Ǹjẹ́ O Máa Ń Ní Àròdùn Ọkàn?
ÈRÒ òdì ni ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lena máa ń ní nípa ara rẹ̀ ṣáá. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ ló sì fi ní èrò tí kò tọ́ yìí. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi bá mi ṣèṣekúṣe nígbà tí mo wà lọ́mọdé kò jẹ́ kí n fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan lójú ara mi. Ńṣe ló dà bíi pé mi ò tiẹ̀ wúlò fún ohunkóhun.” Simone náà ronú nípa ìgbà èwe rẹ̀, ó sọ pé: “Àwọn èèyàn lè má mọ̀ o, àmọ́ nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún mi ò kì í láyọ̀ rárá, èrò mi sì ni pe mi ò já mọ́ nǹkan kan.” Ó dà bíi pé ìbànújẹ́ tí irú ẹ̀dùn ọkàn bẹ́ẹ̀ máa ń fà ti gbòde kan lóde òní. Ilé iṣẹ́ kan tó máa ń fi tẹlifóònù gba àwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn sọ pé nǹkan bí ìdajì àwọn tó máa ń tẹ̀ wọ́n láago ló máa ń sọ pé “ìgbà gbogbo lèrò pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan máa ń wá sọ́kàn àwọn.”
Ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ ni pé, táwọn èèyàn bá ń ṣe ẹnì kan bíi pé ẹni náà kò já mọ́ ohunkóhun ni onítọ̀hún náà á wá máa rò pé òun ò lè ṣe nǹkan kó dáa lóòótọ́. Tí wọ́n bá ń bẹnu àtẹ́ luni ní gbogbo ìgbà, tí wọ́n ń ṣàríwísí ẹni ṣáá, tàbí tí wọ́n bá ń ṣeni níṣekúṣe, èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí ní irú èrò òdì bẹ́ẹ̀. Ohun yòówù kó fà á, àbájáde rẹ̀ kì í dára, kódà ó lè bayé onítọ̀hún jẹ́ pátápátá. Ìwádìí kan táwọn dókítà ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn tí wọ́n ní èrò òdì nípa ara wọn máa ń rò pé kò sóhun táwọn lè ṣe tó lè dáa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í fọkàn tán àwọn ẹlòmíràn, wọ́n sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ bẹ́gi dínà àjọṣe tímọ́tímọ́ tí ì bá wà láàárín àwọn àtàwọn ẹlòmíràn, wọn kì í sì í lọ́rẹ̀ẹ́. Ìròyìn náà sọ pé: “Lọ́rọ̀ kan, ohun tí wọn ò fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ gan-an ló máa ń ṣẹlẹ̀.”
‘Ìrònú tí ń gbéni lọ́kàn sókè’ ni Bíbélì pe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó máa ń ní irú èrò òdì nípa ara wọn. (Sáàmù 94:19) Wọ́n máa ń rò pé àwọn ò lè ṣe dáadáa. Bí ohun kan kò bá lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, wọ́n á ti yára dá ara wọn lẹ́bi. Báwọn ẹlòmíràn tiẹ̀ ń yìn wọ́n nítorí àṣeyọrí tí wọ́n ṣe, nínú wọn lọ́hùn-ún, ńṣe ni wọ́n á máa wo ara wọn bí oníjìbìtì èèyàn kan táṣìírí rẹ̀ ò ní pẹ́ tú. Gbígbà tí wọ́n gbà pé àwọn ò lè láyọ̀ ti mú ki ọ̀pọ̀ lára wọn máa ṣe ohun tó lè ba ìgbésí ayé wọn jẹ́, tí wọ́n á sì máa rò pé àwọn ò lè rí nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà. Lena tá a mẹ́nu kan níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí wá dẹni tí kò lè jẹun dáadáa mọ́ nítorí pé ó ka ara rẹ̀ sẹ́ni tí kò já mọ́ nǹkan kan, ó sọ pé, “Kò sí ohun tí mo lè ṣe sí ọ̀ràn náà.”
Ṣé báwọn tó ní irú ‘ìrònú tí ń gbéni lọ́kàn sókè’ bẹ́ẹ̀ á ṣe máa ronú nípa ara wọn nìyẹn ní gbogbo ìyókù ìgbésí ayé wọn? Ǹjẹ́ a rí ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọn ò fi ní ronú bẹ́ẹ̀ mọ́? Àwọn ìlànà àti ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an wà nínú Bíbélì, èyí tó ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti bọ́ lọ́wọ́ àròdùn ọkàn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìlànà wọ̀nyí, báwo ni wọ́n sì ṣe ran àwọn tó ní àròdùn ọkàn lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ ní ìgbésí ayé wọn? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò ṣàlàyé.