 5:12) Ǹjẹ́ àìgbọràn tọkọtaya àkọ́kọ́ yìí yí ohun tí Ọlọ́run tìtorí rẹ̀ dá ayé padà?

Ọlọ́run Tí Kò Yí Padà

Ọlọ́run tipasẹ̀ Málákì wòlíì rẹ̀ kéde pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Faransé nì, L. Fillion, mẹ́nu kan nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí ni pé ìkéde yìí kan ìmúṣẹ àwọn ìlérí Ọlọ́run. Fillion wá kọ̀wé pé: “Jèhófà ì bá ti pa àwọn ènìyàn rẹ̀ tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ run, àmọ́ nítorí pé a-wí-má-yẹhùn ni, ohun yòówù tí ì bá ṣẹlẹ̀, yóò mú àwọn ìlérí tó ti ṣe láti ọjọ́ pípẹ́ ṣẹ ṣáá ni.” Àwọn ìlérí Ọlọ́run kò lè di ìgbàgbé láé, yóò ṣẹ nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀, ì báà jẹ́ èyí tó ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ni o, tàbí èyí tó ṣe fún orílẹ̀-èdè kan, tàbí èyí tó ṣe fún ìran ènìyàn lápapọ̀. “Ó ti rántí májẹ̀mú rẹ̀ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin, ọ̀rọ̀ tí ó pa láṣẹ, títí dé ẹgbẹ̀rún ìran.”—Sáàmù 105:8.

Àmọ́, báwo ló ṣe dá wa lójú pé Jèhófà kò tí ì yí ohun tó ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé padà? Èyí dá wa lójú nítorí pé àtìbẹ̀rẹ̀ dópin ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ti mẹ́nu kan ète Ọlọ́run láti fi ilẹ̀ ayé fún àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn. (Sáàmù 25:13; 37:9, 22, 29, 34) Yàtọ̀ síyẹn, Ìwé Mímọ́ tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí Jèhófà bù kún pé wọ́n ń gbé ní ààbò, olúkúlùkù sì jókòó “lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,” láìsí “ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:4; Ìsíkíẹ́lì 34:28) Àwọn tí Jèhófà bá ní kó wà níbẹ̀ “yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” Kódà, àlàáfíà á wà láàárín èèyàn àtàwọn ẹranko ìgbẹ́ pàápàá.—Aísáyà 11:6-9; 65:21, 25.

Bíbélì tún jẹ́ ká rí àpẹẹrẹ ìlérí Ọlọ́run ní ọ̀nà mìíràn. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní àlàáfíà àti aásìkí lákòókò tí Sólómọ́nì Ọba ń ṣàkóso. “Júdà àti Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní gbígbé ní ààbò, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà tirẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀, láti Dánì dé Bíá-ṣébà, ní gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì.” (1 Àwọn Ọba 4:25) Bíbélì sọ pé Jésù “ju Sólómọ́nì lọ,” nígbà tí Bíbélì sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣàkóso Jésù, onísáàmù náà sọ ọ́ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́.” Ní àkókò yẹn, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Lúùkù 11:31; Sáàmù 72:7, 16.

Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run kì í parọ́, yóò rí i dájú pé ọwọ́ àwọn èèyàn tẹ ogún tí òun ṣèlérí rẹ̀, yóò tún rí sí i pé ó jẹ́ ibi ẹlẹ́wà ní gbogbo ọ̀nà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa nínú ìwé Ìṣípayá 21:4 pé nínú ayé tuntun tá a ṣèlérí yẹn, Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [àwọn èèyàn], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀ yìí gan-an ni Párádísè.—Lúùkù 23:43.

Bá A Ṣe Lè Rí Ogún Tí Ọlọ́run Ṣèlérí Náà Gbà

Yíyí ayé padà sí Párádísè yóò ṣẹlẹ̀ nínú ìjọba tí yóò ṣàkóso láti ọ̀run, ìyẹn Ìjọba kan tí Jésù Kristi yóò jẹ́ Ọba rẹ̀. (Mátíù 6:9, 10) Lákọ̀ọ́kọ́, Ìjọba yẹn yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18; Dáníẹ́lì 2:44) Lẹ́yìn náà, Jésù Kristi tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà,” yóò mú àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7) Lábẹ́ Ìjọba yẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn, títí kan àwọn tí yóò padà wá nípasẹ̀ àjíǹde yóò láǹfààní láti jogún ayé.— Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.

Àwọn wo ni yóò láǹfààní láti gbádùn ogún gíga lọ́lá yẹn? Ronú lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Kí ni ìtumọ̀ kéèyàn jẹ́ onínú tútù, tàbí ọlọ́kàntútù? Àwọn ìwé atúmọ̀ èdè sábà máa ń túmọ̀ “inú tútù,” tàbí “ọkàn tútù” sí jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, ẹni tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó máa ń tẹrí ba, tó jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́, àní tó tiẹ̀ máa ń tijú pàápàá. Àmọ́, ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a lò túmọ̀ sí jinlẹ̀ jùyẹn lọ. Ìwé William Barclay tó pè ní New Testament Wordbook sọ pé: Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà tún túmọ̀ sí “ìwà jẹ́jẹ́, àmọ́ nínú ìwà jẹ́jẹ́ náà ni agbára bíi ti irin wà.” Ó túmọ̀ sí ẹ̀mí téèyàn kan ní tó máa jẹ́ kó lè fara da ìwà àìdáa tẹ́nì kan hù sí i, tí kò sì ní bínú sí onítọ̀hún tàbí kó sọ pé òun fẹ́ gbẹ̀san, gbogbo èyí sì jẹ́ nítorí pé ó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, irú àjọṣe yẹn sì ti di orísun okun fún un.—Aísáyà 12:2; Fílípì 4:13.

Ńṣe ni ẹni tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ fara mọ́ ìlànà Ọlọ́run ní gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ̀; kì í rin kinkin pé òun gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó wu òun bẹ́ẹ̀ sì ni kì í jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn máa da òun ríborìbo. Ó tún jẹ́ ẹni tó gbẹ̀kọ́, tó múra tán láti jẹ́ kí Jèhófà kọ́ òun. Dáfídì, onísáàmù kọ̀wé pé: “[Jèhófà] yóò mú kí àwọn ọlọ́kàn tútù máa rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀, yóò sì kọ́ àwọn ọlọ́kàn tútù ní ọ̀nà rẹ̀.”—Sáàmù 25:9; Òwe 3:5, 6.

Ṣé wàá wà lára “àwọn ọlọ́kàn tútù” tó máa jogún ayé? Tó o bá mọ Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀ dáadáa nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jinlẹ̀, àti nípa fífi ohun tó ò ń kọ́ ṣèwà hù, ìwọ náà lè retí pé wàá jogún Párádísè orí ilẹ̀ ayé wàá sì gbé inú rẹ̀ títí láé.—Jòhánù 17:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ayé rí hàn kedere nínú àṣẹ tó pa fún Ádámù àti Éfà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Àlàáfíà àti ààbò tó gbilẹ̀ nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣàkóso jẹ́ ká mọ bí ogún tí Ọlọ́run ṣèlérí náà ṣe máa rí

[Àwọn Credit Line]

Àwọn àgùntàn àti òkè tó wà lẹ́yìn wọn; Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.; ẹranko oryx ti ilẹ̀ Arébíà: Hai-Bar, Yotvata, Israel; àgbẹ̀ tó ń túlẹ̀: Garo Nalbandian

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ayé tuntun òdodo kan ń bọ̀—ṣé wàá wà níbẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́