ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 5/1 ojú ìwé 14-16
  • Má Bẹ̀rù Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Bẹ̀rù Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Nípa Ìbẹ̀rù
  • “Ọlọ́run Oníṣẹ́ Ìgbàlà”
  • Àwọn Àpẹẹrẹ ti Òde Òní
  • Jàǹbá Kan Yí Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Padà
  • Bó Ṣe Kápá Ìdààmú Ọkàn
  • Máa Fi Ìgbẹ́kẹ̀lé Sin Jèhófà Nìṣó
  • Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro Tó Dé Bá Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Bẹ̀rù Jèhófà Káyé Rẹ Lè Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ Bẹru Jehofa Ki Ẹ Sì Fi Ogo Fun Orukọ Mímọ́ rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 5/1 ojú ìwé 14-16

Má Bẹ̀rù Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!

KÉTÉ lẹ́yìn tí wọ́n ju bọ́ǹbù àkọ́kọ́ ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ni Harold C. Urey tó gba Ẹ̀bùn Ẹ̀yẹ Nobel lórí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa bọ́ǹbù sọ nípa ọjọ́ iwájú pé: “A ó máa jẹun nínú ìbẹ̀rù, a ó máa sùn nínú ìbẹ̀rù, a ó máa gbé nínú ìbẹ̀rù, a ó sì kú sínú ìbẹ̀rù.” Ó dájú pé ayé tá à ń gbé lónìí kún fún ìbẹ̀rù, ìyẹn kò sì yà wá lẹ́nu! Ojoojúmọ́ làwọn ìwé ìròyìn ń sọ nípa àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ táwọn apániláyà ń ṣe, àwọn ìwà ọ̀daràn tó burú jáì, àtàwọn àìsàn téèyàn ò rí irú rẹ̀ rí.

Nítorí pé a jẹ́ Kristẹni, a mọ ohun tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí. Wọ́n ń fi hàn pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò nǹkan búburú yìí la wà, èyí tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la ó fi dá a mọ̀. (2 Tímótì 3:1) Èyí wá jẹ́ kí ìgbọ́kànlé wa túbọ̀ lágbára sí i pé láìpẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yóò mú ayé tuntun níbi tí òdodo yóò ti gbilẹ̀ wá. (2 Pétérù 3:13) Àmọ́, ní báyìí ná, ǹjẹ́ àwa Kristẹni náà bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù?

Èrò Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Nípa Ìbẹ̀rù

Jékọ́bù, Dáfídì, àti Èlíjà wà lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó bẹ̀rù nígbà tí wọ́n bára wọn nínú ipò eléwu. (Jẹ́nẹ́sísì 32:6, 7, 1 Sámúẹ́lì 21:11, 12, 1 Àwọn Ọba 19:2, 3) Kì í ṣe pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kò nígbàgbọ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó gbára lé Jèhófà dáadáa ni wọ́n. Àmọ́, nítorí pé èèyàn ni Jékọ́bù, Dáfídì, àti Èlíjà, àwọn ìgbà kan wà tẹ́rù ba àwọn náà. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Èlíjà jẹ́ ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa.”—Jákọ́bù 5:17.

Àwa náà lè máa bẹ̀rù bá a ti ń ronú nípa àwọn ìṣòro tá à ń bá yí nísinsìnyí tàbí èyí tá a lè dojú kọ lọ́jọ́ iwájú. Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kò yà wá lẹ́nu. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé Sátánì Èṣù ti pinnu láti gbógun ja “àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 12:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ni àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kàn jù lọ, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.” (2 Tímótì 3:12) Síbẹ̀, kò yẹ ká bẹ̀rù ju bó ti yẹ lọ nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro. Kí nìdí?

“Ọlọ́run Oníṣẹ́ Ìgbàlà”

Dáfídì onísáàmù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà fún wa.” (Sáàmù 68:20) Àìmọye ìgbà ni Jèhófà ti fi hàn pé òun lágbára láti gba àwọn èèyàn òun là, yálà nípa kíkó wọn yọ nínú ewu tàbí nípa fífún wọn lókun láti ní ìfaradà. (Sáàmù 34:17; Dáníẹ́lì 6:22; 1 Kọ́ríńtì 10:13) Látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o ti kọ́, mélòó lo lè rántí lára irú àwọn ‘iṣẹ́ ìgbàlà’ bẹ́ẹ̀?

O ò ṣe fi ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Indexa ṣe ìwádìí nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé àwọn kan, irú bí Àkúnya Omi tó kárí ayé ní ọjọ́ Nóà, bí Jèhófà ṣe gba Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ là kúrò ní Sódómù àti Gòmórà, báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jáde kúrò ní Íjíbítì tí wọ́n sì fẹsẹ̀ rìn la Òkun Pupa já, tàbí bí ọ̀tẹ̀ tí Hámánì dì láti pa gbogbo àwọn Júù run ṣe forí ṣánpọ́n? Tó o bá ń ka àwọn ìtàn amúniláyọ̀ wọ̀nyí tó o sì ń ṣàṣàrò lórí wọn, yóò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára sí i pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà. Èyí yóò sì wá ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ láìbẹ̀rù.

Àwọn Àpẹẹrẹ ti Òde Òní

Ǹjẹ́ o mọ àwọn kan tó ti fara dà ìṣòro tó le gan-an lágbègbè rẹ? Ó lè jẹ́ ẹnì kan tí wọ́n ti sọ sẹ́wọ̀n rí nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run. O lè mọ àgbàlagbà kan tó ń sin Jèhófà nìṣó láìfi àìlera ara pè. O sì tún lè ronú nípa àwọn ọ̀dọ́ tí kò dara pọ̀ mọ́ ayé pẹ̀lú gbogbo ohun táwọn tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé ń fojú wọn rí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òbí tó ń nìkan tọ́mọ láìsí ọkọ tàbí aya tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ tún wà níbẹ̀, tàbí ẹnì kan tí kò lọ́kọ tàbí aya síbẹ̀ tó ń sin Jèhófà nìṣó láìfi ìṣòro àìní alábàárò pè. Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀? Ríronú nípa bí wọ́n ṣe di ìgbàgbọ́ wọn mú gírígírí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìfaradà láìbẹ̀rù, bó o tiẹ̀ ń kojú ìṣòro.

Kì í ṣe kìkì ìgbà táwọn èèyàn bá ń ṣe àtakò sí wa tàbí tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa nìkan la nílò ìgboyà, a tún nílò ìgboyà nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé ọ̀ràn ẹbọ Kristi kàn wá gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. (Gálátíà 2:20) Ìgbà yẹn la tó lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ láìsí pé à ń bẹ̀rù tàbí ká máa ṣojo. Tá a bá ń rò pé a ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà lè nífẹ̀ẹ́ sí, a lè ṣàṣàrò lórí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kì í ha ṣe ológoṣẹ́ méjì ni a ń tà ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré? Síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù: ẹ níye lórí púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.”—Mátíù 10:29-31.

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! sábà máa ń gbé ìtàn ìgbésí ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti òde òní jáde, ìyẹn àwọn tó ti fìgboyà kojú àwọn ìṣòro tó le. Èyí kò túmọ̀ sí pé ìṣòro tí wọ́n ní kì í kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn o. Àmọ́ wọn ò jẹ́ kírú ìrẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Àwọn ìtàn wọn tá a kọ sínú àwọn ìwé ìròyìn wa lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti ní ìfaradà kó o má sì ṣe bẹ̀rù. Gbé àwọn àpẹẹrẹ méjì yìí yẹ̀ wò.

Jàǹbá Kan Yí Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Padà

Ìwé ìròyìn Jí! ti April 22, 2003 (Gẹ̀ẹ́sì) ní àpilẹ̀kọ kan nínú tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Bí Jàǹbá Kan Ṣe Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà.” Inú àpilẹ̀kọ náà ni Stanley Ombeva tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Kẹ́ńyà ti mẹ́nu kan gbogbo ìṣòro tó ní lẹ́yìn tí mọ́tò kan tó ń sáré àsápajúdé kọ lù ú. Bí àìsàn rẹ̀ ṣe túbọ̀ ń le sí i, ó pàdánù iṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo owó tó yẹ kí wọ́n san fún un. Arákùnrin Ombeva sọ pé: “Bí mo ti wá ń mọ bí ipò tí mo wà ti le tó, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ro èrò tí kò tọ́, màá máa ronú nípa ipò tí mo bá ara mi yìí, bẹ́ẹ̀ ni màá sì máa kanra. Mó tún máa ń bínú, mo sì máa ń kanra mọ́ àwọn èèyàn nígbà míì.” Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tí arákùnrin yìí ní, kò fòyà rárá. Kò jẹ́ kí ìjákulẹ̀ borí òun débi tí yóò fi wá juwọ́ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbára lé Jèhófà. Arákùnrin Ombeva tún sọ pé: “Jèhófà tì mí lẹ́yìn gan-an ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà nínú ìṣòro yẹn, ó tì mí lẹ́yìn débi pé ńṣe lojú ara mi máa ń tì mí nígbà míì. Mo wá pinnu láti máa ka àwọn Ìwé Mímọ́ tí mo mọ̀ pé ó lè tù mí nínú nírú ipò tí mo wà.”

Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Ombeva sọ láìfi nǹkan kan bò yìí ti ran ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro wọn láìbẹ̀rù. Arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Mo sunkún nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ yìí. Ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà lo àpilẹ̀kọ náà láti jẹ́ kí n mọ̀ pé inú òun yọ́ sí mi, pé òun ń fìfẹ́ bójú tó mi, òun sì ń tù mí nínú.” Ẹlẹ́rìí mìíràn kọ̀wé pé: “Àwọn àpilẹ̀kọ bí èyí máa ń fún wa níṣìírí tó ga, ìyẹn àwa tá a wà nírú ipò tó jọ èyí àmọ́ tá à ń mú un mọ́ra láìfọhùn.”

Bó Ṣe Kápá Ìdààmú Ọkàn

Ìtàn ìgbésí ayé ẹlòmíràn tó tún wọni lọ́kàn gan-an bẹ́ẹ̀ ni ti Herbert Jennings, èyí tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó sọ pé “Ẹ Kò Mọ Ohun Tí Ìwàláàyè Yín Yóò Jẹ́ Lọ́la.”b Ìṣòro híhùwà lódìlódì ni Arákùnrin Jennings ní. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí àìsàn náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é, ó ní: “Ìṣòro ńlá ni lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ fún mi. Síbẹ̀síbẹ̀, mi o ṣiyèméjì rárá nípa bí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tẹ̀mí ṣe níye lórí tó. Kí n lè borí ìṣòro náà, mo sábà máa ń wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn tí gbogbo èèyàn bá ti jókòó tán, màá sì kúrò níbẹ̀ kó tó di pé àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sókè lọ sódò lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ.”

Kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tún jẹ́ ìṣòro fún Arákùnrin Jennings. Ó sọ pé: “Nígbà míì, tí mo bá tiẹ̀ dé ilé kan pàápàá, ẹ̀rù àtitẹ aago ẹnu ilẹ̀kùn máa ń bà mí. Síbẹ̀ náà, mi ò ní padà sílé, nítorí mo mọ̀ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò jẹ́ kí àwa àti ẹnikẹ́ni tó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ní ìgbàlà. (1 Tímótì 4:16) Tó bá wá ṣe díẹ̀, màá gbìyànjú àtikápá ìmọ̀lára mi, màá lọ sílé tó tẹ̀ lé ìyẹn, màá sì tún gbìyànjú lẹ́ẹ̀kan sí i. Nípa bíbá a nìṣó láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ó ṣeé ṣe fún mi láti ní ìlera nípa tẹ̀mí, ìyẹn sì túbọ̀ fún mi lágbára láti máa fara dà á.”

Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Jennings ran ọ̀pọ̀ àwọn tó kà á lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tiwọn náà láìbẹ̀rù. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Láti ọdún kejìdínlọ́gbọ̀n tí mo ti ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, kò tíì sígbà kankan tí nǹkan tí mo kà wọ̀ mí lára tó bí àpilẹ̀kọ yìí ṣe wọ̀ mí lára. Nígbà tí mo fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sílẹ̀, ńṣe ni mo máa ń dá ara mi lẹ́bi ṣáá. Mo máa ń rò pé ká ní ìgbàgbọ́ mi lágbára ni, mi ò ní fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Bí mo ṣe wá ka ìrírí Arákùnrin Jennings tó ní láti fi iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un nínú ìjọ sílẹ̀ kó lè bójú tó àìsàn tó ń ṣe é ti ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé ohun tí mo ṣe yẹn kò burú. Ìdáhùn àdúrà mi gan-an ni àpilẹ̀kọ yìí jẹ́!”

Bákan náà ni arákùnrin kan kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn tí mo ti jẹ́ alàgbà nínú ìjọ fún odindi ọdún mẹ́wàá, mo ní láti fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ nítorí àìsàn ọpọlọ. Inú mi máa ń bà jẹ́ nítorí pé mi ò lè ṣe alàgbà mọ́ débi pé kì í sábà wù mí láti ka àwọn àpilẹ̀kọ tó bá sọ nípa ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn Jèhófà. Ìdí ni pé àwọn ohun kàǹkàkàǹkà táwọn èèyàn Jèhófà ń gbé ṣe ló sábà máa ń wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà. Àmọ́, ìfaradà Arákùnrin Jennings tù mí nínú gan-an. Mo ti ka àpilẹ̀kọ náà láìmọye ìgbà.”

Máa Fi Ìgbẹ́kẹ̀lé Sin Jèhófà Nìṣó

Bíi ti Arákùnrin Ombeva àti Arákùnrin Jennings, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bá ìjọsìn wọn sí Jèhófà Ọlọ́run lọ láìbẹ̀rù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó le gan-an. Tó o bá wà lára àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà nìṣó láìfi ìṣòro pè, a kí ọ pé o káre. Mọ̀ dájú pé: ‘Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé o ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, o sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.’—Hébérù 6:10.

Bí Jèhófà ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn láyé ìgbàanì, ó lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti borí ìṣòro èyíkéyìí tó lè dé bá ọ. Nítorí náà, máa fi ọ̀rọ̀ Jèhófà sọ́kàn nígbà gbogbo, ìyẹn ọ̀rọ̀ tó ti ẹnu wòlíì Aísáyà sọ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

b Wo Ilé Ìṣọ́ December 1, 2000, ojú ìwé 24 sí 28.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ń sin Jèhófà láìbẹ̀rù bíi ti Stanley Ombeva (lókè) àti Herbert Jennings (lápá ọ̀tún)

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]

Fọ́tò USAF

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́