Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Dáhùn Nípàdé
ỌMỌBÌNRIN kan tó ń jẹ́ Perla, tó wá láti ìlú Mẹ́síkò, rántí pé nígbà tóun wà ní kékeré, màmá òun máa ń kọ́ òun láti múra ìdáhùn ṣókí tóun máa dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀. Perla náà ti di ìyá báyìí, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sì ti pé ọdún márùn-ún. Báwo ló ṣe ń ran ọmọ náà lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Màá kọ́kọ́ múra Ilé Ìṣọ́ náà sílẹ̀. Bí mo ṣe ń múra ẹ̀ sílẹ̀ ni màá máa fọkàn wá ìpínrọ̀ tó lè yé ọmọ mi, èyí táá lè fi ọ̀rọ̀ ara ẹ̀ ṣàlàyé. Lẹ́yìn ìyẹn la óò wá pọkàn pọ̀ sórí ìpínrọ̀ tó máa ń pè ní ‘ìpínrọ̀ mi.’ Mo máa ń sọ fún un pé kó ṣàlàyé ẹ̀ nípa lílo àpèjúwe tó bá mọ̀ pé ó rọrùn fóun. Lẹ́yìn náà la óò wá fi ìdáhùn náà dánra wò nígbà mélòó kan. Ó ní kiní kan tá a máa ń lò láti fi ṣe makirofóònù kó lè mọ bó ṣe máa gbé e dání bó bá ń dáhùn. Inú mi máa ń dùn gan-an pé kò sí ìpàdé náà tí kì í ti í dáhùn tàbí kó nawọ́ sókè. Lọ́pọ̀ ìgbà, á lọ bá olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ á sì sọ ìpínrọ̀ tó fẹ́ láti dáhùn fún un.”
Jens, alàgbà kan tó wà pẹ̀lú àwùjọ kan tó ń sọ èdè Hindi, ní ọmọkùnrin méjì, ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún méjì, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin. Bí òun àti ìyàwó ẹ̀ bá ń múra ìpàdé sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ, ọgbọ́n kan tí Jens kọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ̀ ló máa ń lò. Ó sọ pé: “A máa wo ibi táwọn ọmọ á lè lóye nínú àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn náà la óò wá gbìyànjú láti ṣàlàyé ráńpẹ́ fún wọn lórí ọ̀rọ̀ tí àpilẹ̀kọ náà dá lé tàbí ká sọ àwọn kókó tó wà níbẹ̀ fún wọn, ká tó wá bi wọ́n láwọn ìbéèrè tá a ní lọ́kàn pé kí wọ́n dáhùn ní ìpàdé. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìdáhùn tó tọkàn wọn wá tí wọ́n máa ń fún wa máa ń yà wá lẹ́nu. Ọ̀nà tí wọ́n máa ń gbà ṣàlàyé ara wọn máa ń jẹ́ ká mọ bí òye wọn ṣe tó. Nítorí èyí, ìdáhùn wọn máa ń fìyìn fún Jèhófà, ó sì jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́.”