ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 12/1 ojú ìwé 17-19
  • Ìṣòtítọ́ Lérè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣòtítọ́ Lérè
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Fi Ohun Tó O Jẹ́ Pa Mọ́
  • Ìṣòtítọ́ Lérè
  • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Ohun Gbogbo
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Jíjẹ́ Olóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ìwà Rere Tó Ṣeyebíye Ju Dáyámọ́ǹdì Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 12/1 ojú ìwé 17-19

Ìṣòtítọ́ Lérè

INÚ ọgbà Édẹ́nì ni àìṣòótọ́ ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ibi làwọn èèyàn ti mọyì kéèyàn jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n sì ka irọ́ pípa àti ẹ̀tàn sí ohun tí kò dára tí kò sì bojú mu rárá. Ohun àmúyangàn ni tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́, lóde òní, ńṣe làwọn tó gbà pé ó di dandan kéèyàn parọ́ kó tò lè rọ́wọ́ mú túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Kí ni èrò tìẹ? Ṣé ó yẹ kéèyàn máa ṣòótọ́? Kí lo lè fi dá ẹni tó ń ṣòótọ́ àti ẹni tí kì í ṣòótọ́ mọ̀?

Tá a bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, a ní láti jẹ́ olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé: “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Kì í ṣe torí pé a fẹ́ káwọn èèyàn máa yìn wá la ṣe fẹ́ jẹ́ olóòótọ́. Nítorí pé a fẹ́ bọ̀wọ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa a sì fẹ́ máa múnú rẹ̀ dùn ni.

Má Ṣe Fi Ohun Tó O Jẹ́ Pa Mọ́

Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn máa ń pe ara wọn ni ohun tí wọn kò jẹ́ káwọn nǹkan kan lè tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n máa ń gba ìwé àṣẹ, ìwé ẹ̀rí àti ìwé ìdánimọ̀ tó jẹ́ ayédèrú kí wọ́n lè wọ orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́nà tí kò bófin mu tàbí kí wọ́n lè rí iṣẹ́ tàbí kí wọ́n lè dé ipò kan tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Kódà àwọn òbí kan máa ń yí ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí àwọn ọmọ wọn káwọn ọmọ náà bàa lè láǹfààní àtikàwé sí i.

Àmọ́, tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹlẹ́tàn. Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́,” ó sì fẹ́ káwọn tí wọ́n ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun máa ṣòótọ́. (Sáàmù 31:5) Tí a kò bá fẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà bà jẹ́, a ò ní máa fara wé “àwọn tí kì í sọ òtítọ́,” ìyẹn “àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́.”—Sáàmù 26:4.

Àwọn èèyàn tún máa ń parọ́ tí wọ́n bá mọ̀ pé wọ́n máa fìyà jẹ àwọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Kódà nínú ìjọ Kristẹni, èèyàn lè bá ara rẹ̀ nípò kan tó lè mú kó fẹ́ purọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìjọ kan, ọ̀dọ́kùnrin kan jẹ́wọ́ fáwọn alàgbà pé òun dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan, àmọ́ kò jẹ́wọ́ pé òun jalè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí wà pé ó jalè. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àṣírí tú, wọ́n sì yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ. Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu ká ló ti sòótọ́ délẹ̀délẹ̀ kí wọ́n sì ti ràn án lọ́wọ́ kó lè padà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà? Ó ṣe tán Bíbélì sọ pé: “Má fi ojú kékeré wo ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni kí o má rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá tọ́ ọ sọ́nà; nítorí ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.”—Hébérù 12:5, 6.

Nígbà mìíràn, arákùnrin tó wù láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ lè gbìyànjú láti fi àwọn ìṣòro tó ní tàbí ìwà àìtọ́ tó ti hù sẹ́yìn pa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tẹ́nì kan bá gba fọ́ọ̀mù àkànṣe iṣẹ́ ìsìn kan, ó lè má dáhùn gbogbo ìbéèrè tó jẹ mọ́ ìlera àti ìwà rẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kó máa rò pé tóun bá sọ gbogbo òtítọ́ ibẹ̀, ìyẹn ò ní jẹ́ kí wọ́n fún òun láǹfààní àkànṣe náà. Ó lè sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘ìyẹn kì í ṣe irọ́,’ àmọ́ ṣé gbogbo òótọ́ ibẹ̀ ló sọ yẹn? Gbé ohun tí ìwé Òwe 3:32 sọ yẹ̀ wò, ó ní: “Nítorí oníbékebèke jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn adúróṣánṣán.”

Ohun tí jíjẹ́ olóòótọ́ túmọ̀ sí ni kéèyàn kọ́kọ́ yẹ ara rẹ̀ wò kó rí i pé òun jẹ́ olóòótọ́ nínú ọkàn òun. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun téèyàn bá fẹ́ gbà gbọ́ ló máa ń gbà gbọ́ dípò kó gba ohun tó jóòótọ́ gbọ́. Ó máa ń rọrùn gan-an féèyàn láti di ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, Sọ́ọ̀lù Ọba gbìyànjú láti dá ara rẹ̀ láre pé ohun tóun ṣe kò burú, ó sì di ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíràn. Nítorí bẹ́ẹ̀, Jèhófà kọ̀ ọ́ ní ọba. (1 Sámúẹ́lì 15:20-23) Ọ̀rọ̀ ti Dáfídì Ọba yàtọ̀ síyẹn gan-an, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀. Mo wí pé: ‘Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.’ Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.”—Sáàmù 32:5.

Ìṣòtítọ́ Lérè

Jíjẹ́ olóòótọ́ tàbí aláìṣòótọ́ ló máa sọ irú ojú tàwọn èèyàn á fi máa wò ọ́. Táwọn èèyàn bá mọ̀ pé o ti tan àwọn jẹ, bí ò tilẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ, wọ́n ò ní fọkàn tán ẹ mọ́, á sì pẹ́ gan-an kí wọ́n tó tún lè gbà ọ́ gbọ́. Àmọ́, tó o bá jẹ́ olóòótọ́, tó ò kì í ṣe alábòsí èèyàn, wàá dẹni táwọn èèyàn lè gbára lé tí wọ́n sì lè fọkàn tán. Àwọn èèyàn ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sírú ẹni bẹ́ẹ̀. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan mọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn òṣìṣẹ́ òun ń lu ilé iṣẹ́ òun ní jìbìtì, nítorí náà, ó kó àwọn ọlọ́pàá wá láti ṣèwádìí ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tó gbọ́ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n mú náà, ó lọ bá àwọn ọlọ́pàá pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀gá náà mọ̀ pé olóòótọ́ èèyàn ni àti pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́. Iṣẹ́ kò bọ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí yìí, àmọ́ wọ́n lé àwọn òṣìṣẹ́ yòókù dànù. Inú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí dùn gan-an nítorí pé ìwà Ẹlẹ́rìí náà bọlá fún orúkọ Jèhófà.

Àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ìwà rere téèyàn bá ń hù. Ní ìlú kan nílẹ̀ Áfíríkà, afárá kan tí wọ́n ṣe sórí kòtò ọ̀gbàrá ńlá kan nílò àtúnṣe nítorí pé àwọn kan ti jí lára àwọn pákó ibẹ̀ lọ. Àwọn èèyàn ìlú náà pinnu láti dáwó tí wọ́n á fi ra pákó mìíràn, àmọ́ ta ló máa bójú tó owó náà? Gbogbo wọn panu pọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kó bójú tó o.

Nígbà tí ìjà òṣèlú àti ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bẹ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, ilé iṣẹ́ kan tó lẹ́ka sáwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbé Ẹlẹ́rìí kan tó ń ṣiṣẹ́ aṣírò owó fún ilé iṣẹ́ náà lọ́ sí orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu. Ilé iṣẹ́ náà ṣètò pé kó ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù, wọ́n sì ń gbọ́ bùkátà rẹ̀ títí dìgbà tí wàhálà náà fi yanjú. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe gbogbo èyí? Ìdí ni pé ṣáájú ìgbà yẹn, Ẹlẹ́rìí náà ti kọ̀ láti bá àwọn kan lẹ̀dí àpò pọ̀ láti lu ilé iṣẹ́ náà ní jìbìtì. Àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà ti wá mọ̀ ọ́n sí olóòótọ́ èèyàn. Ǹjẹ́ wọn ì bá ran Ẹlẹ́rìí yìí lọ́wọ́ ká ní pé ó jẹ́ ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ kò mọ́?

Ìwé Òwe 20:7 sọ pé: “Olódodo ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀.” Olóòótọ́ èèyàn lẹni tá a lè fọkàn tán, tí kì í rẹ́ àwọn èèyàn jẹ tí kì í sì í tanni jẹ. Ǹjẹ́ kì í ṣe bó o ṣe fẹ́ káwọn èèyàn máa fòótọ́ inú bá ọ lò nìyẹn? Ẹni tó bá ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ èèyàn. Ìyẹn ló ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, à ń fi hàn pé a fẹ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù sọ pé kó máa darí ìwà wa nìyẹn, ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12; 22:36-39.

Kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà lè ní ìṣòro tiẹ̀ o, àmọ́ ẹ̀rí ọkàn rere tó máa jẹ́ kéèyàn ní sàn ju ohunkóhun lọ. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, jíjẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin ní àǹfààní tó pọ̀ gan-an. Dájúdájú, níní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà ṣeyebíye ju ohunkóhun lọ. Kí nìdí tí wàá fi ba àjọṣe náà jẹ́ nípa híhùwà àìṣòótọ́ torí káwọn èèyàn bàa lè máa fojú tó dára wò ọ́ tàbí kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àǹfààní kan lọ́nà ẹ̀bùrú? Ìṣòro èyíkéyìí tí ì báà dé bá wa, ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ó fi Jèhófà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ tí kò sì yíjú sí àwọn aṣàyàgbàǹgbà-peni-níjà, tàbí sí àwọn tí ń yà sínú irọ́.”—Sáàmù 40:4.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í ra àwọn ìwé ẹ̀rí tó jẹ́ ayédèrú, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í lò wọ́n

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́