ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 11/1 ojú ìwé 8-13
  • Aláyọ̀ ni Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aláyọ̀ ni Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Yẹ Ká Mọ̀ Pé A Nílò Nǹkan Tẹ̀mí
  • Bí Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Ṣe Lè Láyọ̀
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Onínú Tútù
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ebi Òdodo Ń Pa
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú
  • Àwọn Ẹni Mímọ́ Gaara Ní Ọkàn-Àyà Àtàwọn Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà
  • Bí Ọ̀rọ̀ Jésù Ṣe Lè Sọni Di Aláyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Aláyọ̀ Ni Àwọn Tó Ń Sin “Ọlọ́run Aláyọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 11/1 ojú ìwé 8-13

Aláyọ̀ ni Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà

“Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—MÁTÍÙ 5:3.

1. Kí ni ayọ̀ tòótọ́, kí ni ayọ̀ náà sì ń fi hàn?

KÒṢEÉMÁÀNÍ ni ayọ̀ jẹ́ fún àwọn èèyàn Jèhófà. Dáfídì onísáàmù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!” (Sáàmù 144:15) Inú dídùn ló ń mórí yá. Tá a bá sì rí i pé Jèhófà ń bù kún wa, èyí á mú kí ayọ̀ wa pọ̀ gan-an. (Òwe 10:22) Irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Baba wa ọ̀run, ó sì tún fi hàn pé à ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 112:1; 119:1, 2) Jésù tiẹ̀ mẹ́nu kan ohun mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó máa jẹ́ kéèyàn láyọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a ó ṣe àyẹ̀wò nípa ohun tó máa jẹ́ ká láyọ̀, àyẹ̀wò náà yóò jẹ́ ká mọ bí ayọ̀ wa ṣe máa pọ̀ tó tá a bá ń fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tímótì 1:11.

Ó Yẹ Ká Mọ̀ Pé A Nílò Nǹkan Tẹ̀mí

2. Ìgbà wo ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ayọ̀, kí sì ni gbólóhùn tó fi bẹ̀rẹ̀ ìwàásù rẹ̀?

2 Ní ọdún 31 Sànmánì Tiwa, Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó wà lára ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ jù lọ láyé yìí. Ìwàásù Lórí Òkè là ń pe àwọn ọ̀rọ̀ náà nítorí pé ẹ̀bá òkè kan téèyàn lè dúró sí wo Òkun Gálílì ni Jésù ti sọ ọ́. Ìwé Ìhìn rere Mátíù sọ pé: “Nígbà tí [Jésù] rí àwọn ogunlọ́gọ̀, ó gòkè lọ sí orí òkè ńlá; lẹ́yìn tí ó sì jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé: ‘Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.’” (Mátíù 5:1-3) Tá a bá túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ ìwàásù náà ní ṣáńgílítí, ohun tó máa jẹ́ rèé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláìní ní ti ẹ̀mí,” tàbí “Aláyọ̀ ni àwọn alágbe nípa tẹ̀mí.” (Mátíù 5:1-3; Kingdom Interlinear; aláyè ìsàlẹ̀ ìwé) Bíbélì Today’s English Version sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tó mọ̀ pé àwọn jẹ́ aláìní nípa tẹ̀mí.”

3. Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè mú kéèyàn láyọ̀?

3 Nínú ìwàásù Jésù lẹ́bàá òkè, ó fi hàn pé ayọ̀ èèyàn máa pọ̀ jọjọ tí onítọ̀hún bá mọ̀ pé òun nílò àwọn nǹkan tẹ̀mí. Nítorí pé àwọn Kristẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ mọ̀ dájú pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, èyí mú kí wọ́n máa tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Jèhófà lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi. (1 Jòhánù 1:9) Ìdí rèé tí ọkàn wọn fi balẹ̀ tí wọ́n sì ní ayọ̀ tòótọ́. “Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.”—Sáàmù 32:1; 119:165.

4. (a) Kí ni àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a nílò àwọn nǹkan tẹ̀mí, ká sì tún fi hàn pé á fẹ́ káwọn ẹlòmíràn rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ? (b) Kí ló máa jẹ́ kí ayọ̀ wa túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tí nǹkan tẹ̀mí bá ń jẹ wá lọ́kàn?

4 Mímọ̀ tá a mọ̀ pé a nílò àwọn nǹkan tẹ̀mí ń mú ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó mú ká máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” ó sì tún mú ká máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. (Mátíù 24:45; Sáàmù 1:1, 2; 119:111; Hébérù 10:25) Ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni mú ká mọ̀ pé àwọn èèyàn nílò oúnjẹ tẹ̀mí, ó sì ń mú ká máa fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ká sì máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. (Máàkù 13:10; Róòmù 1:14-16) Sísọ òtítọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn ń mú ká jẹ́ aláyọ̀. (Ìṣe 20:20, 35) Ayọ̀ wa á sì túbọ̀ máa pọ̀ sí i tá a bá ronú nípa àwọn nǹkan ìyanu tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe àti ìbùkún tí Ìjọba náà máa mú wá. Ìjọba náà máa fún “agbo kékeré” ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìyè àìleèkú ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ara Ìjọba Kristi. (Lúùkù 12:32; 1 Kọ́ríńtì 15:50, 54) Àwọn “àgùntàn mìíràn” yóò wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba náà.—Jòhánù 10:16; Sáàmù 37:11; Mátíù 25:34, 46.

Bí Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Ṣe Lè Láyọ̀

5. (a) Kí ni gbólóhùn náà “àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀” túmọ̀ sí? (b) Báwo ní irú àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe ń rí ìtùnú?

5 Ohun kejì tí Jésù sọ pé ó máa jẹ́ ká láyọ̀ dà bí òdìkejì ayọ̀. Ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, níwọ̀n bí a ó ti tù wọ́n nínú.” (Mátíù 5:4) Báwo lẹnì kan ṣe lè máa ṣọ̀fọ̀ kí inú rẹ̀ sì tún máa dùn? Láti lè lóye ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí, a ní láti mọ irú ọ̀fọ̀ tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jákọ́bù, ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ṣàlàyé pé jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ohun tó máa mú ká ṣọ̀fọ̀. Ó kọ ọ́ pé: “Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara, ẹ̀yin aláìnípinnu. Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣíṣẹ̀ẹ́, kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì sunkún. Kí ẹ̀rín yín di ọ̀fọ̀, kí ìdùnnú yín sì di ìdoríkodò. Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà, yóò sì gbé yín ga.” (Jákọ́bù 4:8-10) Àwọn tó banú jẹ́ nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ń rí ìtùnú nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé àwọn lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn táwọn bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, táwọn sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn nípa ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Jòhánù 3:16; 2 Kọ́ríńtì 7:9, 10) Èyí lè mú kí wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì máa retí àtiwàláàyè títí láé láti máa sin Jèhófà kí wọ́n sì máa yìn ín. Ayọ̀ tí èyí ń fún wọn pọ̀ gan-an.—Róòmù 4:7, 8.

6. Lọ́nà wo ni àwọn kan gbà ń ṣọ̀fọ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe ń rí ìtùnú?

6 Ọ̀rọ̀ Jésù tún kan àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn nǹkan búburú tó gbòde kan láyé. Jésù sọ pé òun alára ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 61:1, 2 ṣẹ sí lára, ibẹ̀ kà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń bẹ lára mi, nítorí ìdí náà pé Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” Iṣẹ́ náà tún kan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó kù sórí ilẹ̀ ayé, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn “àwọn àgùntàn mìíràn” sì ń kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn. Gbogbo wọn ló jọ ń sàmì síwájú orí àwọn èèyàn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ìyẹn “àwọn ènìyàn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe ní àárín rẹ̀ [ìyẹn Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà, tó ṣàpẹẹrẹ àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì].” (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Ọ̀rọ̀ ìtùnú ni “ìhìn rere ìjọba” náà jẹ́ fún irú àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ yìí. (Mátíù 24:14) Inú wọn dùn láti mọ̀ pé ayé tuntun òdodo Jèhófà ò ní pẹ́ rọ́pò ètò àwọn nǹkan Sátánì.

Aláyọ̀ Ni Àwọn Onínú Tútù

7. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “onínú tútù” kò túmọ̀ sí?

7 Jésù ń bá Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè lọ, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń rò pé òmùgọ̀ làwọn tó ní ìwà tútù. Àmọ́, ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ o. Nínú ìwé kan tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan kọ tó fi ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tá a tú sí “onínú tútù,” ó ní: “Ohun kan tó dáa gan-an nípa ẹni tó bá jẹ́ [onínú tútù] ni pé ó jẹ́ ẹni tó mọ bá a ṣe ń kó ara ẹni níjàánu gan-an. Kì í kàn án ṣe pé ó jẹ́ èèyàn jẹ́jẹ́, ẹni tó tètè máa ń ṣàánú èèyàn, tàbí ẹni tó tútù. Ìwà tútù jẹ́ ànímọ́ kan tó lágbára àmọ́ tó ṣeé kó níjàánu.” Jésù sọ pé “onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni [òun].” (Mátíù 11:29) Síbẹ̀ náà, Jésù kì í gba gbẹ̀rẹ́ tó bá di pé kó jà fún ìlànà òdodo.—Mátíù 21:12, 13; 23:13-33.

8. Ìwà tútù àti ànímọ́ wo ni wọ́n jọ wọnú ara wọn gan-an, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ní ànímọ́ yìí bá a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn da nǹkan pọ̀?

8 Inú tútù àti ẹ̀mí ìkóra-ẹni-níjàánu wọnú ara wọn gan-an. Kódà, níbi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti mẹ́nu kan àwọn “èso ti ẹ̀mí” níkọ̀ọ̀kan, ẹ̀gbẹ́ ìkóra-ẹni-níjàánu ló fi ìwà tútù sí. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ̀mí mímọ́ ló máa ran èèyàn lọ́wọ́ láti di onínú tútù. Ó jẹ́ ànímọ́ Kristẹni tó máa jẹ́ kéèyàn bá àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí àtàwọn tó wà nínú ìjọ gbé lálàáfíà. Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.”—Kólósè 3:12, 13.

9. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àárín àwa àtàwọn èèyàn nìkan kọ́ ni ìwà tútù ti ṣe pàtàkì? (b) Ọ̀nà wo làwọn onínú tútù gbà “jogún ilẹ̀ ayé”?

9 Àmọ́, àárín àwa àtàwọn èèyàn nìkan kọ́ ni ìwà tútù ti ṣe pàtàkì o. Tó bá jẹ́ pé tinútinú la fi fi ara wa sábẹ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, à ń fi hàn pé a jẹ́ onínú tútù nìyẹn. Jésù Kristi lẹni tí àpẹẹrẹ rẹ̀ tayọ jù lọ tó bá dọ̀ràn ká jẹ́ onínú tútù, nítorí pé nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó jẹ́ onínú tútù ó sì ṣe gbogbo ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́ láìkù síbì kan. (Jòhánù 5:19, 30) Jésù lẹ́ni tó kọ́kọ́ jogún ayé, nítorí pé òun la yàn láti jẹ́ Alákòóso lórí rẹ̀. (Sáàmù 2:6-8; Dáníẹ́lì 7:13, 14) Òun àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni wọ́n jọ jẹ ogún yìí, ìyẹn “àwọn ajùmọ̀jogún,” tá a yàn “lára aráyé” láti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Róòmù 8:17; Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3, 4; Dáníẹ́lì 7:27) Kristi àtàwọn tó máa bá a ṣèjọba yóò ṣàkóso lórí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́kùnrin lóbìnrin, ìyẹn àwọn tí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ sáàmù yóò ṣẹ sí lára, tó sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11; Mátíù 25:33, 34, 46.

Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ebi Òdodo Ń Pa

10. Kí ni ọ̀nà kan tí àwọn tí “ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo” lè gbà yó?

10 Ohun tí Jésù tún sọ pé ó máa jẹ́ kéèyàn láyọ̀ bó ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ lẹ́bàá òkè ní Gálílì rèé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, níwọ̀n bí a ó ti bọ́ wọn yó.” (Mátíù 5:6) Jèhófà ló fún àwọn Kristẹni ní ìlànà nípa ohun tó jẹ́ òdodo. Nítorí náà, ebi àti òùngbẹ ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run ló ń gbẹ àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ́ fún òdodo. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ̀ dájú pé ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé ni àwọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sapá lójú méjèèjì kí wọ́n lè rí ojú rere Jèhófà. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì wá mọ̀ pé tí àwọn bá ronú pìwà dà, tí àwọn sì tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní ọlá ẹbọ ìràpadà Kristi, àwọn yóò rí ojú rere Ọlọ́run!—Ìṣe 2:38; 10:43; 13:38, 39; Róòmù 5:19.

11, 12. (a) Báwo làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe di olódodo? (b) Báwo ni àwọn alábàákẹ́gbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró ṣe rí nǹkan mu sí òùngbẹ òdodo tó ń gbẹ wọ́n?

11 Jésù sọ pé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ yóò láyọ̀, nítorí pé a ó “bọ́ wọn yó.” (Mátíù 5:6) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tá a pè wá “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run ni a ti polongo ní “olódodo fún ìyè.” (Róòmù 5:1, 9, 16-18) Jèhófà sọ wọ́n di ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Wọ́n di àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, a pè wọ́n wá jẹ ọba àti àlùfáà nínú Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run.—Jòhánù 3:3; 1 Pétérù 2:9.

12 A ò tíì polongo àwọn alábàákẹ́gbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró ní olódodo fún ìyè. Àmọ́, Jèhófà kà wọ́n sí olódodo dé ìwọ̀n àyè kan nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi tí wọ́n ta sílẹ̀. (Jákọ́bù 2:22-25; Ìṣípayá 7:9, 10) Tó bá dìgbà “ìpọ́njú ńlá,” wọ́n á di olódodo tán pátápátá gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run wọ́n á sì rí ìgbàlà. (Ìṣípayá 7:14) Wọ́n á túbọ̀ rí nǹkan mu sí òùngbẹ tó ń gbẹ wọ́n fún òdodo nígbà tí wọ́n bá di ọmọ ayé tuntun nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé,” ìyẹn lábẹ́ “ọ̀run tuntun.”—2 Pétérù 3:13; Sáàmù 37:29.

Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú

13, 14. Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ ká máa gbà ṣàánú àwọn èèyàn, kí ni yóò sì jẹ́ èrè wa tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀?

13 Bí Jésù ṣe ń bá Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè lọ, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mátíù 5:7) Tó bá jẹ́ ọ̀ràn ìdájọ́ là ń sọ, àánú yóò tọ́ka sí ojú àánú tí adájọ́ kan ní tí kò fi fi gbogbo ìyà tí ó tọ́ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan lábẹ́ òfin jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀ ọ̀hún. Àmọ́, bí Bíbélì ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà tá a tú sí “àánú,” wọ́n sábà máa ń tọ́ka sí ìgbatẹnirò tàbí ojú àánú tá a ní sí àwọn aláìní kí ara lè tù wọ́n. Ìdí nìyẹn tí àwọn tó lójú àánú fi máa ń ṣe nǹkan tìyọ́nútìyọ́nú. Àkàwé Jésù nípa aláàánú ará Samáríà jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà, torí pé ó ‘hùwà tàánú-tàánú’ sí ẹnì kan tó wà nínú ìṣòro.—Lúùkù 10:29-37.

14 Tá a bá fẹ́ ní ayọ̀ tí àwọn aláàánú máa ń ní, a ní láti máa ṣoore fáwọn aláìní. (Gálátíà 6:10) Jésù máa ń ṣàánú àwọn tó bá rí. “Àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Jésù mọ̀ pé nǹkan tẹ̀mí ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn ju nǹkan tara lọ. Àwa náà lè máa ṣàánú àwọn èèyàn nípa fífún wọn ní ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní jù lọ, ìyẹn “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 24:14) A tún lè ṣe àwọn nǹkan tó jọjú fáwọn tó ti dàgbà lára àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni, àwọn opó, àtàwọn ọmọ aláìní baba, ká sì “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14; Òwe 12:25; Jákọ́bù 1:27) Kì í ṣe pé èyí máa fún wa láyọ̀ nìkan ni, àmọ́ á tún jẹ́ kí àwa náà máa rí àánú Jèhófà.—Ìṣe 20:35; Jákọ́bù 2:13.

Àwọn Ẹni Mímọ́ Gaara Ní Ọkàn-Àyà Àtàwọn Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà

15. Báwo la ṣe lè jẹ́ ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà?

15 Jésù sọ ohun kẹfà àti ìkeje tó máa jẹ́ kéèyàn láyọ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà, níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run. Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run.’” (Mátíù 5:8, 9) Ọkàn tó mọ́ gaara kì í ro èròkérò, ńṣe ló mọ́ gaara nípa tẹ̀mí, ó sì tún ṣọ̀kan nínú ìfọkànsìn Jèhófà. (1 Kíróníkà 28:9; Sáàmù 86:11) Ńṣe lẹni tó bá lẹ́mìí àlàáfíà máa ń bá àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ gbé lálàáfíà, tó bá sì ṣeé ṣe, á tún gbé lálàáfíà pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ̀. (Róòmù 12:17-21) Ńṣe ni wọ́n máa ń “wá àlàáfíà,” tí wọ́n sì ń “lépa rẹ̀.”—1 Pétérù 3:11.

16, 17. (a) Kí nìdí tá a fi ń pe àwọn ẹni àmì òróró ní “ọmọ Ọlọ́run,” ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ń “rí Ọlọ́run”? (b) Ọ̀nà wo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” gbà ń “rí Ọlọ́run”? (d) Báwo ni “àwọn àgùntàn mìíràn” yóò ṣe di “ọmọ Ọlọ́run” tán pátápátá, ìgbà wo nìyẹn sì máa ṣẹlẹ̀?

16 Ìlérí tó wà fáwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà àtàwọn tó mọ́ gaara ní ọkàn ni pé, a óò máa “pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run’” wọn yóò sì “rí Ọlọ́run.” Ọmọ tẹ̀mí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, Jèhófà sì ti sọ wọ́n di “ọmọ” kí wọ́n tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Róòmù 8:14-17) Nígbà tí wọ́n sì jíǹde lọ bá Kristi ní ọ̀run, wọ́n ń sìn níwájú Jèhófà, wọ́n sì ń rí Jèhófà lójúkojú.—1 Jòhánù 3:1, 2; Ìṣípayá 4:9-11.

17 “Àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ń sin Jèhófà lábẹ́ ìdarí Kristi Jésù, Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà, tó di “Baba Ayérayé” fún wọn. (Jòhánù 10:14, 16; Aísáyà 9:6) Àwọn tó bá wá yege ìdánwò ìkẹyìn lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi yóò di ọmọ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n “yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21; Ìṣípayá 20:7, 9) Bí wọ́n sì ti ń fojú sọ́nà fún èyí, wọ́n ń pe Jèhófà ní Baba wọn nítorí pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un, wọ́n sì gbà pé òun ni Ẹni tó fún wọn ní ìyè. (Aísáyà 64:8) Bíi ti Jóòbù àti Mósè tí wọ́n gbé láyé ọjọ́un, wọ́n ń fi ojú tẹ̀mí “rí Ọlọ́run.” (Jóòbù 42:5; Hébérù 11:27) Wọ́n ń fi ‘ojú ọkàn wọn’ àti ìmọ̀ pípéye tí wọ́n ní nípa Ọlọ́run róye àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní, wọ́n sì ń sapá láti fara wé Ọlọ́run nípa ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Éfésù 1:18; Róòmù 1:19, 20; 3 Jòhánù 11.

18. Pẹ̀lú gbogbo nǹkan méje tí Jésù sọ pé ó ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀, àwọn wo ló ń rí ayọ̀ tòótọ́ lóde òní?

18 A ti wá rí i báyìí pé àwọn tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, àwọn onínú tútù, àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo, àwọn aláàánú, àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn àtàwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ń ní ayọ̀ bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò yéé ta kò wọ́n, wọn ò sì yéé ṣe inúnibíni sí wọn. Ǹjẹ́ èyí ba ayọ̀ wọn jẹ? A ó gbé ìbéèrè yẹn yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ́ tó kàn.

Àtúnyẹ̀wò

• Irú ayọ̀ wo làwọn tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn máa ń ní?

• Àwọn ọ̀nà wo làwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ gbà ń rí ìtùnú?

• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ onínú tútù?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ aláàánú, ká jẹ́ ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn, àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́