Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ a lè tìtorí pé Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run nígbà tó di arúgbó ká wá sọ pé kò ní jíǹde?—1 Àwọn Ọba 11:3-9.
Òótọ́ ni pé Bíbélì dárúkọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan lọ́kùnrin lóbìnrin tó dájú pé wọ́n máa jíǹde, àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn tí orúkọ wọn wà nínú Bíbélì ni Bíbélì sọ ní pàtó pé wọ́n á jíǹde tàbí wọn ò ní jíǹde. (Hébérù 11:1-40) Ṣùgbọ́n ní ti Sólómọ́nì, a lè róye ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nínú ọ̀ràn tirẹ̀ tá a bá fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó kú wé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn olóòótọ́ kan nígbà tí wọ́n kú.
Ipò méjì péré ni Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn òkú wà. Yálà kó jẹ́ pé wọ́n ṣaláìsí fúngbà díẹ̀ tàbí pé wọ́n kú ikú ayérayé. Àwọn tí Ọlọ́run bá ti ṣèdájọ́ wọn pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí àjíǹde la ó jù sínú “Gẹ̀hẹ́nà” tàbí “adágún iná.” (Mátíù 5:22; Máàkù 9:47, 48; Ìṣípayá 20:14) Lára irú àwọn wọ̀nyí ni tọkọtaya kìíní, Ádámù àti Éfà, Júdásì Ísíkáríótù afinihàn àtàwọn kan tó gba ìdájọ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì kú, irú bí àwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà àtàwọn ará Sódómù àti Gòmórà.a Tí àwọn tí Ọlọ́run máa jíǹde bá kú, ipò òkú ni wọ́n wà, tí wọ́n ń pè ní Ṣìọ́ọ̀lù ní èdè Hébérù, tàbí Hédíìsì ní èdè Gíríìkì, ìyẹn àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Nígbà tí Bíbélì ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn wọ̀nyí lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.”—Ìṣípayá 20:13.
Nítorí náà, inú Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì làwọn olóòótọ́ tí Hébérù orí kọkànlá dárúkọ wà títí dìgbà àjíǹde wọn. Lára wọn ni àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run bí Ábúráhámù, Mósè àti Dáfídì. Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa wọn nígbà tí wọ́n kú. Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, ìwọ yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ ní àlàáfíà; a ó sin ọ́ ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:15) Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Ìwọ yóò dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ.” (Diutarónómì 31:16) Ní ti Dáfídì, bàbá Sólómọ́nì, Bíbélì sọ pé: “Dáfídì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì.” (1 Àwọn Ọba 2:10) Nítorí náà, gbólóhùn náà pé ẹnì kan “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀” jẹ́ ọ̀nà mìíràn láti fi sọ pé onítọ̀hún lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù.
Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Sólómọ́nì nígbà tó kú? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn ọjọ́ tí Sólómọ́nì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù lórí gbogbo Ísírẹ́lì sì jẹ́ ogójì ọdún. Nígbà náà ni Sólómọ́nì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì sin ín sí Ìlú Ńlá Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 11:42, 43) Nípa báyìí, ó jọ pé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé inú Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì ni Sólómọ́nì wà títí dìgbà tó fi máa jíǹde.
Kókó tá a sọ yìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn mìíràn tí Ìwé Mímọ́ sọ pàtó nípa wọn pé wọ́n “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá” wọn náà ní àjíǹde. Àní, púpọ̀ nínú àwọn ọba tó jẹ lẹ́yìn Sólómọ́nì ni Bíbélì lo gbólóhùn kan náà yìí fún bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ya aláìṣòótọ́. Kò sì yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Àmọ́ ṣá o, ó dẹ̀yìn ìgbà tí “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí” bá jíǹde tán pátá ká tó lè mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ kó ní àjíǹde. (Jòhánù 5:28, 29) Nítorí náà, dípò ká fi gbogbo ẹnu sọ̀rọ̀ nípa bí àjíǹde èyíkéyìí nínú àwọn ará ìgbàanì yóò ṣe jẹ́, ńṣe ló yẹ ká ní sùúrù, ká gbà gbọ́ pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà máa ṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, June 1, 1988, ojú ìwé 30 àti 31.