Ẹwà Ìṣẹ̀dá Jèhófà
“Àwọn Iṣẹ́ Rẹ Mà Pọ̀ O, Jèhófà!”
ÌBÁÀ jẹ́ ìgbèríko là ń gbé tàbí ìlú ńlá, bó bá sì jẹ́ orí òkè tàbí pẹ̀tẹ́lẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ni, a óò rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ẹlẹ́wà tí Ọlọ́run dá ló yí wa ká. Ìyẹn ló fi bá a mu bí kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2004 ṣe fi onírúurú àwòyanu iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run hàn.
Látìgbà ìjímìjí títí di àkókò wa yìí làwọn tí nǹkan máa ń jọ lójú tí máa ń nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Gbé àpẹẹrẹ Sólómọ́nì yẹ̀ wò, ẹni tí ọgbọ́n rẹ̀ “pọ̀ jaburata ju ọgbọ́n gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn.” Bíbélì sọ pé: “Òun a sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, láti orí kédárì tí ó wà ní Lẹ́bánónì dórí hísópù tí ń jáde wá lára ògiri; òun a sì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko àti nípa àwọn ẹ̀dá tí ń fò àti nípa àwọn ohun tí ń rìn ká àti nípa àwọn ẹja.” (1 Àwọn Ọba 4:30, 33) Bàbá Sólómọ́nì, Dáfídì Ọba, sábà máa ń ronú nípa àwọn nǹkan ribiribi tí Ọlọ́run dá. Ohun tó rí sún un láti bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sọ̀rọ̀ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.”—Sáàmù 104:24.a
Ó yẹ káwa náà máa wo àwọn ohun tí Jèhófà dá ká sì máa ronú nípa wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwa náà lè “gbé ojú [wa] sókè réré” ká sì béèrè pé: “Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí?” Jèhófà Ọlọ́run mà ni, ẹni tó ní “ọ̀pọ̀ yanturu okun” tó sì jẹ́ ‘alágbára ńlá’ lóòótọ́!—Aísáyà 40:26.
Àwọn ọ̀nà wo ni àṣàrò tá a bá ṣe lórí àwọn ohun tí Jèhófà dá lè gbà ṣe wá láǹfààní? Ó kéré tán, ó lè ṣe wá láǹfààní lọ́nà mẹ́ta. Ó lè (1) mú ká rántí pé ó yẹ ká mọyì ìwàláàyè wa, ó lè (2) mú ká ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ látara ìṣẹ̀dá, ó sì lè (3) mú ká túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá wa ká sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Bí Ọlọ́run ṣe dá àwa èèyàn mú ká gbọ́n fíìfíì ju “àwọn ẹran tí kì í ronú,” ìyẹn ló mú ká lè máa wo àwọn ohun ìyanu tí Ọlọ́run dá kó sì jọ wá lójú. (2 Pétérù 2:12) Ojú wa máa ń wo ẹwà ojú ilẹ̀ tó jẹ́ àrímáleèlọ. Etí wa máa ń gbọ́ orin aládùn táwọn ẹyẹ máa ń kọ. Nítorí pé ọpọlọ wa máa ń rántí nǹkan, a kì í gbàgbé àkókò tá a ṣe àwọn nǹkan alárinrin àtàwọn ibi ẹlẹ́wà tá a ti lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé tá à ń gbé yìí kò rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí, síbẹ̀ ó ń gbádùn mọ́ni!
Inú àwọn òbí máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá rí bí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ṣe máa ń jọ àwọn ọmọ wọn lójú. Ẹ ò rí i bí inú àwọn ọmọdé ṣe máa ń dùn tó nígbà tí wọ́n bá ń ṣa karawun òkòtó ní etíkun, tí wọ́n bá ń bá ẹran ilé ṣeré àti nígbà tí wọ́n bá ń gun igi! Àwọn òbí yóò fẹ́ láti ran àwọn ọmọ wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé Ẹnì kan wà tó dá àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Jíjọ tí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá máa ń jọ àwọn ọmọdé lójú lè máà kúrò lára wọn ní gbogbo ìgbésí ayé wọn.—Sáàmù 111:2, 10.
Bí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá bá jọ wá lójú, àmọ́ tá ò gbé ògo rẹ̀ fún un, á jẹ́ pé òye kù fún wa nìyẹn. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Ṣé o kò tíì mọ̀ ni tàbí ṣé o kò tíì gbọ́ ni? Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Kò sí àwárí òye rẹ̀.”—Aísáyà 40:28.
Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn iṣẹ́ Jèhófà fi hàn pé ó ní ọgbọ́n tí kò láfiwé, ó fi hàn pé ó ní agbára tó ju gbogbo agbára lọ, ó sì tún fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa jinlẹ̀-jinlẹ̀. Nígbà tá a bá rí àwọn ohun ẹlẹ́wà tó wà láyìíká wa, tá a sì fòye mọ àwọn ànímọ́ Ẹni tó dá gbogbo wọn, ó yẹ kíyẹn sún wa láti sọ̀ ohun tí Dáfídì sọ, pé: “Jèhófà, kò sí ẹni tí ó dà bí rẹ . . . , bẹ́ẹ̀ ni kò sí iṣẹ́ kankan tí ó dà bí tìrẹ.”—Sáàmù 86:8.
Ó dá wa lójú pé àwọn ohun tí Jèhófà dá kò ní yéé jọ àwọn èèyàn onígbọràn lójú. Títí ayé la óò láǹfààní láti máa kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Jèhófà. (Oníwàásù 3:11) Bá a bá sì ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa tó, bẹ́ẹ̀ náà lá o ṣe máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù November àti December nínú 2004 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Wọ́n Yin Ẹlẹ́dàá
Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n mọyì àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ ló wà nísàlẹ̀ yìí:
“Ìgbà tí ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ńsì tí mo ti ń ṣiṣẹ́ túbọ̀ máa ń wù mí tó sì máa ń fún mi láyọ̀ ni ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí mo bá ṣàwárí ohun tuntun kan tí mo sì sọ fún ara mi pé, ‘Àṣé bí Ọlọ́run ṣe ṣe é rèé.’ Ohun tí mò ń wá ni pé kí n sáà ní òye bíńtín nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣe àwọn nǹkan.”—Henry Schaefer, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀ka ìmọ̀ sáyẹ́ńsì tá à ń pè ní Kẹ́mísìrì.
“Tó bá dorí ọ̀rọ̀ ohun tó ń mú kí ayé òun ìsálú ọ̀run máa fẹ̀ sí i, òǹkàwé ló máa fúnra rẹ̀ sọ ohun tó jẹ́ èrò rẹ̀ nípa ìyẹn, àmọ́, òye tá a ní nípa ohun tó mú kí ayé òun ìsálú ọ̀run máa fẹ̀ sí i kò lè kún tá ò bá fi Tirẹ̀ [Ọlọ́run] ṣe.”—Edward Milne, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ayé òun ìsálú ọ̀run.
“Gbogbo ohun tá a rí nínú ìṣẹ̀dá ló fi ọgbọ́n àgbà ìṣirò tí ò sírú ẹ̀ hàn nítorí pé Ọlọ́run ló dá wọn.”—Alexander Polyakov, oníṣirò ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà.
“Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, ńṣe là ń ṣàgbéyẹ̀wò èrò Ẹlẹ́dàá, a wá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ bó ṣe ṣètò àwọn nǹkan, à ń ṣàlàyé ètò ìṣẹ̀dá tó jẹ́ tirẹ̀, tí kì í ṣe tiwa.”—Louis Agassiz, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó jẹ́ onímọ̀ nípa ohun alààyè.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Àwọn ẹyẹ Gentoo penguin ní àgbègbè kan ní Ilẹ̀ Antarctic tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí ká
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọgbà Ìtura Grand Teton, Wyoming, ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
[Credit Line]
Jack Hoehn/Index Stock Photography