Ǹjẹ́ O Lè Lọ Sìn ní Ìjọ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Èdè Ilẹ̀ Òkèèrè?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣípayá 14:6) Bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ń fi onírúurú ahọ́n tàbí èdè wàásù kárí ayé lónìí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ. Púpọ̀ lára èdè wọ̀nyí làwọn tó fi orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀ tí wọ́n lọ ń gbé nílẹ̀ òkèèrè ń sọ. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ń gbọ́ ìhìn rere látẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà onítara tí wọ́n ti kọ́ èdè wọn.
Ǹjẹ́ o wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń sìn nínú ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè? Àbí ò ń ronú nípa bó o ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? Kó o lè ṣe èyí láṣeyọrí, kò yẹ kó jẹ́ pé torí àǹfààní ara rẹ lo ṣe fẹ́ lọ. Bákan náà, o ní láti ní èrò tó tọ́ nípa ohun tó o fẹ́ ṣe. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nítorí àtiran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lo ṣe fẹ́ kọ́ èdè míì, àmì pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì rẹ nìyẹn, ohun tó sì dára jù lọ nìyẹn téèyàn lè tìtorí rẹ̀ kọ́ èdè tuntun. (Mátíù 22:37-39; 1 Kọ́ríńtì 13:1) Tó bá jẹ́ pé torí ìdí yìí lo fi ń kọ́ èdè wọn, ìyẹn á jẹ́ kó túbọ̀ wù ọ́ láti kọ́ èdè náà ju pé kó kàn jẹ́ torí àtilè máa bá wọn kẹ́gbẹ́, àtilè máa gbádùn oúnjẹ wọn tàbí torí àtilè mọ àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ǹjẹ́ o rò pé ìṣòro ńlá ló jẹ́ láti kọ́ èdè míì? Bó o bá rò bẹ́ẹ̀, á dára kó o ní èrò tó tọ́ nípa rẹ̀, kó o má ṣe ro ara rẹ pin. Arákùnrin James tó kọ́ èdè àwọn ará Japan sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí èdè náà bà ọ́ lẹ́rù.” Tó o bá ń rántí pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti gbìyànjú rẹ̀ wò ṣáájú rẹ ló ti ṣe é láṣeyọrí, wàá lè tẹpẹlẹ mọ́ ọn, o ò sì ní rẹ̀wẹ̀sì. Nígbà náà, báwo lo ṣe lè kọ́ èdè míì? Kí ló máa jẹ́ kí ara rẹ mọlé ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè náà? Kí ló sì yẹ kó o ṣe kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa jó rẹ̀yìn?
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Èdè Mìíràn
Onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà kọ́ èdè. Bí ọ̀nà táwọn kan gbà ń kọ́ èèyàn lédè ṣe yàtọ̀ síra náà ni ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń kọ́ èdè ṣe yàtọ̀ síra. Àmọ́, ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbà pé ó rọrùn jù tó sì máa jẹ́ kí wọ́n tètè mọ èdè ni pé, kí olùkọ́ tó dáńgájíá kọ́ wọn fúngbà díẹ̀. Tó o bá ń ka Bíbélì àtàwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì tó wà lédè tó o fẹ́ kọ́, tó o sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbà sórí kásẹ́ẹ̀tì lédè náà, wàá lè mọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ lédè náà, wàá sì tún túbọ̀ mọ àwọn àkànlò èdè táwa Ẹlẹ́rìí máa ń lò. Àwọn ètò tó bójú mu lórí rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti fídíò tún lè jẹ́ kó o túbọ̀ mọ̀ nípa èdè àti àṣà ìbílẹ̀ náà. Ní ti bó ṣe yẹ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gùn tó, kéèyàn máa kọ́ ọ díẹ̀díẹ̀ lójoojúmọ́ máa ń dára ju kéèyàn kàn máa lo àkókò gígùn jàn-ànrànjan-anran lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Èdè kíkọ́ dà bíi kéèyàn fẹ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń lúwẹ̀ẹ́. O ò lè mọ bí wọ́n ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ tó bá jẹ́ pé ìwé lo kàn kà nípa rẹ̀. O gbọ́dọ̀ wọnú omi kó o sì máa kọ́ bí wọ́n ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ díẹ̀díẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ kíkọ́ èdè ṣe rí nìyẹn. Yóò ṣòro gan-an bó o bá kàn ń kọ́ ọ tí o kò lò ó. O ní láti lọ sáàárín àwọn elédè nígbàkigbà tí àyè bá yọ, kó o fetí sí bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, kó o sì máa bá wọn sọ èdè náà. Ìgbòkègbodò Kristẹni á jẹ́ kó o lè ṣe èyí. Lọ́pọ̀ ìgbà, o lè lo ohun tó o kọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lóde ẹ̀rí. Arábìnrin Midori tó ń kọ́ èdè àwọn ará Ṣáínà sọ pé: “Ó lè dà bíi pé ó nira, àmọ́ àwọn tá à ń wàásù fún á rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí ń gbìyànjú gan-an. Èyí lè jẹ́ kí wọ́n fẹ́ gbọ́rọ̀ wa. Bá a bá kàn ti sọ pé, ‘Báwo ni nǹkan o?’ lédè wọn, kíá lara wọn máa ń yá sí wa!”
Ìpàdé ìjọ náà á tún ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an. Rí i pé ò ń dáhùn ìbéèrè ní gbogbo ìpàdé bí kò tiẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ. Bó ti wù kó le tó níbẹ̀rẹ̀, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Máa rántí pé ohun táwọn ará ìjọ fẹ́ ni pé kó o mọ èdè náà sọ! Arábìnrin Monifa tó ń kọ́ èdè àwọn ará Kòríà sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ arábìnrin tó ń jókòó tì mí nípàdé tó ń kọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan fún mi. Sùúrù tó ní àti ọ̀yàyà rẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Bó o bá ṣe ń mọ èdè náà sí i, wàá lè máa fi ronú, ìyẹn ni pé wàá mọ ohun tí ọ̀rọ̀ tí ò ń gbọ́ túmọ̀ sí gan-an dípò tí wàá fi máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan lọ́kàn rẹ.
Bó o ṣe ń kọ́ èdè náà, ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ sapá láti ṣe ni pé kó o máa “sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye.” (1 Kọ́ríńtì 14:8-11) Àwọn èèyàn lè rí i pé ò ń gbìyànjú lóòótọ́, àmọ́ wọ́n lè máà fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tó o bá ń ṣe àṣìṣe tàbí tí o kò pe ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ. Tó bá jẹ́ pé látilẹ̀ lo ti ń pe ọ̀rọ̀ dáadáa, tó ò ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dán mọ́rán, àṣàkaṣà tó máa ṣòro láti fi sílẹ̀ kò ní mọ́ ọ lára. Arákùnrin Mark tó kọ́ èdè Swahili dábàá pé: “Sọ fáwọn tó gbọ́ èdè náà dáadáa pé kí wọ́n sọ fún ọ bó ṣe yẹ kó o sọ ọ̀rọ̀ tó ò bá sọ dáadáa, kó o sì dúpẹ́ lọwọ́ wọn tí wọ́n bá sọ fún ọ!” Àmọ́ o, má gba àkókò àwọn tó ń ràn ọ́ lọ́wọ́ jù, má sì dà wọ́n láàmú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè sọ fún ẹnì kan pé kó máa yẹ ìwé tó o fi ń kọ́ èdè wò, fúnra rẹ ni kó o máa múra iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe nípàdé àti ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ fi dáhùn ìbéèrè sílẹ̀, kó o máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó o mọ̀ dáadaa àtàwọn tó o ti wo ìtumọ̀ wọn nínú ìwé atúmọ̀ èdè. Èyí á jẹ́ kó o tètè mọ ohun tí ò ń kọ́, kó o sì lè fi ìdánilójú sọ̀rọ̀.
Máa Tẹ̀ Síwájú
Arábìnrin Monifa sọ pé: “Kíkọ́ èdè tó yàtọ̀ sí tèmi ni ohun tó nira jù lọ tí mo tíì dáwọ́ lé láyé mi. Àwọn ìgbà kan wà tó máa ń ṣe mí bíi pé kí n jáwọ́. Àmọ́ mo máa ń rántí bí inú àwọn ará Kòríà tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣe máa ń dùn tí wọ́n bá gbọ́ tí mò ń fi táá-tàà-tá tí mo gbọ́ nínú èdè wọn kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀, àti bí inú àwọn ará ṣe máa ń dùn tí wọ́n bá rí i pé mo ti tẹ̀ síwájú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Kókó ibẹ̀ ni pé, má ṣe jẹ́ kó sú ọ. Fi sọ́kàn pé ńṣe lo fẹ́ fi ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń gbani là kọ́ àwọn èèyàn. (1 Kọ́ríńtì 2:10) Kó o sì tó lè fi èdè míì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, o ní láti pọkàn pọ̀ sórí èdè náà, má sì gbàgbé pé èdè kíkọ́ ò lópin. Bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú, má ṣe máa wò ó pé o ò ṣe dáadáa bíi tàwọn ẹlòmíràn. Ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tó ń kọ́ èdè máa ń gbà tẹ̀ síwájú, wọ́n sì lè tètè gbọ́ ọ jura wọn lọ. Síbẹ̀, ó yẹ kó o máa sapá láti tẹ̀ síwájú. (Gálátíà 6:4) Arákùnrin Joon tó ń kọ́ èdè àwọn ará Ṣáínà sọ pé: “Ńṣe ni ìtẹ̀síwájú nínú èdè kíkọ́ dà bí ìgbà téèyàn bá ń gun àtẹ̀gùn. Ìgbà téèyàn bá rò pé òun ò tíì dé ibì kankan ló máa rí i pé òun ti tẹ̀ síwájú.”
Èdè kì í ṣe ohun téèyàn ń mọ̀ tán lẹ́ẹ̀kan, títí ayé lèèyàn á máa mọ̀ ọ́n sí i. Nítorí náà, máa fi ìdùnnú kọ́ èdè àmọ́ má ṣe rò pé o ò ní ṣe àṣìṣe. (Sáàmù 100:2) Kò sẹ́ni tí kì í ṣe àṣìṣe. Ara ẹ̀kọ́ kíkọ́ ni èyí jẹ́. Nígbà tí arákùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè Ítálì wàásù, ó bi ẹnì kan tó ń wàásù fún pé: “Ǹjẹ́ o mọ ìgbálẹ̀ tí a fi wà láàyè?” Ohun tó sì fẹ́ sọ ni pé “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí a fi wà láàyè?” Ẹlẹ́rìí kan tí kò tíì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè àwọn ará Poland fẹ́ sọ pé kí àwọn ará ìjọ kọ orin ṣùgbọ́n ńṣe ló ní kí wọ́n kọ ajá. Bákan náà, nítorí pé arákùnrin kan tó ń kọ́ èdè àwọn ará Ṣáìnà kò pe ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, ńṣe ló ní káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ nígbàgbọ́ nínú àpótí ìwé Jésù dípò ìràpadà Jésù. Àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ṣe àṣìṣe ni pé, tí wọ́n bá ti tọ́ni sọ́nà, èèyàn kì í sábàá gbàgbé.
Bí Wàá Ṣe Máa Bá Àwọn Ará Ìjọ Lò
Kì í ṣe èdè tó yàtọ̀ síra nìkan ló ń fa ìpínyà láàárín aráyé. Àṣà ìbílẹ̀, ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè wọn tó yàtọ̀ tún sábà máa ń fà á. Àmọ́, àwọn ohun tó dà bí òkè ìṣòro yìí kì í ṣe ohun téèyàn ò lè borí. Ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣèwádìí nípa àwọn ìsìn táwọn tó ń sọ èdè àwọn ará Ṣáínà ń ṣe nílẹ̀ Yúróòpù sọ pé, kò sí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀kan náà ni wọ́n ka ara wọn sí kárí ayé. Ó sọ pé: “[Àwọn Ẹlẹ́rìí] kì í jẹ́ kí ìran tàbí ẹ̀yà tí wọ́n ti wá dá ìṣòro sílẹ̀ láàárín wọn, wọn ò sì ka èdè kálukú wọn sí nǹkan míì ju ohun tí wọ́n á kàn fi túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ká sòótọ́, ìlànà Bíbélì táwọn Kristẹni tòótọ́ ń tẹ̀ lé ni kò jẹ́ kí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà wà láàárín wọn. ‘Kò sí ọ̀rọ̀ pé Gíríìkì tàbí Júù tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni mí láàárín àwọn tó ti fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara wọn láṣọ.’—Kólósè 3:10, 11.
Nítorí èyí, ó yẹ kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ rí i pé àwọn ń ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ìrẹ́pọ̀ wà. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní láti fi tinútinú tẹ́wọ́ gba èrò, ìwà àti àṣà àwọn elédè mìíràn. Kí àṣà ìbílẹ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó yàtọ̀ síra má bàa dá èdè àìyedè sílẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ máa rin kinkin mọ́ ọn pé àṣà ìbílẹ̀ tiwa nìkan ló dáa jù. (1 Kọ́ríńtì 1:10; 9:19-23) Gbìyànjú láti mọ ohun táwọn èèyàn fẹ́ràn jù lọ nínú àṣà ìbílẹ̀ wọn. Rántí o, ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan ló ń jẹ́ kí àlàáfíà wà.
Ọ̀pọ̀ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ló jẹ́ pé àwùjọ kéékèèké ni wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó di ìjọ. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ èdè náà ló sábà máa ń pọ̀ jù níbẹ̀, àtàwọn míì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé awuyewuye tó máa ń wà láàárín àwọn tó wà nírú àwùjọ bẹ́ẹ̀ máa ń ju tàwọn ìjọ ńlá tó ti fìdí múlẹ̀ dáadáa lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú ní láti sapá gidigidi kí wọ́n lè dẹni tó ń mú kí nǹkan lọ déédéé àti létòlétò nínú ìjọ. Bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ tí wọ́n sì ń hùwà ọmọlúwàbí, èyí yóò jẹ́ kí ìjọ tòrò, yóò sì ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú.
Àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn láti lọ ṣèrànwọ́ ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ní láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kì í ṣe kí wọ́n máa retí pé káwọn èèyàn ṣe nǹkan lọ́nà pípé. Irú ìjọ bẹ́ẹ̀ ni alàgbà kan tó ń jẹ́ Rick wà. Ó sọ pé: “Àwọn ará kan tí kò tíì pẹ́ púpọ̀ nínú òtítọ́ lè máà tíì mọ bá a ṣe ń ṣètò nǹkan dáadáa bíi tàwọn ará tó wà nínú àwọn ìjọ tó ti fìdí múlẹ̀ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀. Àmọ́ o, bí wọn ò tilẹ̀ lè ṣe púpọ̀, ìfẹ́ àti ìtara wọn máa ń pọ̀ gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ló sì ti ń wá sínú òtítọ́.” Bó o bá ń wá sípàdé déédéé, tó ò ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ míì, tó o sì ń sa gbogbo ipá rẹ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, kò sí àní-àní pé àwọn ará á jàǹfààní lára rẹ, kódà lásìkò tó o ṣì ń kọ́ èdè ọ̀hún pàápàá. Bí gbogbo ìjọ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ó dájú pé tọmọdé tàgbà á tẹ̀ síwájú.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Rẹ Jó Rẹ̀yìn
Arákùnrin kan tí kò tíì pẹ́ púpọ̀ nínú ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè fetí kọ́ ọ̀rọ̀ ìyá kan tó ń kọ́ ọmọ rẹ̀ ní bó ṣe máa dáhùn ìbéèrè nípàdé. Ọmọ náà sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Mọ́mì, ṣé ìdáhùn náà ò lè kúrú ju báyìí lọ ni?” Ìyá rẹ̀ fèsì pé: “Rárá o, ọmọ mi. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ èdè ló yẹ ká jẹ́ kó máa sọ ìdáhùn ṣókí.”
Bí àwọn àgbàlagbà ò bá lè sọ èdè kan kó já gaara fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún, èyí lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn, ó sì lè ṣàkóbá fún ìtẹ̀síwájú wọn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Arábìnrin Janet tó ti ń sọ èdè Spanish dáadáa báyìí sọ pé: “Mi ò kì í pẹ́ rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé mi ò lè sọ èdè náà kó já gaara.” Arábìnrin Hiroko tó kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé nígbà kan òun tiẹ̀ máa ń rò ó pé: ‘Kódà àwọn ajá àti ológbò tó wà láwọn àgbègbè tá a ti ń jẹ́rìí gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì jù mí lọ.’ Arábìnrin Kathie ní tiẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí mo lọ sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Spanish, èmi tí mo ti ń ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìpadàbẹ̀wò wá dẹni tí kò ní rárá. Ńṣe ló dà bíi pé mi ò ṣe nǹkan kan rárá.”
Kò yẹ kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì lákòókò téèyàn ń kọ́ èdè. Hiroko sọ pé nígbà tóun rẹ̀wẹ̀sì, òun sọ pé: “Báwọn ẹlòmíì bá lè ṣe é, èmi náà á ṣe é.” Kathie sọ pé: “Mo máa ń ronú nípa ọkọ mi tó ń tẹ̀ síwájú dáadáa tó sì ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọ. Ìyẹn ló jẹ́ kí n borí ìrẹ̀wẹ̀sì mi, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ síwájú. Iṣẹ́ ńlá ṣì ni o, àmọ́ mo ti ń lè fi èdè náà wàásù mo sì ń fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀díẹ̀ nísinsìyí, èyí sì ń fún mi láyọ̀ gan-an ni.” Ọkọ rẹ̀ Jeff sọ pé: “Kì í dùn mọ́ni nínú rárá tí kì í bá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ nínú ìfilọ̀ tàbí nípàdé alàgbà ló yé èèyàn. Bí ohun kan kò bá yé mi mi ò kì í tanra mi jẹ kí n ní ó yé mi. Mo máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ béèrè èyí tí kò bá yé mi dáadáa, inú àwọn ará sì máa ń dùn láti ṣàlàyé rẹ̀ fún mi.”
Kó má bàa di pé ìgbàgbọ́ rẹ jó rẹ̀yìn ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè tó o wà, rí i pé ohunkóhun kò ṣàkóbá fún ìgbòkègbodò rẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Arákùnrin Kazuyuki tó ti sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún láàárín àwọn tó ń sọ èdè Potogí sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé ká máa rí oúnjẹ tẹ̀mí tí ó tó jẹ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àti èdè wa àti èdè Potogí la fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tá a sì fi ń múra ìpàdé sílẹ̀.” Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn kan máa ń lọ sí ìpàdé tí wọ́n ń ṣe ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, rí i pé ò ń sinmi dáadáa.—Máàkù 6:31.
Gbéṣirò Lé E
Tó o bá ń ronú nípa lílọ sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀, ó yẹ kó o gbéṣirò lé ohun tí èyí máa ná ọ. (Lúùkù 14:28) Lórí kókó yìí, àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ kó o kíyè sí ni ìgbòkègbodò rẹ nínú ìjọ àti àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà. Fi ọ̀rọ̀ rẹ sí àdúrà. Ronú nípa ohun tó máa ṣe ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ àtàwọn ọmọ yín láǹfààní. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ipò tí mo wà á jẹ́ kó rọrùn fún mi láti dáwọ́ lé ohun tí kì í ṣe nǹkan téèyàn máa ṣe fún ìgbà kúkúrú yìí? Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ mi lágbára tó láti ṣe é, ǹjẹ́ mo sì lẹ́mìí ẹ̀?’ Ó bọ́gbọ́n mu pé kó o ṣe ohun tó máa ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ láǹfààní tó ga jù nínú ìjọsìn yín sí Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà fún ọ láti ṣe níbikíbi tó o bá ti ń wàásù ìhìn rere, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì máa fún ọ láyọ̀ níbẹ̀.
Èrè jaburata ń bẹ fáwọn tó bá lè lọ sìn ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Barbara, tí òun àti ọkọ rẹ̀ lọ sí ìjọ tí wọn ti ń sọ èdè Spanish sọ pé: “Èyí ni ọ̀kan lára ohun tó ń fún mi láyọ̀ jù lọ láyé mi. Ńṣe ló dà bíi pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Mo dúpẹ́ gidigidi pé mo láǹfààní rẹ̀, pàápàá níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a ò lè ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè míì.”
Jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Kristẹni tí kò kàwé púpọ̀, lọ́mọdé lágbà, ló ń sapá láti kọ́ èdè míì fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere. Bó o bá wà lára wọn, má ṣe jẹ́ kí èrò tó tọ́ tó wà lọ́kàn rẹ tó o fi ń kọ́ ọ yí padà, má sì jẹ́ kó sú ọ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kó o lè ṣàṣeyọrí.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Tó bá jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá ló ń kọ́ èèyàn lédè, ó máa ń rọrùn fún èèyàn láti tètè gbọ́ èdè náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Bó o ṣe ń kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè, rí i pé ohunkóhun kò ṣàkóbá fún ìtẹ̀síwájú rẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run