ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Màríà Magidalénì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • “Mo Ti Rí Olúwa!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ọlọ́run Ti Jí Jésù Dìde, Ibojì Rẹ̀ sì Ti Ṣófo!
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí nìdí tí Jésù fi ní kí Tọ́másì fọwọ́ kan òun àmọ́ tí kò gba Màríà Magidalénì tó ti kọ́kọ́ fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láyè?

Ọ̀nà táwọn Bíbélì kan tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ díẹ̀ gbà tú gbólóhùn yìí ló jẹ́ kò dà bíi pé ńṣe ni Jésù ń sọ fún Màríà Magidalénì pé kó má fọwọ́ kan òun rárá. Bí àpẹẹrẹ, bí Bibeli Mimọ ṣe tú ọ̀rọ̀ Jésù yìí rèé: “Máṣe fi ọwọ́ kàn mi; nitoriti emi kò ti igòke lọ sọdọ Baba mi.” (Jòhánù 20:17) Àmọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ táwọn atúmọ̀ èdè máa ń tú sí “fọwọ́ kàn” lọ́pọ̀ ìgbà túmọ̀ sí ni “dì mọ́, rọ̀ mọ́, gbá mú, dì mú.” Èyí lè mú wa gbà pé kì í ṣe òun tí Jésù ń sọ fún Màríà Magidalénì ni pé kó má fọwọ́ kan òun, nítorí pé ó gba àwọn obìnrin míì tí wọ́n wà níbi ibojì rẹ̀ láyè láti “di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú.”—Mát. 28:9.

Ọ̀pọ̀ Bíbélì tí wọ́n fi èdè tó bóde mu túmọ̀, irú bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, The New Jerusalem Bible àti The New English Bible jẹ́ ká lóye ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù yìí dáadáa. Ọ̀nà tí wọ́n gbà tú u nìyí: “Dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ mi.” Kí ló lè fà á tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀ fún Màríà Magidalénì tó mọ̀ dáadáa?—Lúùkù 8:1-3.

Láìsí àní-àní, ńṣe ni Màríà ń bẹ̀rù pé Jésù ti fẹ́ kúrò láyé tó sì fẹ́ gòkè re ọ̀run. Nítorí pé ó wu Màríà láti wà pẹ̀lú Olúwa rẹ̀ ló mú kó di Jésù mú, tí kò jẹ́ kó lọ. Kí Jésù lè fi dá Màríà lójú pé òun ò tíì lọ, Jésù sọ fún un pé kó má di òun mú, àmọ́ kó lọ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn òun pé òun ti jíǹde.—Jòhánù 20:17.

Ìjíròrò tó wáyé láàárín Jésù àti Tọ́másì yàtọ̀. Nígbà tí Jésù yọ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bíi mélòó kan, Tọ́másì ò sí níbẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Tọ́másì sọ pé òun ò gbà pé Jésù ti jíǹde àti pé òun ò ní gbà láìjẹ́ pé òun rí ojú ọgbẹ́ ibi tí wọ́n ti kan Jésù níṣòó kí òun sì fọwọ́ kan ẹgbẹ́ Jésù tí wọ́n fi ọkọ̀ gún. Ọjọ́ kẹjọ sígbà náà, Jésù tún yọ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, Tọ́másì wà níbẹ̀, Jésù sì sọ fún un pé kó wá fọwọ́ kan àwọn ojú ọgbẹ́ náà.—Jòhánù 20:24-27.

Nítorí náà, ní ti Màríà Magidalénì, ohun tó mú kí Jésù sọ gbólóhùn yẹn fún un ni pé kò fẹ́ kí Jésù lọ, èrò yẹn ò sì tọ̀nà, àmọ́ ni ti Tọ́másì, ńṣe ni Jésù ń ràn án lọ́wọ́ nítorí pé ó ń ṣiyèméjì. Nínú ọ̀ràn méjèèjì, ohun tó yẹ kí Jésù ṣe gẹ́lẹ́ ló ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́