ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 36
Àwa Èèyàn Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Òdodo
“Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ.”—MÁT. 5:6.
ORIN 9 Jèhófà Ni Ọba Wa!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Àdánwò wo ni Jósẹ́fù dojú kọ, kí ló sì ṣe?
JÓSẸ́FÙ ọmọ Jékọ́bù dojú kọ àdánwò kan tó le gan-an. Obìnrin kan sọ fún un pé: “Wá bá mi sùn.” Ìyàwó Pọ́tífárì ni obìnrin náà. Àmọ́ Jósẹ́fù ò gbà. Ẹnì kan lè sọ pé, ‘Kí nìdí tí Jósẹ́fù ò fi gbà?’ Ó ṣe tán Pọ́tífárì ò sí nílé. Yàtọ̀ síyẹn, ẹrú ni Jósẹ́fù níbẹ̀, tí ò bá sì gbà, obìnrin yẹn lè fayé ni ín lára. Síbẹ̀ Jósẹ́fù ò gbà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ló ń fúngun mọ́ ọn. Kí nìdí tí ò fi gbà? Ó sọ pé: “Ṣé ó wá yẹ kí n hùwà burúkú tó tó báyìí, kí n sì ṣẹ Ọlọ́run?”—Jẹ́n. 39:7-12.
2. Báwo ni Jósẹ́fù ṣe mọ̀ pé ìwà burúkú ni àgbèrè lójú Ọlọ́run?
2 Báwo ni Jósẹ́fù ṣe mọ̀ pé ‘ìwà burúkú’ ni àgbèrè lójú Ọlọ́run? Ó ṣe tán, ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún lẹ́yìn tí nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù ni Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin tó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè.” (Ẹ́kís. 20:14) Síbẹ̀, Jósẹ́fù mọ̀ pé Jèhófà ò fẹ́ ká ṣàgbèrè, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì mọ Òfin yìí nígbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, Jósẹ́fù mọ̀ pé Jèhófà ṣètò ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan. Ó sì ṣeé ṣe kó ti gbọ́ nípa bí Jèhófà ṣe gba Sérà ìyá bàba bàbá ẹ̀ sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ bá a ṣàgbèrè. Nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe ohun kan náà sí Rèbékà ìyàwó Ísákì, Jèhófà gba òun náà sílẹ̀. (Jẹ́n. 2:24; 12:14-20; 20:2-7; 26:6-11) Bí Jósẹ́fù ṣe ń ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ó mọ ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ lójú Ọlọ́run. Torí pé Jósẹ́fù nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà òdodo rẹ̀, ó pinnu pé ohun tó tọ́ lòun máa ṣe.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Ṣé o nífẹ̀ẹ́ òdodo? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ torí pé aláìpé ni gbogbo wa, tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé a ò nífẹ̀ẹ́ òdodo bíi tàwọn èèyàn ayé. (Àìsá. 5:20; Róòmù 12:2) Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa mọ ohun tí òdodo jẹ́ àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣòdodo. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká ṣe ká lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà Jèhófà.
KÍ NI ÒDODO?
4. Èrò tí ò tọ́ wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn ní nípa ohun tí òdodo jẹ́?
4 Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olódodo, ọ̀pọ̀ ló gbà pé ẹni náà ní láti jẹ́ agbéraga, ó máa ń dá àwọn míì lẹ́jọ́, ó sì gbà pé òun dáa ju àwọn tó kù lọ. Àmọ́ inú Ọlọ́run ò dùn sí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó dẹ́bi fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó gbé ìlànà òdodo tiwọn kalẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe òdodo àṣelékè. (Oníw. 7:16; Lúùkù 16:15) Ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ìlànà òdodo Jèhófà kì í ronú pé òun dáa ju àwọn ẹlòmíì lọ.
5. Kí ni Bíbélì sọ pé òdodo jẹ́? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.
5 Ànímọ́ tó dáa ni òdodo. Ní ṣókí, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. Nínú Bíbélì, tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olódodo, ó túmọ̀ sí pé ẹni náà ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà délẹ̀délẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé ‘òṣùwọ̀n tó tọ́’ ni káwọn oníṣòwò máa lò. (Diu. 25:15) Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “tọ́” tún lè túmọ̀ sí “òdodo.” Torí náà, tí Kristẹni kan bá fẹ́ jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nídìí iṣẹ́ tó ń ṣe. Ẹni tó jẹ́ olódodo máa ń ṣèdájọ́ òdodo, inú ẹ̀ kì í sì í dùn tí wọ́n bá rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ronú lórí ojú tí Jèhófà máa fi wo nǹkan tóun fẹ́ ṣe torí pé ó fẹ́ “ṣe ìfẹ́ [Jèhófà] ní kíkún.”—Kól. 1:10.
6. Kí ló mú ká gbà pé Jèhófà nìkan ló mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? (Àìsáyà 55:8, 9)
6 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni òdodo ti wá. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “ibùgbé òdodo.” (Jer. 50:7) Torí pé Jèhófà ló dá wa, òun nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bóyá ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́. Àmọ́ aláìpé làwa èèyàn, a sì máa ń dẹ́ṣẹ̀, ìdí nìyẹn tá a kì í fi í mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n ẹni pípé ni Jèhófà ní tiẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi máa ń mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Òwe 14:12; ka Àìsáyà 55:8, 9.) Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara ẹ̀, ìyẹn mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo ẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Ó sì máa ń wu àwa náà pé ká ṣe ohun tó tọ́. Torí náà, ìfẹ́ tá a ní fún Bàbá wa ọ̀run ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fìwà jọ ọ́.—Éfé. 5:1.
7. Kí nìdí táwọn ìlànà pàtó kan fi gbọ́dọ̀ wà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé? Sọ àpẹẹrẹ kan.
7 A máa jàǹfààní tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tíì bá ṣẹlẹ̀ ká sọ pé àwọn ilé iṣẹ́ tó ń bá àwọn èèyàn kọ́lé ò ní ìdíwọ̀n pàtó tí wọ́n ń lò, àmọ́ tí kálukú wọn ń ṣe ohun tó wù ú. Jàǹbá ló máa yọrí sí. Tí àwọn dókítà náà ò bá sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà fún ìtọ́jú ara, àwọn aláìsàn lè kú. Torí náà, ó dájú pé ìlànà pàtó kan gbọ́dọ̀ wà táwọn èèyàn á máa tẹ̀ lé kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀. Lọ́nà kan náà, àwọn ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ máa ń dáàbò bò wá.
8. Kí ni Jèhófà máa ṣe fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo?
8 Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀. Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.” (Sm. 37:29) Ẹ wo bí ayé ṣe máa rí tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. Gbogbo èèyàn máa wà níṣọ̀kan, àlàáfíà máa wà, inú wa á sì máa dùn. Bí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa nìyẹn. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú ká nífẹ̀ẹ́ òdodo! Àmọ́ kí lá mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òdodo? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tá a lè ṣe.
TÚBỌ̀ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÌLÀNÀ JÈHÓFÀ
9. Kí ló máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òdodo?
9 Àkọ́kọ́: Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fi ìlànà òdodo lélẹ̀. Tá a bá fẹ́ nífẹ̀ẹ́ òdodo, ó yẹ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹni tó fún wa ní ìlànà nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Bá a bá ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i, bẹ́ẹ̀ lá máa wù wá láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé Ádámù àti Éfà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni, wọn ò bá ti gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu.—Jẹ́n. 3:1-6, 16-19.
10. Kí ni Ábúráhámù ṣe kó lè túbọ̀ mọ bí Jèhófà ṣe ń ṣe nǹkan?
10 A ò ní fẹ́ ṣe àṣìṣe tí Ádámù àti Éfà ṣe. Tá ò bá fẹ́ kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ká mọyì àwọn ànímọ́ rẹ̀, ká sì máa ronú lọ́nà tó ń gbà ronú. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà á túbọ̀ máa lágbára sí i. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù yẹ̀ wò. Ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé láwọn ìgbà kan, ó ṣòro fún un láti mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe àwọn ìpinnu kan, Ábúráhámù ò torí ìyẹn kẹ̀yìn sí Jèhófà. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ló gbìyànjú láti túbọ̀ mọ ẹni tí Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó gbọ́ pé Jèhófà fẹ́ pa Sódómù àti Gòmórà run, Ábúráhámù kọ́kọ́ rò pé “Onídàájọ́ gbogbo ayé” máa pa àwọn èèyàn burúkú pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olódodo. Ábúráhámù gbà pé Jèhófà ò ní ṣe irú ẹ̀ láé, torí náà ó fìrẹ̀lẹ̀ bi Jèhófà láwọn ìbéèrè kan, Jèhófà náà sì fi sùúrù dá a lóhùn. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ábúráhámù rí i pé Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn gbogbo àwa èèyàn, kì í sì í fìyà jẹ àwọn aláìṣẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.—Jẹ́n. 18:20-32.
11. Kí ni Ábúráhámù ṣe tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e?
11 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Ábúráhámù sọ nípa ìlú Sódómù àti Gòmórà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ó dájú pé ìyẹn mú kó túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Bàbá ẹ̀, kó sì bọ̀wọ̀ fún un ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó dán ìgbàgbọ́ Ábúráhámù nínú Jèhófà wò. Jèhófà ní kó fi Ísákì ọmọ ẹ̀ kan ṣoṣo rúbọ sí òun. Àmọ́ ní báyìí, Ábúráhámù ti túbọ̀ mọ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, torí náà lọ́tẹ̀ yìí kò bi Jèhófà ní ìbéèrè kankan. Ṣe ni Ábúráhámù kàn lọ ṣe ohun tí Jèhófà ní kó ṣe. Ẹ wo ìdààmú tó máa bá Ábúráhámù bó ṣe ń múra láti lọ fi ọmọ ẹ̀ rúbọ! Ó dájú pé Ábúráhámù ti ronú jinlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó kọ́ nípa Jèhófà. Ó mọ̀ pé Jèhófà ò ní hùwà ìkà láé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Ábúráhámù gbà pé Jèhófà lè jí Ísákì ọmọ òun dìde. (Héb. 11:17-19) Ó ṣe tán, Jèhófà ti ṣèlérí pé Ísákì máa di bàbá orílẹ̀-èdè, Ísákì ò sì tíì bí ọmọ kankan lásìkò yẹn. Torí pé Ábúráhámù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó fọkàn tán Jèhófà pé ohun tó tọ́ ló máa ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe ò rọrùn, ó nígbàgbọ́, ó sì ṣègbọràn.—Jẹ́n. 22:1-12.
12. Báwo la ṣe lè fara wé Ábúráhámù? (Sáàmù 73:28)
12 Báwo la ṣe lè fara wé Ábúráhámù? Bíi ti Ábúráhámù, ó yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka Sáàmù 73:28.) A máa dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn á sì jẹ́ ká máa ronú lọ́nà tí Jèhófà ń gbà ronú. (Héb. 5:14) Torí pé a ti dá ẹ̀rí ọkàn wa lẹ́kọ̀ọ́, tẹ́nì kan bá sọ pé ká ṣe ohun tí ò dáa, a ò ní gbà. Ìdí sì ni pé a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà, tó sì máa ba àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ jẹ́. Àmọ́ nǹkan míì wo la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òdodo?
13. Báwo la ṣe lè máa wá òdodo? (Òwe 15:9)
13 Ìkejì: Máa ṣe ohun táá jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ òdodo lójoojúmọ́. Tí ẹnì kan bá fẹ́ kí iṣan ara òun le dáadáa, ó gba pé kó máa ṣeré ìmárale déédéé. Bẹ́ẹ̀ náà ló gba iṣẹ́ àṣekára tá a bá máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Ohun tó yẹ ká máa ṣe lójoojúmọ́ ni. Jèhófà máa ń gba tiwa rò, kò sì retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. (Sm. 103:14) Ó fi dá wa lójú pé òun “nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń wá òdodo.” (Ka Òwe 15:9.) Tá a bá ní ohun kan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àá máa sapá kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ẹ́. Ohun kan náà la máa ṣe tá a bá ń wá òdodo. Jèhófà á máa fi sùúrù ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ síwájú, àá sì máa sunwọ̀n sí i bá a ṣe ń wá òdodo.—Sm. 84:5, 7.
14. Kí ni “àwo ìgbàyà òdodo,” kí sì nìdí tá a fi nílò ẹ̀?
14 Nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, ó jẹ́ ká mọ̀ pé kò nira fún wa láti máa ṣòdodo. (1 Jòh. 5:3) Torí náà, tá a bá ń ṣòdodo, ó máa dáàbò bò wá lójoojúmọ́. Ṣé ẹ rántí ìhámọ́ra ogun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀? (Éfé. 6:14-18) Èwo nínú àwọn ìhámọ́ra yẹn ló máa ń dáàbò bo ọkàn àwọn ọmọ ogun? “Àwo ìgbàyà òdodo” tó ṣàpẹẹrẹ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà ni. Bí àwo ìgbàyà ṣe máa ń dáàbò bo ọkàn ọmọ ogun kan, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìlànà òdodo Jèhófà máa ń dáàbò bo èrò inú wa, ìyẹn ẹni tá a jẹ́ gan-an. Torí náà, rí i pé àwo ìgbàyà òdodo wà lára ìhámọ́ra ogun rẹ!—Òwe 4:23.
15. Báwo lo ṣe lè gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀?
15 Báwo lo ṣe lè gbé àwo ìgbàyà òdodo wọ̀? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń ronú nípa àwọn ìlànà Jèhófà kó o tó ṣèpinnu. Tó o bá fẹ́ pinnu irú ọ̀rọ̀ tó o máa sọ, eré ìnàjú tó o máa wò, orin tó o máa gbọ́ àti irú ìwé tó o máa kà, kọ́kọ́ bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo fi ń bọ́ ọkàn mi? Ṣé Jèhófà máa fọwọ́ sí àwọn nǹkan tí mò ń ṣe, ṣé inú ẹ̀ sì máa dùn sí mi? Ṣé àwọn nǹkan yìí máa mú kí n ṣèṣekúṣe, mú kí n hùwà ipá, kí n di oníwọra àti onímọtara-ẹni-nìkan?’ (Fílí. 4:8) Torí náà, tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí inú Jèhófà dùn sí lo pinnu láti máa ṣe, o ò ní máa ro èròkerò, ìlànà òdodo Jèhófà sì máa dáàbò bo ọkàn ẹ.
Òdodo ẹ máa “dà bí ìgbì òkun” (Wo ìpínrọ̀ 16-17)
16-17. Kí ni Àìsáyà 48:18 sọ tó jẹ́ kó dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe fún wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà títí láé?
16 Ṣé o máa ń bẹ̀rù pé o ò ní lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ? Ẹ jẹ́ ká wo àfiwé tí Jèhófà lò nínú Àìsáyà 48:18. (Kà á.) Jèhófà ṣèlérí pé òdodo wa máa “dà bí ìgbì òkun.” Jẹ́ ká sọ pé o wà létí òkun kan tí ìgbì òkun ń lọ, tó sì ń bọ̀ láìdáwọ́ dúró. Bó o ṣe dúró síbẹ̀, ṣé wàá máa ronú pé ìgbì náà máa dáwọ́ dúró lọ́jọ́ kan? Rárá o! Ìdí ni pé o mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni ìgbì yẹn ti wà níbẹ̀, kò sì ní yéé ru gùdù.
17 Òdodo tìẹ náà lè dà bí ìgbì òkun yẹn. Lọ́nà wo? Kó o tó ṣèpinnu, kọ́kọ́ ronú nípa nǹkan tí Jèhófà máa fẹ́ kó o ṣe. Tó o bá ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe, ṣe nǹkan náà. Kò sí bí ìpinnu náà ṣe le tó, máa rántí pé Jèhófà Bàbá ẹ onífẹ̀ẹ́ ò ní fi ẹ́ sílẹ̀, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀ lójoojúmọ́.—Àìsá. 40:29-31.
18. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa fi ìlànà tá a gbé kalẹ̀ fúnra wa dá àwọn míì lẹ́jọ́?
18 Ìkẹta: Gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Bá a ṣe ń sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà lójoojúmọ́, kò yẹ ká máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ tàbí ká di olódodo àṣelékè. Dípò ká máa fi ìlànà tiwa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà ni “Onídàájọ́ gbogbo ayé.” (Jẹ́n. 18:25) Jèhófà ò sì bẹ̀ wá níṣẹ́ pé ká máa bá òun dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Kódà, Jésù pàṣẹ fún wa pé: “Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.”—Mát. 7:1.b
19. Kí ni Jósẹ́fù ṣe tó fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa dájọ́ lọ́nà tó tọ́?
19 Ẹ jẹ́ ká tún gbé àpẹẹrẹ Jósẹ́fù yẹ̀ wò. Kò dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ títí kan àwọn tó hùwà ìkà sí i. Àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ lù ú, wọ́n tà á sóko ẹrú, wọ́n sì jẹ́ kí bàbá wọn gbà pé ó ti kú. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Jósẹ́fù àti ìdílé ẹ̀ tún jọ wà pa pọ̀. Lásìkò yẹn, ó ti di olórí orílẹ̀-èdè kan, torí náà ó lè sọ pé òun á fìyà jẹ àwọn ẹ̀gbọ́n òun, òun á sì gbẹ̀san lára wọn. Ẹ̀rù wá ń ba àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù pé ó lè jẹ́ nǹkan tó máa ṣe fún wọn gan-an nìyẹn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà. Àmọ́ Jósẹ́fù fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù. Ṣé èmi ni Ọlọ́run ni?” (Jẹ́n. 37:18-20, 27, 28, 31-35; 50:15-21) Ìrẹ̀lẹ̀ mú kí Jósẹ́fù gbà pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dáni lẹ́jọ́.
20-21. Kí ni kò ní jẹ́ ká di olódodo àṣelékè?
20 Bíi ti Jósẹ́fù, ó yẹ ká fi ìdájọ́ lé Jèhófà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, a ò ní sọ pé a mọ ìdí táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa fi ṣe nǹkan tí wọ́n ṣe. A ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, torí pé ‘Jèhófà nìkan ló máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn.’ (Òwe 16:2) Gbogbo èèyàn ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ láìka ibi tí wọ́n ti wá sí àti àṣà ìbílẹ̀ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbà wá níyànjú pé ká “ṣí ọkàn [wa] sílẹ̀ pátápátá.” (2 Kọ́r. 6:13) Lọ́nà kan náà, gbogbo àwọn ará wa ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́, kò yẹ ká máa dá wọn lẹ́jọ́.
21 Kì í ṣe àwọn ará nìkan ni kò yẹ ká máa dá lẹ́jọ́, kò tún yẹ ká máa dá àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́. (1 Tím. 2:3, 4) Ṣé o máa ń dá àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́, kó o wá máa sọ pé, “Ọkùnrin yẹn ò lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láé”? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ torí ìyẹn máa fi hàn pé o ti ń kọjá àyè ẹ, o sì ń ṣe òdodo àṣelékè. Ìdí sì ni pé Jèhófà ṣì ń “fún gbogbo èèyàn níbi gbogbo” láyé ní àǹfààní láti ronú pìwà dà. (Ìṣe 17:30) Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé lójú Jèhófà, aláìṣòdodo làwọn tó bá ń ṣe òdodo àṣelékè.
22. Kí ló mú kó o pinnu pé wàá máa nífẹ̀ẹ́ òdodo?
22 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà, inú wa máa dùn, àá sì di àpẹẹrẹ rere fáwọn èèyàn. Kódà, á mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, kí wọ́n sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà náà. Torí náà, ẹ jẹ́ kí ‘ebi òdodo máa pa wá, kí òùngbẹ òdodo sì máa gbẹ wá.’ (Mát. 5:6) Ó dájú pé Jèhófà ń kíyè sí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, inú ẹ̀ sì ń dùn sí ẹ bó o ṣe ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn túbọ̀ ń hùwà àìṣòdodo nínú ayé yìí, fọkàn balẹ̀! Máa rántí pé “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo.”—Sm. 146:8.
ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
a Nínú ayé burúkú yìí, ó ṣòro kéèyàn tó rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òdodo tó sì fẹ́ ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń ṣe ohun tó tọ́ lákòókò wa yìí. Ó dájú pé ìwọ náà wà lára wọn. Ìdí tó o fi nífẹ̀ẹ́ òdodo ni pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Jèhófà náà sì nífẹ̀ẹ́ òdodo. Àmọ́, báwo la ṣe lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òdodo? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa mọ ohun tí òdodo jẹ́ àti bí ayé wa ṣe lè dáa sí i tá a bá ń ṣòdodo. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òdodo.
b Nígbà míì, ó máa ń pọn dandan fáwọn alàgbà láti gbọ́ ẹjọ́ àwọn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá àtàwọn tó ronú pìwà dà. (1 Kọ́r. 5:11; 6:5; Jém. 5:14, 15) Síbẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ gbọ́dọ̀ mú kí wọ́n gbà pé àwọn ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, kí wọ́n sì máa rántí pé Jèhófà ni wọ́n ń ṣojú fún tí wọ́n bá ń dájọ́. (Fi wé 2 Kíróníkà 19:6.) Torí náà bíi ti Jèhófà, tí wọ́n bá ń dájọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ fàánú hàn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúṣàájú.