Ìtàn Ìgbésí Ayé
Ìgbésí Ayé Mi Yí Padà Nígbà Tí Mo Mọ Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ohun Tó Ń fa Ìbànújẹ́
GẸ́GẸ́ BÍ HARRY PELOYAN ṢE SỌ Ọ́
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn nǹkan tó ń ba àwọn èèyàn nínú jẹ́ máa ṣẹlẹ̀? Àtìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni ìbéèrè yìí ti máa ń jà gùdù lọ́kàn mi. Òṣìṣẹ́ gidi làwọn òbí mi, olóòótọ́ èèyàn ni wọ́n, wọn ò sì fọ̀rọ̀ ìdílé wọn ṣeré rárá. Àmọ́ bàbá mi kò ka ẹ̀sìn sí rárá bẹ́ẹ̀ ni ìyá mi kò sì fọwọ́ dan-in-dan-in mú ẹ̀sìn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò lè dáhùn ìbéèrè yẹn.
ÌGBÀ tí Ogun Agbáyé Kejì ń lọ lọ́wọ́ àti ìgbà tó parí ni mo rónú lórí ìbéèrè yẹn jù. Àkókò yẹn ni mo wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà fún ohun tó lé lọ́dún mẹ́ta. Lẹ́yìn tógun yẹn parí, wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun tó ń kó àwọn ohun àfiṣèrànwọ́ lọ sílẹ̀ Ṣáínà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan tí mo fi ṣiṣẹ́ yẹn, ìyà tó sì jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lójú mi kì í ṣe kékeré.
Òṣìṣẹ́ gidi àti ọlọ́pọlọ pípé làwọn èèyàn Ṣáínà. Àmọ́ ojú ọ̀pọ̀ lára wọn rí màbo lákòókò Ogun Àgbáyé Kejì nítorí ipò òṣì àti ìwà ipá tí ogun náà fà. Èyí tó bà mí nínú jẹ́ jù ni tàwọn ọmọ kéékèèké tó rẹwà tí wọ́n máa ń bẹ̀ wá pé ká fáwọn ní nǹkan. Ọ̀pọ̀ lára wọn kò róúnjẹ jẹ kánú, àkísà ni wọ́n sì máa ń wọ̀ sọ́rùn.
Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Ń Jẹ Àwọn Èèyàn?
Ọdún 1925 ni wọ́n bí mi nílùú California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti tọ́ mi dàgbà. Mi ò rí irú ìyà bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Èyí mú kí n máa bi ara mi léraléra pé, ‘Bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Ẹlẹ́dàá alágbára gbogbo wà, kí nìdí tó fi jẹ́ kí irú ìyà ńlá báyìí máa jẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, pàápàá àwọn ọmọdé tí wọn ò mọ nǹkan kan?’
Mo tún máa ń rò ó lọ́kàn mi pé, bí Ọlọ́run bá wà lóòótọ́, kí nìdí tó fi jẹ́ kí irú ìparun bẹ́ẹ̀ wáyé, tí wọ́n pa àwọn èèyàn nípakúpa, tí ikú àti ìpọ́njú sì ti ń bá aráyé fínra látayébáyé, àgàgà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì táwọn èèyàn tó kú lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù. Ìyẹn nìkan kọ́, kí nìdí táwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn kan náà fi ń para wọn látìbẹ̀rẹ̀ ogun náà títí tó fi parí, tó sì jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn wọn ló ń fún wọn níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀ síra?
Awò Awọ̀nàjíjìn
Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1939 tí wọ́n sì ń pa àwọn èèyàn lọ bẹẹrẹbẹ níbi gbogbo láyé, mo rò ó lọ́kàn mi pé, dájúdájú Ọlọ́run kò sí. Nígbà tá a wá ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa sáyẹ́ǹsì nílé ẹ̀kọ́ girama, wọ́n ní kí akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan lọ ṣe ohun kan tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì wá. Nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ nípa ìràwọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe awò awọ̀nàjíjìn ńlá kan tí gíláàsì ojú rẹ̀ fẹ́ tó ogún sẹ̀ǹtímítà.
Kí n lè ṣe awò awọ̀nàjíjìn yìí, mo ra gíláàsì tó nípọn gan-an tó fẹ̀ tó ogún sẹ̀ǹtímítà. Mo wá ní kí ẹnì kan tó ń gé gíláàsì bá mi gé e kó rí roboto. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́ inú rẹ̀ kó lè jinnú. Iṣẹ́ ńlá gbáà ni. Òun ló sì gba gbogbo àkókò tó yẹ kí n fi sinmi ní sáà ẹ̀kọ́ náà. Nígbà tí mo gbẹ́ gíláàsì náà tán, mo fi dí ojú irin gígùn kan tó níhò mo sì fi àwọn awò ojú tí agbára wọn yàtọ̀ síra dí ojú kejì irin náà.
Lálẹ́ ọjọ́ kan tí kò sí òṣùpá, tí ojú ọ̀run sì mọ́ kedere, mo gbé awò awọ̀nàjíjìn mi tí mo ti ṣe parí bọ́ síta fún ìgbà àkọ́kọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wo àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí oòrùn po. Ẹnu yà mí nígbà tí mo rí bí àwọn ìràwọ̀, pílánẹ́ẹ̀tì, àtàwọn òṣùpá tó wà ṣe pọ̀ tó àti bí ohun gbogbo ṣe wà létòlétò gan-an. Nígbà tí mo tún wá mọ̀ pé ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ làwọn kan tí mo rò pé ìràwọ̀ lásán ni wọ́n, irú bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ onírìísí wàrà (Milky Way galaxy), tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ nínú, ẹnu túbọ̀ yà mí gan-an.
Mo wá rò ó lọ́kàn mi pé, ‘Ó dájú pé gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣàdédé wà fúnra wọn. Kò sí ohun kan tó wà létòlétò tó ń ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Àgbáálá ayé àti inú sánmà lọ́hùn-ún wà létòlétò débi pé, ẹnì kan tó ní òye àrà ọ̀tọ̀ la lè sọ pé ó ṣètò rẹ̀. Àbí òótọ́ ni Ọlọ́run wà ni?’ Ohun tí mo fi awò awọ̀nàjíjìn mi rí yìí mú kí n yí èrò mi padà díẹ̀, ìyẹn èrò tí mo ti ní tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run kò sí.
Lẹ́yìn náà mo wá bi ara mi pé: ‘Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run kan wà tó lágbára tó sì ní ọgbọ́n débi tó fi lè dá àwọn ohun tó jọni lójú báyìí, ṣé kò wá lè mú àwọn nǹkan tó ń ba èèyàn nínú jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé kúrò ni? Kí nìdí tó tiẹ̀ fi fàyè gba àwọn nǹkan wọ̀nyí látilẹ̀wá?’ Nígbà tí mo bi àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn ní ìbéèrè yìí, wọn ò rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn fún mi.
Lẹ́yìn tí mo jáde ilé ẹ̀kọ́ girama tí mo sì ti lo bí ọdún mélòó kan ní yunifásítì, mo lọ wọṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àmọ́ àwọn àlùfáà ológun pàápàá kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Ohun táwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn sì sábà máa ń sọ fún mi ni pé: “Àwámárìídìí niṣẹ́ Olúwa.”
Mi Ò Dẹ́kun Wíwá Ìdáhùn sí Ìbéèrè Mi
Lẹ́yìn tí mo kúrò nílẹ̀ Ṣáínà, àwọn ìbéèrè nípa ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ máa ṣẹlẹ̀ kò yéé wá sí mi lọ́kàn. Mi ò yéé ronú nípa rẹ̀ ṣáá, pàápàá nígbà tí mo rí àwọn ibi tí wọ́n sin òkú àwọn ológun sí ní gbogbo erékùṣù tá a ti dúró nígbà tá a ń gba òkun Pàsífíìkì bọ̀ wálé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ikú dá ẹ̀mí wọn légbodò ni gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn sàréè náà.
Nígbà tí mo padà dé sí Amẹ́ríkà tí wọ́n sì dá mi sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi, mo ṣì ní ọdún kan láti parí ẹ̀kọ́ mi ní Yunifásítì Harvard nílùú Cambridge ní ìpínlẹ̀ Massachusetts. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni mo jáde tí mo sì gba oyè àkọ́kọ́ ní yunifásítì, àmọ́ mi ò padà sílé ní ìpínlẹ̀ California. Mo pinnu láti dúró lágbègbè Etíkun Ìlà Oòrùn Amẹ́ríkà fúngbà díẹ̀ kí n lè wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi. Ìlú New York City tí ẹ̀sìn pọ̀ sí ni mo ní lọ́kàn láti lọ kí n lè lọ sí onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì láti mọ ohun táwọn ìsìn náà fi kọ́ni.
Nígbà tí mo dé ìlú New York, ẹ̀gbọ́n màmá mi tó ń jẹ́ Isabel Kapigian ní kí n wá máa gbé lọ́dọ̀ òun. Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun àtàwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì tí ọ̀kan ń jẹ́ Rose tí èkejì sì ń jẹ́ Ruth. Níwọ̀n bí mi ò ti rò pé màá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn, mò ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, mo sì ń ka àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn. Mo máa ń bi wọ́n pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn nǹkan tó ń ba èèyàn nínú jẹ́, àmọ́ bí mi ò ṣe mọ ìdáhùn rẹ̀ làwọn náà ò ṣe mọ̀ ọ́n. Ni mo bá gbà lọ́kàn mi pé ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run kò sí nìyẹn.
Mo Rí Ìdáhùn
Mo wá bi ẹ̀gbọ́n màmá mi àtàwọn ọmọ rẹ̀ bóyá wọ́n lè fún mi ní díẹ̀ lára àwọn ìwé wọn kà kí n lè mọ èrò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo ka àwọn ìwé tí wọ́n fún mi náà, kíá ni mo rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹ̀sìn mìíràn. Inú Bíbélì làwọn ìdáhùn náà ti wá, wọ́n sì tẹ́ mi lọ́rùn gan-an. Láìpẹ́, mo rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè mi nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn nǹkan tó ń ba èèyàn nínú jẹ́.
Ìyẹn nìkan kọ́ o, mo tún rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, mo béèrè lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n màmá mi pé kí làwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣe nílẹ̀ Jámánì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì? Ǹjẹ́ wọ́n wọṣẹ́ ológun, ṣé wọ́n sọ gbólóhùn náà: “Ẹ kókìkí Hitler!,” ṣé wọ́n sì kí àsíá Násì? Ó dá mi lóhùn pé rárá, wọn ò ṣe ọ̀kankan nínú gbogbo rẹ̀. Àti pé nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sógun, wọ́n sọ wọ́n sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, níbi tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀ lára wọn. Ó ṣàlàyé pé lákòókò ogun yẹn, ohun kan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe níbi gbogbo. Wọn ò lọ́wọ́ sógun. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè oníjọba tiwa-n-tiwa, wọ́n sọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti jagun.
Ẹ̀gbọ́n màmá mi ní kí n ka Jòhánù 13:35, tó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” Ó ní àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ní àmì tá a máa fi dá wọn mọ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n bá ń gbé, àmì náà sì ni ìfẹ́. Wọn ò ní lọ́wọ́ sí ogun táwọn orílẹ̀-èdè ń bára wọn jà, kí wọ́n sì wá máa para wọn nítorí pé orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀ síra! Ó wá bi mí pé: “Ṣé o rò pé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á jẹ́ lọ́wọ́ sí àwọn ogun ilẹ̀ Róòmù kí wọ́n sì máa pa ara wọn?”
Ó tún ní kí n ka 1 Jòhánù 3:10-12. Ẹsẹ náà kà pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. . . . A ní láti ní ìfẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì; kì í ṣe bí Kéènì, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa arákùnrin rẹ̀.”
Ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó yìí ṣe kedere. Ìyẹn ni pé, àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn, láìka orílẹ̀-èdè yòówù kí wọ́n máa gbé sí. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò jẹ́ pa àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí ẹlòmíràn pàápàá. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.”—Jòhánù 17:16.
Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Àwọn Ohun Tó Ń Bani Nínú Jẹ́
Kò pẹ́ tí mo fi wá mọ̀ pé Bíbélì sọ ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ máa ṣẹlẹ̀. Ó ṣàlàyé pé nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, ó dá wọn ní ẹni pípé, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà kan tó dà bíi Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; 2:15) Ó tún fún wọn lẹ́bùn kan tó ṣeyebíye, ẹ̀bùn náà sì ni òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n. Àmọ́ wọ́n ní láti lo ẹ̀bùn yìí lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Bí wọ́n bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, wọ́n á máa jẹ́ ẹni pípé nìṣó wọ́n á sì máa gbé inú Párádísè títí lọ. Wọ́n á mú Párádísè náà gbòòrò títí gbogbo ayé pátá yóò fi di Párádísè. Bákan náà, àwọn ọmọ wọn náà á jẹ́ ẹni pípé, bí àkókò sì ti ń lọ, gbogbo ayé yóò wá di Párádísè ológo, táwọn èèyàn pípé tó jẹ́ aláyọ̀ ń gbé.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Àmọ́ bí Ádámù àti Éfà bá yàn láti máa fúnra wọn ṣèpinnu, tí wọn ò fi ti Ọlọ́run ṣe, wọn ò ní máa jẹ́ ẹni pípé nìṣó. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Àmọ́ ó ṣeni láàánú fún aráyé pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣi òmìnira wọn lò, wọ́n yàn láti máa dá ìpinnu wọn ṣe láìtẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó di ọlọ̀tẹ̀ tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù ló tì wọ́n sí i. Ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ò fẹ́ wà lábẹ́ Ọlọ́run, ó sì tún fẹ́ máa gba ìjọsìn tó jẹ́ ti Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-19; Ìṣípayá 4:11.
Bí Sátánì ṣe di “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” nìyẹn. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 14:30) Àìgbọràn Sátánì àti tàwọn òbí wa àkọ́kọ́ ló mú àìpé, ìwà ipá, ikú, ìbànújẹ́, àti ìpọ́njú wá sórí aráyé.—Róòmù 5:12.
“Kì Í Ṣe Ti Ènìyàn”
Kí ẹ̀dá èèyàn lè rí ohun tí kíkọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn òfin Ẹlẹ́dàá máa fà ni Ọlọ́run ṣe fàyè sílẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ká lè rí àwọn àbájáde náà. Àkókò tí Ọlọ́run fi sílẹ̀ yìí ti jẹ́ kí gbogbo ìran èèyàn rí i dáadáa pé òtítọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀. Tọ́ mi sọ́nà, Jèhófà.”—Jeremáyà 10:23, 24.
Ní báyìí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti kọjá, a lè rí i pé asán ni ìṣàkóso èèyàn láìfi ti Ọlọ́run ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ti pinnu láti fòpin sí dídarí táwọn èèyàn ń gbìyànjú láti darí ara wọn láìfi tirẹ̀ ṣe, èyí tó ti mú àwọn àbájáde búburú wá.
Ọjọ́ Iwájú Yóò Dára Gan-an
Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé láìpẹ́ sígbà tá a wà yìí, Ọlọ́run yóò mú ètò àwọn nǹkan burúkú yìí wá sópin. Ó ní: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.
Àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:44 sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìyẹn gbogbo onírúurú ìṣàkóso tó wà báyìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ọlọ́run kò tún ní gba èèyàn láyè láti ṣàkóso ara wọn mọ́. Ìjọba Ọlọ́run ni yóò máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé. Lábẹ́ ìṣàkóso yẹn, gbogbo ayé yóò di Párádísè, aráyé á di pípé, wọ́n á sì máa wà láàyè títí láé nínú ayọ̀. Bíbélì ṣèlérí pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Ẹ ò rí i pé ọjọ́ iwájú tó dára gan-an ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wa!
Ìgbésí Ayé Mi Yí Padà
Rírí tí mo rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn sáwọn ìbéèrè mi mú kí ìgbésí ayé mi yí padà. Látìgbà náà lọ, mo fẹ́ láti sin Ọlọ́run mo sì fẹ́ láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìdáhùn wọ̀nyí. Mo wá lóye bí ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 2:17 ti ṣe pàtàkì tó, èyí tó sọ pé: “Ayé [ìyẹn ètò nǹkan ìsinsìnyí tí Sátánì ń ṣàkóso rẹ̀] ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Ó wù mí gan-an láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Ni mo bá kúkú pinnu láti dúró sílùú New York níbẹ̀ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í dára pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo láyọ̀ gan-an bí mo ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun témi náà ti mọ̀.
Lọ́dún 1949, mo pàdé Rose Marie Lewis. Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun àti màmá rẹ̀ tó ń jẹ́ Sadie, àtàwọn ẹ̀gbọ́n àtàbúrò rẹ̀ mẹ́fà tí wọ́n jẹ́ obìnrin. Òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó ń fi àkókò tó pọ̀ gan-an wàásù ni Rose. Ó ní àwọn ànímọ́ tó dára gan-an, kíá lọkàn mi sì fà mọ́ ọn. A ṣègbéyàwó lóṣù June ọdún 1950 a sì fìdí kalẹ̀ sílùú New York. Ohun tí à ń ṣe múnú wa dùn gan-an, ìrètí tá a ní pé a ó wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ sì ń fún wa láyọ̀.
Lọ́dún 1957, wọ́n pe èmi àti Rose Marie láti wá máa ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, nílùú New York. Oṣù June ọdún 2004 ló pé ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] tá a ti jọ ń gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya a sì láyọ̀ gan-an. A ti lo mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] lára àwọn ọdún náà ní oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn. Ọdún aláyọ̀ gbáà làwọn ọdún wọ̀nyí jẹ́ nítorí pé inú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà la ti lò wọ́n tá a sì ń bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa ṣiṣẹ́.
Ohun Tó Tíì Bà Mí Nínú Jẹ́ Jù Lọ
Níbẹ̀rẹ̀ oṣù December ọdún 2004, inú wa bà jẹ́ nígbà tí àyẹ̀wò táwọn dókítà ṣe fi hàn pé ibì kan wú nínú ẹ̀dọ̀fóró Rose Marie àti pé àrùn jẹjẹrẹ ni. Àwọn dókítà sọ pé ńṣe ni ibẹ̀ yóò máa yara wú sí i, wọ́n sì ní láti mú un kúrò. Ìparí oṣù December ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà, kò sì ju ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà tí dókítà tó ṣiṣẹ́ abẹ ọ̀hún wá sínú yàrá ọsibítù tí Rose wà nígbà tí mo wà níbẹ̀, tó sì sọ pé: “Rose Marie, máa lọ sílé! Ara rẹ ti yá!”
Àmọ́ kò ju ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí Rose Marie dé sílé tó tún bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìrora tó le gan-an nínú ikùn rẹ̀ àti láwọn ibòmíràn. Nígbà tí ìrora yìí kò dín kù, ló bá tún padà sí ọsibítù fún àwọn àyẹ̀wò mìíràn. Àwọn àyẹ̀wò náà fi hàn pé, fún ìdí kan, ẹ̀jẹ̀ inú àwọn ẹ̀ya ara rẹ̀ pàtàkì kan ń dì, afẹ́fẹ́ ò sì ráyè dénú àwọn ẹ̀ya ara náà. Àwọn dókítà náà ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú ìṣòro yìí kúrò, àmọ́ pàbó ló já sí. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ìyẹn ní January 30, 2005, ohun tó tíì bà mí nínú jẹ́ jù lọ nígbèésí ayé mi ṣẹlẹ̀ sí mi. Rose Marie mi ọ̀wọ́n kú.
Lákòókò yẹn, mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rin ọdún, àtikékeré mi ni mo sì ti máa ń ráwọn èèyàn tó ń wà nínú ìbànújẹ́, àmọ́ èyí yàtọ̀. Bí Bíbélì ṣe sọ lèmi àti Rose Marie rí, a jẹ́ “ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Mo ti rí i táwọn èèyàn máa ń wà nínú ìbànújẹ́, èmi fúnra mi sì ti máa ń ní ìbànújẹ́ ọkàn nígbà táwọn ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí mi bá kú. Àmọ́, ìbànújẹ́ tí mo ní nítorí ikú ìyàwó mi yìí pọ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ, kó sì kúrò lọ́kàn mi. Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ dáadáa pé ìbànújẹ́ kékeré kọ́ lọmọ aráyé ti ń fara dà bọ̀ látìgbà pípẹ́ sẹ́yìn nígbà téèyàn bá kú.
Síbẹ̀, mímọ̀ tí mo mọ ohun tó ń fa ìbànújẹ́ àti bí yóò ṣe dópin ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Sáàmù 34:18 sọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.” Ohun pàtàkì tó jẹ́ kí n lè fara da ìbànújẹ́ yìí ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Bíbélì kọ́ni pé àjíǹde yóò wà, pé àwọn tó wà nínú ibojì yóò jáde wá, wọ́n á sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀. Ìṣe 24:15 sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Rose Marie nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gan-an. Ó sì dá mi lójú pé Ọlọ́run náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, yóò sì rántí rẹ̀. Yóò mú un padà wá nígbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀, mo sì nírètí pé ìgbà yẹn kò pẹ́ mọ́ rárá.—Lúùkù 20:38; Jòhánù 11:25.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbànújẹ́ kékeré kọ́ ni ikú èèyàn ẹni máa ń fà, síbẹ̀ ayọ̀ tá a máa ní nígbà tá a bá rí wọn padà nígbà àjíǹde á pọ̀ jùyẹn lọ gan-an. (Máàkù 5:42) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. . . . Ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.” (Aísáyà 26:19) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára “àwọn olódodo” tí Bíbélì mẹ́nu kàn nínú Ìṣe 24:15 yẹn ni yóò kọ́kọ́ jí dìde. Àkókò yẹn á ti lọ wà jù! Rose Marie á wà lára àwọn tó máa jíǹde. Ó dájú pé tayọ̀tayọ̀ láwa èèyàn rẹ̀ yóò kí i káàbọ̀! A ó láyọ̀ gan-an lákòókò yẹn nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nínú ayé tí kò ti ní sí ìbànújẹ́ mọ́!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Nígbà tí mo wà lórílẹ̀-èdè Ṣáínà, mo rí i bí ìyà ṣe jẹ àwọn èèyàn gan-an
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Látọdún 1957 ni mo ti ń sìn ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Mo fẹ́ Rose Marie lọ́dún 1950
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìgbà tá à ń ṣe ayẹyẹ àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó wa rèé lọ́dún 2000