Wíwá Òdodo Yóò Dáàbò Bò Wá
‘Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá òdodo Ọlọ́run.’—MÁTÍÙ 6:33.
1, 2. Ohun wo ni ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan ṣe, kí nìdí tó sì fi ṣe bẹ́ẹ̀?
NÍLẸ̀ Éṣíà, ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé ní ọ́fíìsì ìjọba. Kì í fi iṣẹ́ rẹ̀ ṣeré, ó tètè máa ń dé ibi iṣẹ́, kì í sì í ṣe ìmẹ́lẹ́. Àmọ́, níwọ̀n bí wọn ò ti gbà á pé kó máa ṣiṣẹ́ lọ títí níbẹ̀, wọ́n tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbé yẹ̀ wò. Olórí ẹ̀ka ibi tó ti ń ṣiṣẹ́ wá sọ fún ọ̀dọ́mọbìnrin náà pé, òun á gbà á kó máa bá wọn ṣíṣẹ́ lọ, òun á sì tún fún un ní ipò gíga tó bá lè gbà káwọn jọ ní àṣepọ̀. Ọ̀dọ́bìnrin náà kọ̀ jálẹ̀, kódà bí ìyẹn tiẹ̀ máa jẹ́ kó pàdánù iṣẹ́ rẹ̀.
2 Ṣé ohun tí kò bọ́gbọ́n mu ni ọ̀dọ́bìnrin Ẹlẹ́rìí yẹn ṣe? Rárá o, ńṣe ló fi ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ sílò dáadáa, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá . . . òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Ó mọ̀ pé títẹ̀lé ìlànà òdodo ṣe pàtàkì ju àǹfààní tí ìṣekúṣe máa mú wá lọ.—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Ìdí Tí Òdodo Fi Ṣe Pàtàkì
3. Kí ni òdodo?
3 “Òdodo” túmọ̀ sí kéèyàn máa hùwà tó dára kó sì jẹ́ aláìlábòsí. Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti Hébérù tí wọ́n tú sí òdodo ní ìdúróṣinṣin nínú. Kò túmọ̀ sí jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni. (Lúùkù 16:15) Ìdúróṣinṣin tó bá ìlànà Jèhófà mu ló jẹ́. Òdodo Ọlọ́run ni.—Róòmù 1:17; 3:21.
4. Kí nìdí tí òdodo fi ṣe pàtàkì fáwọn Kristẹni?
4 Kí nìdí tí òdodo fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run òdodo” máa ń fojú rere wo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣòdodo. (Sáàmù 4:1; Òwe 2:20-22; Hábákúkù 1:13) Ẹni tí kò bá ṣòdodo kò lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. (Òwe 15:8) Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rọ Tímótì pé: “Sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn, ṣùgbọ́n máa lépa òdodo,” pẹ̀lú àwọn ànímọ́ mìíràn tó ṣe pàtàkì gan-an. (2 Tímótì 2:22) Ìdí tún nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń dárúkọ oríṣiríṣi apá tí ìhámọ́ra wa tẹ̀mí ní, ó fi “àwo ìgbàyà ti òdodo” kún un.—Éfésù 6:14.
5. Báwo làwọn ẹ̀dá aláìpé ṣe lè máa wá òdodo?
5 Àmọ́ ṣá o, kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè jẹ́ olódodo tán yán-ányán-án. Gbogbo wa la ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù, ẹlẹ́ṣẹ̀ sì ni gbogbo wa, tó túmọ̀ sí pé gbogbo wa la jẹ́ aláìṣòdodo látìgbà tí wọ́n ti bí wa. Síbẹ̀ Jésù sọ pé a ní láti máa wá òdodo. Báwo nìyẹn ṣe máa ṣeé ṣe? Yóò ṣeé ṣe nípasẹ̀ ìràpadà tí Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé ṣe fún wa, tá a bá sì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ yẹn, Jèhófà yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; Róòmù 5:8, 9, 12, 18) Nípa bẹ́ẹ̀, bá a ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo Jèhófà, tá a ń sa gbogbo ipá wa láti tẹ̀ lé ìlànà náà, tá a sì tún ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí àwọn àìlera wa ni Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa. (Sáàmù 1:6; Róòmù 7:19-25; Ìṣípayá 7:9, 14) Ẹ ò rí i pé èyí tuni nínú gan-an!
Bá A Ṣe Lè Ṣòdodo Nínú Ayé Aláìṣòdodo
6. Kí nìdí tí ayé fi jẹ́ ibi eléwu fáwọn Kristẹni ìjímìjí?
6 Nígbà tí Jésù yan iṣẹ́ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní pé kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” wọ́n dojú kọ ìṣòro. (Ìṣe 1:8) Gbogbo ibi tí wọ́n yàn fún wọn láti ṣiṣẹ́ ló “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì. (1 John 5:19) Ẹ̀mí burúkú tí Sátánì ń gbé lárugẹ kúnnú ayé, ó sì lè ran àwọn Kristẹni náà. (Éfésù 2:2) Ibi eléwu ni ayé jẹ fáwọn Kristẹni wọ̀nyẹn. Kìkì nípa wíwá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ ni wọ́n fi lè fara dà á kí wọ́n sì pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Kristẹni ìjímìjí ló fara dà á, àmọ́ àwọn díẹ̀ yà kúrò ní “ipa ọ̀nà òdodo.”—Òwe 12:28; 2 Tímótì 4:10.
7. Iṣẹ́ wo la gbé láwọn Kristẹni lọ́wọ́ tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ gba àwọn ẹ̀mí tí ń sọni dìdàkudà láyè?
7 Ṣé ayé ti wá di ibi ààbò fáwọn Kristẹni lónìí? Rárá o! Ó tiẹ̀ bà jẹ́ ju bó ṣe wà ní ọ̀rúndún kìíní lọ. Láfikún síyẹn, wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń dojú ìjà burúkú kọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ìyẹn “àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára irú-ọmọ [obìnrin náà] . . . àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:12, 17) Sátánì tún ń gbéjà ko ẹni yòówù tó bá ń ti “irú ọmọ” náà lẹ́yìn. Síbẹ̀ àwọn Kristẹni ò lè sá kúrò nínú ayé yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kì í ṣe apá kan ayé, wọ́n ní láti máa gbénú ayé. (Jòhánù 17:15, 16) Wọ́n sì ní láti wàásù nínú ayé kí wọ́n lè wá àwọn olóòótọ́ ọkàn rí, kí wọ́n sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. (Matthew 24:14; 28:19, 20) Nítorí náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò sọ́gbọ́n táwọn Kristẹni máa dá tí wọ́n ò ní bá àwọn ẹ̀mí ti ń sọni dìdàkudà inú ayé yìí pàdé, wọ́n ò gbọ́dọ̀ gba àwọn ẹ̀mí náà láyè. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́rin lára wọn yẹ̀ wò.
Èèyàn Lè Kó Sínú Ìdẹkùn Ìṣekúṣe
8. Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn ọlọ́run Móábù?
8 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì parí ìrìn tí wọ́n fi ogójì ọdún rìn nínú aginjù, ọ̀pọ̀ lára wọn yà kúrò ní ọ̀nà òdodo. Wọ́n ti fojú ara wọn rí ọ̀pọ̀ ohun tí Jèhófà ṣe láti gbà wọ́n là, láìpẹ́ wọ́n yóò sì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Síbẹ̀, àkókò tó yẹ kí wọ́n wà lójúfò yẹn gan-an ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn ọlọ́run Móábù. Kí ló fà á? Nítorí pé wọ́n fàyè gba “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara” ni. (1 John 2:16) Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù.”—Númérì 25:1.
9, 10. Àwọn ohun wo ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí tó mú kó pọn dandan pé ká máa rántí ipa burúkú tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara lè ní lórí wa?
9 Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ṣe lè sọ ẹni tí kò bá fura dìdàkudà. Ó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, pàápàá nísinsìnyí tí ìṣekúṣe ti di ohun táwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà níbi gbogbo. (1 Kọ́ríńtì 10:6, 8) Ìròyìn kan láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ṣáájú ọdún 1970, àṣà kí ọkùnrin àti obìnrin jọ máa gbé láìṣègbéyàwó lòdì sófin ní gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ ìwà yìí ló wá gbòde kan nísinsìnyí. Èyí tó ju ìdajì lára gbogbo ìgbéyàwó tí wọ́n ń ṣe ló jẹ́ pé àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin náà ti ń gbé pa pọ̀ ṣáájú kí wọ́n tó ṣègbéyàwó.” Gbígbé pa pọ̀ láìṣègbéyàwó àti irú ìwà pálapàla mìíràn bẹ́ẹ̀ kò mọ sí orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo o. Wọ́n ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé, ó sì ṣeni láàánú pé àwọn Kristẹni kan ti lọ́wọ́ sírú ìwà yìí, àní wọ́n tiẹ̀ ti pàdánù àjọṣe wọn pẹ̀lú ìjọ Kristẹni.—1 Kọ́ríńtì 5:11.
10 Síwájú sí i, ó jọ pé gbogbo ọ̀nà làwọn èèyàn fi ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Àwọn fíìmù àtàwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n máa ń fi hàn pé kò sóhun tó burú rárá nínú káwọn ọ̀dọ́ máa ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Wọ́n tún ń fi hàn pé ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àtọkùnrin kò burú. Ọ̀pọ̀ eré ló túbọ̀ ń fi báwọn èèyàn ṣe ń ní ìbálòpọ̀ hàn ní kedere. Àwọn àwòrán tó ń fi ìbálòpọ̀ hàn tún rọrùn láti rí lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí àpẹẹrẹ, akọ̀ròyìn kan sọ pé ọmọkùnrin òun tó jẹ́ ọmọ ọdún méje dé láti iléèwé lọ́jọ́ kan ó sì ń sọ fóun tayọ̀tayọ̀ pé ọ̀rẹ́ òun kan nílé ìwé rí ibì kan lórí íńtánẹ́ẹ̀tì táwọn obìnrin ti wà níhòòhò tí wọ́n sì ń bára wọn ṣèṣekúṣe. Àyà bàbá náà já, àmọ́ ohun tó wá burú jù lọ ni pé ọ̀pọ̀ ọmọ ló ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì láìsọ fáwọn òbí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn òbí ni kò mọ ohun tó wà nínú eré kọ̀ǹpútà táwọn ọmọ wọn ń ṣe. Ọ̀pọ̀ eré kọ̀ǹpútà tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó ló jẹ́ pé eré oníṣekúṣe, eré ẹlẹ́mìí èṣù àti ti oníwà ipa ló wà nínú wọn.
11. Báwo ni ìdílé kan ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣekúṣe tó ń bẹ́ nínú ayé yìí?
11 Báwo ni ìdílé kan ṣe lè yàgò fún irú àwọn “eré ìnàjú” tó ń tàbùkù ẹ̀dá bẹ́ẹ̀? Nípa wíwá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ àti ṣíṣàì lọ́wọ́ nínú ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣekúṣe ni. (2 Kọ́ríńtì 6:14; Éfésù 5:3) Àwọn òbí tó ń mójú tó ohun táwọn ọmọ wọn ń ṣe tí wọ́n sì ń gbin ìfẹ́ fún Jèhófà àtàwọn òfin rẹ̀ tó jẹ́ òdodo sọ́kàn àwọn ọmọ wọn ń ran àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ gan-an. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè yẹra fáwọn àwòrán tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, àwọn eré kọ̀ǹpútà tí ń fi àwòrán oníhòòhò hàn, àwọn fíìmù tí ń fi ìṣekúṣe hàn, àtàwọn ìdẹwò mìíràn tí ń múni hùwà àìṣòdodo.— Diutarónómì 6:4-9.a
Ewú Tó Wà Nínú Ṣíṣe Ohun Táwọn Èèyàn Tó Yí Wa Ká Ń Ṣe
12. Ìṣòro wo ló wáyé ní ọ̀rúndún kìíní?
12 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Lísírà ní Éṣíà Kékeré, ó wo ọkùnrin kan sàn lọ́nà ìyanu. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Nígbà tí wọ́n rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, àwọn ogunlọ́gọ̀ náà gbé ohùn wọn sókè, wọ́n wí ní ahọ́n Likaóníà pé: ‘Àwọn ọlọ́run ti dà bí ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì ti sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ wá wá!’ Wọ́n sì ń pe Bánábà ní Súúsì, ṣùgbọ́n wọ́n ń pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun ni ó ń mú ipò iwájú nínú ọ̀rọ̀ sísọ.” (Ìṣe 14:11, 12) Ẹ̀yìn ìgbà yẹn làwọn ogunlọ́gọ̀ yìí kan náà tún fẹ́ pa Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. (Ìṣe 14:19) Ó dájú pé ohun táwọn èèyàn mìíràn ń ṣe ló nípa gan-an lórí wọn. Ó jọ pé nígbà táwọn kan láti ìpínlẹ̀ yìí di Kristẹni, wọ́n ṣì ní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni ní Kólósè, ó kìlọ̀ fún wọ́n nípa “ìjọsìn àwọn áńgẹ́lì.”—Kólósè 2:18.
13. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣà tí Kristẹni kan ní láti yẹra fún, báwo ló sì ṣe lè rí okun gbà láti yẹra fáwọn àṣà náà?
13 Lóde òní bákan náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti yẹra fáwọn àṣà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń tẹ̀ lé tó wá látinú ìsìn èké, èyí tó ta ko ìlànà Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, láwọn orílẹ̀-èdè kan, ọ̀pọ̀ ayẹyẹ táwọn èèyàn máa ń ṣe tí wọ́n bá bímọ tàbí téèyàn bá kú ló wá látinú ìgbàgbọ́ èké pé téèyàn bá kú ẹ̀mí rẹ̀ kò kú. (Oníwàásù 9:5,10) Àwọn orílẹ̀-èdè kan wà tí wọ́n ní àṣà dídá abẹ́ fún ọmọbìnrin. Ìwà ìkà ni, àṣà tí kò wúlò ni, ó sì lòdì sí ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ tó yẹ káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa fún àwọn ọmọ wọn. (Diutarónómì 6:6, 7; Éfésù 6:4) Báwo làwọn Kristẹni kò ṣe ní jẹ́ kóhun táwọn èèyàn tó yí wọn ká ń ṣe ní ipa burúkú lórí àwọn, tí wọn ò sì ní tẹ̀ lé irú àwọn àṣa bẹ́ẹ̀? Nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà pátápátá ni. (Sáàmù 31:6) Ọlọ́run òdodo yóò fún àwọn tí ń ké pè é látọkànwá lókun yóò sì bójú tó wọn, ìyẹn àwọn tí ń sọ pé: “Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.”—Sáàmù 91:2; Òwe 29:25.
Má Ṣe Gbàgbé Jèhófà
14. Ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kété kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí?
14 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n má gbàgbé òun. Ó sọ pé: “Ṣọ́ra rẹ, kí o má bàa gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, láti ṣàìpa àwọn àṣẹ rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ mọ́, tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí; kí o má bàa jẹun yó ní ti tòótọ́, kí o sì kọ́ àwọn ilé dáradára, kí o sì máa gbé inú wọn ní ti tòótọ́, kí ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti agbo ẹran rẹ sì pọ̀ sí i, kí fàdákà àti wúrà sì pọ̀ sí i fún ọ, kí gbogbo ohun tí ó jẹ́ tìrẹ sì pọ̀ sí i; kí ọkàn-àyà rẹ sì gbé sókè ní tòótọ́, kí o sì gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní tòótọ́.”—Diutarónómì 8:11-14.
15. Báwo lá ṣe lè rí i dájú pé a kò gbàgbé Jèhófà?
15 Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, tó bá jẹ́ pé ohun tí kò yẹ kó gba iwájú la lọ fi sípò iwájú. Àmọ́, tá a bá ń wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, ìjọsìn mímọ́ ni yóò jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wa. A ó ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú láti ṣe pé ká “ra àkókò tí ó rọgbọ padà” ká má sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Kólósè 4:5; 2 Tímótì 4:2) Àmọ́ ṣá o, bí a bá ka eré ìtura tàbí gbígbafẹ́ sí ohun tó ṣe pàtàkì ju lílọ sípàdé àti òde ẹ̀rí, a lè tipa bẹ́ẹ̀ gbàgbé Jèhófà, èyí sì túmọ̀ sí pé a ti fi sípò kejì nígbèésí ayé wa nìyẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:4) Àwọn Kristẹni tó ń fòótọ́ inú yẹ ara wọn wò déédéé máa ń sapá kí irú èrò yẹn má bàa nípa lórí àwọn.—2 Kọ́ríńtì 13:5.
Ṣọ́ra fún Ẹ̀mí Ohun-Tó-Wù-Mí-Ni-Màá-Ṣe
16. Ẹ̀mí tí kò dára wo ni Éfà àtàwọn kan lọ́jọ́ Pọ́ọ̀lù ní?
16 Fífẹ́ tí Éfà fẹ́ láti máa ṣe ohun tó wù ú, ló jẹ́ kí Sátánì rí i tàn jẹ lọ́gbà Édẹ́nì. Éfà fẹ́ máa fúnra rẹ̀ pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn èèyàn kan ní ìjọ Kọ́ríńtì ní irú ẹ̀mí ohun-tó-wù-mí-ni-màá-ṣe yẹn. Wọ́n rò pé àwọn nímọ̀ ju Pọ́ọ̀lù lọ, ó sì pè wọ́n ní àwọn àpọ́sítélì adárarégèé.—2 Kọ́ríńtì 11:3-5; 1 Tímótì 6:3-5.
17. Báwo la ṣe lè yẹra fún níní ẹ̀mí ohun-tó-wù-mí-ni-màá-ṣe?
17 Nínú ayé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga,” irú ìwà bẹ́ẹ̀ sì ti ran àwọn Kristẹni kan. Àwọn kan tiẹ̀ ti dẹni tó ń tá ko òtítọ́. (2 Tímótì 3:4; Fílípì 3:18) Nínú ọ̀ràn ìjọsìn, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wo Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà ká sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àtàwọn alàgbà ìjọ. Ọ̀nà kan tá a lè gbà máa wá òdodo nìyẹn, kò sì ní jẹ́ ká ní ẹ̀mí ohun-tó-wù-mí-ni-màá-ṣe. (Mátíù 24:45-47; Sáàmù 25:9, 10; Aísáyà 30:21) “Ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́” ni ìjọ àwọn ẹni àmì òróró jẹ́. Jèhófà ti gbé ìjọ náà kalẹ̀ láti dáàbò bò wá kó sì máa tọ́ wa sọ́nà. (1 Tímótì 3:15) Mímọ ipa pàtàkì tí ìjọ Ọlọ́run ń kó yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ‘ṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí ìgbéra-ẹni-lárugẹ’ bá a ti ń fìrẹ̀lẹ̀ tẹrí ba fún ìfẹ́ Jèhófà tó jẹ́ òdodo.—Fílípì 2:2-4; Òwe 3:4-6.
Ẹ Di Aláfarawé Jésù
18. Àwọn ọnà wo la gbà wá níyànjú pé ká máa gbà fara wé Jésù?
18 Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ nípa Jésù pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà burúkú.” (Sáàmù 45:7; Hébérù 1:9) Irú ẹ̀mí rere yìí mà dára láti tẹ̀ lé o! (1 Kọ́ríńtì 11:1) Kì í ṣe pé Jésù mọ àwọn ìlànà Jèhófà nìkan, ó tún nífẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Sátánì dán Jésù wò ní aginjù, Jésù kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní kúrò ní “ipa ọ̀nà òdodo.”—Òwe 8:20; Mátíù 4:3-11.
19, 20. Kí làwọn àbájáde rere tó ń wá látinú wíwá òdodo?
19 Òótọ́ ni pé àwọn ìfẹ́ ti ara tí kò bá òdodo mu máa ń lágbára. (Róòmù 7:19, 20) Àmọ́, bí òdodo bá ṣeyebíye lójú wa, èyí yóò fún wa lókun láti yẹra fún ìwà ibi. (Sáàmù 119:165) Bá a bá nífẹ̀ẹ́ òdodo jinlẹ̀jinlẹ̀, yóò dáàbò bò wá nígbà tí ìfẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́ bá wá sọ́kàn wa. (Òwe 4:4-6) Ẹ rántí pé ìgbàkígbà tá a juwọ́ sílẹ̀ fún ìdẹwò, Sátánì lá mú kó ṣẹ́gun yẹn. Ohun tó dára jù ni pé ká má gba Èṣù láyè kí ògo lè jẹ́ ti Jèhófà!—Òwe 27:11; Jákọ́bù 4:7, 8.
20 Nítorí pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ń wá òdodo, wọ́n “kún fún èso òdodo, èyí tí í ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.” (Fílípì 1:10, 11) Wọ́n ń gbé “àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.” (Éfésù 4:24) Ti Jèhófà ni wọ́n jẹ́, wọ́n sì wà láàyè láti máa sìn ín, kì í ṣe láti máa ṣe ohun tó wù wọ́n. (Róòmù 14:8; 1 Pétérù 4:2) Èyí ló ń dárí ìrònú àti ìṣe wọn. Ẹ sì wo bí wọ́n ṣe ń múnú Bàbá wọn ọ̀run dùn!—Òwe 23:24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn àbá nípa bí àwọn òbí ṣe lè dáàbò bo ìdílé wọn láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe wà nínú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti wá òdodo?
• Báwo làwọn Kristẹni aláìpé ṣe lè wá òdodo?
• Àwọn ohun wo làwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún nínú ayé yìí?
• Báwo ni wíwá òdodo ṣe ń dáàbò bò wá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ibi eléwu ni ayé yìí jẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn ọmọ tá a kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà yóò ní okun tẹ̀mí láti yẹra fún ìṣekúṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan gbàgbé Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n ti dọlọ́rọ̀ ní Ilẹ̀ Ìlérí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn Kristẹni kórìíra àìṣòdodo bí Jésù ṣe kórìíra rẹ̀