“Ilé Dáfídì”—Òtítọ́ Ha Ni Tàbí Ìtàn Àròsọ?
DÁFÍDÌ—ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí ó di olórin, akéwì, jagunjagun, wòlíì, àti ọba—yàtọ̀ gédégbé ní ti ìtayọlọ́lá lọ́nà kíkàmàmà nínú Bíbélì. Ìgbà 1,138 ni a dárúkọ rẹ̀; a lo gbólóhùn náà “Ilé Dáfídì”—tí ó sábà máa ń tọ́ka sí ìlà ọba Dáfídì—ní ìgbà 25. (Sámúẹ́lì Kìíní 20:16) Ọba Dáfídì àti ìlà ọba rẹ̀ ha jẹ́ ìtàn àròsọ lásán bí? Kí ni ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìwalẹ̀pìtàn ṣí payá? Ìròyìn fi tó wa létí pé àwárí pípẹtẹrí kan láìpẹ́ yìí ní ibi ìwújáde ti ìwalẹ̀pìtàn kan ní Tel Dan ní àríwá Gálílì ti ìjótìítọ́ ìtàn Dáfídì àti ìlà ọba rẹ̀ lẹ́yìn.
Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1993, àwùjọ àwọn awalẹ̀pìtàn kan, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Avraham Biran kó sọ̀dí, gbá agbègbè kan lẹ́yìn òde ẹnubodè Dánì ìgbàanì mọ́ féfé. Wọ́n wú gbàgede kan tí a kọnkéré. Pẹ̀lú ìrọ̀rùn ni wọ́n fi wú òkúta dúdú kirikiri kan tí ó yọ gọnbu nínú ilẹ̀. Nígbà tí a kọ ojú òkúta náà sí oòrùn ọ̀sàn, àkọlé ara rẹ̀ hàn ketekete. “Ọlọ́run ọba ò, àkọlé kan wà lára rẹ̀!” Bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Biran ṣe kígbe nìyẹn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Biran àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Joseph Naveh ti Hebrew University ní Jerúsálẹ́mù, yára kọ ìròyìn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kan lórí àkọlé náà. Lórí ìròyìn yìí, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn, Biblical Archaeology Review, ti March/April ọdún 1994, kà pé: “Kì í ṣe gbogbo ìgbà ní àwárí ìwalẹ̀pìtàn kan máa ń fara hàn ní ojú ìwé àkọ́kọ́ ìwé agbéròyìnjáde New York Times (kí a má tilẹ̀ mẹnu kan ìwé ìròyìn Time). Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó kọjá nìyẹn sí àwárí tí a ṣe ní Tel Dan, òkìtì rírẹwà kan ní àríwá Gálílì, ní ẹsẹ̀ Òkè Hámónì, lẹ́bàá ọ̀kan nínú orísun Odò Jọ́dánì.
“Níbẹ̀, Avraham Biran àti ẹgbẹ́ àwọn awalẹ̀pìtàn rẹ̀ rí àkọlé pípẹtẹrí kan, tí ó ti wà láti ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, tí ń tọ́ka sí ‘Ilé Dáfídì’ àti sí ‘Ọba Ísírẹ́lì.’ Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a óò rí orúkọ Dáfídì nínú àkọlé ìgbàanì èyíkéyìí yàtọ̀ sí Bíbélì. Ohun tí ó pẹtẹrí jù lọ ni pé, àkọlé náà kò wulẹ̀ tọ́ka sí ‘Dáfídì’ ṣùgbọ́n sí Ilé Dáfídì, ìlà ọba ti ọba ńlá Ísírẹ́lì ìgbàanì.
“‘Ọba Ísírẹ́lì’ jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí a sábà máa ń rí nínú Bíbélì, ní pàtàkì nínú Ìwé Àwọn Ọba. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí lè jẹ́ ìtọ́kasí tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ, tí ó yàtọ̀ sì ti Bíbélì nípa Ísírẹ́lì, nínú àkájọ ìwé àwọn Semite. Bí àkọlé yìí bá fi ohunkóhun hàn, ó fi hàn pé Ísírẹ́lì àti Júdà jẹ́ ìjọba tí ó ṣe pàtàkì ní àkókò yẹn, ní ìtakora pẹ̀lú ohun tí àwọn ọ̀mọ̀wé àkẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tí wọ́n jẹ́ olùjá-Bíbélì-níkoro sọ.”
A gbé àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà ka ìrísí ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ sára ohun àfamọ̀ṣe tí a rí lẹ́bàá àfọ́kù òkúta àti ọ̀rọ̀ inú àkọlé náà. Gbogbo ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tọ́ka sí àkókò kan náà, ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn Ọba Dáfídì. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà gbọ́ pé àkọlé náà jẹ́ apá kan ohun ìrántí ìṣẹ́gun tí ọmọ Árámù kan tí ó jẹ́ ọ̀tá “Ọba Ísírẹ́lì” àti “[Ọba] Ilé Dáfídì” gbé kalẹ̀ ní Dánì. Àwọn ọmọ Árámù, tí wọ́n ń jọ́sìn Hadad, gbajúmọ̀ ọlọ́run ìjì líle, gbé ní apá ìlà oòrùn.
Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1994, a tún rí àfọ́kù méjì òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ yìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Biram ròyìn pé: “Nínú àfọ́kù méjèèjì yìí, a rí orúkọ ọlọ́run àwọn ọmọ Árámù, Hadad, àti ìtọ́kasí kan sí ogun tí ó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Árámù.”
Olórí àfọ́kù tí a rí ní ọdún 1993 ní àwọn ìlà 13 tí a lè rí fírífírí, tí a kọ ní èdè Hébérù àtijọ́. Ní àkókò yẹn, a máa ń lo àmì tó-ín fún pípín àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kan sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo pẹ̀lú àwọn lẹ́tà náà “bytdwd” (tí a túmọ̀ sí àwọn lẹ́tà èdè Róòmù) ni a fi kọ “Ilé Dáfídì” dípò “byt” (ilé), àmì tó-ín, lẹ́yìn náà “dwd” (Dáfídì). Lọ́nà tí ó yéni, a ti gbé ìbéèrè dìde nípa ìtumọ̀ “bytdwd.”
Ògbógi nínú ìmọ̀ èdè púpọ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Anson Rainey, ṣàlàyé pé: “Joseph Naveh àti Avraham Biran kò ṣàlàyé àkọlé náà ní kúlẹ̀kúlẹ̀, bóyá nítorí pé wọ́n rò pé àwọn òǹkàwé yóò mọ̀ pé a sábà máa ń fo ọ̀rọ̀ tí ń pín ọ̀rọ̀ láàárín ọ̀rọ̀ méjì nínú irú ìgbékalẹ̀ bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì bí ọ̀rọ̀ tí a pa pọ̀ náà bá jẹ́ orúkọ gidi tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Dájúdájú, ‘Ilé Dáfídì’ jẹ́ orúkọ tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìṣèlú àti ẹkùn kan ní pàtó ní àárín gbùngbùn ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa.”
Ẹ̀rí Ìwalẹ̀pìtàn Míràn
Lẹ́yìn àwárí yẹn, ògbógi kan lórí òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha (tí a tún ń pè ní Òkúta Móábù), Ọ̀jọ̀gbọ́n André Lemaire, ròyìn pé ó tún ń tọ́ka sí “Ilé Dáfídì.”a Òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha, tí a rí ní ọdún 1868, jọ òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Tel Dan lọ́nà púpọ̀. Àwọn méjèèjì ti wà láti ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n ní àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ kan náà, wọ́n tóbi bákan náà, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé èdè àwọn Semite kan náà ni a fi kọ wọ́n.
Ní ti títún ìlà kan tí ó ti bù lára òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha náà gbẹ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Lemaire kọ̀wé pé: “Ní nǹkan bí ọdún méjì kí a tó ṣàwárí àfọ́kù Tel Dan, mo parí èrò pé òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha ní ìtọ́kasí ‘Ilé Dáfídì’ nínú. . . . Ìdí tí a kò fi ṣàkíyèsí ìtọ́kasí yìí nípa ‘Ilé Dáfídì’ tẹ́lẹ̀ lè jẹ́ nítorí òkodoro òtítọ́ náà pé, òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha kò tí ì fìgbà kankan ní editio princeps [ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́]. Ohun tí mò ń múra láti ṣe nìyẹn, ní 125 ọdún lẹ́yìn tí a ti ṣàwárí òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha.”
Irú ìsọfúnni ìwalẹ̀pìtàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ohun tí ó fani lọ́kàn mọ́ra nítorí pé, áńgẹ́lì kan, Jésù fúnra rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àti àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò jẹ́rìí sí ìjótìítọ́ ìtàn Dáfídì. (Mátíù 1:1; 12:3; 21:9; Lúùkù 1:32; Ìṣe 2:29) Àwárí àwọn awalẹ̀pìtàn fohùn ṣọ̀kan pé òun àti ìlà ọba rẹ̀, “Ilé Dáfídì,” jẹ́ òtítọ́, kì í ṣe ìtàn àròsọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn òǹkàwé Watch Tower Society mọ òkúta fẹ̀ǹfẹ̀ Mesha. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1990, ojú ìwé 30 àti 31.) Ó wà níbi ìtẹ́fádà ohun ìṣẹ̀m̀báyé sí ní Ilé Àkójọ Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé Louvre, Paris.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àfọ́kù Tel Dan,* tí a ṣàwárí ní ọdún 1993 ní ìlú Dánì, ní ìhà àríwá Gálílì
* A gbé àwòrán karí fọ́tò kan tí ó fara hàn nínú ìwé agbéròyìnjáde Israel Exploration Journal.