ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 11/1 ojú ìwé 17-21
  • Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń Jùmọ̀ Kọ́lé fún Ìyìn Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń Jùmọ̀ Kọ́lé fún Ìyìn Rẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Wọ́n Ṣe Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn àti Tẹ́ńpìlì
  • “Ilé Ọlọ́run Tòótọ́”
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ti Òde Òní
  • Ìtìlẹ́yìn Wa Ṣe Pàtàkì
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀ Pé Ayọ̀ Wà Nínú Ṣíṣètọrẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Fífúnni Ní Nǹkan Látọkàn Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Gbogbo Wọn Ń Fi “Ọkàn Kan” Sin Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Rí Ayọ̀ Nínú “Àǹfààní Ìfúnni Onínúrere”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 11/1 ojú ìwé 17-21

Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń Jùmọ̀ Kọ́lé fún Ìyìn Rẹ̀

NÍGBÀ táwọn èèyàn tó wà ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Solomon Islands rí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́, obìnrin kan lára wọn sọ pé: “Ní ṣọ́ọ̀ṣì wa, ọ̀pọ̀ ìgbà la ti kóra jọ ká lè dáwó tá a máa fi kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. A máa ń ní káwọn ọmọ ìjọ wa dáwó, àmọ́ owó tá a máa ń rí ò tóó kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì tuntun. Báwo lẹ̀yin Ẹlẹ́rìí ṣe ń rí owó tiyín?” Ẹlẹ́rìí tó ń bá sọ̀rọ̀ wá fèsì pé: “Bí ìdílé kan ni gbogbo wa ṣe ń jùmọ̀ sin Jèhófà jákèjádò ayé. Àwọn ará nínú ìjọ wa, àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kárí ayé ló ń dá owó àtàwọn nǹkan míì tá a nílò láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Jèhófà ti kọ́ wa láti wà níṣọ̀kan nínú ohun gbogbo.”

Ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú gbogbo ìgbòkègbodò wọn, títí kan iṣẹ́ kíkọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba. Irú ìṣọ̀kan tó ń jẹ́ kí wọ́n lè gbé àwọn ohun kàǹkàkàǹkà ṣe yìí kì í ṣe tuntun rárá. Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ ti wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Bí Wọ́n Ṣe Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn àti Tẹ́ńpìlì

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà ń bá sọ̀rọ̀ ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn nígbà tó sọ fún Mósè pé: “Kí wọ́n . . . ṣe ibùjọsìn fún mi.” (Ẹ́kísódù 25:8) Nígbà tí Jèhófà tún ń sọ nípa ọ̀nà tí wọ́n máa gbà kọ́ àgọ́ ìjọsìn náà, ó ní: “Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí èmi yóò fi hàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àwòṣe àgọ́ ìjọsìn àti àwòṣe gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe é.” (Ẹ́kísódù 25:9) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jèhófà wá sọ bí ibùjọsìn náà ṣe máa rí ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ó tún sọ nípa bí àwọn ohun èlò tí wọ́n á fi igi ṣe àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n á fi ṣe ẹ̀ṣọ́ sínú rẹ̀ ṣe máa rí. (Ẹ́kísódù 25:10–27:19) “Àgọ́ ìjọsìn” tàbí àgọ́ yìí ló máa jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

A kò mọ báwọn tó ṣe iṣẹ́ náà ṣe pọ̀ tó, àmọ́ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Mósè pè láti mú ọrẹ wá. Mósè sọ fún wọn pé: “Láti àárín yín, ẹ gba ọrẹ fún Jèhófà. Kí gbogbo ọlọ́kàn ìmúratán mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 35:4-9) Kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ṣe? Ẹ́kísódù 36:3 sọ pé: “Lẹ́yìn náà, wọ́n kó gbogbo ọrẹ náà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú wá láti fi ṣe iṣẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ kúrò níwájú Mósè, àti pé, ní ti àwọn wọ̀nyí, wọ́n ṣì ń mú ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe wá fún un síbẹ̀ ní òròòwúrọ̀.”

Láìpẹ́ àwọn ohun tí wọ́n dá jọ wá pọ̀ rẹpẹtẹ, síbẹ̀ àwọn èèyàn náà ṣì ń mú ọrẹ wá sí i. Níkẹyìn, àwọn oníṣẹ́ ọnà tó ń ṣe iṣẹ́ náà sọ fún Mósè pé: “Àwọn ènìyàn ń mú púpọ̀púpọ̀ wá ju ohun tí iṣẹ́ ìsìn náà béèrè láti ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà pa láṣẹ pé kí a ṣe.” Nítorí náà, Mósè sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin ọkùnrin àti ẹ̀yin obìnrin, ẹ má ṣe mú ohun èlò wá mọ́ fún ọrẹ mímọ́.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ohun èlò náà sì tó fún gbogbo iṣẹ́ tí a ó ṣe, ó tó, ó sì ṣẹ́ kù.”—Ẹ́kísódù 36:4-7.

Nítorí ẹ̀mí ọ̀làwọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní yìí, wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn náà tán láàárín ọdún kan péré. (Ẹ́kísódù 19:1; 40:1, 2) Àwọn èèyàn Ọlọ́run bọlá fún Jèhófà nípa ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. (Òwe 3:9) Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ní láti dáwọ́ lé iṣẹ́ ìkọ́lé mìíràn tó tóbi jùyẹn lọ. Lákòókò yẹn náà, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ lè kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé yìí, yálà wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́ tàbí wọn ò mọ̀ nípa rẹ̀.

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún márùn-ún lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ àgọ́ ìjọsìn tán, wọ́n tún dáwọ́ lé iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (1 Àwọn Ọba 6:1) Èyí jẹ́ ilé tó tóbi gan-an tí wọ́n fi òkúta àti igi gẹdú kọ́ tó sì máa wà títí lọ. (1 Àwọn Ọba 5:17, 18) Jèhófà fi àwòrán ọ̀nà tí wọ́n máa gbà kọ́ tẹ́ńpìlì náà han Dáfídì “nípasẹ̀ ìmísí.” (1 Kíróníkà 28:11-19) Àmọ́, Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ni Jèhófà yàn láti bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé náà. (1 Kíróníkà 22:6-10) Dáfídì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. Ó kó àwọn òkúta, opó igi ńláńlá, àtàwọn ohun èlò mìíràn jọ, ó sì tún fi ọ̀pọ̀ yanturu wúrà àti fàdákà tó jẹ́ tiẹ̀ fúnra rẹ̀ ṣètọrẹ. Ó tún gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tirẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n lẹ́mìí ọ̀làwọ́, ó sọ fún wọn pé: “Ta sì ni ń bẹ níbẹ̀ tí ó fẹ́ fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti fi ẹ̀bùn kún ọwọ́ rẹ̀ lónìí fún Jèhófà?” Kí ni àwọn èèyàn náà wá ṣe?—1 Kíróníkà 29:1-5.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwọ̀n tọ́ọ̀nù wúrà àti fàdákà ti wà nílẹ̀ fún Sólómọ́nì kó tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Àwọn bàbà àti irin tó wà nílẹ̀ pọ̀ débi pé wọn ò ṣeé wọ̀n mọ́. (1 Kíróníkà 22:14-16) Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Jèhófà àti ti gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n kọ́ ilé náà tán láàárín ọdún méje ààbọ̀ péré.—1 Àwọn Ọba 6:1, 37, 38.

“Ilé Ọlọ́run Tòótọ́”

“Ilé Ọlọ́run tòótọ́” ni wọ́n pe àgọ́ ìjọsìn yẹn àti tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 18:31; 2 Kíróníkà 24:7) Jèhófà ò fìgbà kan nílò ilé láti gbé. (Aísáyà 66:1) Fún àǹfààní àwọn èèyàn ló ṣe ní kí wọ́n kọ́ àwọn ilé wọ̀nyẹn. Kódà, nígbà tí wọ́n ń ṣe ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì náà, Sólómọ́nì béèrè pé: “Ọlọ́run yóò ha máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí? Wò ó! Àwọn ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́; nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí ilé yìí tí mo kọ́!”—1 Àwọn Ọba 8:27.

Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà fún gbogbo ènìyàn.” (Aísáyà 56:7) Gbogbo ẹbọ tí wọ́n ń rú àtàwọn àdúrà tí wọ́n ń gbà nínú tẹ́ńpìlì náà, títí kan àwọn ààtò ìsìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀, ló ń fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láǹfààní láti sún mọ́ Ọlọ́run tòótọ́, yálà wọ́n jẹ́ Júù tàbí wọn kì í ṣe Júù. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀rẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ń rí ààbò rẹ̀ nípa jíjọ́sìn nínú ilé rẹ̀. Àdúrà tí Sólómọ́nì gbà nígbà tí wọ́n ń ṣe ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì náà fi hàn pé òótọ́ gidi lọ̀rọ̀ yìí. O lè ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ń wúni lórí tí Sólómọ́nì sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run nínú ìwé 1 Àwọn Ọba 8:22-53 àti 2 Kíróníkà 6:12-42.

Ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọ́run nígbà yẹn lọ́hùn-ún ti pa rẹ́ tipẹ́, àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àkókò kan nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè yóò kóra jọ pọ̀ láti jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kan tó ṣeyebíye gan-an ju tìgbà yẹn lọ. (Aísáyà 2:2) Ẹbọ pípé kan ṣoṣo tí àyànfẹ́ Ọmọ Ọlọ́run fi ara rẹ̀ rú, èyí táwọn ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ nínú tẹ́ńpìlì ìgbàanì ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ni yóò wá jẹ́ ọ̀nà téèyàn lè gbà sún mọ́ Jèhófà. (Jòhánù 14:6; Hébérù 7:27; 9:12) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tó dára jù lọ yẹn báyìí, wọ́n sì ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe bákan náà.

Àwọn Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ti Òde Òní

Jákèjádò ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń sin Ọlọ́run tòótọ́. Wọ́n para pọ̀ jẹ́ “alágbára ńlá òrílẹ̀-èdè,” táwọn èèyàn ibẹ̀ ń pọ̀ sí i. (Aísáyà 60:22) Gbọ̀ngàn Ìjọba ni ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣe àwọn ìpàdé wọn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú àwọn gbọ̀ngàn bẹ́ẹ̀ là ń lò báyìí, àmọ́ kò tíì tó, a ṣì nílò ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọngàn Ìjọba sí i.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń “fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn” láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a nílò wọ̀nyí. (Sáàmù 110:3) Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè kan lè má mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́, àwọn àgbègbè kan sì wà táwọn Ẹlẹ́rìí ń pọ̀ sí i, àmọ́ táwọn ará ibẹ̀ kò lówó rárá. Lọ́dún 1999, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ètò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kalẹ̀ láti lè yanjú àwọn ìṣòro yìí. Nípasẹ̀ ètò yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ilé kíkọ́ ti rìnrìn àjò lọ sáwọn ibi tó jìnnà gan-an láti lọ dá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àtìgbà yẹn làwọn tí wọ́n dá lẹ́kọ̀ọ́ yìí ti ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé láwọn àgbègbè náà. Kí ni ìsapá àrà ọ̀tọ̀ yìí ti yọrí sí?

Nígbà tó fi máa di oṣù February ọdún 2006, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn àgbègbè táwọn èèyàn ò ti lówó wọ̀nyí ti ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá. Ka ohun táwọn kan lára àwọn tó ń lo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà sọ.

“Ní ìjọ kan, nǹkan bí ọgọ́jọ [160] èèyàn ló máa ń wá sípàdé tẹ́lẹ̀. Àmọ́, igba [200] èèyàn ló wá sípàdé àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tuntun tán. Ní báyìí, ìyẹn oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn tó ń wá sípàdé ti di igba ó lé ọgbọ̀n [230]. Ó hàn gbangba pé ìbùkún Jèhófà wà lórí àwọn ilé tó mọ níwọ̀nba tó sì wúlò gan-an wọ̀nyí.”—Alábòójútó àyíká kan ní Ecuador.

“Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń bi wá pé, ‘Ìgbà wo lẹ máa ní irú Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a máa ń rí nínú àwọn ìwé yín?’ A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a ti wá ní ibi tó dára gan-an báyìí láti jọ́sìn. Ilé ìtajà arákùnrin kan la ti máa ń ṣèpàdé tẹ́lẹ̀, àwa tá a sì ń wá síbẹ̀ kò ju ọgbọ̀n lọ. Àmọ́ àádọ́fà [110] èèyàn làwa tó wá sípàdé tá a kọ́kọ́ ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun yìí.”—Ìjọ kan ní orílẹ̀-èdè Uganda.

“Àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé sọ pé iṣẹ́ ìwàásù ti wá dùn ún ṣe gan-an ní ìpínlẹ̀ àwọn látìgbà tí wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn èèyàn máa ń fetí sílẹ̀ gan-an nígbà tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí níbikíbi tí wọ́n bá ti rí àwọn èèyàn. Àwọn arábìnrin wọ̀nyí ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàdínlógún báyìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló sì ń wá sípàdé.”—Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa ní Solomon Islands.

“Pásítọ̀ kan tó ń gbé nítòsí ibi tí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan sí sọ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba náà fi kún iyì gbogbo àgbègbè náà, gbogbo àwọn tó ń gbé ládùúgbò ibẹ̀ ló sì ń fi Gbọ̀ngàn Ìjọba náà yangàn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kọjá níbẹ̀ ló máa ń sọ nípa bí gbọ̀ngàn ọ̀hún ti lẹ́wà tó. Èyí ń fún àwọn ará láǹfààní láti jẹ́rìí. Ńṣe làwọn èèyàn tó fẹ́ mọ̀ nípa ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé sì ń pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò wá sípàdé mọ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé déédéé báyìí.”—Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa ní orílẹ̀-èdè Myanmar

“Arábìnrin kan pe ọkùnrin kan tó máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa pé kó wá wo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ń kọ́ nítòsí ilé rẹ̀. Ọkùnrin náà sọ lẹ́yìn náà pé: ‘Mo rò pé àwọn òṣìṣẹ́ náà ò ní jẹ́ kí n wọlé ni. Ó yà mí lẹ́nu pé ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí náà kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Tọkùnrin tobìnrin ló ń ṣiṣẹ́ láìfi àkókò ṣòfò rárá. Ìṣọ̀kan àti ayọ̀ wà láàárín wọn.’ Ọkùnrin náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Nígbà tó yá, ó sọ pé: ‘Èrò mi ti yí padà. Mi ò ní fi Ọlọ́run sílẹ̀ mọ́ nísinsìnyí tí mo ti rí i.’”—Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa ní orílẹ̀-èdè Colombia.

Ìtìlẹ́yìn Wa Ṣe Pàtàkì

Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ apá pàtàkì lára iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tá à ń ṣe. Ọ̀nà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé gbà ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà, nípa owó dídá tàbí láwọn ọ̀nà míì, ń wúni lórí gan-an. Àmọ́, a tún gbọ́dọ̀ rántí pé àwọn ọ̀nà mìíràn tá a gbà ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tún ṣe pàtàkì gan-an. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àjálù máa ń bá àwọn Kristẹni, wọ́n sì máa ń nílò ìrànlọ́wọ́. Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń tẹ̀ jáde tún ń kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Èyí tó pọ̀ jù lára wa ló ti rí ohun ribiribi táwọn ìwé ìròyìn tàbí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ṣe, ìyẹn àwọn ìwé tá a máa ń fún àwọn ọlọ́kàn tútù èèyàn pé kí wọ́n fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, ìtìlẹ́yìn tá à ń ṣe fáwọn míṣọ́nnárì àtàwọn mìíràn tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tún ṣe pàtàkì gan-an. Irú àwọn Kristẹni tó yọ̀ǹda ara wọn bẹ́ẹ̀ ń kó ipa pàtàkì nínú mímú iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.

Àwọn tó kó ọrẹ tí wọ́n lò láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà sílẹ̀ láyọ̀ gan-an ni. (1 Kíróníkà 29:9) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, fífi ọrẹ wa ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ ń fún wa láyọ̀ gan-an. (Ìṣe 20:35) A máa ń ní ayọ̀ tá à ń wí yìí nígbà tá a bá ń fi owó sínú àpótí fún lílò tá à ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba àti nígbà tá a bá dáwó láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé, tá a sì tipa bẹ́ẹ̀ ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ètò mìíràn tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Wíwà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́ jẹ́ ohun àgbàyanu. Ẹ jẹ́ kínú gbogbo wa máa dùn bá a ti ń ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́ yìí!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

ÀWỌN Ọ̀NÀ TÁWỌN KAN Ń GBÀ ṢÈTỌRẸ

ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ

Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí kí wọ́n ṣètò iye kan tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé]—Mátíù 24:14” sí lára.

Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi àwọn owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè wọn. O tún lè fi ọrẹ owó tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, kọ “Watch Tower” sórí rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wa láti rí owó náà gbà. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó máa fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ wà lára rẹ̀.

ỌRẸ TÍ A WÉWÈÉ

Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ tó máa ṣe iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run láǹfààní kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:

Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.

Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó tá a ní sí báńkì, owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì wa lẹ́nu iṣẹ́ síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí owó náà ṣeé san fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni, níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.

Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debenture Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ẹ̀tọ́ ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ.

Ilẹ̀: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà ta Watch Tower lọ́rẹ, yálà nípa fífi ṣe ẹ̀bùn, tàbí tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbénú rẹ̀ ni, a lè fi ilé náà sílẹ̀ kí olùtọrẹ náà ṣì máa gbénú rẹ̀ nígbà tó bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ èyíkéyìí di èyí tó o fi tọrẹ.

Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tí A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jàǹfààní ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.

Irú ọrẹ tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí gba pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà fara balẹ̀ wéwèé dáadáa.

Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó lè kàn sí Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o pè wá lórí tẹlifóònù, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.

Jehovah’s Witnesses,

P.M.B. 1090,

Benin City 300001,

Edo State, Nigeria.

Telephone: (052) 202020

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Káàkiri ayé, ìtìlẹ́yìn tí gbogbo wa ń ṣe ti mú kó ṣeé ṣe láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lẹ́wà gan-an

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun ní Gánà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́