Ẹ Máa Gbé Ara Yín Ró Lẹ́nì Kìíní-Kejì Nípa Dídáhùn ní Àwọn Ìpàdé
1 A gbà wá níyànjú nínú Hébérù 10:24 láti “ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Èyí kan gbígbé ara wa ró lẹ́nì kìíní-kejì nípa dídáhùn lọ́nà tí ó ní ìtumọ̀ ní àwọn ìpàdé ìjọ. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a máa dáhùn? Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? Ta ni yóò ṣe láǹfààní?
2 Ronú nípa ọ̀pọ̀ ìgbà tí o jèrè láti inú gbígbọ́ tí àwọn ẹlòmíràn ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn tí ó sì ṣe kedere, tí ó mú kí o túbọ̀ lóye sí i tí ó sì sọ ọ́ di alágbára nípa tẹ̀mí. O ní àǹfààní láti máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn náà. Nígbà tí o bá ń dáhùn, o ń fi ìfẹ́-ọkàn rẹ láti “fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀” fún gbogbo àwọn tí ó wà níbẹ̀ hàn kedere, kí èyí lè fún wọn níṣìírí.—Róòmù 1:11, 12.
3 Bí A Ṣe Lè Dáhùn Dáradára: Má ṣe jẹ́ kí ìdáhùn rẹ gùn, ní sísọ gbogbo èrò tí ó wà nínú ìpínrọ̀ náà. Ìdáhùn gígùn sábà máa ń kùnà láti sọ ojú abẹ níkòó, kìí sìí fún àwọn ẹlòmíràn ní ìṣírí láti kópa. Ìdáhùn àkọ́kọ́ lórí ìpínrọ̀ náà gbọ́dọ̀ mọ níwọ̀n kí ó sì jẹ́ ìdáhùn tààrà sí ìbéèrè náà ní pàtó. Àwọn tí ó ń ṣe àfikún lè wá sọ bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà ṣe wúlò sí tàbí kí wọ́n fi hàn bí a ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a lò níbẹ̀ sílò. Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 90 sí 92.
4 Bí ìrònú nípa dídáhùn bá ń kó ìpayà bá ọ, múra ìdáhùn ṣókí ṣáájú àkókò, kí o sì sọ fún olùdarí pé kí ó pè ọ́ fún ìpínrọ̀ yẹn. Lẹ́yìn tí o bá ṣe èyí ní àwọn ìpàdé bí mélòó kan, dídáhùn yóò túbọ̀ rọrùn. Rántí pé Mósè àti Jeremáyà sọ̀rọ̀ nípa àìní ìdánilójú nínú agbára wọn láti sọ̀rọ̀ ní gbangba. (Ẹ́kís. 4:10; Jer. 1:6, àkíyèsí ẹsẹ ìwé) Ṣùgbọ́n Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀ lórúkọ òun, yóò sì ran ìwọ náà lọ́wọ́ pẹ̀lú.
5 Ta Ni Yóò Jàǹfààní Nínú Ìdáhùn Rẹ? Ìwọ fúnra rẹ ń jàǹfààní, nítorí pé àwọn ìdáhùn rẹ túbọ̀ ń mú kí òtítọ́ jinlẹ̀ sí i ní èrò-inú àti ọkàn-àyà rẹ ní mímú kí ó rọrùn fún ọ láti rántí àwọn ìsọfúnni náà nígbà mìíràn. Bákan náà, àwọn ẹlòmíràn tún ń jàǹfààní nínú gbígbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró tí o ń sọ jáde. A ń rí ìṣírí gbà nígbà tí gbogbo ìjọ, yálà àwọn tí ó ní ìrírí, ọmọdé, onítìjú, tàbí àwọn ẹni tuntun, bá ń gbìyànjú láti sọ ìgbàgbọ́ wọn jáde ní àwọn ìpàdé ìjọ.
6 A ní ìdánilójú pé a óò rí i pé ‘àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bọ́ sí àkókò mà dára o’ nígbà tí a bá lò wọ́n láti gbe ara wa ro lẹ́nì kìíní-kejì ní àwọn ìpàdé!—Òwe 15:23.