Ohun Mìíràn Yàtọ̀ sí Bíbélì Tó Mẹ́nu Kan Àwọn Èèyàn Tó Ń Jẹ́ Ísírẹ́lì
WÀLÁÀ kan tí wọ́n fi akọ òkúta gbẹ́ wà ní Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ìlú Káírò lórílẹ̀-èdè Íjíbítì. Wọ́n fi wàláà náà ṣe ìrántí àwọn ibi tí Fáráò Mánẹ́tà ṣẹ́gun. Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà gbọ́ pé Fáráò Mánẹ́tà yìí tí í ṣe ìkẹtàlá nínú àwọn ọmọkùnrin ọba Ramses Kejì ṣàkóso láti nǹkan bí ọdún 1212 sí ọdún 1202 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní apá ìparí àkókò táwọn onídàájọ́ ṣàkóso ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ìlà méjì tó gbẹ̀yìn nínú ọ̀rọ̀ tó wà lára wàláà Mánẹ́tà náà kà pé: “Mo gbógun ja Kénáánì mo sì kó gbogbo nǹkan wọn. Mo gba Áṣíkẹ́lónì, mo ṣẹ́gun Gésérì, mo sì sọ Yano‘am dahoro. Mo pa Ísírẹ́lì run pátápátá, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ kò sì sí mọ́.”
Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà “Ísírẹ́lì” nínú àlàyé yìí? Nínú ọ̀nà ìgbàkọ̀wé aláwòrán tí wọ́n fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, wọ́n fi àwọn àmì kan sí ara àwọn ọ̀rọ̀ náà láti jẹ́ kéèyàn mọ ohun tí wọ́n jẹ́ gan-an. Ìwé The Rise of Ancient Israel ṣàlàyé pé: “Àwọn àmì tí wọ́n fi sí ara mẹ́ta nínú àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́rin yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìlú ni wọ́n. Àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta ọ̀hún ni Áṣíkẹ́lónì, Gésérì àti Yanoam. . . . Àmọ́ àmì tí wọ́n fi sí ara Ísírẹ́lì ní tiẹ̀ fi hàn pé èèyàn ni wọ́n.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Kí ló ṣe pàtàkì nípa ọ̀rọ̀ yẹn? Ọ̀gbẹ́ni Hershel Shanks tó jẹ́ olóòtú àti òǹkọ̀wé ṣàlàyé pé: “Wàláà Òkúta Mánẹ́tà fi hàn pé àwọn èèyàn kan tí wọ́n ń pè ní Ísírẹ́lì gbé ayé ní ọdún 1212 ṣáájú Sànmánì Kristẹni àti pé yàtọ̀ sí pé fáráò ọba Íjíbítì mọ̀ wọ́n, ó tún wò ó pé wọ́n jẹ́ ẹni tó yẹ kóun fi yangàn pé òun ṣẹ́gun.” William G. Dever tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìwalẹ̀pìtàn nípa àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé sọ pé: “Wàláà òkúta Mánẹ́tà fi hàn kedere pé: Àwọn kan wà ní ilẹ̀ Kénáánì tí wọ́n ń pe ara wọn ní ‘Ísírẹ́lì,’ tí àwọn ará Íjíbítì náà sì pè ní ‘Ísírẹ́lì.’ Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, kì í kúkú ṣe pé àwọn ará Íjíbítì fẹ́ ṣe ohun tó máa ti Bíbélì lẹ́yìn o, kò sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn gbé ìtàn àròsọ kan kalẹ̀ pé àwọn èèyàn kan wà tó ń jẹ́ ‘Ísírẹ́lì’ láti lè polongo ara wọn.”
Ibi àkọ́kọ́ tí Bíbélì ti mẹ́nu kan Ísírẹ́lì ni ibi tí wọ́n ti fi orúkọ yẹn pe baba ńlá náà, Jákọ́bù. Nígbà tó yá, wọ́n wá ń pe àwọn àtọmọdọ́mọ ọmọ Jákọ́bù méjìlá ní “àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Jẹ́nẹ́sísì 32:22–28, 32; 35:9, 10) Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, Mósè wòlíì àti Fáráò ọba Íjíbítì lo orúkọ náà “Ísírẹ́lì” nígbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àtọmọdọ́mọ Jákọ́bù. (Ẹ́kísódù 5:1, 2) Yàtọ̀ sí Bíbélì, wàláà òkúta Mánẹ́tà lohun tí wọ́n tíì rí pé ó jẹ́ ohun tó kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn èèyàn tí wọ́n ń pè ní Ísírẹ́lì.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Wàláà òkúta Mánẹ́tà
Àpapọ̀ àmì mẹ́ta tó gbẹ̀yìn, ìyẹn ọ̀pá àti ọkùnrin àti obìnrin tó jókòó, fi hàn pé àwọn èèyàn láti ilẹ̀ àjèjì ni Ísírẹ́lì jẹ́
[Credit Line]
Egyptian National Museum, Cairo, Egypt/Giraudon/The Bridgeman Art Library