ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 1/1 ojú ìwé 30
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Máa Fi Ojú Tó Tọ́ Wo Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Wa Yìí Yóò Pa Run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Jèhófà Ń fi Bí a ó Ṣe Máa Ka Àwọn Ọjọ́ Wa Hàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Jèhófà Fẹ́ Ká Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 1/1 ojú ìwé 30

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìwé Sáàmù 102:26 sọ pé ayé àti ọ̀run “yóò ṣègbé.” Ṣé ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run yóò pa ilẹ̀ Ayé run?

Nínú àdúrà tí ẹni tó kọ sáàmù yìí gbà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó; àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó. Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò pààrọ̀ wọn, wọn yóò sì lo ìgbà wọn parí.” (Sáàmù 102:25, 26) Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí àwọn ẹsẹ yìí ká fi hàn pé kì í ṣe pípa ayé àti ọ̀run rẹ́ làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí kò ṣe wíwà tí Ọlọ́run wà títí ayérayé. Àwọn ọ̀rọ̀ tó yí àwọn ẹsẹ náà ká tún jẹ́ ká mọ ìdí tí kókó pàtàkì yìí fi jẹ́ ìtùnú fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

Onísáàmù yìí, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbèkùn ló wà ní Bábílónì lákòókò yẹn, bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ bí àwọn ìpọ́njú rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Ó kédàárò pé, ìgbésí ayé òun kúrú “bí èéfín” tí kì í pẹ́ pòórá. Ìdààmú ọkàn rẹ̀ tó lékenkà ti ba àgọ́ ara rẹ̀ jẹ́, ó ti mú kó dà bíi pé ńṣe làwọn egungun rẹ̀ ń “gbóná yoyo gẹ́gẹ́ bí ibi ìdáná.” Kò lókun nínú mọ́, ó “gbẹ dànù bí ewéko lásán-làsàn,” ó sì dà “bí ẹyẹ tí ó dá wà lórí òrùlé.” Àwọn àdánwò rẹ̀ kò jẹ́ kí oúnjẹ wù ú jẹ, inú ìbànújẹ́ ló sì ń wà lójoojúmọ́. (Sáàmù 102:3-11) Àmọ́ síbẹ̀, onísáàmù yìí kò sọ̀rètínù rárá. Kí nìdí? Nítorí ohun tí Jèhófà ṣèlérí láti ṣe fún Síónì tàbí Jerúsálẹ́mù ni.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ti pa Síónì run, Jèhófà ṣèlérí pé òun á tún mú kó padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. (Aísáyà 66:8) Nípa bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ ni onísáàmù náà fi sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ yóò ṣàánú fún Síónì, nítorí pé ó jẹ́ àsìkò láti ṣe ojú rere sí i, nítorí pé àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti dé. Nítorí ó dájú pé Jèhófà yóò gbé Síónì ró.” (Sáàmù 102:13, 16) Lẹ́yìn èyí ni onísáàmù náà wá padà sórí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ń fojú winá rẹ̀. Lẹ́nu kan, ó ronú pé, bí Ọlọ́run bá lè fi agbára rẹ̀ mú ìlú Jerúsálẹ́mù tó ti dahoro padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ó dájú pé Jèhófà lè yọ òun nínú ipò ìbànújẹ́ tí òun wà. (Sáàmù 102:17, 20, 23) Ohun kan ṣì tún wà o, tó mú kí onísáàmù náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Kí lohun náà? Ìyẹn ni wíwà tí Ọlọ́run wà títí ayérayé.

Wíwà tí Jèhófà wà títí ayérayé kò ṣeé fi wé kíkúrú tí ìgbésí ayé onísáàmù náà kúrú. Ó sọ fún Jèhófà pé: “Jálẹ̀jálẹ̀ ìran-ìran ni àwọn ọdún rẹ.” (Sáàmù 102:24) Onísáàmù náà tún sọ pé: “Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni ìwọ ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”—Sáàmù 102:25.

Kódà, a ò lè fi wíwà tí ilẹ̀ ayé àti ọ̀run ti wà tipẹ́tipẹ́ wé bí Jèhófà ṣe wà títí ayérayé. Onísáàmù náà wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn [ayé àti ọ̀run] tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó.” (Sáàmù 102:26) Ayé àti ọ̀run lè ṣègbé. Òótọ́ ni pé lápá ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́, Jèhófà sọ pé ayé àtọ̀run yóò wà títí láé. (Sáàmù 119:90; Oníwàásù 1:4) Àmọ́ wọ́n ṣeé pa run, tó bá jẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ẹ nìyẹn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò lè kú. Nítorí pé Ọlọ́run ń mójú tó àwọn nǹkan tó dá ló jẹ́ kí wọ́n “dúró títí láé.” (Sáàmù 148:6) Bí Jèhófà kò bá sọ àwọn ohun tó dá dọ̀tun mọ́, “gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, [ni] gbogbo wọn yóò gbó.” (Sáàmù 102:26) Bí èèyàn ṣe máa ń wà nìṣó lẹ́yìn tí aṣọ rẹ̀ bá ti gbó, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà yóò máa wà nìṣó nígbà táwọn ohun tó dá kò bá sí mọ́, tó bá jẹ́ bó ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn. Àmọ́, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn jẹ́ ká mọ̀ pé ìyẹn kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé àṣẹ Jèhófà ni pé kí ayé àti ọ̀run máa wà lọ títí láé.—Sáàmù 104:5.

Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà kò ní ṣàì mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ jẹ́ ohun tó ń tù wá nínú. Láìka irú àdánwò yòówù tó lè dé bá wa sí, bá a bá ké pè é, ọkàn wa balẹ̀ pé dájúdájú “òun yóò yíjú sí àdúrà àwọn tí a kó gbogbo nǹkan ìní wọn lọ, kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àdúrà wọn.” (Sáàmù 102:17) Láìsí àní-àní, ìdánilójú tí Jèhófà fún wa pé òun yóò máa tì wá lẹ́yìn, èyí tó wà nínú Sáàmù kejìlélọ́gọ́rùn-ún [102], tiẹ̀ tún fìdí múlẹ̀ ju ayé tá a dúró lé lórí lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́