Ìtàn Ìgbésí Ayé
A Jà Fitafita Ká Lè Dúró Gbọin-gbọin Nínú Ìgbàgbọ́
Gẹ́gẹ́ bí Rolf Brüggemeier ti sọ ọ́
Àtọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ mi kan ni lẹ́tà tí mo kọ́kọ́ gbà lẹ́yìn tí wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n ti wá. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé wọ́n ti mú màmá mi àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin, ìyẹn Peter, Jochen, àti Manfred. Èyí túmọ̀ sí pé kò sí màmá tàbí ẹ̀gbọ́n kankan tó máa bójú tó àwọn àbúrò wa obìnrin kékeré. Kí nìdí táwọn aláṣẹ́ Ìlà Oòrùn Jámánì fi ń ṣenúnibíni sí ìdílé wa? Kí ló sì ràn wá lọ́wọ́ tá a fi lè dúró gbọin-gbọin nínú ìgbàgbọ́?
OGUN ÀGBÁYÉ KEJÌ kò jẹ́ ká lè máa gbádùn ìgbà èwe wa nìṣó. A fojú ara wa rí ọṣẹ́ tí ogun ń ṣe. Bàbá wa lọ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Jámánì, nígbà tọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá tẹ̀ ẹ́, wọ́n fi sẹ́wọ̀n, ó sì kú síbẹ̀. Èyí wá sọ màmá wa, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Berta, di ẹni tó ń dá nìkan tọ́ ọmọ mẹ́fà, tọ́jọ́ orí wọn wà láàárín ọdún kan sí ọdún mẹ́rìndínlógún.
Ṣọ́ọ̀ṣì tí màmá wa ń lọ mú kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sú u pátápátá, kò sì fẹ́ láti gbọ́ nǹkan kan mọ́ nípa Ọlọ́run. Àmọ́ lọ́jọ́ kan lọ́dún 1949, obìnrin pẹ́lẹ́ńgẹ́ kan tí kò ga tó sì jẹ́ olóye èèyàn wá sílé wa. Orúkọ rẹ̀ ni Ilse Fuchs, ó sì bá wa sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ìbéèrè tó béèrè àti àlàyé tó ṣe mú kó wu màmá mi láti fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi màmá mi lọ́kàn balẹ̀.
Àmọ́ ńṣe làwa ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kọ́kọ́ ń ṣiyèméjì nípa ohun tí obìnrin náà sọ. Ìjọba Násì, àti ìjọba tó tún dé lẹ́yìn náà, ìyẹn ìjọba Kọ́múníìsì, ti ṣe àwọn ìlérí kàǹkàkàǹkà, àmọ́ wọn ò mú àwọn ìlérí náà ṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í yára gba ìlérí èyíkéyìí gbọ́ mọ́, orí wa wú nígbà tá a gbọ́ pé wọ́n sọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ogun. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni èmi, màmá wa, àti Peter, ṣèrìbọmi.
Àbúrò wa ọkùnrin tó kéré jù, ìyẹn Manfred náà ṣèrìbọmi, àmọ́ kò sí àní-àní pé ẹ̀kọ́ Bíbélì kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀. Nígbà tí ìjọba Kọ́múníìsì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́dún 1950, táwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó ń jẹ́ Stasi tí wọ́n rorò gan-an sì fúngun mọ́ ọn, ló bá sọ ibi tá a ti ń ṣe àwọn ìpàdé wa fún wọn. Èyí ló wá yọrí sí mímú tí wọ́n mú màmá wa àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin yòókù.
Bá A Ṣe Ń Sin Jèhófà Nígbà Tí Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Ìwàásù Wa
Nítorí pé ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, ńṣe la máa ń dọ́gbọ́n kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ Ìlà Oòrùn Jámánì. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lọ ń kó o. Láti apá ìwọ̀ oòrùn ìlú Berlin tí wọn kò ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa ni mo ti lọ máa ń kó o, màá sì kó o gba ẹnubodè kọjá. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni mo lọ táwọn ọlọ́pàá ò sì rí mi mú, àmọ́ lóṣù November ọdún 1950, ọwọ́ wọn tẹ̀ mí.
Àwọn ọlọ́pàá Stasi fi mí sínú àhámọ́ tí kò ní fèrèsé, tó sì jẹ́ pé àjàalẹ̀ ló wà. Wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò lóru, tó bá sì dọ̀sán wọn kì í jẹ́ kí n sùn, wọ́n sì máa ń nà mí nígbà míì. Èmi àtàwọn ará ilé mi ò gbúròó ara wa títí fi di oṣù March ọdún 1951, nígbà tí màmá mi, Peter, àti Jochen wá síbi ìgbẹ́jọ́ mi ní kóòtù. Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà ni wọ́n dá fún mi.
Kò ju ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ mi yìí tí wọ́n fi mú Peter, Jochen, àti màmá mi. Lẹ́yìn náà ni arábìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bíi tiwa wá ń bá wa tọ́jú àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Hannelore, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá lákòókò náà, ẹ̀gbọ́n màmá mi obìnrin sì mú Sabine, tó jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà yẹn tira. Bí ọ̀daràn paraku làwọn ẹ̀ṣọ́ Stasi ṣe ṣe màmá mi àtàwọn àbúrò mi ọkùnrin, kódà wọ́n yọ okùn bàtà ẹsẹ̀ wọn kúrò. Orí ìdúró ni wọ́n sì wà jálẹ̀ gbogbo àkókò tí wọ́n fi fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́fà-mẹ́fà ni wọ́n dá fún àwọn náà.
Lọ́dún 1953, àwọn aláṣẹ ní kí èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan lọ máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ pápákọ̀ òfuurufú àwọn ológun, àmọ́ a kọ̀. Àwọn aláṣẹ sì jù wá sí àhámọ́ aládàáwà fún ọjọ́ mọ́kànlélógún, èyí tó túmọ̀ sí pé kò sí iṣẹ́ fún wa, a ò lè gba lẹ́tà, ìwọ̀nba oúnjẹ díẹ̀ ni wọ́n sì ń fún wa. Àwọn arábìnrin wa kan ló ń fún wa ní díẹ̀ lára búrẹ́dì tí kò tó nǹkan tí wọ́n ń fún àwọn náà, ńṣe ni wọ́n sì máa ń yọ́ mú búrẹ́dì náà wá fún wa. Èyí ló jẹ́ kí n mọ Anni, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arábìnrin wọ̀nyẹn, tí mo sì fẹ́ ẹ lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ lọ́dún 1956 tí wọ́n sì dá èmi sílẹ̀ lọ́dún 1957. Lẹ́yìn ọdún kan tá a ṣègbéyàwó, a bí ọmọ obìnrin kan, a sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ruth. Àárín àkókò yìí náà làwọn àbúrò mi, Peter, Jochen, àti Hannelore ṣègbéyàwó.
Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀, wọ́n tún mú mi. Ọlọ́pàá Stasi kan gbìyànjú láti yí mi lérò padà kí n lè máa ṣe amí fún wọn. Ó sọ pé: “Ọ̀gbẹ́ni Brüggemeier, ṣàánú ara rẹ. O mọ ohun tójú èèyàn ń rí téèyàn bá wà lẹ́wọ̀n, a ò sì fẹ́ kí gbogbo ìyà tó jẹ́ ọ lákọ̀ọ́kọ́ tún padà jẹ ọ́. O ṣì lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí, kó o máa ka àwọn ìwé yín, kó o sì máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì bó bá ṣe wù ẹ́. A kàn fẹ́ kó o jẹ́ ká máa mọ ohun tó ń lọ ni. Ro ti aya rẹ àti ti ọmọ rẹ kékeré.” Gbólóhùn tó sọ gbẹ̀yìn yẹn wọ̀ mí lára gan-an. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé nígbà tí mo bá wà lẹ́wọ̀n, Jèhófà á bójú tó ìdílé mi dáadáa ju bí èmi alára ṣe lè bójú tó wọn lọ. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀!
Àwọn aláṣẹ gbìyànjú láti fipá mú Anni kó máa ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ káwọn ẹlòmíràn sì máa bá a tọ́jú Ruth láàárín ọ̀sẹ̀. Àmọ́ Anni kọ̀, ó wá ń ṣiṣẹ́ lóru kó bàa lè ráyè bójú tó Ruth lójú mọmọ. Àwọn ará fìfẹ́ hàn gan-an, wọ́n fún ìyàwó mi ni ọ̀pọ̀ nǹkan débi pé, ńṣe ló tún ń fún àwọn mìíràn lára rẹ̀. Àmọ́ ní tèmi, mo fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún mẹ́fà sí i lẹ́wọ̀n.
Ohun Tá A Ṣe Tí Ìgbàgbọ́ Wa Ò Fi Yẹ̀ Nígbà Tá A Wà Lẹ́wọ̀n
Nígbà tí mo padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àwọn Ẹlẹ́rìí tá a jọ wà nínú àhámọ́ fẹ́ láti mọ àwọn ohun tuntun tí ètò Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde. Inú mi dùn gan-an pé mo ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ dáadáa, mo sì lọ sípàdé déédéé, èyí jẹ́ kí n lè fún wọn ní ìṣírí tẹ̀mí!
Nígbà tá a sọ fáwọn ẹ̀ṣọ́ pé kí wọ́n fún wa ní Bíbélì, èsì tí wọ́n fún wa ni pé: “Téèyàn bá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bíbélì, bí ìgbà téèyàn fún fọ́léfọ́lé tó wà lẹ́wọ̀n ní irinṣẹ́ tó máa fi sá jáde ni.” Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú máa ń yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tá a máa jíròrò rẹ̀. Lójoojúmọ́, àwa tá a wà lẹ́wọ̀n máa ń rin ìrìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú káàkiri inú ọgbà kí ara wa lè le ká sì lè gba atẹ́gùn sára, àmọ́ èyí kò jẹ wá lógún tó àǹfààní tá a máa rí nínú ẹsẹ Bíbélì ọjọ́ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún la fi ní láti jìnnà síra wa, tí wọn ò sì gbà wá láyè ká máa bára wa sọ̀rọ̀, síbẹ̀, a ṣì máa ń wá ọ̀nà láti sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ náà fún ara wa. Nígbà tá a bá padà sínú àhámọ́ wa, a ó pa ìwọ̀nba ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ti rí gbọ́ pọ̀, àá sì ṣe ìjíròrò Bíbélì gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa lójoojúmọ́.
Àmọ́ nígbà tó yá, ẹnì kan lọ tú àṣírí wa, bí wọ́n sì ṣe lọ jù mí sínú àhámọ́ aládàáwà nìyẹn. Inú mi dùn gan-an pé nígbà yẹn, mo ti mọ ohun tó ju ọgọ́rùn-ún méjì ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sórí! Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti ṣàṣàrò lórí onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì láwọn ọjọ́ tí mo fi dá wà yẹn. Bí wọ́n tún ṣe gbé mi lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n mìíràn nìyẹn, níbi tí ẹ̀ṣọ́ kan ti fi èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí méjì mìíràn sínú àhámọ́ kan náà. Ohun tó múnú mi dùn jù ni pé, ẹ̀ṣọ́ náà fún wa ní Bíbélì kan. Lẹ́yìn tí mo ti dá nìkan wà ní àhámọ́ fún oṣù mẹ́fà, mo dúpẹ́ pé mo tún lè bá àwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi jíròrò ohun tó wà nínú Bíbélì.
Peter tó jẹ́ àbúrò mi sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti ní ìfaradà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi sí, ó ní: “Mo máa ń ronú nípa bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú ayé tuntun, àwọn nǹkan tó wà nínú Bíbélì ni mo sì máa ń jẹ́ kó gbà mí lọ́kàn. Àwa tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí máa ń fún ara wa lókun nípa bíbi ara wa láwọn ìbéèrè tó dá lórí Bíbélì, tàbí ká máa ṣèdánwò fún ara wa lórí àwọn ohun tó wà nínú Ìwé mímọ́. Nǹkan ò rọrùn fún wa níbẹ̀ rárá. Nígbà míì, àwa mọ́kànlá ni wọ́n máa kó sínú yàrá kékeré kan. Ibẹ̀ la sì ti ń ṣe gbogbo ohun tá a bá fẹ́ ṣe. Ibẹ̀ la ti ń jẹun, ibẹ̀ là ń sùn sí, ibẹ̀ náà la ti ń wẹ̀, kódà ibẹ̀ là ń yàgbẹ́ sí. Nígbà tó yá, ara wa kọ̀ ọ́.”
Àbúrò mi ọkùnrin mìíràn tó ń jẹ́ Jochen, sọ ohun tójú tiẹ̀ náà rí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó ní: “Mo máa ń kọ àwọn orin tí mo bá rántí látinú ìwé orin wa. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí mo ti há sórí. Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀, mi ò jáwọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Lójoojúmọ́, èmi àti ìdílé mi jọ máa ń jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Gbogbo ìpàdé la sì máa ń múra rẹ̀ sílẹ̀.”
Wọ́n Dá Màmá Mi Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n
Lẹ́yìn tí màmá mi ti lo nǹkan bí ọdún méjì ó lé díẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n dá a sílẹ̀. Ó lo òmìnira tó ní yìí láti kọ́ àwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Hannelore àti Sabine, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọin. Ó tún kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè kójú àwọn ìṣòro tó bá yọjú nítorí ìgbàgbọ́ wọn nílé ìwé. Hannelore sọ pé: “A ò bẹ̀rù ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀, nítorí pé a máa ń fún ara wa níṣìírí nílé. Ìfẹ́ tá a ní fún ara wa nínú ìdílé wa kò sì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyà kankan jẹ wá.”
Hannelore ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “A tún máa ń mú oúnjẹ tẹ̀mí lọ fáwọn arákùnrin wa tó wà lẹ́wọ̀n. A máa ń fi lẹ́tà wẹ́wẹ́ ṣàdàkọ gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sínú bébà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́. Lẹ́yìn náà, àá wá fi àwọn bébà náà sáàárín àwọn èso tó dà bí àgbálùmọ̀ tá a máa ń kó mọ́ àwọn nǹkan tá a fi ń ránṣẹ́ lóṣooṣù. Inú wa máa ń dùn gan-an nígbà táwọn arákùnrin wa bá fèsì padà pé àwọn gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí tó wà láàárín àwọn èso yẹn gan-an. Iṣẹ́ yẹn gbà wá lọ́kàn débi pé, àkókò tó lárinrin ni àkókò náà jẹ́ fún wa.”
Bá A Ṣe Ń Jọ́sìn Nígbà Tí Ìjọba Fòfin De Iṣẹ́ Ìwàásù Wa
Peter sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Jámánì, ó ní: “Ilé àwọn ará la ti máa ń pàdé, ìwọ̀nba sì làwa tá a máa ń pàdé lójú kan. Ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la máa ń débẹ̀, a kì í sì í kúrò nígbà kan náà. Tá a bá parí ìpàdé kan, àá sọ ibi tá a ti máa ṣe òmíràn. Ọwọ́ la sì fi ń bára wa sọ̀rọ̀ tàbí ká kọ ọ́ síwèé torí pé ìgbàkígbà làwọn ọlọ́pàá Stasi lè fi ẹ̀rọ gbọ́ ohun tá à ń sọ.”
Hannelore náà ṣàlàyé pé: “Nígbà míì, àwọn ará máa ń fi kásẹ́ẹ̀tì ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ ránṣẹ́ sí wa. Èyí sì jẹ́ ohun kan tó máa ń mú ká gbádùn ìpàdé wa gan-an. Àwùjọ wa kékeré máa ń pàdé pọ̀ fún bíi wákàtí mélòó kan láti tẹ́tí sí ìtọ́ni látinú Bíbélì. Bá ò tiẹ̀ rí àwọn tó ń sọ̀rọ̀, a máa ń fọkàn bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lọ, a sì máa ń ṣe àkọsílẹ̀.”
Peter sọ pé: “Àwọn arákùnrin wa ní orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe gudugudu méje láti rí i pé àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kòọ́ Bíbélì ń tẹ̀ wá lọ́wọ́. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ṣáájú kí wọ́n tó wó Odi Ìlú Berlin lulẹ̀ lọ́dún 1989, wọ́n ṣe àwọn àkànṣe ìwé kékeré fún wa. Àwọn kan lára wọn múra tán láti pàdánù ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn, owó wọn, kódà wọn ò kọ̀ káwọn aláṣẹ mú wọn nítorí kí wọ́n lè kó oúnjẹ tẹ̀mí wọ Ìlà Oòrùn Jámánì. Lálẹ́ ọjọ́ kan, a ò rí tọkọtaya kan tí à ń retí. Àwọn ọlọ́pàá rí àwọn ìwé táwọn tọkọtaya náà ń kó bọ̀, wọ́n sì gba ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ewu yìí, a ò ronú rẹ̀ rí pé ká dáwọ́ iṣẹ́ tí à ń ṣe dúró kí nǹkan lè dẹrùn fún wa díẹ̀.”
Àbúrò mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Manfred tó jẹ́ kí wọ́n rí wa mú lọ́dún 1950 sọ ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti tún ní ìgbàgbọ́ padà tí kò sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ náà yẹ̀ mọ́, ó ní: “Lẹ́yìn tí wọ́n ti jù mí sí àtìmọ́lé fún oṣù díẹ̀, mo ṣí lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì, mo sì fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀. Lọ́dún 1954, mo padà sí Ìlà Oòrùn Jámánì mo sì ṣègbéyàwó lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ìyàwó mi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1957. Ẹ̀rí ọkàn mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìyàwó mi, mo padà sínú ìjọ Kristẹni.”
Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Tìfẹ́tìfẹ́ làwọn arákùnrin tó ti mọ̀ mí kí n tó kúrò nínú òtítọ́ tẹ́wọ́ gbà mí, bí ẹni pé nǹkan ò ṣẹlẹ̀. Táwọn èèyàn bá kíni tẹ̀ríntẹ̀rín tí wọ́n sì gbáni mọ́ra, ó máa ń múnú ẹni dùn gan-an. Inú mi dùn pé mo tún lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà àti sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi.”
A Ò Jáwọ́ Nínú Ìjà Tẹ̀mí
Gbogbo wa nínú ìdílé wa ló ti jà fitafita nítorí ohun tá a gbà gbọ́. Àbúrò mi tó ń jẹ́ Peter sọ pé: “Lọ́jọ́ òní, ọ̀pọ̀ ohun tó lè pín ọkàn níyà àtàwọn nǹkan tara tó ń fani mọ́ra ti wá pọ̀ gan-an ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn. Bí àpẹẹrẹ, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó fẹ́ láti wà nínú àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan nítorí àǹfààní tara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́nì kankan nínú wa tó ráhùn pé àwọn ibi tá a ti lọ ń ṣèpàdé jìnnà jù tàbí pé à ń pẹ́ jù ká tó parí ìpàdé. Gbogbo wa la máa ń láyọ̀ nígbà tá a bá pàdé pọ̀, kódà bó tiẹ̀ gba pé káwọn kan lára wa dúró títí di aago mọ́kànlá alẹ́ kó tó kàn wọ́n láti kúrò níbi ìpàdé náà.”
Lọ́dún 1959, màmá wa sọ pé òun fẹ́ lọ máa gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì pẹ̀lú Sabine tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà yẹn. Nítorí pé àwọn méjèèjì nífẹ̀ẹ́ láti lọ máa wàásù níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run, ẹ̀ka ọ́fíìsì wá sọ pé kí wọ́n lọ sílùú kékeré kan tó ń jẹ́ Ellwangen, ní ìpínlẹ̀ Baden-Württemberg. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara Sabine kò fi bẹ́ẹ̀ le, ìtara tí màmá wa ní fún iṣẹ́ ìwàásù mú kó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nígbà tó pé ọmọ ọdún méjìdínlógún. Nígbà tí Sabine ṣègbéyàwó, màmá wa kọ́ bí wọ́n ṣe ń wakọ̀ lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta, kó bàa lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ó sì nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ yìí gan-an títí tó fi kú lọ́dún 1974.
Ní tèmi, lẹ́yìn tí mo ti lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́fà lára ọdún tí wọ́n dá fún mi pé kí n lọ fi ṣẹ̀wọ̀n lẹ́ẹ̀kejì, ìjọba ni kí n fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Jámánì lọ́dún 1965 láìjẹ́ kí ìdílé mi mọ̀. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìyàwó mi àti ọmọ mi fi kó wá bá mi. Mo kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti mọ̀ bóyá a lè lọ máa wàásù níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ sáwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run, ni wọ́n bá ní ká lọ sí àgbègbè Nördlingen, ní ìpínlẹ̀ Bavaria. Ibẹ̀ ni Ruth àti Johannes, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin, dàgbà sí. Ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àpẹẹrẹ rere rẹ̀ sì mú kí Ruth náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní gbàrà tó ṣe tán ní iléèwé. Aṣáájú-ọ̀nà làwọn ọmọ wa méjèèjì fẹ́. Àwọn náà ti ní ìdílé tiwọn báyìí, inú wa sì dùn gan-an pé a ní àwọn ọmọ ọmọ mẹ́fà tí wọ́n wuni.
Lọ́dún 1987, mo pinnu láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ kí n tó pé ọjọ́ orí tó yẹ kí n ṣe bẹ́ẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bíi ti Anni. Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n pè mí sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè Selters pé kí n wá ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ mímú ẹ̀ka náà gbòòrò sí i. Lẹ́yìn tí iṣẹ́ náà parí, a tún kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Glauchau, èyí tó jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Jámánì, wọ́n sì yan èmi àti aya mi láti máa bójú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà nígbà tó yá. Nítorí àìlera ara, a padà sọ́dọ̀ ọmọ wa obìnrin tó ń dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Nördlingen, ibẹ̀ la sì ti ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.
Mo láyọ̀ gan-an pé gbogbo àwọn àbúrò mi, àtèyí tó pọ̀ jù lọ lára ìdílé wa ṣì ń bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ àgbàyanu. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa ti kọ́ wa pé, níwọ̀n ìgbà tá a bá ti dúró gbọin nínú ìgbàgbọ́, ohun tó wà nínú Sáàmù 126:3 yóò jẹ́ ìpín wa, ẹsẹ náà sọ pé: “Jèhófà ti ṣe ohun ńlá nínú ohun tí ó ṣe fún wa. Àwa ti kún fún ìdùnnú.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ọjọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1957
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Èmi, màmá mi, àtàwọn àbúrò mi lọ́dún 1948; (iwájú, láti apá òsì sápá ọ̀tún) Manfred, Berta, Sabine, Hannelore, Peter; (ẹ̀yìn, láti apá òsì sápá ọ̀tún) èmi àti Jochen
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọ̀kan lára àwọn ìwé kékeré tí à ń lò lákòókò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa àti ẹ̀rọ táwọn ọlọ́pàá “Stasi” máa ń lò láti fi gbọ́ ọ̀rọ̀ téèyàn bá ń sọ
[Credit Line]
Forschungs- und Gedenkstätte NORMANNENSTRASSE
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Èmi àtàwọn àbúrò mi: (iwájú, láti apá òsì sápá ọ̀tún) Hannelore àti Sabine; (ẹ̀yìn, láti apá òsì sápá ọ̀tún) èmi, Jochen, Peter, àti Manfred