ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 11/1 ojú ìwé 4-7
  • Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lórí Ọ̀rọ̀ Ọmọ Títọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lórí Ọ̀rọ̀ Ọmọ Títọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Wá Àyè Láti Wà Pẹ̀lú Wọn
  • Kọ́ Wọn Ní Ìwà Ọmọlúwàbí
  • Máa Fòye Bá Wọn Lò
  • Jẹ́ Kí Ìmọ̀ràn Tó Ṣé E Gbára Lé Ṣe Ọ́ Láǹfààní
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 11/1 ojú ìwé 4-7

Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lórí Ọ̀rọ̀ Ọmọ Títọ́

OHUN tí Ruth sọ nípa ìgbà tó lóyún àkọ́kọ́ rèé, ó ní: “Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni mí nígbà yẹn, kò sí mọ̀lẹ́bí mi kankan nítòsí, mi ò sì múra sílẹ̀ rárá.” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun nìkan làwọn òbí rẹ̀ bí, ọ̀rọ̀ pé òun lè di ìyá lọ́jọ́ kan kì í fi bẹ́ẹ̀ wá sọ́kàn rẹ̀. Ibo ló wá lè yíjú sí láti gba ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé?

Àmọ́, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jan tó lọ́mọ méjì táwọn ọmọ náà sì ti dàgbà báyìí rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sóun, ó ní: “Ọkàn mi kọ́kọ́ balẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi rí i pé mi ò mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe gan-an.” Ì báà jẹ́ gbàrà táwọn òbí bímọ ni wọ́n rí i pé àwọn ò mọ̀nà tó dára jù láti tọ́mọ, tàbí kó jẹ́ pé ìgbà tó yá ni wọ́n tó wá rí i bẹ́ẹ̀, ibo ni wọ́n ti lè rí ìtọ́sọ́nà láti tọ́ àwọn ọmọ wọn?

Láyé òde òní, inú Íńtánẹ́ẹ̀tì lọ̀pọ̀ òbí máa ń wò. Àmọ́, ìwọ alára lè máa wò ó pé bóyá làwọn ìmọ̀ràn tó wà níbẹ̀ á ṣeé gbára lé. Ó sì yẹ káwọn òbí ṣọ́ra lóòótọ́. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó ń fún ọ nímọ̀ràn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ǹjẹ́ àwọn gan-an ti tọ́mọ tiwọn yanjú? Ó dájú pé wàá fẹ́ láti kíyè sára gan-an nípa àwọn ọ̀ràn tó lè ṣàkóbá fún ìdílé rẹ. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú ti fi hàn, nígbà míì, ìmọ̀ràn tó wá látọ̀dọ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n pàápàá máa ń jáni kulẹ̀. Ibo lo wá lè yíjú sí láti gbàmọ̀ràn?

Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀, lẹni tó gbọ́n jù lọ láti fúnni nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́. (Éfésù 3:15) Òun nìkan ni ọ̀jọ̀gbọ́n tó ju gbogbo ọ̀jọ̀gbọ́n lọ. Nínú Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó fún àwọn òbí ní ìtọ́ni tó ṣeé gbára lé, tó sì wúlò gan-an. (Sáàmù 32:8; Aísáyà 48:17, 18) Àmọ́ ọwọ́ wa ló kù sí láti fi ìtọ́ni náà sílò.

Wọ́n ní káwọn tọkọtaya bíi mélòó kan sọ ohun tí wọ́n rí kọ́ nígbà tí wọ́n ń tọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́, táwọn ọmọ náà fi jẹ́ ẹni tó wúlò, tó mọ ohun tí wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì tún bẹ̀rù Ọlọ́run nígbà tí wọ́n dàgbà. Wọ́n sọ pé olórí ohun tó jẹ́ káwọn ṣàṣeyọrí ni pé àwọn fi ìlànà Bíbélì sílò. Wọ́n rí i pé bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe jẹ́ èyí tó ṣeé gbára lé nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ọ́ náà ló ṣì ṣe rí títí dòní.

Máa Wá Àyè Láti Wà Pẹ̀lú Wọn

Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Catherine tó lọ́mọ méjì pé ìmọ̀ràn wo ló ràn án lọ́wọ́ jù lọ, kíá ló dáhùn pé ìmọ̀ràn tó wà nínú Diutarónómì 6:7 ni. Ẹsẹ yẹn kà pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ [gbin àwọn ìlànà Bíbélì] sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” Catherine rí i pé kóun tó lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, òun ní láti máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ òun.

O lè máa rò pé, ‘Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ dùn ún sọ, àmọ́ kò rọrùn láti ṣe.’ Báwo làwọn òbí tọ́wọ́ wọn dí ṣe lè ráyè jókòó ti àwọn ọmọ wọn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bàbá àti ìyá ní láti ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè rówó gbọ́ bùkátà ìdílé wọn? Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Torlief, tọ́mọ rẹ̀ ọkùnrin náà ti dẹni tó ní ìdílé tirẹ̀ báyìí sọ pé, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Diutarónómì yẹn. Máa mú àwọn ọmọ rẹ dání lọ síbikíbi tó o bá ń lọ, àǹfààní á sì yọjú láti jọ sọ̀rọ̀. Torlief sọ pé: “Èmi àtọmọ mi jọ máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan nínú ilé. Gbogbo ìdílé wa jọ máa ń rìnrìn àjò ni. Ńṣe la sì jọ ń jẹun pa pọ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ìgbà gbogbo lọkàn ọmọ wa máa ń balẹ̀ láti sọ ohun tó wà nínú rẹ̀ fún wa.”

Àmọ́ tí àárín yín ò bá gún régé ńkọ́, tó sì di pé agbára káká lẹ fi ń bára yín sọ̀rọ̀? Èyí máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì báwọn ọmọ ti ń dàgbà. Nírú àkókò yìí náà, títúbọ̀ wá àyè láti wà pẹ̀lú wọn á ṣèrànwọ́. Ken tó jẹ́ ọkọ Catherine rántí pé nígbà tí ọmọ wọn obìnrin di ọ̀dọ́, ọmọ náà sọ pé, òun tòun jẹ́ bàbá kì í tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tóun ọmọ bá ń sọ̀rọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń fi irú ẹ̀sùn yìí kan àwọn òbí wọn. Kí ni Ken ṣe? Ó sọ pé: “Mo pinnu lọ́kàn mi pé màá túbọ̀ máa wá àyè láti wà pẹ̀lú rẹ̀, á sì jẹ́ èmi àtòun nìkan, kí n lè bá a jíròrò àwọn ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, kí n sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, àtàwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀. Èyí ṣèrànwọ́ gan-an.” (Òwe 20:5) Àmọ́ Ken gbà pé ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé, nínú ìdílé àwọn, àwọn ti jọ máa ń sọ̀rọ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé: “Àárín èmi àti ọmọ mi gún gan-an, èyí ló jẹ́ ki ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láti lè máa bá mi sọ̀rọ̀.”

Ohun tí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn ni pé, àwọn ọ̀dọ́ ló sábà máa ń sọ pé àwọn òbí kì í lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Agbára káká la lè fi gbọ́ bẹ́ẹ̀ lẹ́nu àwọn òbí. Nípa báyìí, o ò ṣe tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì? Máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, tẹ́ ẹ bá ń najú, tẹ́ ẹ bá ń ṣiṣẹ́, tẹ́ ẹ bá wà nínú ilé, tẹ́ ẹ bá ń rìnrìn àjò, ní òwúrọ̀ tẹ́ ẹ bá jí, àti lálẹ́ kẹ́ ẹ tó lọ sùn. Bó bá ṣeé ṣe, máa mú wọn dání lọ síbikíbi tó o bá ń lọ. Gẹ́gẹ́ bí Diutarónómì 6:7 ti sọ, kò sóhun tó o lè fi rọ́pò wíwà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.

Kọ́ Wọn Ní Ìwà Ọmọlúwàbí

Bákan náà, Mario tó lọ́mọ méjì sọ pé: “Rí i pé ò ń fìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ rẹ gan-an, kó o sì máa kàwé sí wọn létí.” Àmọ́ kì í ṣe mímú ọpọlọ ọmọ jí pépé nìkan lohun tó ṣe pàtàkì jù. O ní láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó dára àtohun tí kò dára. Mario fi kún un pé: “Máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ìdí rèé tí Bíbélì fi ṣí àwọn òbí létí pé: “Ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu, ṣugbọn ẹ ma tọ́ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.” (Éfésù 6:4 Bibeli Mimọ) Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé lónìí, àwọn òbí kò fi bẹ́ẹ̀ ka kíkọ́ ọmọ ní ìwà rere sí ohun tó ṣe pàtàkì. Àwọn kan gbà pé táwọn ọmọ bá dàgbà, wọ́n á máa fúnra wọn pinnu irú ìlànà táwọn máa tẹ̀ lé. Ǹjẹ́ o rò pé irú èrò yìí bọ́gbọ́n mu? Bí ara àwọn ọmọdé ṣe nílò oúnjẹ aṣaralóore kí wọ́n lè lágbára kí ara wọn sì lè jí pépé bí wọ́n ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n nílò ìtọ́ni láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ronú àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa hùwà. Báwọn ọmọ rẹ̀ kò bá kọ́ ìwà tó dára látọ̀dọ̀ rẹ nínú ilé, kò sí àní-àní pé irú èrò táwọn ọmọléèwé wọn àtàwọn olùkọ́ wọn ní làwọn náà á máa ní, tàbí kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n ń gbọ́ lórí rédíò tàbí tí wọ́n ń wò nínú tẹlifíṣọ̀n ṣèwàhù.

Bíbélì lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe lè mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó dára àtohun tí kò dára. (2 Tímótì 3:16, 17) Arákùnrin Jeff tó jẹ́ alàgbà tó lóye nínú ìjọ Kristẹni, tó sì ti tọ́ ọmọ méjì dàgbà, dábàá pé káwọn òbí máa lo Bíbélì láti kọ́ àwọn ọmọ ní ìwà ọmọlúwàbí. Ó sọ pé: “Lílo Bíbélì máa ń jẹ́ káwọn ọmọ mọ ohun tó jẹ́ èrò Ẹlẹ́dàá lórí ọ̀ràn, kì í kàn án ṣe èrò màmá àti bàbá wọn nìkan. Ohun tá a ti kíyè sí ni pé, ọ̀nà tí Bíbélì ń gbà nípa lórí èrò àti ọkàn ọmọ kò lẹ́gbẹ́ rárá. Tá a bá fẹ́ bójú tó ìṣòro kan tó dá lórí ìwà tàbí èrò tí kò dára, a máa ń wá àyè láti wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ìṣòro náà mu. Lẹ́yìn náà, tó bá ku àwa àtọmọ náà nìkan, àá jẹ́ kó ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe lomi á bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lójú rẹ̀. Ìyàlẹ́nu gbáà lèyí máa ń jẹ́ fún wa. Bíbélì ṣèrànwọ́ gan-an ju ohunkóhun tá a lè ti ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti sọ tàbí láti ṣe lọ.”

Ìwé Hébérù 4:12 ṣàlàyé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” Èyí fi hàn pé ohun tó wà nínú Bíbélì kì í kàn án ṣe èrò àwọn tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì tàbí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ èrò Ọlọ́run nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà. Èyí ló mú kí ohun tó wà nínú Bíbélì yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ìmọ̀ràn yòókù. Bó o bá ń lo Bíbélì láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ, ńṣe lò ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní èrò Ọlọ́run lórí àwọn ọ̀ràn tó bá yọjú. Ẹ̀kọ́ tó ò ń fún wọn á túbọ̀ lágbára, ohun tó ò ń kọ́ wọn á sì túbọ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

Catherine tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ gbà pé òótọ́ lèyí. Ó sọ pé: “Bí ìṣòro tó wà nílẹ̀ bá ṣe lágbára tó la ṣe máa ń wá ìtọ́sọ́nà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó, èyí sì gbéṣẹ́ gan-an!” Ṣé ìwọ náà á túbọ̀ máa lo Bíbélì láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti mọ̀yàtọ̀ láàárín ohun tó dára àtohun tó burú?

Máa Fòye Bá Wọn Lò

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìlànà mìíràn tó ṣe pàtàkì tó lè ranni lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ọmọ títọ́. Ó rọ àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Dájúdájú, èyí kan jíjẹ́ káwọn ọmọ wa rí i pé à ń fòye bá àwọn lò. Sì rántí o, ńṣe ni fífòyebánilò ń fi hàn pé ẹnì kan ní “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.”—Jákọ́bù 3:17.

Àmọ́, ipa wo ni ìfòyebánilò ń kó nínú títọ́ àwọn ọmọ wa? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́, kò yẹ ká máa ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Mario tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè, ó sì sọ ohun tó rántí pé àwọn ṣe, ó ní: “A máa ń gba àwọn ọmọ wa níyànjú pé kí wọ́n ṣèrìbọmi, pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, kí wọ́n sì tún máa lépa àwọn iṣẹ́ ìsìn mìíràn. Àmọ́ a jẹ́ kó yé wọn pé àwọn ló ní ìpinnu náà láti ṣe tí àkókò bá tó.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Àwọn ọmọ wọn méjèèjì ló wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún báyìí.

Bíbélì kìlọ̀ fáwọn bàbá nínú Kólósè 3:21 pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.” Catherine mọyì ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí gan-an. Tí òbí ò bá ní sùúrù, ó rọrùn láti bínú kí wọ́n sì fẹ́ mú àwọn ọmọ wọn ní tipátipá láti ṣe ohun táwọn fẹ́. Àmọ́ Catherine sọ pé, “má ṣe retí pé gbogbo ohun tó o lè ṣe ló yẹ káwọn ọmọ rẹ lè ṣe.” Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Catherine pẹ̀lú, ó sì fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Jẹ́ kí wọ́n máa láyọ̀ pé wọ́n ń sin Jèhófà.”

Jeff tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè sọ gbólóhùn kan tó gbéṣẹ́, ó ní: “Báwọn ọmọ wa ti ń dàgbà, ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ kan sọ fún wa pé òun rí i pé ọ̀pọ̀ ìgbà lòun ti sọ fáwọn ọmọ òun pé kò sáyè nígbà tí wọ́n bá sọ pé àwọn fẹ́ ṣe nǹkan kan. Ìyẹn máa ń múnú bí wọn, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n rò pé ńṣe lòun ń fara ni wọ́n. Kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀, ó dábàá pé ká máa wá bá a ṣe lè máa fún wọn láyè.”

Jeff wá sọ pé: “A rí i pé ìmọ̀ràn tó dára ni ìmọ̀ràn yìí. La bá bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ọ̀nà táwọn ọmọ wa lè gbà máa bá àwọn ọmọ mìíràn ṣe nǹkan pọ̀, tóhun tí wọ́n fẹ́ ṣe bá ti jẹ́ ohun tó tọ́ lójú wa. Nítorí náà, a máa ń pè wọ́n nígbà mìíràn, àá sì sọ fún wọn pé: ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé lágbájá báyìíbáyìí ń ṣe nǹkan? Ẹ̀yin náà ò ṣe lọ?’ Tàbí, táwọn ọmọ wa bá sọ pé ká mú àwọn lọ síbì kan, àá tiraka láti lọ kódà bó tilẹ̀ ti rẹ̀ wá. Idi tá a fi ń ṣe èyí ni pé a ò fẹ́ sọ fún wọn pé kò sáyè.” Ohun tó ń jẹ́ ìfòyebánilò gan-an nìyí, ìyẹn ni pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í ṣojúsàájú, tó ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò, tó sì ń fara mọ́ èrò wọn láìjẹ́ pé èèyàn tẹ ìlànà Bíbélì lójú.

Jẹ́ Kí Ìmọ̀ràn Tó Ṣé E Gbára Lé Ṣe Ọ́ Láǹfààní

Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn níbí ló ti ní ọmọ ọmọ báyìí. Inú wọn sì ń dùn bí wọ́n ti ń rí i táwọn ìlànà Bíbélì wọ̀nyí ń ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ tiwọn náà. O ò ṣe jẹ́ kí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe ìwọ náà láǹfààní?

Nígbà tí Ruth tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí bímọ, ìgbà mìíràn wà tòun àtọkọ rẹ̀ máa ń rò pé kò síbi táwọn ti lè rí ìmọ̀ràn tó lè tọ́ àwọn sọ́nà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n ní ìmọ̀ràn tó ju gbogbo ìmọ̀ràn lọ, ìyẹn ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ ìwé tó dá lórí Bíbélì tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́. Lára wọn ni: Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, Iwe Itan Bibeli Mi, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, àti Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Torlief, ìyẹn ọkọ Ruth, sọ pé: “Lọ́jọ́ òní, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìmọ̀ràn tó dá lórí Bíbélì ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn òbí. Ká ní wọ́n lè mú wọn lò ni, wọ́n á rí ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó ìṣòro èyíkéyìí tó lè yọjú báwọn ọmọ wọn ti ń dàgbà.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ohun Táwọn Ọ̀JỌ̀GBỌ́N Sọ àti Ohun Tí BÍBÉLÌ Sọ

Lórí Fífi Ìfẹ́ Hàn sí Ọmọ:

Nínú ìwé kan tí Ọ̀mọ̀wé John Broadus Watson pè ní The Psychological Care of Infant and Child, èyí tó ṣe jáde lọ́dún 1928, tó sọ̀rọ̀ lórí báwọn ọmọdé ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń hùwà, ó rọ àwọn òbí pé: “Ẹ má ṣe gbá àwọn ọmọ yín mọ́ra, ẹ má sì ṣe máa fẹnu kò wọ́n lẹ́nu. Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n jókòó lé e yín nítan.” Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n méjì kan, ìyẹn Vera Lane àti Dorothy Molyneaux sọ nínú ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Our Children (ti March 1999) pé: “Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọdé tí wọn kì í fọwọ́ kàn tàbí tí wọn kì í fìfẹ́ hàn sí kì í sábà ṣe dáadáa.”

Àmọ́ ti Ọlọ́run yàtọ̀ o, nítorí pé ìwé Aísáyà 66:12 tọ́ka sí bí Ọlọ́run ṣe fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ nípa lílo gbólóhùn tó fìfẹ́ hàn, èyí táwọn òbí máa ń lò fáwọn ọmọ wọn. Bákan náà, nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbìyànjú láti dá àwọn èèyàn lẹ́kun pé kí wọ́n má ṣe kó àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun má ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Lẹ́yìn náà, ó “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.”—Máàkù 10:14, 16.

Lórí Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Ní Ìwà Tó Dára:

Nínú àpilẹ̀kọ kan tó jáde lọ́dún 1969 nínú ìwé ìròyìn New York Times Magazine, Ọ̀jọ̀gbọ́n Bruno Bettelheim sọ pé ọmọdé “lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó bá wá sí i lọ́kàn, láìsí pé àwọn òbí rẹ̀ ń darí ọ̀nà tó ń gbà ronú, nípa sísọ pé báyìí ni kó ṣe tàbí báyìí ni kó má ṣe, àmọ́ kó jẹ́ pé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí i nígbèésí ayé rẹ̀ ló máa kọ́ ọ bí yóò ṣe máa ronú.” Ṣùgbọ́n ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1997, Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Coles ṣe ìwé kan tó ń jẹ́ Moral Intelligence of Children tó dá lórí irú ìwà tó yẹ kí ọmọdé máa hù. Ó sọ nínú ìwé náà pé: “Àwọn ọmọdé ní láti mọ ìdí táwọn fi wà láàyè, wọ́n sì nílò ìtọ́sọ́nà nígbèésí ayé wọn, wọ́n nílò àwọn ìlànà tó dára” táwọn òbí wọn àtàwọn àgbàlagbà mìíràn fọwọ́ sí.

Ìwé Òwe 22:6 rọ àwọn òbí pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “tọ́” tún túmọ̀ sí “bẹ̀rẹ̀,” ohun tó sì ń tọ́ka sí níbí yìí ni bíbẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọdé jòjòló láwọn ohun tó yẹ kó kọ́kọ́ mọ̀. Nípa báyìí, Bíbélì fún àwọn òbí níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìlànà tó dára látìgbà tí wọ́n bá ti wà ní kékeré jòjòló. (2 Tímótì 3:14, 15) Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa rántí ohun tí wọ́n kọ́ ní kékeré yìí títí láé.

Lórí Bíbá Ọmọ Wí:

Ọ̀jọ̀gbọ́n James Dobson sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Strong-Willed Child, èyí tó ṣe jáde lọ́dún 1978 pé: “Nína ọmọ lẹ́gba jẹ́ ọ̀nà kan táwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ fi ń kọ́ ọmọ kí ọmọ náà lè kiwọ́ ìwàkiwà bọlẹ̀.” Àmọ́, nínú àpilẹ̀kọ kan tí wọ́n mú jáde látinú ẹ̀dà keje ìwé kan táwọn èèyàn mọ̀ gan-an tó ń jẹ́ Baby and Child Care, tí wọ́n ṣe jáde lọ́dún 1998, Ọ̀mọ̀wé Benjamin Spock sọ nínú àpilẹ̀kọ ọ̀hún pé: “Ńṣe ni nína ọmọ ńjẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹni tó dàgbà jù wọ́n tó sì lágbára jù wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ohun tó wù ú, yálà onítọ̀hún jẹ̀bi tàbí ó jàre.”

Lórí ọ̀ràn bíbá ọmọ wí, Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pá àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ni ohun tí ń fúnni ní ọgbọ́n.” (Òwe 29:15) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ọmọ ló nílò nínà o. Òwe 17:10 sọ fún wa pé: “Ìbáwí mímúná ń ṣiṣẹ́ jinlẹ̀ nínú ẹni tí ó ní òye ju lílu arìndìn ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.”

[Àwòrán]

Lo Bíbélì kí ẹ̀kọ́ rẹ lè wọ ọmọ rẹ lọ́kàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn òbí tó gbọ́n máa ń ṣètò eré ìnàjú fáwọn ọmọ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́