Irú Ẹ̀mí Ìdúródeni Wo Lo Ní?
LÓDE òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò lè fara balẹ̀ dúró de ẹnì kan tàbí ohun kan. Ìyẹn ni pé wọn ò lè ní sùúrù. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run níṣìírí pé kí wọ́n ní “ẹ̀mí ìdúródeni.” Wòlíì Míkà kò dà bí àwọn èèyàn tó yí i ká rárá, ó sọ pé: “Èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Míkà 7:7; Ìdárò 3:26.
Àmọ́, kí ni dídúró de Jèhófà túmọ̀ sí? Báwo ló ṣe yẹ kí Kristẹni kan dúró de Ọlọ́run? Ọ̀nà wo ló tọ́ láti dúró de Ọlọ́run, ọ̀nà wo ni kò sì tọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Jónà ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Tiwa kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ kan lórí ọ̀ràn náà.
Àpẹẹrẹ Ẹnì Kan Tó Dúró Deni Lọ́nà Tí Kò Tọ́
Jèhófà Ọlọ́run ní kí Jónà lọ wàásù fún àwọn ará Nínéfè, olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ásíríà. “Ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀” làwọn èèyàn máa ń pe Nínéfè nítorí ìwà ìkà àti ìwà òǹrorò tí wọ́n máa ń hù níbẹ̀, àwọn òpìtàn àtàwọn awalẹ̀pìtàn sì jẹ́rìí sí èyí. (Náhúmù 3:1) Jónà kọ́kọ́ fẹ́ sá fún iṣẹ́ yìí, àmọ́ Jèhófà rí i dájú pé wòlíì náà lọ sí Nínéfè lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn.—Jónà 1:3–3:2.
“Jónà bẹ̀rẹ̀ sí wọnú ìlú ńlá náà ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń pòkìkí, ó sì ń wí pé: ‘Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.’” (Jónà 3:4) Ohun tí Jónà sọ yìí wọ àwọn èèyàn náà lọ́kàn gan-an, wọ́n sì ṣe ohun kan tó pabanbarì: “Àwọn ènìyàn Nínéfè sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pòkìkí ààwẹ̀, wọ́n sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀, láti orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn àní dórí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn.” (Jónà 3:5) Nítorí èyí, Jèhófà Ọlọ́run tí “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n [tó] fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà,” kò pa ìlú náà run.—2 Pétérù 3:9.
Kí ni Jónà wá ṣe? Ẹsẹ Bíbélì náà sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.” (Jónà 4:1) Kí nìdí? Ó ṣeé ṣe kí Jónà máa rò pé àwọn èèyàn ò ní ka òun sí wòlíì gidi mọ́ nítorí pé ìparun tóun polongo rẹ̀ kò dé lọ́jọ́ tóun sọ pé ó máa dé. Ojú táwọn èèyàn fi máa wò ó ló ká a lára ju kó ṣàánú àwọn ẹlòmíràn kò sì ro ti ìgbàlà wọn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónà ò sọ pé òun ò ṣe iṣẹ́ wòlíì mọ́. Síbẹ̀, ó dúró láti “rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú ńlá náà.” Ní ti gidi, ẹ̀mí ká-ṣì-máa-wò-ó ni Jónà ní, inú sì ń bí i. Nígbà tó rí i pé ohun tí òun sọ kò ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó retí pé kó gbà ṣẹlẹ̀, ó kọ́ àtíbàbà kan, ó sì jókòó sábẹ́ ìbòòji rẹ̀, ó wá ń fi ìbínú dúró de ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Àmọ́, inú Jèhófà ò dùn sí ohun tí Jónà ṣe yìí, ó sì fi ìfẹ́ bá Jónà wí pé èrò tó ní yẹn ò tọ̀nà.—Jónà 4:5, 9-11.
Ìdí Tí Jèhófà Fi Mú Sùúrù
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, a ò sì pa wọn run, síbẹ̀ wọ́n tún padà sínú àwọn ọ̀nà búburú wọn. Jèhófà sì tipasẹ̀ wòlíì Náhúmù àti Sefanáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìlú náà. Nígbà tí ọ̀rọ̀ dórí “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀,” Jèhófà sọ pé òun yóò pa Ásíríà run, òun á sì sọ Nínéfè di ahoro. (Náhúmù 3:1; Sefanáyà 2:13) Nínéfè pa run ní ọdún 635 ṣáájú Sànmánì Tiwa, kò sì tún gbérí mọ́ láé.
Bákan náà, ayé òde òní ti jẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ púpọ̀, tó tiẹ̀ burú gan-an ju ti Nínéfè ìgbàanì lọ. Nítorí ìdí yìí àtàwọn ìdí mìíràn, Jèhófà ti sọ pé ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí yóò wá kógbá sílé nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí.—Mátíù 24:21, 22.
Síbẹ̀ náà, Jèhófà ò fẹ́ tètè mú ìparun tó ṣèlérí rẹ̀ yìí ṣẹ kí àwọn olóòótọ́ èèyàn òde òní lè ronú pìwà dà kí á sì dá wọn sí bíi tàwọn tó ronú pìwà dà ní Nínéfè. Àpọ́sítélì Pétérù tọ́ka sí sùúrù Ọlọ́run lọ́nà yìí pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pétérù 3:9, 10, 13.
Dídúródeni Lọ́nà Tó Tọ́
Pétérù tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (2 Pétérù 3:11, 12) Kíyè sí i pé bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa fi “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” hàn—ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ló bójú mu, wíwà láìṣe nǹkan kan kò dára.
Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀mí ìdúródeni tó tọ̀nà fi hàn pé ó dá wa lójú hán-ún pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé lákòókò tí Jèhófà fẹ́ kó dé gan-an. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú ká máa hu ìwà mímọ́ ká sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, èyí tó sì ṣe pàtàkì jù lọ lára wọn ni iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Jésù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí abẹ́nú yín wà ní dídì ní àmùrè, kí àwọn fìtílà yín sì máa jó, kí ẹ̀yin fúnra yín sì dà bí àwọn ọkùnrin tí ń dúró de ọ̀gá wọn nígbà tí ó padà dé láti ibi ìgbéyàwó, kí ó bàa lè jẹ́ pé ní dídé rẹ̀ àti kíkànkùn, wọn yóò lè ṣílẹ̀kùn ní kíá. Aláyọ̀ ni ẹrú wọnnì tí ọ̀gá náà bá tí ń ṣọ́nà nígbà tí ó dé!”—Lúùkù 12:35-37.
Àwọn ẹrú ní ọ̀rúndún kìíní máa ń ‘di abẹ́nú wọn ní àmùrè’ nípa kíkó etí aṣọ wọn pa pọ̀ tí wọ́n á sì kì í bọ abẹ́ ìgbànú wọn kó lè rọrùn fún wọn láti ṣe iṣẹ́ tó lágbára. Nípa bẹ́ẹ̀, Kristẹni kan ní láti jẹ́ alágbára, kó jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ rere. Ó gbọ́dọ̀ gbógun ti ohunkóhun tó lè mú kó “ṣe ìmẹ́lẹ́” nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, kó ní máa lo agbára tó yẹ kó lò fún nǹkan tẹ̀mí sórí fàájì ṣíṣe tàbí sórí lílépa àwọn nǹkan ti ara. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa,” lákòókò tó ń dúró de ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ìbẹ̀rù ti Jèhófà.—Róòmù 12:11; 1 Kọ́ríńtì 15:58.
Kí Ọwọ́ Wa Dí Bí A Ṣe Ń Dúró Dè É
Ńṣe lọwọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí gan-an bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìpíndọ́gba iye wákàtí tá a fi ń wàásù ọ̀rọ̀ Jèhófà lójúmọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2003 jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́ta àti ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlógún ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún wákàtí [3,383,000]. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ẹnì kan ní láti fi ọdún mẹ́rìnlá dín nírínwó [386] wàásù kó tó lè ṣe ohun tá a ṣe lọ́jọ́ kan ṣoṣo!
Síbẹ̀ ná, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ léèrè pé, ‘Irú ẹ̀mí ìdúródeni wo ni mo ní?’ Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe retí pé kí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tẹpá mọ́ṣẹ́ tó. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹrú mẹ́ta, ó ní: “[Ọ̀gá náà] sì fi tálẹ́ńtì márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, àti ẹyọ kan fún òmíràn síbẹ̀, fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀, ó sì lọ sí ìdálẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tí ó gba tálẹ́ńtì márùn-ún bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì fi wọ́n ṣòwò, ó sì jèrè márùn-ún sí i. Lọ́nà kan náà, ẹni tí ó gba méjì jèrè méjì sí i. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba ẹyọ kan ṣoṣo lọ, ó sì wa ilẹ̀, ó sì fi owó fàdákà ọ̀gá rẹ̀ pa mọ́. Lẹ́yìn àkókò gígùn, ọ̀gá ẹrú wọnnì dé, ó sì yanjú ìṣírò owó pẹ̀lú wọn.”—Mátíù 25:15-19.
Gbogbo àwọn ẹrú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ń dúró de ọ̀gá wọn. Ohun tí ọ̀gá náà sọ fún àwọn méjì tí ọwọ́ wọn dí lákòókò tí wọ́n ń dúró dè é ni pé: “O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́!” Àmọ́ nǹkan mìíràn ló ṣe fún ẹrú tó dúró dè é láìṣe ohunkóhun. Ọ̀gá náà sọ pé: “Ẹ . . . ju ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun náà síta nínú òkùnkùn lóde.”—Mátíù 25:20-30.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni àkàwé yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ kan wà níbẹ̀ fún gbogbo wa láti kọ́ ì báà jẹ́ ọ̀run là ń lọ tàbí a fẹ́ gbé lórí ilẹ̀ ayé. Jésù Kristi, Ọ̀gá wa retí pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa tẹpá mọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lákòókò tá a fi ń dúró de dídé rẹ̀ ní ọjọ́ ńlá Jèhófà. Ó mọyì iṣẹ́ olúkúlùkù “ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀” àti bí ipò rẹ̀ bá ṣe gbà. Ayọ̀ ńlá ló sì máa jẹ́ láti gbọ́ “o káre láé” lẹ́nu Ọ̀gá náà nígbà tí àkókò tá a fi ń dúró náà bá parí!
Sùúrù Olúwa Wa Túmọ̀ Sí Ìgbàlà
Bí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí bá ti wá pẹ́ ju bá a ṣe rò pé ó máa pẹ́ tó tàbí tó pẹ́ ju bá a ṣe retí lọ ńkọ́? Ó nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” (2 Pétérù 3:15) Ìmọ̀ pípéye nípa ète Ọlọ́run àti fífi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ mọ̀ pé àwa fúnra wa ò ṣe pàtàkì tó ìmúṣẹ àwọn ète Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú sùúrù níwọ̀n bí Jèhófà bá ṣì rí i pé ó yẹ kí òun mú sùúrù fún ètò ògbólógbòó yìí.
Jákọ́bù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ àpèjúwe kan láti rọ àwọn Kristẹni pé kí wọn mu sùúrù. Ó kọ̀wé pé: “Wò ó! Àgbẹ̀ a máa dúró de èso ṣíṣeyebíye ilẹ̀ ayé, ní mímú sùúrù lórí rẹ̀ títí yóò fi rí òjò àkọ́rọ̀ àti òjò àrọ̀kúrò. Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fìdí ọkàn-àyà yín múlẹ̀ gbọn-in, nítorí wíwàníhìn-ín Olúwa ti sún mọ́lé.”—Jákọ́bù 5:7, 8.
Jèhófà Ọlọ́run ò fẹ́ ká ṣàárẹ̀ nípa tẹ̀mí, kò sì fẹ́ ká bọ́hùn lákòókò tá a fi ń dúró yìí. Ó ní iṣẹ́ kan fún wa láti ṣe, inú rẹ̀ yóò sì dùn tá a bá lo àkókò tá a fi ń dúró yìí láti jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ náà. Ó fẹ́ ká wà lára àwọn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù, tó sọ pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn, kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin, kí ẹ má bàa di onílọ̀ọ́ra, ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.”—Hébérù 6:11, 12.
Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí àárẹ̀ mú wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, àti ìrètí aláyọ̀ tá a ní pé ètò àwọn nǹkan tuntun ń bọ̀ jẹ́ ohun tó ń fún wa lókun nínú ìgbésí ayé wa. Bíi tàwọn ẹ̀rú “rere àti olùṣòtítọ́” inú àkàwé Jésù yẹn, ẹ jẹ́ kí àwa náà fi hàn pé a tóótun láti gba ìyìn àti èrè nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú fífi ìyìn fún Ọlọ́run wa, bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Ní tèmi, èmi yóò máa dúró nígbà gbogbo, ṣe ni èmi yóò sì máa fi kún gbogbo ìyìn rẹ.”—Sáàmù 71:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Inú Jónà ò dùn, ó ń dúró de ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Nínéfè
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ẹ jẹ́ ká máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run hàn lákòókò tá a fi ń dúró de ọjọ́ Jèhófà