Ǹjẹ́ O Mọ̀ Pé Ayọ̀ Wà Nínú Ṣíṣètọrẹ?
ÓTI fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọdún tí obìnrin náà ti ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni bọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara tó ti dara àgbà kò jẹ́ kó fi bẹ́ẹ̀ lókun mọ́, ó pinnu láti dé Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Arákùnrin kan rọra dì í mú wọnú gbọ̀ngàn náà. Bó ṣe wọlé, ó tẹ̀ kẹ̀jẹ́kẹ̀jẹ́ lọ síbi tó wà lọ́kàn rẹ̀, ìyẹn ìdí àpótí ọrẹ. Bó ṣe dẹ́bẹ̀, ó ju owó díẹ̀ tó ti ń fi pa mọ́ láti fi ṣètọrẹ sínú àpótí náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè bá wọn ṣiṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń kọ́ gbọ̀ngàn náà, òun náà fẹ́ ṣèrànwọ́ tiẹ̀.
Obìnrin yìí lè mú ọ rántí obìnrin olóòótọ́ mìíràn, ìyẹn “òtòṣì opó” tí Jésù rí tó ń ju ẹyọ owó kékeré méjì sínú àpótí ọrẹ tẹ́ńpìlì. Bíbélì kò sọ bí ipò rẹ̀ ṣe rí fún wa, àmọ́ bí obìnrin kan ò bá lọ́kọ láyé ìgbà yẹn, àtirí owó ná lè nira gan-an fún irú obìnrin bẹ́ẹ̀. Kò sí àní-àní pé àánú obìnrin náà ṣe Jésù, nítorí ó mọ irú ìṣòro tó dojú kọ ọ́. Nígbà tí Jésù ń fi obìnrin náà ṣe àpẹẹrẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ pé ẹ̀bùn kékeré tó fi sílẹ̀ yẹn dúró fún “gbogbo ohun tí ó ní, . . . gbogbo ohun ìní ìgbésí ayé rẹ̀.”—Máàkù 12:41-44.
Kí lohun tó sún opó aláìní yìí láti fi gbogbo ohun tó ní ṣètọrẹ? Ohun tó sún un ni pé gbogbo ọkàn rẹ̀ ló fi ń sin Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tí ojúkò ìjọsìn rẹ̀ wà ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba lóhun tóbìnrin náà lè ṣe, ó wù ú láti ti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ lẹ́yìn. Ó sì dájú pé ayọ̀ rẹ̀ pọ̀ jọjọ nítorí pé gbogbo ohun tágbára rẹ̀ gbé ló fi ṣètọrẹ.
Fífi Ọrẹ Ṣètìlẹyìn fún Iṣẹ́ Jèhófà
Látìgbà táwọn èèyàn ti ń ṣe ìjọsìn mímọ́ ni wọ́n ti ń fi nǹkan ìní àti owó ṣètọrẹ, èyí sì jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́, kò sì sígbà kan tí èyí kì í mú ọ̀pọ̀ ayọ̀ wá. (1 Kíróníkà 29:9) Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, kì í ṣe ṣíṣe tẹ́ńpìlì lọ́ṣọ̀ọ́ nìkan ni wọ́n ń lo ọrẹ fún, wọ́n tún ń lò ó láti mú kí gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà lè máa bá a nìṣó lójoojúmọ́. Òfin Mósè dìídì béèrè pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa dá ìdámẹ́wàá irè oko wọn láti fi ṣèrànwọ́ fáwọn ọmọ Léfì tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́, àwọn ọmọ Léfì alára tún gbọ́dọ̀ ṣètọrẹ ìdámẹ́wàá fún Jèhófà látinú gbogbo ohun tí wọ́n bá rí gbà.—Númérì 18:21-29.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni ò sí lábẹ́ májẹ̀mú Òfin mọ́, síbẹ̀ ìlànà náà pé káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa fi ohun ìní wọn ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́ kò yí padà. (Gálátíà 5:1) Láfikún sí i, nǹkan ayọ̀ làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kà á sí láti ṣètọrẹ káwọn arákùnrin wọn tó ṣaláìní lè rí ohun tí wọ́n nílò. (Ìṣe 2:45, 46) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni létí pé bí Ọlọ́run ṣe ń pèsè àwọn ohun rere fún wọn lọ́pọ̀ yanturu, ó yẹ káwọn náà máa ṣoore fáwọn ẹlòmíràn. Ó kọ̀wé pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa; láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín, kí wọ́n máa fi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:17-19; 2 Kọ́ríńtì 9:11) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbé ìgbésí ayé òun fúnra rẹ̀ yẹ̀ wò, ó rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
Ọ̀nà Táwọn Kristẹni Ń Gbà Ṣètọrẹ Lónìí
Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti máa fi àwọn nǹkan ìní wọn ran ara wọn lọ́wọ́ àti láti fi ti iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́yìn. Kódà, àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ máa ń fi ohun tí wọ́n lágbára ṣètọrẹ. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” sì mọ̀ pé ojúṣe àwọn sí Jèhófà ni láti lo gbogbo owó tá a fi ń ṣètọrẹ náà lọ́nà tó dára jù lọ. (Mátíù 24:45) Wọ́n ń lo àwọn owó náà láti bójú tó àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́, láti túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti láti tẹ̀ wọ́n jáde, láti ṣètò àwọn àpéjọ ńláńlá táwa Kristẹni máa ń ṣe, láti dá àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì rán wọn jáde, láti pèsè nǹkan ìrànwọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àti fún ọ̀pọ̀ ohun mìíràn tó ṣe pàtàkì. Ẹ jẹ́ ká ṣàlàyé ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì náà tá à ń fi àwọn owó náà ṣe, ìyẹn kíkọ́ àwọn ilé ìjọsìn.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa láti jàǹfààní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí àti ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró. Àmọ́, bí ipò ọrọ̀ ajé ṣe rí lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè kò jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láìsí pé wọ́n rí ìrànlọ́wọ́ owó. Nítorí náà, lọ́dún 1999, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ ètò kan, ìyẹn fífi àwọn owó tó ń wá láti àwọn ilẹ̀ tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ. Ìyẹn nìkan kọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti yọ̀ǹda àkókò wọn tí wọ́n sì ń fi iṣẹ́ tí wọ́n mọ̀ ṣèrànwọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa ń lọ ṣiṣẹ́ láwọn ibi tó wọnú gan-an láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí. Nígbà tí iṣẹ́ kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà bá ń lọ lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní àgbègbè náà máa ń kọ́ṣẹ́ ilé kíkọ́ àti bá a ṣe ń ṣe àmójútó wọn. Àtinú àpótí Owó Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni wọ́n sì ti ń rí owó fi ra nǹkan èlò àtàwọn irinṣẹ́ tí wọ́n nílò. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń lo àwọn gbọ̀ngàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ yìí ń dúpẹ́, wọ́n ń tún ọpẹ́ dá fún àkókò táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn fi ṣiṣẹ́ àti owó tí wọ́n fi ṣètọrẹ. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí sì ń ṣètọrẹ lóṣooṣù láti lè máa fi ṣàbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà àti láti lè máa dá lára owó tí wọ́n fi kọ́ ọ padà. Èyí sì ń jẹ́ ká lè rówó kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i.
Àwọn ohun èlò ìkọ́lé àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́lé láwọn orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan la máa ń lò láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gbọ̀ngàn yìí kì í ṣe ilé olówó gọbọi, wọ́n wuni, wọ́n bá ohun tá a nílò mu, wọ́n sì tuni lára. Nígbà tí ètò ìkọ́lé yìí bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1999, nǹkan bí ogójì orílẹ̀-èdè tí ò fi bẹ́ẹ̀ ní ọrọ̀ ni a ṣètò láti ràn lọ́wọ́. Àmọ́ látìgbà yẹn, ètò ìkọ́lé náà ti gbòòrò, orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [116] ló ti ń jàǹfààní ètò náà báyìí. Èyí túmọ̀ sí pé ó lé ní ìdajì gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé tó ṣì nílò ìrànwọ́. Láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn, Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti kọ́ lábẹ́ ètò yìí lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000], tó túmọ̀ sí pé ó lé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun márùn-ún tá à ń kọ́ lójúmọ́! Síbẹ̀, láwọn orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́fà yìí, Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tá a ṣì nílò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá àtààbọ̀ [14,500]. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà àti nípa ẹ̀mí ìmúratán àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àwa Ẹlẹ́rìí yíká ayé, ìrètí wa ni pé a óò rí owó tó pọ̀ tó láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ṣì nílò náà.—Sáàmù 127:1.
Gbọ̀ngàn Ìjọba Jẹ́ Ká Ní Ìbísí
Ipa wo làwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń kọ́ yìí ń ní lórí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà láwọn ìlú tá a kọ́ wọn sí àti lórí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà? Lọ́pọ̀ àgbègbè, àwọn tó ń wá sípàdé lẹ́yìn kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun máa ń pọ̀ sí i. Àpẹẹrẹ irú ẹ̀ ni ti ìròyìn kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Burundi tó sọ pé: “Bá a bá ti ń parí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba báyìí, ńṣe ló máa ń kún dẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, a kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan fún ìjọ kan tí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún èèyàn máa ń wá sípàdé. Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tuntun gba àádọ́jọ èèyàn. Nígbà tá a kọ́ ọ tán, àádọ́ta lé nígba [250] èèyàn ló ń wá sípàdé.”
Kí ló mú káwọn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ máa wá sípàdé? Ohun kan ni pé, nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń fura sáwọn akéde Ìjọba náà tí kò nílé ìpàdé gidi, tó jẹ́ pé abẹ́ igi tàbí orí pápá ni wọ́n ti ń pàdé. Lórílẹ̀-èdè kan, wọ́n sọ pé irú àwọn ìsìn tó ń pàdé láwùjọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ ló ń dá ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀, ni wọ́n bá ṣòfin pé inú ilé ìsìn ni kí wọ́n ti máa ṣe gbogbo ìjọsìn.
Níní táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ibi ìpàdé tiwọn tún jẹ́ kí wọ́n lè fi han àwọn èèyàn pé àwọn kì í ṣe ọmọlẹ́yìn pásítọ̀ kankan. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Zimbabwe kọ̀wé pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, inú ilé àdáni làwọn arákùnrin tó wà lágbègbè yìí ti máa ń pàdé, ẹni tó ni ilé tí wọ́n ti ń pàdé sì làwọn èèyàn máa ń wò bí ẹni tó ni ìjọ náà. Bí wọ́n bá fẹ́ tọ́ka sáwọn ará, wọ́n á ní àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Ọ̀gbẹ́ni Lágbájá. Gbogbo èyí ti ń yí padà báyìí báwọn èèyàn ti ń rí àkọlé gàdàgbà tó ń tọ́ka sí gbọ̀ngàn kọ̀ọ̀kan, ìyẹn ni ‘Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’”
Aláyọ̀ Làwọn Tó Ń Ṣètọrẹ
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Ká sòótọ́, gbígbé owó ńlá kalẹ̀ máa ń ṣèrànwọ́ gan-an. Àmọ́, látinú àwọn àpótí ọrẹ tó wà láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba lèyí tó pọ̀ jù lára owó tá a fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wá. Yálà owó tá a fi sílẹ̀ pọ̀ tàbí ó kéré, gbogbo ọrẹ pátá ló ṣe pàtàkì, kò sí èyí tá a gbójú fò dá. Rántí pé ibi tí Jésù dúró sí ló ti rí opó aláìní yẹn tó ń fi owó ẹyọ rẹ̀ kéékèèké méjì ṣètọrẹ. Àwọn áńgẹ́lì àti Jèhófà pàápàá kò ṣàì rí obìnrin náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ orúkọ opó náà, àmọ́ Jèhófà mú kí ohun tí obìnrin náà ṣe tọkàntọkàn yìí wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì, títí dòní làwọn èèyàn sì ń kà nípa rẹ̀.
Yàtọ̀ sí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ọrẹ wa la tún fi ń bójú tó gbogbo apá pàtàkì mìíràn nínú iṣẹ́ Ìjọba náà. Fífọwọ́sowọ́pọ̀ lọ́nà yìí ń jẹ́ ká láyọ̀ ká sì máa “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìfọpẹ́hàn fún Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 9:12) Àwọn arákùnrin wa ní orílẹ̀-èdè Benin ròyìn pé: “Ojoojúmọ́ ni àdúrà ọpẹ́ wa ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Jèhófà nítorí ìrànlọ́wọ́ owó tá a rí gbà látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé.” Lọ́wọ́ kan náà, gbogbo wa tá à ń fi owó wa ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà ń rí ayọ̀ tó wà nínú kí àwa Kristẹni máa ṣètọrẹ!
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Ń Gbà Ṣètọrẹ
ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ
Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí kí wọ́n ṣètò iye kan tí wọ́n máa ń fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé]—Mátíù 24:14” sí lára.
Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi àwọn owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè wọn. O tún lè fi ọrẹ tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania, c/o Office of the Secretary and Treasurer, 25 Columbia Heights, Brooklyn, New York 11201-2483, tàbí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́, ọ̀rọ̀ náà, “Watch Tower” ni kó o kọ sórí rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wa láti rí owó náà gbà. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó fi hàn pé ẹ̀bùn pọ́ńbélé nirú ọrẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ wà lára rẹ̀.
ỌRẸ TÁ A FI SÍNI NÍKÀÁWỌ́ TÓ ṢEÉ GBÀ PADÀ
A lè fi owó síkàáwọ́ Watch Tower pé kí wọ́n máa lò ó. Àmọ́, a óò dá owó náà padà bí ẹni tó ni ín bá ti béèrè fún un. Fún àfikún àlàyé, jọ̀wọ́ kàn sí Ọ́fíìsì Akọ̀wé àti Akápò ní àdírẹ́sì tá a kọ sókè yẹn.
ỌRẸ TÍ A WÉWÈÉ
Yàtọ̀ sí pé ká dìídí fi owó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:
Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.
Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi àkáǹtì owó ní báńkì, ìwé ẹ̀rí owó ìdókòwò, tàbí àkáǹtì owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ síkàáwọ́ Watch Tower tàbí ká mú kí owó náà ṣeé san fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni, níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.
Ẹ̀tọ́ Owó Ìdókòwò àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó: A lè fi ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ.
Ilé Tàbí Ilẹ̀: A lè fi ilé tàbí ilẹ̀ tó ṣeé tà ta Watch Tower lọ́rẹ. Tó bá jẹ́ ilé téèyàn ṣì ń gbé ni, ẹni náà lè dá a dúró kó sì máa gbénú ẹ̀ nígbà tó bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilé tàbí ilẹ̀ èyíkéyìí di ọrẹ.
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tá A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jàǹfààní ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́. Àwọn ohun ìní téèyàn fi síkàáwọ́ ìsìn kí wọ́n lè jàǹfààní rẹ̀ máa ń mú kéèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sáwọn àjẹmọ́nú kan lábẹ́ ètò owó orí.
Irú àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí ń béèrè pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà wéwèé. Láti ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tó fẹ́ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nípasẹ̀ oríṣiríṣi ọrẹ tá a wéwèé, a ti ṣe ìwé pẹlẹbẹ kan lédè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Spanish, orúkọ rẹ̀ ni, Charitable Planning to Benefit Kingdom Service Worldwide. A kọ ìwé pẹlẹbẹ náà láti fi ṣàlàyé oríṣiríṣi ọ̀nà tá a lè gbà ṣètọrẹ bóyá nísinsìnyí tàbí gẹ́gẹ́ bí ogún tá a fúnni lẹ́yìn ikú. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ti ka ìwé pẹlẹbẹ náà, tí àwọn àti lọ́yà wọn sì ti jíròrò ọ̀ràn náà, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yíká ayé tí wọ́n sì tún rí àwọn àjẹmọ́nú gbà látinú owó orí tí wọ́n ń san. A lè rí ìwé yìí gbà nípa bíbéèrè ní tààràtà láti ẹ̀ka Charitable Planning Office.
Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, o lè kàn sí ẹ̀ka Charitable Planning Office, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o pè wọ́n lórí tẹlifóònù, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.
Charitable Planning Office
Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
100 Watchtower Drive,
Patterson, New York 12563-9204
Telephone: (845) 306-0707
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]
Ilé ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀ àti ilé ìpàdé tí wọ́n ń lò nísìnyí
Orílẹ̀-èdè Zambia
Orílẹ̀-èdè Central African Republic