Ta Ló Dáńgájíá Láti Jẹ́ Aṣáájú Lóde Òní?
Ní ọdún 1940, àríyànjiyàn kan wáyé ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nípa ẹni tó máa jẹ́ aṣáájú. David Lloyd George, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí àríyànjiyàn náà ṣojú rẹ̀ ló mú kí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣẹ́gun nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Pípẹ́ tó ti pẹ́ nínú ìṣèlú mú kó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba. Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fún Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Kékeré ní May 8, ó ní: “Orílẹ̀-èdè yìí ti múra tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ ní ṣíṣe tó bá ṣáà ti ní aṣáájú, tó ní Ìjọba tó máa jẹ́ káwọn aráàlú mọ ohun táwọn fẹ́ ṣe, tí ọkàn àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yìí sì tún balẹ̀ pé àwọn aṣáájú wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn.”
Ọ̀RỌ̀ tí Lloyd George sọ jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn èèyàn retí pé kí àwọn aṣáájú wọn dáńgájíá kí wọ́n sì máa sa gbogbo ipá wọn láti mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i. Ọ̀nà tí obìnrin kan tó ń polongo ìbò gbà sọ ọ́ ni pé: “Nígbà táwọn èèyàn bá ń dìbò láti yan ààrẹ, èyí túmọ̀ sí pé ẹni tí wọ́n ń dìbò fún jẹ́ ẹnì kan tí wọ́n gbà pé àwọn lè fi ìgbésí ayé wọn, ọjọ́ ọ̀la wọn, àtàwọn ọmọ wọn síkàáwọ́ rẹ̀.” Kò rọrùn láti ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
Ayé tá a wà yìí kún fún àwọn ìṣòro tó dà bíi pé kò ṣeé yanjú. Bí àpẹẹrẹ, aṣáájú wo ló ti fi hàn àwọn èèyàn pé òun gbọ́n dáadáa, pé òun sì lágbára gan-an láti mú ìwà ọ̀daràn àti ogun kúrò? Èwo nínú àwọn aṣáájú òde òní ló lágbára tó sì láàánú láti pèsè oúnjẹ, omi tó mọ́ gaara, àti ìtọ́jú fún gbogbo ènìyàn? Ta ló ní ìmọ̀ tó sì múra tán láti dáàbò bo àyíká wa kó sì sọ ọ́ dọ̀tun? Tá ló dáńgájíá tó sì lágbára tó pọ̀ tó láti mú un dá ìràn ènìyàn lójú pé wọ́n á pẹ́ láyé tí inú wọn á sì máa dùn?
Ó Kọjá Agbára Ẹ̀dá Èèyàn
Òótọ́ ni pé àwọn aṣáájú kan ti kẹ́sẹ járí dé àyè kan. Àmọ́, pátápinrá wọ́n á wà níbẹ̀ fún ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ̀, ta ló sì mọ irú ẹni tó máa rọ́pò wọn? Ọ̀kan lára àwọn aṣáájú tó dáńgájíá jù lọ láyé, ìyẹn Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ronú lórí ìbéèrè yẹn. Ó wá sọ pé: “Èmi, àní èmi, sì kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi tí mo ṣe kárakára lábẹ́ oòrùn, tí èmi yóò fi sílẹ̀ sẹ́yìn fún ènìyàn tí yóò wá wà lẹ́yìn mi. Ta sì ni ó mọ̀ bóyá yóò jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀? Síbẹ̀, òun ni yóò ṣe àkóso gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi tí mo ṣe kárakára, tí mo sì fi ọgbọ́n hàn nídìí rẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Asán ni èyí pẹ̀lú.”—Oníwàásù 2:18, 19.
Sólómọ́nì ò mọ̀ bóyá ẹni tó máa jọba lẹ́yìn òun yóò máa bá iṣẹ́ rere tí òun ti ṣe sílẹ̀ lọ, tàbí ó máa bà á jẹ́. Lójú Sólómọ́nì, ọ̀rọ̀ ká máa fi aṣáájú tuntun rọ́pò èyí tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ jẹ́ “asán.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn lédè Gẹ̀ẹ́sì pè é ní òtúbáńtẹ́, tàbí ìranù. Bíbélì kan tiẹ̀ sọ pé kò mọ́gbọ́n dání rárá.
Àwọn ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé ipá ni wọ́n fi máa lé aṣáájú kan kúrò lórí oyè. Wọ́n ti dá ẹ̀mí àwọn aṣáájú kan tó dáńgájíá légbodò nígbà tí wọ́n ṣì ń bá iṣẹ́ wọn lọ. Abraham Lincoln, tó jẹ́ ààrẹ kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, sọ nígbà kan fáwọn èèyàn tó pé jọ síbi kan pé: “Ẹ ti yàn mí sípò pàtàkì kan àmọ́ àkókò kúkúrú ni mo ní, èmi sì rèé, níwájú yín, tẹ́ ẹ fún ní agbára tí kò ní pẹ́ dópin.” Ìgbà kúkúrú ló sì fi ṣèjọba lóòótọ́. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan tó ṣe àti bó ṣe túbọ̀ fẹ́ ṣe ohun púpọ̀ sí i fáwọn èèyàn náà, ọdún mẹ́rin péré ni Ààrẹ Lincoln fi ṣe olórí orílẹ̀-èdè rẹ̀. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lẹ́ẹ̀kejì ni ọkùnrin kan gbẹ̀mí rẹ̀ nítorí pé ọkùnrin náà fẹ́ káwọn ní aṣáájú mìíràn.
Kódà àwọn aṣáájú tó dára jù lọ pàápàá kò lè fọwọ́ sọ̀yà pé ọjọ́ ọ̀la wọn á dára. Ṣé ó wá yẹ kó o fọkàn tán wọn tí wọ́n bá sọ pé ọjọ́ ọ̀la tìẹ á dára? Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:3, 4.
Ó lè ṣòro láti gbà pé kò yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé àwọn aṣáájú ayé. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì ò sọ pé títí ayé ni ìran ènìyàn kò fi níí ní aṣáájú tó dára tí ìṣàkóso rẹ̀ kò sì ní lópin. Aísáyà 32:1 sọ pé: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo.” Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá èèyàn ti pèsè “ọba kan,” Aṣáájú kan, tí yóò máa darí gbogbo ohun tó ń lọ láyé láìpẹ́. Ta lonítọ̀hún? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi ẹni náà hàn.
Ẹni Tó Dáńgájíá Láti Jẹ́ Aṣáájú
Ní ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, áńgẹ́lì kan sọ fún ọ̀dọ́bìnrin Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màríà pé: “Ìwọ yóò lóyún nínú ilé ọlẹ̀ rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù. Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:31-33) Láìsí àní-àní, Jésù ti Násárétì ni Ọba tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ náà.
Àwọn onísìn sábà máa ń yà Jésù bí ọmọ jòjòló kan, wọ́n tún máa ń yà á bí ẹni kan tí kò jẹun kánú, tàbí bí ẹnì kan tó ń fìyà jẹ ara rẹ̀ tí kò sì láápọn. Àwọn àwòrán wọ̀nyí kò lè jẹ́ káwọn èèyàn gbẹ́kẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú. Àmọ́, Jésù Kristi tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ dàgbà di alágbára, ó di ọkùnrin tó nítara tó sì ń gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ṣe. Ó tún ní àwọn ànímọ́ mìíràn tó mú kó dáńgájíá láti jẹ́ aṣáájú. (Lúùkù 2:52) Díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ títayọ tó ní rèé.
Jésù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ láìkù síbì kankan. Ìwà rẹ̀ dára débi pé gbangba ìta ló ti sọ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ pé kí wọ́n sọ ẹ̀ṣẹ̀ kan tí wọ́n lè dá òun lẹ́bi rẹ̀. Wọn ò rí ohunkóhun sọ. (Jòhánù 8:46) Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí kò ní àgàbàgebè mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́kàn rere di ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Jòhánù 7:46; 8:28-30; 12:19.
Jésù ya ara rẹ̀ sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run. Ó múra tán láti parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un débi pé kò sí alátakò kankan, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹ̀mí èṣù, tó lè dí i lọ́wọ́. Kódà àwọn tó ń fipá kọlu èèyàn kò lè dáyà fò ó. (Lúùkù 4:28-30) Àárẹ̀ àti ebi ò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. (Jòhánù 4:5-16, 31-34) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sá fi í sílẹ̀, síbẹ̀ kò yà kúrò lórí ohun tó ń lépa àtiṣe.—Mátíù 26:55, 56; Jòhánù 18:3-9.
Ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ Jésù lọ́kàn gan-an. Ó fún àwọn tí ebi ń pa lóúnjẹ. (Jòhánù 6:10, 11) Ó tu àwọn tó sorí kọ́ nínú. (Lúùkù 7:11-15) Ó la ojú afọ́jú, ó mú kí adití gbọ́ran, ó sì mú àwọn tí ń fẹ́ ìwòsàn lára dá. (Mátíù 12:22; Lúùkù 8:43-48; Jòhánù 9:1-6) Ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó ń siṣẹ́ kára níṣìírí. (Jòhánù, orí 13–17) Ó fi hàn pé òun jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” tó bìkítà fún àwọn àgùntàn rẹ̀.—Jòhánù 10:11-14.
Iṣẹ́ máa ń wu Jésù ṣe. Ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kó lè kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. (Jòhánù 13:4-15) Ẹsẹ̀ òun alára dọ̀tí nígbà tó ń wàásù ìhìn rere náà láwọn ọ̀nà eléruku tó wà ní Ísírẹ́lì. (Lúùkù 8:1) Kódà nígbà tó ń wá bóun ṣe máa sinmi ní “ibì kan tí ó dá,” ó pàpà sọ̀rọ̀ nígbà táwọn èrò wá a kàn kó lè túbọ̀ fún wọn nítọ̀ọ́ni. (Máàkù 6:30-34) Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ jíjẹ́ aláápọn lélẹ̀ fún gbogbo Kristẹni.—1 Jòhánù 2:6.
Jésù parí iṣẹ́ rẹ̀ ó sì kúrò láyé. Nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run fún un ní ipò ọba àti àìleèkú ní ọ̀run. Bíbélì sọ nípa Jésù tí Ọlọ́run jí dìde náà pé: “Kristi, nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, kò tún kú mọ́; ikú kò tún jẹ́ ọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.” (Róòmù 6:9) Láìsí àní-àní, òun ni Aṣáájú to dára jù lọ fún ìran ènìyàn. Tí Kristi Jésù bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, kò tún ní sí ìdí kankan láti gbé ìjọba lé ẹlòmíràn lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sídìí fún pípààrọ̀ aṣáájú. Kò ní sẹ́ni tó máa lè pa á nígbà tó bá ń ṣèjọba, kò sì ní sí èèyànkéèyàn kan tó máa gbàjọba lọ́wọ́ rẹ̀ débi tí yóò ba iṣẹ́ tó ṣe sílẹ̀ jẹ́. Àmọ́, kí ni ohun náà gan-an tó máa ṣe láti ṣe ọmọ aráyé láǹfààní?
Ohun Tí Aṣáájú Tuntun Yìí Máa Ṣe
Sáàmù kejìléláàádọ́rin sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọ̀nà tí Ọba tó jẹ́ ẹni pípé tí ò lè kú yìí máa gbà ṣàkóso. Ẹsẹ keje àti ìkẹjọ rẹ̀ kà pé: “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́. Òun yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò dé òpin ilẹ̀ ayé.” Nínú ìṣàkóso rẹ̀ tó máa ṣeni láǹfààní yẹn, ọkàn àwọn olùgbé orí ilẹ̀ ayé yóò balẹ̀ títí ayé fáàbàdà. Yóò pa gbogbo ohun ìjà run yóò sì mú ẹ̀mí ìjà kúrò lọ́kàn àwọn ènìyàn. Àwọn tó ń kọ lu àwọn ẹlòmíràn bí ìgbà tí kìnnìún bá kọ luni tàbí àwọn tó máa ń ṣe bí béárì oníkanra sí ọmọnìkejì wọn yóò ti yí ìwà wọn padà pátápátá nígbà yẹn. (Aísáyà 11:1-9) Àlàáfíà yóò wà níbi gbogbo.
Sáàmù Kejìléláàádọ́rin tún sọ ní ẹsẹ kejìlá sí ìkẹrìnlá pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.” Àwọn gbáàtúù èèyàn, àwọn òtòṣì, àtàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ yóò wà lára àwọn èèyàn tó máa jẹ́ ìdílé kan ṣoṣo tó láyọ̀, tó sì wà níṣọ̀kan lábẹ́ ìṣàkóso Ọba náà, Jésù Kristi. Ayọ̀ ló máa kúnnú ayé wọn, kì í ṣe ìrora àti àìnírètí.—Aísáyà 35:10.
Ẹsẹ kẹrìndínlógún ṣèlérí pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni ebi ń hàn léèmọ̀ lórí ilẹ̀ ayé lóde òní. Ètò ìṣèlú àti ẹ̀mí ìwọra ni kì í sábà jẹ́ kí wọ́n pín oúnjẹ bó ṣe yẹ, tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń kú nítorí ebi, àgàgà àwọn ọmọdé. Àmọ́ ìṣòro yìí yóò dópin nígbà ìṣàkóso Jésù Kristi. Ilẹ̀ ayé yóò mú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ aládùn jáde. Gbogbo èèyàn ni yóò jẹ àjẹyó.
Ǹjẹ́ ó wù ọ́ láti gbádùn àwọn ìbùkún tí aṣáájú rere yìí yóò mú wá? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Aṣáájú náà tó máa ṣàkóso gbogbo ayé láìpẹ́. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. O ò ní kábàámọ̀ rẹ̀, nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti sọ nípa Ọmọ rẹ̀ pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ Lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi.”—Sáàmù 2:6.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
WỌ́N PÀDÁNÙ IPÒ WỌN LÓJIJÌ
Alákòóso kan mọ̀ pé àwọn ọmọ abẹ́ òun á bọ̀wọ̀ fóun, wọ́n á sì kọ́wọ́ ti òun lẹ́yìn tóun bá jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín wọn, tóun sì mú kí nǹkan ṣẹnuure fún wọn. Àmọ́ tó bá di pé àwọn èèyàn náà ò lè fọkàn tán an mọ́ nítorí ìdí kan, ó ṣeé ṣe kí ẹlòmíràn gbapò rẹ̀ láìpẹ́. Díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ ohun tó ṣàdédé mú káwọn alákòóso tó lágbára gan-an pàdánù ipò wọn rèé.
Ipò nǹkan tí kò bára dé. Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kejìdínlógún, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé ni nǹkan ò rọgbọ fún, owó orí tí wọ́n ń san ga, kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí oúnjẹ. Bí ipò nǹkan ṣe rí yìí ló fa Ìyípadà Tegbòtigaga Nílẹ̀ Faransé, èyí tó mú kí wọ́n bẹ́ Ọba Louis Kẹrìndínlógún lórí lọ́dún 1793.
Ogun. Ogun Àgbáyé Kìíní ló fòpin sí ìṣàkóso àwọn olú ọba kan tí wọ́n lágbára jù lọ láyé yìí. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1917, ogun kan tó fa àìtó oúnjẹ ní ìlú St. Petersburg, ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ló fa Ìdìtẹ̀gbàjọba ní February ọdún yẹn. Ọ̀tẹ̀ yìí ló mú Czar Nicholas Kejì kúrò lórí oyè táwọn Kọ́múníìsì sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Ilẹ̀ Jámánì fẹ́ kí àlàáfíà wà ní November 1918, àmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ kọ̀, wọ́n láwọn ò ní dá ìjà náà dúró àyàfi tí wọ́n bá pààrọ̀ alákòóso wọn. Nítorí ìdí èyí, wọ́n fagbára mú Wilhelm Kejì, tó jẹ́ Olú Ọba Ilẹ̀ Jámánì nígbà yẹn lọ́ sígbèkùn ní Netherlands.
Àwọn èèyàn fẹ́ ìjọba mìíràn tó yàtọ̀. Ní ọdún 1989, Ètò Ìṣèlú kan tó ya àwọn kan sọ́tọ̀ kúrò lára aráyé yòókù di èyí tí wọ́n mú kúrò. Ìṣàkóso tó le koko bí òkúta tẹ́lẹ̀ forí ṣánpọ́n nígbà táwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ pa ìjọba Kọ́múníìsì tì, tí wọ́n sì gbé ìjọba mìíràn kalẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jésù bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó sì fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún gbogbo Kristẹni
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Lloyd George: Fọ́tò látọwọ́ Kurt Hutton/Picture Post/Getty Images