ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 2/1 ojú ìwé 22-30
  • Ẹ Túbọ̀ Máa Fi Ìmọrírì Hàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Túbọ̀ Máa Fi Ìmọrírì Hàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Dúpẹ́ Pé O Láǹfààní Láti Mọ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
  • Àwọn Èèyàn Tó Lẹ́mìí Ìmọrírì Ń Rọ́ Wá Sọ́dọ̀ Ọlọ́run
  • Ẹ Mọyì Bí Ọlọ́run Ṣe Mú Wa “Gbára Dì . . . fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”
  • Lo Ìwé Bíbélì Kọ́ni Lọ́nà Rere
  • Ẹ Máa Fi Ìmọrírì Hàn Nìṣó
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Tó Mọrírì Ìsapá Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Yin Jèhófà Lógo!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 2/1 ojú ìwé 22-30

Ẹ Túbọ̀ Máa Fi Ìmọrírì Hàn

“Àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o!”—SÁÀMÙ 139:17.

1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, báwo sì ni onísáàmù ṣe fi ìmọrírì hàn?

LÁKÒÓKÒ tí wọ́n ń ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n rí ohun kan tó jẹ́ ìyàlẹ́nu. Hilikáyà, Àlùfáà Àgbà, rí “ìwé òfin Jèhófà láti ọwọ́ Mósè,” ó sì dájú pé wọ́n ti ní láti kọ ìwé náà láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ọdún ṣáájú àkókò yẹn! Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára Jòsáyà Ọba tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run nígbà tí wọ́n gbé ìwé náà síwájú rẹ̀? Ó dájú pé ó mọyì rẹ̀ gan-an, ojú ẹsẹ̀ ló sì ní kí Ṣáfánì akọ̀wé kà á sókè ketekete.—2 Kíróníkà 34:14-18.

2 Lóde òní, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló láǹfààní àtika Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yálà ní odindi tàbí apá kan rẹ̀. Àmọ́ ṣe ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Ìwé Mímọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ níye lórí mọ́ ni, pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì mọ́? Rárá o! Ṣebí èrò Olódùmarè fúnra rẹ̀ ló wà nínú rẹ̀, fún àǹfààní wa. (2 Tímótì 3:16) Nígbà tí Dáfídì, ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù, ń sọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rí lára òun, ó kọ̀wé pé: “Lójú mi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o!”—Sáàmù 139:17.

3. Kí ló fi hàn pé Dáfídì jẹ́ ẹni tó mọyì àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run dáadáa?

3 Ìmọrírì tí Dáfídì ní fún Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ètò tó ṣe fún ìjọsìn tòótọ́ kò yingin rárá. Ọ̀pọ̀ sáàmù tó wúni lórí gan-an tí Dáfídì kọ fi bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ̀ hàn. Bí àpẹẹrẹ, nínú Sáàmù 27:4, ohun tó kọ ni pé: “Ohun kan ni mo béèrè lọ́wọ́ Jèhófà—ìyẹn ni èmi yóò máa wá, kí n lè máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa rí adùn Jèhófà kí n sì lè máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo tẹ́ńpìlì rẹ̀.” Nínú èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, gbólóhùn náà, “máa fi ẹ̀mí ìmọrírì wo” nǹkan túmọ̀ sí kéèyàn ṣàṣàrò lórí nǹkan fún àkókò gígùn, kó ṣàgbéyẹ̀wò nǹkan fínnífínní, kó wo nǹkan tayọ̀tayọ̀, tìdùnnú-tìdùnnú, àti pẹ̀lú ìmọrírì. Ó hàn gbangba pé Dáfídì jẹ́ ẹni tó mọyì àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run dáadáa, ó mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà pèsè fún un láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára, ó sì mọrírì gbogbo òtítọ́ tí Ọlọ́run ń ṣí payá fún un. Ó yẹ káwa náà máa fi ìmọrírì hàn bíi ti Dáfídì.—Sáàmù 19:7-11.

Máa Dúpẹ́ Pé O Láǹfààní Láti Mọ Ẹ̀kọ́ Bíbélì

4. Kí ló mú kí Jésù “ní ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́”?

4 Níní òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sinmi lé ọgbọ́n orí tàbí ọgbọ́n ayé yìí, èyí tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbéra ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sinmi lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sáwọn onírẹ̀lẹ̀, àwọn tó mọyì òtítọ́, tí àwọn ohun tí wọ́n ṣaláìní nípa tẹ̀mí sì ń jẹ lọ́kàn lójú méjèèjì. (Mátíù 5:3; 1 Jòhánù 5:20) Nígbà tí Jésù ronú lórí bí Ọlọ́run ṣe kọ orúkọ àwọn aláìpé èèyàn kan sílẹ̀ lọ́run, ó “ní ayọ̀ púpọ̀ nínú ẹ̀mí mímọ́, ó sì wí pé: ‘Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.’”—Lúùkù 10:17-21.

5. Kí nìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò fi gbọ́dọ̀ fojú yẹpẹrẹ wo òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run tá a ṣí payá fún wọn?

5 Lẹ́yìn tí Jésù gba àdúrà àtọkànwá yẹn tán, ó wá yíjú sáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tí ó rí àwọn ohun tí ẹ ń rí. Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ wòlíì àti àwọn ọba fẹ́ láti rí àwọn ohun tí ẹ ń rí ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn, àti láti gbọ́ àwọn ohun tí ẹ ń gbọ́ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ wọn.” Jésù gba àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe fojú yẹpẹrẹ wo ìmọ̀ tó ṣeyebíye nípa Ìjọba Ọlọ́run tá a ṣí payá fún wọn. Ọlọ́run kò ṣí òtítọ́ yìí payá fáwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣáájú ìgbà ayé Jésù, ó sì dájú pé kò ṣí i payá fáwọn “ọlọ́gbọ́n àti amòye” ìgbà ayé Jésù!—Lúùkù 10:23, 24.

6, 7. (a) Àwọn ìdí wo ló fi yẹ ká mọrírì òtítọ́ tí Ọlọ́run ṣí payá? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké lónìí?

6 Àkókò tiwa yìí gan-an ló yẹ ká mọyì òtítọ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, nítorí pé Jèhófà ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45; Dáníẹ́lì 12:10) Ohun tí wòlíì Dáníẹ́lì kọ nípa àkókò òpin yìí ni pé: “Ọ̀pọ̀ yóò máa lọ káàkiri, ìmọ̀ tòótọ́ yóò sì di púpọ̀ yanturu.” (Dáníẹ́lì 12:4) Àbí o kò gbà pé ìmọ̀ Ọlọ́run ti di “púpọ̀ yanturu” lóde òní àti pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí ní àjẹyó?

7 Ẹ ò rí i pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n ní ìmọ̀ tó pọ̀ nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé yàtọ̀ pátápátá sáwọn tó wà nínú ìdàrúdàpọ̀ ìsìn Bábílónì Ńlá! Nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn tí ìsìn èké ti já kulẹ̀ tàbí tí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ń kó nírìíra ló ń yíjú sí ìjọsìn tòótọ́ báyìí. Wọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn tí kò “fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú [Bábílónì Ńlá] nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,” tí kò sì “fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” Jèhófà àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń pe gbogbo irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n wá sínú ìjọ Kristẹni tòótọ́.—Ìṣípayá 18:2-4; 22:17.

Àwọn Èèyàn Tó Lẹ́mìí Ìmọrírì Ń Rọ́ Wá Sọ́dọ̀ Ọlọ́run

8, 9. Báwo ni ọ̀rọ̀ Hágáì 2:7 ṣe ń nímùúṣẹ lónìí?

8 Àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nípa ilé ìjọsìn rẹ̀ tẹ̀mí ni pé: “Èmi yóò sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá; èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí.” (Hágáì 2:7) Àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ àgbàyanu yìí nímùúṣẹ nígbà ayé Hágáì, nígbà táwọn àṣẹ́kù tó padà wálé lára àwọn èèyàn Ọlọ́run tún tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́. Lóde òní, ọ̀rọ̀ Hágáì yìí tún ń nímùúṣẹ sára tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tó jẹ́ ti Jèhófà.

9 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ti rọ́ wá sínú tẹ́ńpìlì ìṣàpẹẹrẹ náà kí wọ́n lè jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” Ọdọọdún sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” ń rọ́ wọlé. (Jòhánù 4:23, 24) Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdún 2006 jákèjádò ayé fi hàn pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé méjìdínláàádọ́ta, àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [248,327] èèyàn ló ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ti ya ìgbésí ayé àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Èyí sì jẹ́ nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgọ́rin [680] ẹni tuntun lójoojúmọ́! Ìfẹ́ tí wọ́n ní fún òtítọ́, àti fífẹ́ tí wọ́n fẹ́ láti sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run, fi hàn pé Ọlọ́run ló ń fà wọ́n lóòótọ́.—Jòhánù 6:44, 65.

10, 11. Sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé àwọn èèyàn mọrírì ẹ̀kọ́ Bíbélì.

10 Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọlọ́kàn tútù wọ̀nyí ló wá sínú òtítọ́ nítorí pé wọ́n rí “ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” (Málákì 3:18) Wo àpẹẹrẹ ti Wayne àti Virginia. Tọkọtaya ni wọ́n, ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì ni wọ́n sì ń lọ, àmọ́ wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí wọn ò rẹ́ni báwọn dáhùn. Wọ́n kórìíra ogun, nígbà tí wọ́n sì rí àwọn àlùfáà tí wọ́n ń gbàdúrà fáwọn sójà àtàwọn ohun ìjà wọn, èyí tojú sú wọn bẹ́ẹ̀ ló sì tún bà wọ́n lọ́kàn jẹ́. Bí àgbà ti ń dé sáwọn tọkọtaya yìí, wọ́n rí i pé àwọn èèyàn ó fi bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Virginia ti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wọ́n ní: “Kò sẹ́ni tó ń béèrè wa, kò tiẹ̀ sẹ́ni tó bìkítà nípa ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. Ohun tó ká wọn lára kò ju ọ̀rọ̀ owó lọ. Ọ̀ràn náà tojú sú wa.” Ìgbà tí ṣọ́ọ̀ṣì náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í fàyè gba ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ní gbogbo rẹ̀ wá sú wọn pátápátá.

11 Láàárín àkókò yẹn ni ọmọ ọmọ wọn obìnrin di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ọmọ wọn obìnrin náà sì tún dà á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Wayne àti Virginia ò kọ́kọ́ dùn sí èyí, nígbà tó yá, wọ́n yí èrò wọn padà, wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wayne sọ pé: “Ohun tá a kọ́ nípa Bíbélì láàárín oṣù mẹ́ta péré ju èyí tá a ti kọ́ ní ohun tó lé ní àádọ́rin ọdún lọ! A ò tíì gbọ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run rí, a ò sì mọ ohunkóhun nípa Ìjọba Ọlọ́run àti Párádísè orí ilẹ̀ ayé.” Kò pẹ́ rárá tí àwọn tọkọtaya tó jẹ́ ọlọ́kàn rere yìí bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé Kristẹni, tí wọ́n sì ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Virginia sọ pé: “A fẹ́ jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa òtítọ́.” Àwọn méjèèjì ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún báyìí, wọ́n sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2005. Wọ́n sọ pé: “A ti wá wà nínú agboolé Kristẹni báyìí.”

Ẹ Mọyì Bí Ọlọ́run Ṣe Mú Wa “Gbára Dì . . . fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo”

12. Kí ni Jèhófà máa ń pèsè fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè jàǹfààní nínú rẹ̀?

12 Jèhófà máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Nóà gba ìtọ́ni tó ṣe kedere nípa bó ṣe máa kan ọkọ̀ áàkì, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ tó gbọ́dọ̀ ṣe dáadáa! Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Kí ló mú kíyẹn ṣeé ṣe? Ìdí ni pé Nóà “bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:14-22) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, Jèhófà ń pèsè gbogbo ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nílò fún wọn kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Olórí iṣẹ́ wa ni pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, ká sì ran àwọn ọlọ́kàn rere lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Ìgbọràn ló máa mú káwa náà ṣàṣeyọrí bíi ti Nóà. A gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ọkàn tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

13. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń kọ́ wa?

13 Ká tó lè ṣe iṣẹ́ yẹn dójú àmì, a gbọ́dọ̀ kọ́ bá a ó ṣe fi “ọwọ́ títọ̀nà” mú olórí irin iṣẹ́ wa, ìyẹn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 2:15; 3:16, 17) Bíi ti ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà ń fún wa ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣeyebíye gan-an nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni. Lóde òní, Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú àwọn ìjọ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé àádọ́rin [99,770] jákèjádò ayé ń ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. Ǹjẹ́ o máa ń fi hàn pé o mọrírì àwọn ìpàdé pàtàkì wọ̀nyí nípa wíwá síbẹ̀ déédéé àti nípa fífi àwọn ohun tó ò ń kọ́ níbẹ̀ sílò?—Hébérù 10:24, 25.

14. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń fi hàn pé àwọn mọrírì àǹfààní sísìn táwọn ń sin Ọlọ́run? (Sọ̀rọ̀ lórí àtẹ ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 27 sí 30.)

14 Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn Ọlọ́run jákèjádò ayé ló ń fi hàn pé àwọn mọrírì ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń rí gbà nípa sísa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2006, àwọn mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé mọ́kànlélógójì, àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́rìnlélógójì [6,741,444] akéde Ìjọba Ọlọ́run lo àròpọ̀ bílíọ̀nù kan, mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rìndínláàádọ́rin, àti igba ó dín ẹyọ kan [1,333,966,199] wákàtí nínú gbogbo ọ̀nà tá a gbà ń ṣiṣẹ́ náà, títí kan ṣíṣe mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún, àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìdínlógún [6,286,618] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ péré lára àwọn ìròyìn tó ń fúnni níṣìírí tá a rí níbi tá a to ìròyìn jákèjádò ayé sí lẹ́sẹẹsẹ. Jọ̀wọ́ fara balẹ̀ wo ìròyìn yìí dáadáa lọ́nà tó máa gbà fún ọ níṣìírí gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ní ọ̀rúndún kìíní ṣe rí ìṣírí gbà látinú ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù tó ń gbòòrò sí i lákòókò tiwọn.—Ìṣe 1:15; 2:5-11, 41, 47; 4:4; 6:7.

15. Kí nìdí tí kò fi yẹ kí ẹnikẹ́ni rẹ̀wẹ̀sì nípa iṣẹ́ ìsìn tó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ ṣe fún Jèhófà?

15 Ìyìn tó ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run lọ́dọọdún fì hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọyì rẹ̀ gan-an pé àwọn láǹfààní láti mọ Jèhófà àti pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Aísáyà 43:10) Lóòótọ́, ẹbọ ìyìn tí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kan tí wọ́n jẹ́ arúgbó, àwọn tó ń ṣàìsàn tàbí àwọn tó jẹ́ aláìlera ń rú, lè dà bí owó táṣẹ́rẹ́ tí tálákà opó yẹn fi sínú àpótí ọrẹ. Síbẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ mọrírì gbogbo àwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, bí wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo ohun tágbára wọn gbé.—Lúùkù 21:1-4; Gálátíà 6:4.

16. Àwọn irin iṣẹ́ wo, tó ṣeé kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ni Ọlọ́run pèsè fún wa lákòókò tá a wà yìí?

16 Yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ tá à ń gbà ká lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, Jèhófà tún ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa láwọn irin iṣẹ́ àtàtà tá a ó máa lò láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, a ti ní àwọn ìwé bíi Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Èyí tá a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwọn tó mọyì àwọn ìwé wọ̀nyí máa ń lò wọ́n dáadáa lóde ẹ̀rí.

Lo Ìwé Bíbélì Kọ́ni Lọ́nà Rere

17, 18. (a) Nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí, apá ibo ló máa ń wù ọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni? (b) Kí ni alábòójútó àyíká kan kíyè sí nípa ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?

17 Níní tí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ní orí mọ́kàndínlógún, tó ní àfikún tí àlàyé rẹ̀ kún rẹ́rẹ́, tó tún jẹ́ ìwé tó yéni yékéyéké, tí èdè tí wọ́n lò nínú rẹ̀ sì rọrùn, mú kó wúlò gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. Bí àpẹẹrẹ, orí kejìlá sọ̀rọ̀ lórí kókó tó sọ pé, “Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn.” Àkòrí yìí jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ ọ̀nà tóun lè gbà di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ ohun kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fìgbà kan rí ronú pé ó ṣeé ṣe. (Jákọ́bù 2:23) Ojú wo làwọn èèyàn fi wo ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí?

18 Alábòójútó àyíká kan ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni “tètè máa ń fa àwọn èèyàn mọ́ra, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n fún wa láyè láti bá wọn jíròrò.” Ó fi kún un pé, ìwé náà rọrùn láti lò àti pé ó “ti jẹ́ kí ọkàn ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba Ọlọ́run túbọ̀ balẹ̀ láti wàásù, ayọ̀ wọn sì túbọ̀ pọ̀ sí i. Abájọ táwọn kan fi ń pe ìwé náà ní ohun iyebíye!”

19-21. Mẹ́nu kan àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ ká mọ bí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ṣe wúlò tó.

19 Obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Guyana sọ fún aṣáájú-ọ̀nà tó wá sílé rẹ̀ pé, “ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ló rán ọ.” Kò tíì pẹ́ tí ọkùnrin tí òun àti obìnrin yìí jọ ń gbé já obìnrin náà àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì sílẹ̀. Aṣáájú-ọ̀nà náà ṣí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni sí orí kìíní ó sì ka ìpínrọ̀ kọkànlá fún un, èyí tó wà lábẹ́ àkòrí kékeré náà “Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà ìrẹ́jẹ Táwọn Èèyàn Ń Hù?” Aṣáájú-ọ̀nà náà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí wọ̀ ọ́ lára gan-an. Kódà, ńṣe ló dìde, tó lọ sẹ́yìn ṣọ́ọ̀bù rẹ̀ lọ sunkún.” Obìnrin yìí gbà pé kí arábìnrin kan nítòsí wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, àtìgbà yẹn ló sì ti ń tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ náà.

20 Ìyàwó ọkùnrin kan tó ń jẹ́ José, tó ń gbé nílẹ̀ Sípéènì kú nínú jàǹbá ọkọ̀ kan. José wá bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró láti fi pa ìrònú rẹ́, ó tún wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó máa ń gbani nímọ̀ràn. Àmọ́ agbaninímọ̀ràn lórí ìrònú àti ìhùwàsí ẹ̀dá yìí kò lè dáhùn ìbéèrè tó ń jà gùdù lọ́kàn José. Ìbéèrè náà ni pé: “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìyàwó mi kú?” Lọ́jọ́ kan, José rí Francesc, tó ń bá ilé iṣẹ́ agbaninímọ̀ràn yẹn ṣiṣẹ́. Francesc dámọ̀ràn pé kó jẹ́ káwọn jíròrò orí kọkànlá ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?” Aláyé Ìwé Mímọ́ àti àpèjúwe olùkọ́ àti ọmọ ilé ìwé tó wà níbẹ̀ wọ José lọ́kàn gan-an. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ lójú méjèèjì nìyẹn, ó lọ sípàdé àyíká, ó sì ti ń wá sípàdé déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba báyìí.

21 Roman, tó jẹ́ ẹni ogójì ọdún, tó sì jẹ́ oníṣòwò nílẹ̀ Poland, máa ń bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ nítorí pé iṣẹ́ rẹ̀ máa ń jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ dí gan-an, kò fi bẹ́ẹ̀ tẹ̀ síwájú tó bó ṣe yẹ nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́. Síbẹ̀, ó wá sípàdé àgbègbè kan, ó sì gba ẹ̀dà kan ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Lẹ́yìn ìyẹn, kò fi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣeré mọ́. Roman ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, ó sì ń tẹ̀ síwájú gan-an.

Ẹ Máa Fi Ìmọrírì Hàn Nìṣó

22, 23. Báwo la ṣe lè máa bá a lọ láti fi hàn pé a mọrírì ìrètí tá a gbé ka iwájú wa?

22 Gẹ́gẹ́ bá a ti ṣàlàyé rẹ̀ nígbà ìpàdé àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!,” àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fojú sọ́nà de “ìdáǹdè àìnípẹ̀kun,” tí Ọlọ́run ṣèlérí tó sì máa mú kó ṣeé ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi táwọn èèyàn ta sílẹ̀. Ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé a mọrírì ìrètí ṣíṣeyebíye yìí tọkàntọkàn ni pé ká máa bá a lọ láti wẹ ara wa mọ́ “kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè.”—Hébérù 9:12, 14.

23 Láìsí àní-àní, iṣẹ́ ìyanu gbáà ló jẹ́ pé àwọn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà tí wọ́n jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba náà ń lo ìfaradà nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, nígbà táwọn ohun tó ń mú kéèyàn di onímọ̀-tara-ẹni nìkan túbọ̀ ń pọ̀ sí i nínú ayé yìí. Ó tún jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti máa sin Ọlọ́run, níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé “òpò [àwọn] kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.” Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa fi ìmọrírì wa hàn nìṣó!—1 Kọ́ríńtì 15:58; Sáàmù 110:3.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni onísáàmù fi kọ́ wa nípa bó ṣe yẹ ká mọrírì Ọlọ́run àtàwọn ohun tó ń pèsè fún wa nípa tẹ̀mí?

• Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Hágáì 2:7 ṣe ń nímùúṣẹ lóde òní?

• Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà pèsè gbogbo ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nílò kí wọ́n lè sìn ín bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

• Kí ló lè ṣe láti fi hàn pé o mọrírì oore Jèhófà?

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 27-30]

ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2006 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ

(Wo àdìpọ̀)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jèhófà ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́