ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 10/1 ojú ìwé 8-10
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Káni Lọ́wọ́ Kò Jù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Bíbélì Káni Lọ́wọ́ Kò Jù?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ó Dára Kí Òmìnira Pàpọ̀jù?
  • ‘Ẹrù Mi Fúyẹ́’
  • Kí Ni Èrò Rẹ?
  • Ẹbun Agbayanu ti Ominira Ifẹ-Inu
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ẹ Maṣe Tàsé Ète Ominira Tí Ọlọrun Fi Funni
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bá A Ṣe Lè Ní Òmìnira Tòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Jẹ́ Kí Jèhófà Ṣamọ̀nà Rẹ Síbi Tí Ojúlówó Òmìnira Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 10/1 ojú ìwé 8-10

Ǹjẹ́ Bíbélì Káni Lọ́wọ́ Kò Jù?

Ọ̀DỌ́KÙNRIN kan nílẹ̀ Finland sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, wọn kò fi ìlànà Bíbélì kankan kọ́ mi. Wọn ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run fún mi pàápàá.” Irú ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà tọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Ẹgbàágbèje èèyàn, àgàgà àwọn ọ̀dọ́, ló ka Bíbélì sí ohun tí kò bóde mu rárá, wọ́n tún ka ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sí èyí tó ń káni lọ́wọ́ kò jù. Ohun táwọn kan ń rò ni pé, ńṣe làwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì ń fìyà jẹ ara wọn àti pé òfin má-ṣu-má-tọ̀ ló ń darí ìgbésí ayé wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n rò pé ohun tó dára jù ni pé kéèyàn má tiẹ̀ ka Bíbélì rárá, kó sì máa wá ìtọ́sọ́nà lọ síbòmíràn.

Ìdí táwọn èèyàn kan fi nírú èrò bẹ́ẹ̀ nípa Bíbélì ni pé ó ti pẹ́ gan-an táwọn ìsìn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ti ń kó ìnira bá àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ní àkókò táwọn òpìtàn kan pè ní Ìgbà Ojú Dúdú, àwọn Kátólíìkì nílẹ̀ Yúróòpù jẹ gàba lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn. Nígbà yẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń dá ẹni tó bá gbójú gbóyà ta ko ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lóró tàbí kí wọ́n pa á. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí kì í ṣe Kátólíìkì, tí wọ́n dé lẹ́yìn náà, kò tún jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira bó ṣe yẹ. Lónìí, táwọn èèyàn kan bá gbọ́ orúkọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan, kì í ṣe àwọn ẹlẹ́sìn yẹn ló ń wá sí wọn lọ́kàn bí kò ṣe ìyà burúkú táwọn ẹ̀sìn náà fi jẹ àwọn tí kò fara mọ́ wọn. Nítorí pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń ni àwọn èèyàn lára, ọ̀pọ̀ wá lérò pé ìnira làwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì jẹ́.

Ó kéré tán láwọn orílẹ̀-èdè kan, láti nǹkan bí ọ̀rúndún méjì sẹ́yìn báyìí, kò ṣeé ṣe fáwọn ṣọ́ọ̀ṣì láti jẹ gàba lórí ìgbésí ayé àwọn èèyàn mọ́. Lẹ́yìn táwọn èèyàn ti pa àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tì, èrò tó wá gbòde ni pé, àwọn èèyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu fúnra wọn pé ohun kan tọ́ tàbí kò tọ́. Kí ló jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni Ahti Laitinen, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú òfin nípa ìwà ọ̀daràn àti nípa àjọṣe ẹ̀dá sọ pé: “Ọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ ti dín kù gan-an, àwọn èèyàn kò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ mọ́.” Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì náà ń ní irú èrò yìí. Bíṣọ́ọ̀bù kan tó lókìkí gan-an tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Luther tiẹ̀ sọ pé: “Mi ò gbà pé èèyàn lè rí ìtọ́sọ́nà nípa ìwà rere nínú Bíbélì tàbí látọ̀dọ̀ àwọn olórí ìsìn.”

Ṣé Ó Dára Kí Òmìnira Pàpọ̀jù?

Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, àgàgà àwọn ọ̀dọ́, ó jọ pé ohun tó dára ni kéèyàn lómìnira láti ṣe ohunkóhun tó bá ṣáà ti wù ú. Ọ̀pọ̀ èèyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí kí wọ́n máa ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ fáwọn. Àmọ́, ṣé ó wá yẹ kí kálukú ṣáà máa ṣe ohun tó bá ti wù ú? Ká lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká gbé àpèjúwe kan yẹ̀ wò. Fojú inú wo ìlú ńlá kan tí kò ní òfin ìrìnnà. Wọn kì í béèrè ìwé ìwakọ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ṣe ìdánwò fáwọn tó fẹ́ máa wakọ̀. Ọ̀nà tó wu kálukú ló ń gbà wakọ̀, àní wọ́n tiẹ̀ tún máa ń wakọ̀ nígbà tí wọ́n bá mutí yó pàápàá. Kò sẹ́ni tó ń tẹ̀ lé àwọn òfin ìrìnnà, irú bíi kíkíyèsí iná tó ń dá àwọn ọkọ̀ dúró, bó ṣe yẹ kéèyàn sáré mọ, ibi téèyàn ti gbọ́dọ̀ dúró jẹ́ẹ́, ibi táwọn ẹlẹ́sẹ̀ ti ń sọdá títì, tàbí gbígba ọ̀nà má-kò-mí, ìyẹn ọ̀nà tọ́kọ̀ á gbà lọ tí kò sì gbọ́dọ̀ gbà padà. Ǹjẹ́ irú “òmìnira” bẹ́ẹ̀ dára? Rárá o! Ìdàrúdàpọ̀ àti jàǹbá ńlá ló máa yọrí sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ìrìnnà kì í jẹ́ káwọn èèyàn ṣe bí wọ́n ti fẹ́, síbẹ̀ ohun tá a mọ̀ tó sì dá wa lójú ni pé àwọn òfin yìí máa ń dáàbò bo àwọn awakọ̀ àtàwọn tó ń fẹsẹ̀ rìn.

Lọ́nà kan náà, Jèhófà ń fún wa nítọ̀ọ́ni nípa bó ṣe yẹ ká gbé ìgbésí ayé wa. Èyí sì ń ṣe wá láǹfààní. Ká ní kò sí irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ ni, a ó kàn máa ṣe àwọn nǹkan láìmọ ibi tó máa já sí ni, ìyẹn yóò sì ṣàkóbá fún àwa àtàwọn ẹlòmíràn. Ewu tó wà nínú kéèyàn wà níbi tí kò ti sí ìtọ́sọ́nà nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa hùwà kò yàtọ̀ sí ti ìgbà téèyàn ń gbé nínú ìlú ńlá kan tí kò ní òfin ìrìnnà. Ká sòótọ́, a nílò àwọn ìlànà àtàwọn òfin. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé a nílò wọn lóòótọ́.

‘Ẹrù Mi Fúyẹ́’

Àwọn òfin ìrìnnà lè ní àwọn ìlànà tó pọ̀ rẹpẹtẹ tó sì ṣòro láti lóye. Ní àwọn ibì kan, òfin pọ̀ rẹpẹtẹ lórí pé èèyàn fẹ́ gbé ọkọ̀ síbì kan lásán. Àmọ́ ti Bíbélì kò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì kò kó òfin jọ rẹpẹtẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fún wa láwọn ìlànà pàtàkì tó yẹ ká tẹ̀lé, àwọn ìlànà náà kò sì nira. Nígbà tí Jésù Kristi wà láyé, ó rọ àwọn èèyàn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:28, 30) Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Níbi tí ẹ̀mí Jèhófà bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira wà.”—2 Kọ́ríńtì 3:17.

Àmọ́ ṣá o, òmìnira yẹn ní ààlà o. Jésù jẹ́ ká mọ̀ ní kedere pé àwọn òfin kéékèèké kan wà lára ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.” (Jòhánù 15:12) Wo bí ìgbésí ayé ì bá ṣe rí bí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀lé àṣẹ yẹn! Nítorí náà, òmìnira tí àwọn Kristẹni ní kì í ṣe èyí tí kò ní ààlà. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni òmìnira, síbẹ̀ kí ẹ di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú fún ìwà búburú, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run.”—1 Pétérù 2:16.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbé òfin rẹpẹtẹ kalẹ̀ fáwọn Kristẹni láti máa tẹ̀lé, síbẹ̀ wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n bá ṣáà ti rò lọ́kàn wọn pé ó dára tàbí kò dára. Àwa èèyàn nílò ìtọ́sọ́nà tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo. Bíbélì sọ ní kedere pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Tá a bá ń ṣègbọràn tá a sì gbà kí Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà, èyí á ṣe wá láǹfààní tó pọ̀.—Sáàmù 19:11.

Ọ̀kan lára àǹfààní náà ni ayọ̀. Ọ̀dọ́kùnrin tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ti jẹ́ olè àti òpùrọ́ rí. Ó tún jẹ́ oníṣekúṣe. Nígbà tó kọ́ nípa àwọn ìlànà rere tó wà nínú Bíbélì, ó fi wọ́n sílò, ó sì yí ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ padà. Ó sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún mi láti mú gbogbo ìlànà Bíbélì lò lẹ́ẹ̀kan náà, mo mọ bí wọ́n ti ṣeyebíye tó. Ìgbésí ayé tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀ kò mú kí n ní irú ayọ̀ tí mò ń ní nísinsìnyí. Fífi ìlànà Bíbélì sílò máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé èèyàn rọrùn gan-an. Ó ń jẹ́ kí ìgbésí ayé ẹni nítumọ̀, èyí á sì jẹ́ kéèyàn mọ ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́.”

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni ayé wọn ti nítumọ̀. Lára àwọn àǹfààní tí wọ́n ń rí ni pé, ìtọ́sọ́nà látinú Bíbélì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn, kì í jẹ́ kí wọ́n fi iṣẹ́ wọn ṣeré, ó ti jẹ́ kí wọ́n jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú, èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé tó túbọ̀ láyọ̀. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Markusa tí kò fi ìlànà Bíbélì sílò tẹ́lẹ̀rí àmọ́ tó wá ń fi sílò nígbà tó yá, sọ nípa ìgbésí ayé rẹ̀ pé: “Fífi tí mò ń fi ìlànà Bíbélì darí ìgbésí ayé mi ti jẹ́ kí n níyì lọ́wọ́ ara mi.”b

Kí Ni Èrò Rẹ?

Nítorí náà, ǹjẹ́ Bíbélì káni lọ́wọ́ kò? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí kó bàa lè dára fún gbogbo wa ni. Àmọ́ ǹjẹ́ Bíbélì káni lọ́wọ́ kò jù? Rárá o. Òmìnira tí kò ní ààlà máa ń kóni síyọnu. Ìlànà Bíbélì kò ni ẹnikẹ́ni lára, ó ń jẹ́ ká túbọ̀ ní àlàáfíà, ó sì ń jẹ́ ká láyọ̀. Markus sọ pé: “Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́ ni mò ń rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí ayé ẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ìgbésí ayé mi fi yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, mi ò fìgbà kan rò ó rí pé mo pàdánù ohun pàtàkì kankan ní ìgbésí ayé mi.”

Nígbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í jàǹfààní látinú fífi ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé rẹ, wàá túbọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Èyí yóò wá mú kó o jàǹfààní tó pọ̀ sí i, tó túmọ̀ sí pé wàá nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ni Bíbélì, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. “Nítorí èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 John 5:3.

Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa àti Bàbá wa ọ̀run. Ó mọ ohun tó dára jù lọ fún wa. Kàkà kó ká wa lọ́wọ́ kò, ńṣe ló ń darí wa tìfẹ́tìfẹ́ fún ire wa. Jèhófà rọ̀ wá nínú ọ̀rọ̀ kan tó sọ lọ́nà ewì pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:18.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ náà padà.

b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bíbélì ṣe ní ká máa gbé ìgbésí ayé wa, wo orí 12 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Jésù sọ pé ìtura ni ohun tí Ọlọ́run sọ pé ká ṣe yóò jẹ́ fún wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run máa ń mú kéèyàn láyọ̀ kó sì níyì lọ́wọ́ ara rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́