ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 6/15 ojú ìwé 4-7
  • Ohun Tó Lè Tọ́ Wa Sọ́nà Ayọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Lè Tọ́ Wa Sọ́nà Ayọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtùnú Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú
  • Ìrètí Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
  • Jèhófà Fẹ́ Kó O Máa Láyọ̀
  • Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Olólùfẹ́ Wa Tí Wọ́n Ti Kú?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé A Ń kẹ́dùn, A Kò Wà Láìní Ìrètí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • “A Ti Gbé Ikú Mì Títí Láé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 6/15 ojú ìwé 4-7

Ohun Tó Lè Tọ́ Wa Sọ́nà Ayọ̀

ÈRÒ àwọn tó kọ ìwé Ìpolongo Òmìnira Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni pé, “ìlépa Ayọ̀” jẹ́ ẹ̀tọ́ gbogbo èèyàn. Àmọ́ ọ̀tọ̀ ni kéèyàn máa lépa ohun kan, ọ̀tọ̀ sì ni kọ́wọ́ ẹni tẹ nǹkan ọ̀hún. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń sapá lójú méjèèjì kí wọ́n lè mókè nínú eré ìnàjú àti eré ìdárayá, àmọ́ mélòó lo mọ̀ nínú wọn tọ́wọ́ rẹ̀ ti tẹ ohun tó ń lé? Ohun tí gbajúmọ̀ olórin kan tó mọ ohun tójú ẹni tó bá fẹ́ di olókìkí nídìí iṣẹ́ orin kíkọ máa ń rí sábà máa ń sọ fáwọn tó bá wá gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ẹ lè má rọ́wọ́ mú o.”

Tí ìwọ náà bá ń rò pé o lè má rí ojúlówó ayọ̀, má ṣe bọkàn jẹ́. Mọ̀ dájú pé tó o bá wá ayọ̀ lọ́nà tó tọ́, wàá rí i. Kí ló mú ká sọ bẹ́ẹ̀? Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ti pèsè ìtọ́sọ́nà tó máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ayọ̀. Jèhófà lè jẹ́ kó o borí àwọn ohun tó máa ń kó ìbànújẹ́ báni. Bí àpẹẹrẹ, wo ìtùnú tí Ọlọ́run máa fún ọ nígbà téèyàn rẹ bá kú.

Ìtùnú Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Ǹjẹ́ ikú máa ń ṣe nǹkan ire? Rárá o. Ńṣe ni ikú máa ń ya òbí àtọmọ. Ó ń ya àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ó sì ń fọ́ ilé adùn. Nígbà tí ikú bá ṣọṣẹ́ nínú ìdílé kan, ìbànújẹ́ tó máa ń bá irú ìdílé bẹ́ẹ̀ kì í ṣe kékeré.

Gbogbo wa la mọ oró tí ikú máa ń dá. Àmọ́, àwọn kan ò gbà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìbùkún ni ikú jẹ́. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lóṣù August ọdún 2005, nígbà tí ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Ìjì Katrina jà ní àgbègbè ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Mẹ́síkò. Nígbà ìsìnkú ọ̀kan lára àwọn tí ìjì líle náà pa, àlùfáà tó wàásù níbẹ̀ sọ pé: “Ìjì líle yẹn kọ́ ló pa á o. Ọlọ́run ló mú un lọ sọ́run.” Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti akọ̀wé ilé ìwòsàn kan tó fẹ́ tu ọmọbìnrin kan tí ìyá rẹ̀ kú nínú. Ó sọ fún un pé kó má banú jẹ́ torí pé Ọlọ́run ti mú ìyá rẹ̀ lọ sọ́run. Ni ọmọbìnrin náà bá ń sọ pẹ̀lú omijé lójú pé: “Áà, kí ló dé tí Ọlọ́run fi gba ìyá mi mọ́ mi lọ́wọ́?”

Ó dájú pé lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́ bẹ́ẹ̀ kì í tu àwọn tí èèyàn wọn kú nínú. Kí nìdí? Ìdí ni pé irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ kéèyàn mọ ohun tí ikú jẹ́. Ohun tó tiẹ̀ wá burú jù nínú ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni pé, ńṣe ni irú èrò bẹ́ẹ̀ sọ Ọlọ́run dẹni tó ń fìwà òǹrorò já àwọn èèyàn gbà mọ́ ìdílé àti ọ̀rẹ́ wọn lọ́wọ́. Dípò tí irú èrò yẹn ì bá fi fi Ọlọ́run hàn gẹ́gẹ́ bí orísun ìtùnú, ńṣe ló ń jẹ́ káwọn èèyàn kà á sí òṣìkà nígbà téèyàn bá kú. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tí ikú jẹ́ gan-an.

Bíbélì sọ pé ikú jẹ́ ọ̀tá. Ó ní ikú dà bí ọba tó ń ṣàkóso lórí ìran èèyàn. (Róòmù 5:17; 1 Kọ́ríńtì 15:26) Agbára ikú tí í ṣe ọ̀tá wa yìí pọ̀ débi pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè dènà rẹ̀, àìmọye èèyàn ló sì ń pa. Ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí jẹ́ ká rí ìdí tí ìbànújẹ́ fi máa ń báni nígbà téèyàn ẹni bá kú àti ìdí tí gbogbo nǹkan fi máa ń tojú súni. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé kò sẹ́ni tí irú rẹ̀ kì í ṣẹlẹ̀ sí. Síbẹ̀, ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń lo ikú tó jẹ́ ọ̀tá láti mú àwọn èèyàn wa lọ sọ́run? Ẹ jẹ́ kí Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí.

Oníwàásù 9:5, 10 sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Kí ni Ṣìọ́ọ̀lù? Ipò òkú ni. Ṣìọ́ọ̀lù tí í ṣe ipò òkú yìí làwọn tó bá kú máa ń wà. Àwọn òkú ò lè ṣe ohunkóhun nínú sàréè, wọn ò lè gbápá, wọn ò lè gbẹ́sẹ̀, wọn ò mọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ronú ohunkóhun. Bíi pé wọ́n sun oorun àsùnwọra ló rí.a Ohun tí Bíbélì sọ yẹn fi hàn pé Ọlọ́run kì í mú àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lọ́run. Kíkú tí wọ́n kú ti mú kí wọ́n di aláìlẹ́mìí nínú sàréè tí wọ́n wà.

Jésù fi hàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú. Ó fi ikú wé oorun. Ká ní ọ̀run ni Lásárù lọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè, á jẹ́ pé Jésù ò ṣe é lóore kankan bó ṣe jí i sórí ilẹ̀ ayé padà torí pé ó ṣì tún máa padà kú. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù dé ibi tí wọ́n sin Lásárù sí, ó fi ohùn rara sọ pé: “Lásárù, jáde wá!” Bíbélì sì sọ pé: “Ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá.” Bí Lásárù ṣe tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé padà nìyẹn. Jésù mọ̀ dájú pé Lásárù ò fìgbà kan kúrò lórí ilẹ̀ ayé yìí. Inú ibojì tí wọ́n sin ín sí ló wà láìmọ ohunkóhun.—Jòhánù 11:11-14, 34, 38-44.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì ròyìn rẹ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé Ọlọ́run ń lo ikú láti fi mú àwọn èèyàn láti orí ilẹ̀ ayé lọ sọ́run. Nítorí náà, a lè sún mọ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìdánilójú pé òun kọ́ ló ń kó ìbànújẹ́ bá wa. Ó tún yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run mọ ọ̀fọ̀ àti àdánù tí ikú, ọ̀tá wa, máa ń mú bá wa. Ohun tí Bíbélì sì fi kọ́ni nípa ipò táwọn òkú wà fi hàn pé àwọn tó ti kú kì í lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì tàbí pọ́gátórì láti lọ joró, àmọ́ aláìlẹ́mìí ni wọ́n nínú sàréè tí wọ́n wà. Nípa bẹ́ẹ̀, kò yẹ ká wá máa bínú sí Ọlọ́run tá a bá rántí àwọn èèyàn wa tó ti kú, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa bẹ̀rù pé a ò mọ ipò tí wọ́n wà. Yàtọ̀ síyẹn, ohun mìíràn tún wà nínú Bíbélì tí Jèhófà pèsè láti fi tù wá nínú.

Ìrètí Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀

Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé yẹ̀ wò wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ pé ìrètí jẹ́ ohun pàtàkì téèyàn máa ní kó tó lè ní ayọ̀. Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ìrètí” túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìdánilójú pé ohun tó dára ń bọ̀. Àmọ́, ká lè mọ bí ìrètí ṣe ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀ nísinsìnyí, ẹ jẹ́ ká padà sórí ìtàn bí Jésù ṣe jí Lásárù dìde.

Ohun méjì, ó kéré tán, ló mú kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn. Ohun àkọ́kọ́ ni pé ó fẹ́ mú ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn Màtá, Màríà àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Jíjí tí Jésù jí Lásárù dìde mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti padà ní ìfararora pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́ Jésù sọ ohun kejì, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ, tó mú kó jí Lásárù dìde, ó ní: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé bí ìwọ bá gbà gbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?” (Jòhánù 11:40) Ohun tí Bíbélì The New Testament in Modern English, tí J. B. Phillips ṣe túmọ̀ gbólóhùn tó gbẹ̀yìn ẹsẹ yẹn sí ni “iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run lè ṣe.” Jésù lo àjíǹde Lásárù láti jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Jèhófà Ọlọ́run lè ṣe àtàwọn ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ẹ jẹ́ ká tún ṣe àlàyé díẹ̀ sí i nípa “iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run lè ṣe” yìí.

Nínú Jòhánù 5:28, 29, Jésù sọ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn òkú tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù, títí kan àwọn èèyàn wa, ni yóò jíǹde. Ìṣe 24:15 tún jẹ́ ká mọ̀ sí i nípa ohun ìyanu yìí, ó sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Ìyẹn fi hàn pé “àwọn aláìṣòdodo” pàápàá, ìyẹn ọ̀pọ̀ àwọn tí kò mọ Jèhófà tí wọn ò sì sìn ín, yóò láǹfààní lọ́jọ́ iwájú láti rí ojú rere Ọlọ́run.

Ibo la máa jí wọn dìde sí? Sáàmù 37:29 sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Ìwọ ronú nípa ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná! Àwọn ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ tí ikú ti yà yóò padà rí ara wọn lórí ilẹ̀ ayé ńbí. Bó o bá ṣe ń ronú pé tó bá dìgbà yẹn, wàá máa gbádùn pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ tẹ́ ẹ jọ ń ṣeré pọ̀ tẹ́lẹ̀, ó dájú pé ọkàn rẹ yóò máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀.

Jèhófà Fẹ́ Kó O Máa Láyọ̀

A ti gbé méjì yẹ̀ wò lára ọ̀nà tí Jèhófà lè gbà mú kí ayọ̀ rẹ pọ̀ sí i bó o tilẹ̀ ní ìṣòro. Àkọ́kọ́ ni pé Jèhófà ń lo Bíbélì láti fún ọ ní ìmọ̀ àti ìtọ́sọ́nà tí wàá lè fi borí àwọn ìṣòro rẹ. Yàtọ̀ sí pé Bíbélì ń tù wá nínú nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ wá, àwọn ìlànà inú rẹ̀ tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè borí ìṣòro ìṣúnná owó àti àìsàn. Ó lè fún ọ lókun láti fara da ojúsàájú tó wọ́pọ̀ láwùjọ àti rògbòdìyàn tí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ń dá sílẹ̀. Tó o bá sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Bíbélì, wàá mọ ohun tó o lè ṣe tí ìṣòro rẹ ò fi ní borí rẹ.

Ọ̀nà kejì ni pé tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá ní ìrètí tó dára ju ohunkóhun tí ọmọ aráyé lè ṣèlérí lọ. Lára ohun tí Bíbélì sì ní ká máa retí ni àjíǹde àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìbátan wa tí wọ́n ti kú. Ìṣípayá 21:3, 4 tún jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ náà síwájú sí i, ó ní: “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú [aráyé]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ohun yòówù kó máa fa ìbànújẹ́ fún ọ yóò dohun ìgbàgbé láìpẹ́. Àwọn ohun tí Bíbélì ṣèlérí yóò ṣẹ, o sì lè gbádùn àwọn nǹkan ọ̀hún. Mímọ̀ téèyàn tiẹ̀ mọ̀ pé nǹkan ń bọ̀ wá dára lọ́jọ́ iwájú tó ohun tó ń tuni lára lọ́tọ̀. Mímọ̀ tó o sì mọ̀ pé o ò ní máa joró títí ayé lẹ́yìn ikú tó ohun tó yẹ kó mú ọ láyọ̀.

Bí àpẹẹrẹ: Àrùn jẹjẹrẹ pa ọkọ Maria lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn. Ńṣe ló jẹ̀rora títí tó fi kú. Inú ọ̀fọ̀ yìí ni Maria ṣì wà nígbà tí ìṣòro ìṣúnná owó tún mú kóun àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́ta kó kúrò ní ilé wọn. Lẹ́yìn ọdún méjì, Maria rí i pé òun náà ní àrùn jẹjẹrẹ. Ẹ̀ẹ̀méjì ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ tó díjú fún un, ojoojúmọ́ ló sì ń jẹ̀rora. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìṣòro yẹn náà, Maria ò sọ̀rètí nù, ṣe ló tún ń fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí. Kí ló ń jẹ́ kó máa láyọ̀?

Maria sọ pé: “Nígbà tí mo bá níṣòro, mo máa ń gbìyànjú láti má ṣe ronú jù nípa ìṣòro mi. Mi ò kì í bi ara mi láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ló dé tó jẹ́ pé èmi nirú nǹkan yìí wá ṣẹlẹ̀ sí? Kí ló dé tí irú ìyà yìí fi ń jẹ mí? Kí nìdí tí mo fi ń ṣàìsàn?’ Téèyàn bá ti ń ronú jù nípa ìṣòro tó ní, èèyàn ò ní lókun kankan mọ́. Dípò tí màá sì fi máa ṣe ohun tó máa tán mi lókun, ńṣe ni mò ń lo okun mi láti sin Jèhófà àti láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ìyẹn ló máa ń fún mi láyọ̀.”

Báwo ni ìrètí ṣe ran Maria lọ́wọ́? Ó mú kó fi ọkàn rẹ̀ sí ọjọ́ iwájú nígbà tí Jèhófà yóò mú àìsàn àtàwọn ìṣòro mìíràn tó ń yọ aráyé lẹ́nu kúrò. Tí Maria bá lọ sílé ìwòsàn fún ìtọ́jú, ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó ní yìí fáwọn alárùn jẹjẹrẹ bíi tirẹ̀ tí ìbànújẹ́ ti sorí wọn kodò. Báwo ni ìrètí yìí ti ṣe pàtàkì tó fún Maria? Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ṣe àṣàrò lórí ohun tí Bíbélì sọ nínú Hébérù 6:19, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti fi ìrètí wé ìdákọ̀ró fún ọkàn. Láìsí ìdákọ̀ró yìí, ńṣe lèèyàn máa sú lọ bí ọkọ̀ ojú omi tí ìjì gbé lọ. Àmọ́ téèyàn bá so ara ẹ̀ mọ́ ìdákọ̀ró yìí, kò sí ìṣòro èyíkéyìí tó dà bí ìjì líle tó máa lè mi olúwarẹ̀.” “Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun [yìí], èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí” ló mú kí Maria máa láyọ̀ nígbà gbogbo. Ó lè mú kí ìwọ náà máa láyọ̀.—Títù 1:2.

Láìka ìṣòro yòówù kó o ní sí, tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá rí ojúlówó ayọ̀. Àmọ́, ó lè máa béèrè lọ́kàn ara rẹ pé, ‘Báwo lèyí ṣe lè ṣeé ṣe?’ Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti fi ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé o ní láti mọ̀ tó o bá fẹ́ ní ojúlówó ayọ̀ hàn ọ́. Bó o sì ṣe ń dúró de ìgbà tí Jèhófà máa ṣe àwọn ohun tó ṣèlérí, o lè di ọ̀kan lára àwọn tí Bíbélì sọ nípa wọn pé: “Ọwọ́ wọn yóò sì tẹ ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀, ẹ̀dùn-ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn yóò sì fò lọ.”—Aísáyà 35:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica (2003) sọ pé Ṣìọ́ọ̀lù jẹ́ “ibì kan tí kò ti sí ìrora tàbí ìgbádùn, ìjìyà tàbí èrè.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ẹ̀kọ́ Bíbélì nìkan ló lè tuni nínú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìrètí tó wà nínú Bíbélì pé àwọn òkú máa jíǹde lè jẹ́ kéèyàn láyọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́