ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 2/15 ojú ìwé 21-25
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Ń kó Àwọn Ohun Ti Ọ̀run àti Ti Ayé Jọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ọlọ́run Ṣe Ń kó Àwọn Ohun Ti Ọ̀run àti Ti Ayé Jọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run”
  • Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ sí Kó Wọn Jọ Pọ̀
  • Jésù Bá Wọn Dá Májẹ̀mú Ìjọba
  • Jíjẹ Búrẹ́dì àti Mímu Wáìnì Nígbà Ìrántí Ikú Kristi
  • Kíkó “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Lórí Ilẹ̀ Ayé” Jọ
  • Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìdí Tí A Fi Ń Lọ Síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Báwo Ni Wọ́n Ṣe Ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Idi Ti Ounjẹ Alẹ́ Oluwa Fi Ní Itumọ Fun Ọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 2/15 ojú ìwé 21-25

Bí Ọlọ́run Ṣe Ń kó Àwọn Ohun Ti Ọ̀run àti Ti Ayé Jọ

“Ó jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìdùnnú rere rẹ̀ . . . láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.”—ÉFÉSÙ 1:9, 10.

1. Kí ni “ìdùnnú rere” Jèhófà fún ọ̀run àti ayé?

OHUN àgbàyanu tí Jèhófà, “Ọlọ́run àlàáfíà,” ń fẹ́ ni pé kí àlàáfíà jọba láyé àti lọ́run. (Hébérù 13:20) Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé “ìdùnnú rere” òun ni “láti tún kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 1:9, 10) Kí ni ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì tá a tú sí ‘tún kó jọ pọ̀’ nínú ẹsẹ yìí wá ń fi hàn pé ó máa ṣẹlẹ̀? Ọ̀mọ̀wé J. B. Lightfoot tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa Bíbélì sọ pé: “Gbólóhùn náà túmọ̀ sí pé gbogbo ẹ̀dá ayé àtọ̀run máa wà níṣọ̀kan pátápátá, kò ní sí oníwà àjèjì kankan tó jẹ́ màdàrú mọ́, gbogbo ẹ̀dá yóò sì fìmọ̀ ṣọ̀kan nínú Kristi. Kò sì ní sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, ìbànújẹ́ àti ìjákulẹ̀ àti ìyà mọ́.”

“Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ ní Ọ̀run”

2. Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” tí Ọlọ́run máa kó jọ pọ̀?

2 Àpọ́sítélì Pétérù ṣe àkópọ̀ ìrètí àgbàyanu táwọn Kristẹni tòótọ́ ní nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ìṣàkóso tuntun, ìyẹn Ìjọba Mèsáyà, ni “ọ̀run tuntun” tí ibí yìí sọ pé à ń retí. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Éfésù ni pé Ọlọ́run máa kó “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” jọ pọ̀ “nínú Kristi.” Àwọn èèyàn kéréje tí Ọlọ́run yàn pé kó bá Kristi ṣàkóso lọ́run ni àwọn tí Pọ́ọ̀lù ń wí. (1 Pétérù 1:3, 4) Kristẹni ẹni àmì òróró ni wọ́n, iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì. Ọlọ́run ‘rà wọ́n lára aráyé’ àní “láti ilẹ̀ ayé wá,” kí wọ́n lè di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run.—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:3, 4; 2 Kọ́ríńtì 1:21; Éfésù 1:11; 3:6.

3. Báwo la ṣe lè sọ pé àwọn ẹni àmì òróró “jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run” àní nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé?

3 Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ bí àwọn ẹni àmì òróró, ìyẹn ni pé ó fi tún wọn bí kí wọ́n lè di ọmọ Jèhófà nípa tẹ̀mí. (Jòhánù 1:12, 13; 3:5-7) Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti ‘sọ wọ́n di ọmọ’ rẹ̀, wọ́n ti di arákùnrin Jésù nìyẹn. (Róòmù 8:15; Éfésù 1:5) Ìdí nìyí tí Ìwé Mímọ́ fi sọ pé a ‘gbé wọn dìde pa pọ̀, a sì mú wọn jókòó pa pọ̀ ní àwọn ibi ọ̀run ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù,’ àní nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (Éfésù 1:3; 2:6) Ohun tó jẹ́ kí wọ́n lè wà nínú ipò tó ga lọ́lá bẹ́ẹ̀ ni pé Ọlọ́run ti ‘fi èdìdì dì wọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí, èyí tí ó jẹ́ àmì ìdánilójú ṣáájú nípa ogún’ tí Ọlọ́run fi pa mọ́ dè wọ́n ní ọ̀run. (Éfésù 1:13, 14; Kólósè 1:5) Àwọn ẹni àmì òróró yìí ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run,” tí Jèhófà ti sọ iye wọn, tí yóò sì kó gbogbo wọn jọ pọ̀.

Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ sí Kó Wọn Jọ Pọ̀

4. Ìgbà wo ni Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí kó “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” jọ pọ̀, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀ rẹ̀?

4 Ní ìbámu pẹ̀lú “iṣẹ́ àbójútó” tàbí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bójú tó àwọn nǹkan, ìgbà tí “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀” bá pé ni ìkójọpọ̀ “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” máa bẹ̀rẹ̀. (Éfésù 1:10) Ìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni làkókò yẹn sì pé. Ọjọ́ náà ni Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn àpọ́sítélì àti agbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn kan, lọ́kùnrin lóbìnrin. (Ìṣe 1:13-15; 2:1-4) Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé májẹ̀mú tuntun ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, pé a ti fi ìjọ Kristẹni lọ́lẹ̀, àti pé orílẹ̀-èdè tuntun tí í ṣe Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti fìdí múlẹ̀.—Gálátíà 6:16; Hébérù 9:15; 12:23, 24.

5. Kí nìdí tí Jèhófà fi dá “orílẹ̀-èdè” tuntun sílẹ̀ láti fi rọ́pò Ísírẹ́lì nípa tara?

5 Májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá kò sọ wọn di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́” tó máa lọ ṣe iṣẹ́ wọn lọ́run títí láé. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Jésù sọ fáwọn aṣáájú àwọn Júù pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mátíù 21:43) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú tuntun ni orílẹ̀-èdè yìí, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Àwọn ni àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sí pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́, àwọn ènìyàn fún àkànṣe ìní, kí ẹ lè polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá’ ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀. Nítorí ẹ kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:9, 10) Kò sí májẹ̀mú kankan mọ́ láàárín Ísírẹ́lì nípa tara àti Jèhófà. (Hébérù 8:7-13) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Ọlọ́run ti gba àǹfààní láti jẹ́ ara àwọn tí yóò ṣe Ìjọba Mèsáyà kúrò lọ́wọ́ wọn, ó sì fi fún àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí.—Ìṣípayá 7:4-8.

Jésù Bá Wọn Dá Májẹ̀mú Ìjọba

6, 7. Àkànṣe májẹ̀mú wo ni Jésù bá àwọn arákùnrin rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yàn dá, kí ni ìyẹn sì wá fi hàn pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn?

6 Lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan, kí ẹ lè máa jẹ, kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi, kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” (Lúùkù 22:28-30) Májẹ̀mú tí Jésù ń sọ níbí jẹ́ àkànṣe májẹ̀mú tó bá àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì dá. Àwọn ni arákùnrin rẹ̀ tí Ọlọ́run fẹ̀mí mímọ́ yàn, tí wọ́n ní láti “jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú” káwọn náà lè di ‘aṣẹ́gun.’—Ìṣípayá 2:10; 3:21.

7 Àwọn kéréje yìí ti yááfì ìrètí pé àwọn yóò wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀. Ọ̀run ni wọn yóò ti lọ bá Kristi jọba, tí wọn yóò sì ṣèdájọ́ aráyé láti orí ìtẹ́ wọn. (Ìṣípayá 20:4, 6) Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì tó kan àwọn ẹni àmì òróró yìí nìkan, tó sì jẹ́ ká rí ìdí tí “àwọn àgùntàn mìíràn” kì í fi í jẹ búrẹ́dì tàbí kí wọ́n mu nínú wáìnì ìṣàpẹẹrẹ tá a máa ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi.—Jòhánù 10:16.

8. Kí làwọn ẹni àmì òróró ń fi hàn pé àwọn ṣe tán láti ṣe bí wọ́n ṣe ń jẹ búrẹ́dì ìṣàpẹẹrẹ? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 23.)

8 Àwọn ẹni àmì òróró máa jìyà bíi ti Kristi, wọ́n sì ṣe tán láti kú bíi tirẹ̀ pẹ̀lú. Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára wọn sọ pé òun ṣe tán láti yááfì ohunkóhun láti lè “jèrè Kristi, láti lè mọ òun àti agbára àjíǹde rẹ̀ àti àjọpín nínú àwọn ìjìyà rẹ̀.” Àní sẹ́, Pọ́ọ̀lù ṣé tán láti kú irú “ikú tí ó dà bí tirẹ̀.” (Fílípì 3:8, 10) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ló sì ti fojú winá irú “ìlòsíni tí ń ṣekú pani tí wọ́n fi hàn sí Jésù,” ìyẹn irú ìyà tí wọ́n fi jẹ Jésù.—2 Kọ́ríńtì 4:10.

9. Ara wo ni búrẹ́dì tá à ń lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi dúró fún?

9 Nígbà tí Jésù ń fi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀, ó ní: “Èyí túmọ̀ sí ara mi.” (Máàkù 14:22) Ara òun fúnra rẹ̀ tí wọ́n máa nà láìpẹ́ sígbà yẹn, tí ẹ̀jẹ̀ sì máa bò ló ń sọ o. Búrẹ́dì tí kò ní ìwúkàrà bá a mu gan-an láti ṣàpẹẹrẹ ara yìí. Kí nìdí? Ìdí ni pé, nínú Bíbélì, ìwúkàrà máa ń dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìwà burúkú. (Mátíù 16:4, 11, 12; 1 Kọ́ríńtì 5:6-8) Ṣùgbọ́n ẹni pípé ni Jésù, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ rárá nínú ara èèyàn tó ní. Ara pípé yìí ló fi rúbọ láti fi ṣètùtù ẹ̀ṣẹ̀. (Hébérù 7:26; 1 Jòhánù 2:2) Ẹbọ yẹn sì jẹ́ fún àǹfààní gbogbo Kristẹni olóòótọ́, yálà àwọn tó ń retí àtilọ sí ọ̀run tàbí àwọn tó máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 6:51.

10. Báwo làwọn tó ń mu nínú wáìnì nígbà Ìrántí Ikú Kristi ṣe ń ‘ṣe àjọpín nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi’?

10 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa wáìnì táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń mu nígbà Ìrántí Ikú Kristi nínú ìwé tó kọ, ó ní: “Ife ìbùkún tí àwa ń súre sí, kì í ha ṣe àjọpín kan nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí?” (1 Kọ́ríńtì 10:16) Ọ̀nà wo làwọn tó ń mu wáìnì gbà ń ‘ṣe àjọpín nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi’? Kì í ṣe pé àwọn àti Kristi jọ pèsè ìràpadà o, torí pé àwọn fúnra wọn ń fẹ́ ìràpadà. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní pé ẹ̀jẹ̀ Kristi lè rani padà ló mú kí wọ́n rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, tí Ọlọ́run sì kà wọ́n sí olódodo tí yóò lọ gbé ní ọ̀run. (Róòmù 5:8, 9; Títù 3:4-7) Ẹ̀jẹ̀ Kristi táwọn èèyàn ta sílẹ̀ ni Ọlọ́run fi “sọ” àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi “di mímọ́,” ẹ̀jẹ̀ yẹn ló fi yà wọ́n sọ́tọ̀ tó sì fi wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọn nù kí wọ́n lè di “ẹni mímọ́.” (Hébérù 10:29; Dáníẹ́lì 7:18, 27; Éfésù 2:19) Ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ yìí ni Kristi fi “ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.

11. Kí ni mímu táwọn ẹni àmì òróró ń mu nínú wáìnì Ìrántí Ikú Kristi fi hàn?

11 Nígbà tí Jésù fi Ìrántí Ikú rẹ̀ lọ́lẹ̀, ó gbé ife wáìnì fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, ó ní: “Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (Mátíù 26:27, 28) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ ṣe fìdí májẹ̀mú Òfin tí Ọlọ́run bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá múlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣe fìdí májẹ̀mú tuntun tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí dá láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni múlẹ̀. (Ẹ́kísódù 24:5-8; Lúùkù 22:20; Hébérù 9:14, 15) Bí àwọn ẹni àmì òróró bá ti ń mu nínú wáìnì tó dúró fún “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú náà,” ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn jẹ́ ara àwọn tó wà nínú májẹ̀mú tuntun àti pé àwọn ń jàǹfààní rẹ̀.

12. Ọ̀nà wo làwọn ẹni àmì òróró gbà jẹ́ ẹni tá a batisí sínú ikú Kristi?

12 Mímu táwọn ẹni àmì òróró ń mu nínú wáìnì náà tún ń rán wọn létí nǹkan mìíràn. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Ife tí mo ń mu ni ẹ óò mu, àti ìbatisí tí a fi ń batisí mi ni a ó fi batisí yín.” (Máàkù 10:38, 39) Nígbà tó yá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ti batisí” àwọn Kristẹni “sínú ikú” Kristi. (Róòmù 6:3) Ìgbésí ayé ẹni tó ti fara ẹ̀ rúbọ làwọn ẹni àmì òróró ń gbé. Kíkú tí wọ́n ń kú, ẹbọ ni wọ́n fi rú, torí pé ńṣe ni wọ́n yááfì gbogbo ohun tó jẹ mọ́ wíwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ó dìgbà táwọn ẹni àmì òróró bá jíǹde sípò ẹ̀dá ẹ̀mí lẹ́yìn ikú wọn, tí wọ́n sì lọ bá Kristi lọ́run láti bá a ‘ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba,’ kí batisí tá a batisí wọn sínú ikú Kristi tó parí.—2 Tímótì 2:10-12; Róòmù 6:5; 1 Kọ́ríńtì 15:42-44, 50.

Jíjẹ Búrẹ́dì àti Mímu Wáìnì Nígbà Ìrántí Ikú Kristi

13. Kí nìdí tí àwọn tó ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé kì í fi í jẹ búrẹ́dì tàbí kí wọ́n mu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń wá síbẹ̀?

13 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo nǹkan tá a ti ń sọ bọ̀ yìí ló rọ̀ mọ́ jíjẹ búrẹ́dì tàbí mímu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ, ó dájú pé kò ní bójú mu pé kí àwọn tó máa wà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé jẹ tàbí kí wọ́n mu nínú rẹ̀. Àwọn tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé ti mọ̀ pé wọn kò sí lára àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ara Kristi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sí lára àwọn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú tuntun pé wọ́n á bá Jésù Kristi jọba. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé májẹ̀mú tuntun yìí ni “ife” yẹn dúró fún, kìkì àwọn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú tuntun náà ló ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì yìí. Àwọn tó ń retí pé àwọn máa di ẹni pípé tó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kò sí lára àwọn tá a batisí sínú ikú Jésù, wọn ò sì sí lára àwọn tí Ọlọ́run sọ pé yóò bá Jésù jọba lọ́run. Tí wọ́n bá wá jẹ búrẹ́dì tàbí tí wọ́n mu nínú wáìnì ìṣàpẹẹrẹ, a jẹ́ pé wọ́n ń pe ara wọn ní ohun tí wọn ò jẹ́ nìyẹn. Ìdí nìyí tí wọn kì í fi í jẹ búrẹ́dì tàbí kí wọ́n mu wáìnì Ìrántí yẹn bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń wà níbẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láti wo bí gbogbo ètò yẹn ṣe ń lọ. Wọ́n dúpẹ́ fún gbogbo ohun tí Jèhófà ti tipa Ọmọ rẹ̀ ṣe fún wọn, títí kan bí Ọlọ́run ṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n lọ́lá ẹ̀jẹ̀ Kristi táwọn èèyàn tá sílẹ̀.

14. Báwo ni jíjẹ táwọn ẹni àmì òróró ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì ṣe ń fún wọn lókun nípa tẹ̀mí?

14 Ọlọ́run ò ní pẹ́ parí fífi èdìdì di àwọn Kristẹni kéréje tó pè láti wá bá Kristi jọba ní ọ̀run. Àmọ́ títí dìgbà tí ìwàláàyè àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí á fi dópin, ìyẹn ìwàláàyè tí wọ́n máa fi rúbọ lórí ilẹ̀ ayé, jíjẹ tí wọ́n ń jẹ búrẹ́dì, tí wọ́n sì ń mu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ á máa fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Wọ́n á máa mọ̀ ọ́n lára pé àwọn àtàwọn ẹni àmì òróró yòókù tí wọ́n jọ jẹ́ ara Kristi wà níṣọ̀kan. Bí wọ́n ṣe ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì tó jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ yẹn, wọ́n á máa rántí pé àwọn ní láti jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú.—2 Pétérù 1:10, 11.

Kíkó “Àwọn Ohun Tí Ń Bẹ Lórí Ilẹ̀ Ayé” Jọ

15. Àwọn wo ni Ọlọ́run kó jọ pọ̀ síhà ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró?

15 Láti àárín àwọn ọdún 1930 ni “àwọn àgùntàn mìíràn” tí kì í ṣe ara “agbo kékeré” ti wá ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró. Ilẹ̀ ayé làwọn àgùntàn mìíràn tí iye wọn ń pọ̀ sí i yìí ń retí pé àwọn yóò tí wà láàyè títí láé. (Jòhánù 10:16; Lúùkù 12:32; Sekaráyà 8:23) Wọ́n dúró ti àwọn arákùnrin Kristi gbágbáágbá, wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” láti lè ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mátíù 24:14; 25:40) Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ló máa mú kí wọ́n dẹni tí Kristi kà sí “àwọn àgùntàn” tó máa wà ní “ọwọ́ ọ̀tún” ojú rere rẹ̀ nígbà tó bá wá ṣèdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. (Mátíù 25:33-36, 46) Nítorí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi, wọn yóò di “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” já.—Ìṣípayá 7:9-14.

16. Àwọn wo ni yóò di ara “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” báwo sì ni gbogbo wọn lápapọ̀ yóò ṣe láǹfààní láti di “àwọn ọmọ Ọlọ́run”?

16 Tí Ọlọ́run bá ti wá fi èdìdì di àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tán, “ẹ̀fúùfù” ìparun rẹ̀ yóò wá rọ́ lu ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì tó wà lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì pa á run. (Ìṣípayá 7:1-4) Nígbà Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún tí Kristi àtàwọn ọba àti àlùfáà rẹ̀ yóò ṣe, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òkú yóò jíǹde, wọ́n á sì di ara àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá. (Ìṣípayá 20:12, 13) Gbogbo wọn yóò láǹfààní láti jẹ́ ọmọ abẹ́ ìjọba Kristi Jésù, Mèsáyà Ọba náà títí ayérayé. Ní òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, ìdánwò ìkẹyìn yóò bá gbogbo àwọn “ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” yìí. Gbogbo àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ lára wọn yóò wá di “àwọn ọmọ Ọlọ́run” ti orí ilẹ̀ ayé.—Éfésù 1:10; Róòmù 8:21; Ìṣípayá 20:7, 8.

17. Báwo ni ìpinnu Jèhófà yóò ṣe ṣẹ?

17 Báyìí ni Jèhófà, ọba ọgbọ́n, yóò ṣe fi “iṣẹ́ àbójútó” rẹ̀ mú ohun tó ti pinnu láti ṣe ṣẹ, ìyẹn láti “kó ohun gbogbo jọpọ̀ nínú Kristi, àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Àlàáfíà yóò wá jọba láàárín gbogbo ẹ̀dá olóye tí ń bẹ láyé àti lọ́run, wọn yóò sì fi tayọ̀tayọ̀ fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso òdodo Jèhófà, Ọba Amú-ìpinnu-ṣẹ náà.

18. Àǹfààní wo làwọn ẹni àmì òróró àtàwọn ogunlọ́gọ̀ alábàákẹ́gbẹ́ wọn yóò jẹ tí wọ́n bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi?

18 Ìpàdé tí ìwọ̀nba kéréje àwọn ẹni àmì òróró àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn yóò ṣe ní April 12, 2006 á mà gbé ìgbàgbọ́ wọn ró gan-an o! Wọn yóò ṣe Ìrántí Ikú Kristi, gẹ́lẹ́ bí Jésù ṣe pa á láṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ǹjẹ́ kí gbogbo ẹni tó bá wá síbẹ̀ rántí ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.

Àtúnyẹ̀wò

• Kí ni Jèhófà pinnu láti ṣe nípa àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àtàwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé?

• Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run,” báwo ni Ọlọ́run sì ṣe ń kó wọn jọ?

• Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” kí sì ni ìrètì àwọn wọ̀nyẹn?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

“Ara Kristi”

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nínú 1 Kọ́ríńtì 10:16, 17 nípa bí búrẹ́dì ìṣàpẹẹrẹ yìí ti ṣe pàtàkì tó fáwọn arákùnrin Kristi tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, ó lo ọ̀rọ̀ náà “ara” lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ó ní: “Ìṣù búrẹ́dì tí àwa ń bù, kì í ha ṣe àjọpín kan nínú ara Kristi bí? Nítorí pé ìṣù búrẹ́dì kan ni ó wà, àwa, bí a tilẹ̀ pọ̀, jẹ́ ara kan, nítorí pé gbogbo wa ń ṣalábàápín ìṣù búrẹ́dì kan yẹn.” Nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró bá jẹ nínú búrẹ́dì Ìrántí Ikú Kristi yìí, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ìjọ àwọn ẹni àmì òróró, èyí tó dà bí ara kan tí Kristi jẹ́ Orí rẹ̀.—Mátíù 23:10; 1 Kọ́ríńtì 12:12, 13, 18.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró nìkan ló ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mú wáìnì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Iṣẹ́ àbójútó tí Jèhófà ń ṣe yóò mú kí gbogbo ẹ̀dá ọ̀run àti ti ayé wà níṣọ̀kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́