ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 2/1 ojú ìwé 17-21
  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Tó Mọrírì Ìsapá Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Tó Mọrírì Ìsapá Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà San Èrè fún Ará Etiópíà Kan Tó Jẹ́ Olùbẹ̀rù Ọlọ́run
  • “Baba Rẹ Tí Ń Ríran ní Ìkọ̀kọ̀ Yóò San Án Padà fún Ọ”
  • “Àlùfáà Àgbà Tí Ó Jẹ́ Aláàánú àti Olùṣòtítọ́”
  • Túbọ̀ Máa Fi Ìmọrírì Rẹ Hàn!
  • Olùsẹ̀san fún Gbogbo Àwọn Tó Ń Sìn Ín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń fi Hàn Pé O Moore?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ Túbọ̀ Máa Fi Ìmọrírì Hàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 2/1 ojú ìwé 17-21

Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Tó Mọrírì Ìsapá Wa

“Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—HÉBÉRÙ 6:10.

1. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun mọrírì Rúùtù, tó wá láti ilẹ̀ Móábù?

JÈHÓFÀ mọrírì ìsapá àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn wá ọ̀nà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń san èrè tó pọ̀ gan-an fún wọn. (Hébérù 11:6) Bóásì, tó jẹ́ ọkùnrin olóòótọ́, mọ̀ nípa ànímọ́ rere tí Ọlọ́run ní yìí, ìdí nìyẹn tó fi sọ nípa rẹ̀ fún Rúùtù, tó wá láti ilẹ̀ Móábù, tó fìfẹ́ bójú tó ìyá ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ opó, pé: “Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà, kí owó ọ̀yà pípé sì wà fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Rúùtù 2:12) Ǹjẹ́ Ọlọ́run bù kún Rúùtù? Bẹ́ẹ̀ ni, ó bù kún un! Kódà, ìtàn rẹ̀ wà nínú Bíbélì! Yàtọ̀ síyẹn, ó fẹ́ Bóásì ó sì di ìyá ńlá Dáfídì Ọba àti Jésù Kristi. (Rúùtù 4:13, 17; Mátíù 1:5, 6, 16) Èyí jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo péré lára ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ inú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà máa ń fi mọrírì hàn fàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

2, 3. (a) Kí ló mú kí fífi tí Jèhófà ń fi ìmọrírì hàn fáwọn èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọni lójú gan-an? (b) Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe fún Jèhófà láti fi ojúlówó ìmọrírì hàn? Ṣàpèjúwe.

2 Aláìṣòdodo ni Jèhófà máa ka ara rẹ̀ sí tí kò bá fi ìmọrírì hàn. Ìwé Hébérù 6:10 sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” Ohun tó mú kí gbólóhùn yìí jọni lójú ni pé, Ọlọ́run máa ń mọrírì àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ti kùnà ògo rẹ̀.—Róòmù 3:23.

3 Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, a lè máa rò pé àwọn ohun tá à ń ṣe tó fi hàn pé à ń fọkàn sin Ọlọ́run ò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan, kò sì tó ohun tí Ọlọ́run lè tìtorí rẹ̀ bù kún wa. Àmọ́ Jèhófà mọ ohun tó wà lọ́kàn wa àti ipò tí olúkúlùkù wa wà, ó si mọyì iṣẹ́ ìsìn tá à ń fi gbogbo ọkàn wa ṣe. (Mátíù 22:37) Àpẹẹrẹ kan rèé: Ìyá kan rí ẹ̀bùn kan lórí tábìlì rẹ̀, ẹ̀gbà ọrùn kan tó jẹ́ olówó pọ́ọ́kú ni ẹ̀bùn náà. Ó tiẹ̀ lè kọ́kọ́ fojú pa ẹ̀bùn náà rẹ́ kó sì tì í sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Àmọ́, tí káàdì kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀bùn náà bá fi hàn pé ọmọ rẹ̀ obìnrin kékeré ló fi gbogbo owó tó ti ń tọ́jú pa mọ́ ra ẹ̀bùn náà fún un, ìyá yìí lè wá fojú tó yàtọ̀ wo ẹ̀bùn náà. Ó ṣeé ṣe kí omi bọ́ lójú rẹ̀ bó ṣe ń gbá ọmọ rẹ̀ mọ́ra, tó sì ń fi hàn pé òun mọrírì ẹ̀bùn náà gan-an.

4, 5. Báwo ni Jésù ṣe fara wé Jèhófà nínú fífi ìmọrírì hàn?

4 Jèhófà mọ ìdí tá a fi ń ṣe nǹkan àti ibi tágbára wa mọ, ìyẹn ló ń jẹ́ kó mọrírì rẹ̀ gan-an nígbà tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, yálà ó kéré tàbí ó pọ̀. Jésù fi bí Bàbá rẹ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ hàn lórí kókó yìí. Rántí ìtàn inú Bíbélì tó sọ nípa ọrẹ táṣẹ́rẹ́ tí opó aláìní kan mú wá. “Bí [Jésù] ti gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ń sọ ẹ̀bùn wọn sínú àwọn àpótí ìṣúra. Nígbà náà ni ó rí opó aláìní kan tí ó sọ ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an síbẹ̀, ó sì wí pé: ‘Lótìítọ́ ni mo sọ fún yín, Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé opó yìí jẹ́ òtòṣì, ó sọ sínú rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí sọ ẹ̀bùn sílẹ̀ láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n obìnrin yìí láti inú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé tí ó ní sínú rẹ̀.’”—Lúùkù 21:1-4.

5 Mímọ̀ tí Jésù mọ ipò tí obìnrin náà wà, tó mọ̀ pé opó ni, pé ó tún jẹ́ tálákà ló mú kí ẹ̀bùn rẹ̀ yẹn ṣe pàtàkì gan-an lójú rẹ̀, ìyẹn ló sì mú kó mọrírì rẹ̀ gan-an. Bí Jèhófà ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. (Jòhánù 14:9) Ǹjẹ́ kò wú ọ lórí láti mọ̀ pé ipò yòówù kó o wà, ó lè rí ojú rere Ọlọ́run wa tó lẹ́mìí ìmọrírì àti ojú rere Ọmọ rẹ̀?

Jèhófà San Èrè fún Ará Etiópíà Kan Tó Jẹ́ Olùbẹ̀rù Ọlọ́run

6, 7. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun mọrírì ohun tí Ebedi-mélékì ṣe, kí sì nìdí?

6 Léraléra la rí i nínú Ìwé Mímọ́ pé Jèhófà máa ń san èrè fún àwọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Wo ọ̀nà tó gbà bá Ebedi-mélékì, ará Etiópíà kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run lò. Ọkùnrin yìí gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Jeremáyà ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ ní agboolé Sedekáyà, Ọba Júdà tó jẹ́ aláìṣòótọ́. Ebedi-mélékì gbọ́ pé àwọn ọmọ ọba Júdà ti fi ẹ̀sùn èké kan wòlíì Jeremáyà pé ó ṣọ̀tẹ̀ síjọba, wọ́n sì ti jù ú sínú ìkùdu kan, kí ebi lè pa á kú síbẹ̀. (Jeremáyà 38:1-7) Níwọ̀n bí Ebedi-mélékì ti mọ̀ pé ohun tí Jeremáyà ń wàásù rẹ̀ ló mú káwọn èèyàn náà kórìíra rẹ̀, ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wewu, ó lọ bẹ ọba. Tìgboyàtìgboyà ni ará Etiópíà yìí fi sọ pé: “Olúwa mi ọba, àwọn ọkùnrin yìí ti ṣe ohun búburú nínú gbogbo ohun tí wọ́n ṣe sí Jeremáyà wòlíì, ẹni tí wọ́n sọ sínú ìkùdu, kí ó bàa lè kú sí ibi tí ó wà nítorí ìyàn náà.” Ọba wá pàṣẹ pé kí Ebedi-mélékì kó ọgbọ̀n ọkùnrin lọ síbẹ̀ kí wọ́n lè yọ wòlíì Ọlọ́run náà jáde.—Jeremáyà 38:8-13.

7 Jèhófà rí i pé Ebedi-mélékì ní ìgbàgbọ́, èyí tó mú kó lè borí ohunkóhun tí ì bá ti máa bà á lẹ́rù. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi hàn pé òun mọrírì ohun tí Ebedi-mélékì ṣe yìí gan-an, ó sì tipasẹ̀ Jeremáyà sọ fún un pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ sórí ìlú ńlá yìí ní ti ìyọnu àjálù kì í sì í ṣe fún rere, . . . Ṣe ni èmi yóò sì dá ọ nídè ní ọjọ́ yẹn, . . . a kì yóò sì fi ọ́ lé àwọn ènìyàn tí ìwọ ń fòyà wọn lọ́wọ́. Nítorí, láìkùnà, èmi yóò pèsè àsálà fún ọ . . . ; dájúdájú, ìwọ yóò sì ni ọkàn rẹ bí ohun ìfiṣèjẹ, nítorí pé o ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi.” (Jeremáyà 39:16-18) Láìsí àní-àní, Jèhófà kó Ebedi-mélékì àti Jeremáyà yọ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ọba Júdà tí wọ́n jẹ́ ẹni ibi àti lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì tó pa Jerúsálẹ́mù run. Sáàmù 97:10 sọ pé: “[Jèhófà] ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀; ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.”

“Baba Rẹ Tí Ń Ríran ní Ìkọ̀kọ̀ Yóò San Án Padà fún Ọ”

8, 9. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe fi hàn, irú àdúrà wo ni Jèhófà máa ń mọrírì rẹ̀?

8 Ẹ̀rí mìíràn tó tún fi hàn pé Jèhófà mọyì ìfọkànsìn wa la rí nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa àdúrà. Ọkùnrin ọlọgbọ́n nì sọ pé: “Àdúrà àwọn adúróṣánṣán jẹ́ ìdùnnú [Ọlọ́run].” (Òwe 15:8) Nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn ló máa ń gbàdúrà ní gbangba. Kì í ṣe pé wọ́n ní ojúlówó ẹ̀mí ìjọsìn o, ńṣe ni wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ káwọn èèyàn lè rí wọn. Jésù sọ pé: “Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún.” Ó wá fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé: “Ìwọ, bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.”—Mátíù 6:5, 6.

9 Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé Jésù ní kéèyàn má gbàdúrà ní gbangba o, ó ṣe tán, òun fúnra rẹ̀ gbàdúrà ní gbangba láwọn àkókò kan. (Lúùkù 9:16) Jèhófà máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an nígbà tá a bá gbàdúrà sí i látọkànwá, tí kì í ṣe pé a fẹ́ ṣe àṣehàn. Ká sòótọ́, àdúrà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń dá gbà jẹ́ ohun tá a fi máa ń mọ bí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú rẹ̀ ti jinlẹ̀ tó. Abájọ tí kò fi yẹ kó yà wá lẹ́nu rárá pé Jésù sábà máa ń wá ibi tóun ti máa dá gbàdúrà. Ìgbà kan wà tó ṣe èyí “ní kùtùkùtù òwúrọ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́.” Ní àkókò mìíràn, “ó gun òkè ńlá lọ ní òun nìkan láti gbàdúrà.” Kí Jésù tó yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó fi gbogbo òru gbàdúrà ní òun nìkan.—Máàkù 1:35; Mátíù 14:23; Lúùkù 6:12, 13.

10. Nígbà táwọn àdúrà wa bá fi òótọ́ inú hàn, àti fífẹ́ tá a fẹ́ láti múnú Ọlọ́run dùn, ìdánilójú wo la lè ní?

10 Ó dájú pé Jèhófà ti ní láti fetí sílẹ̀ dáadáa sáwọn ọ̀rọ̀ tí Ọmọ rẹ̀ ń sọ látọkànwá yẹn! Kódà, àwọn ìgbà mìíràn wà tí Jésù gbàdúrà “pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Hébérù 5:7; Lúùkù 22:41-44) Tí àdúrà wa bá fi irú òótọ́ inú bẹ́ẹ̀ hàn, àti fífẹ́ tá a fẹ́ láti múnú Ọlọ́run dùn, kí ó dá wa lójú pé Baba wa ọ̀run ń tẹ́tí sí àdúrà náà dáadáa, ó sì mọrírì rẹ̀ gan-an. Láìsí àní-àní, “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn . . . tí ń ké pè é ní òótọ́.”—Sáàmù 145:18.

11. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ohun tá a bá ṣe níkọ̀kọ̀?

11 Bí Jèhófà bá mọrírì rẹ̀ nígbà tá a bá gbàdúrà sí i níkọ̀kọ̀, ẹ ò rí i pé yóò mọrírì rẹ̀ gan-an nígbà tá a bá ṣègbọràn sí i níkọ̀kọ̀! Dájúdájú, Jèhófà rí ohun tá a bá ṣe níkọ̀kọ̀. (1 Pétérù 3:12) Àní, jíjẹ́ tá a bá jẹ́ olóòótọ́ tá a sì ń ṣègbọràn nígbà tá a bá dá nìkan wà, ń fi hàn pé a ní “ọkàn-àyà pípé pérépéré” sí Jèhófà, ìyẹn ọkàn tó mọ́ tó sì múra tán láti ṣe ohun tó tọ́. (1 Kíróníkà 28:9) Irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń múnú Jèhófà dùn gan-an!—Òwe 27:11; 1 Jòhánù 3:22.

12, 13. Báwo la ṣe lè dáàbò bo èrò inú àti ọkàn wa ká sì dà bíi Nàtáníẹ́lì tó jẹ olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn?

12 Látàrí èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ tó lè ba èrò inú àti ọkàn èèyàn jẹ́, irú bíi wíwo àwòrán oníhòòhò àti ìwà ipá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan lè má hàn sáwọn èèyàn, a mọ̀ pé “ohun gbogbo wà ní ìhòòhò àti ní ṣíṣísílẹ̀ gbayawu fún ojú ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13; Lúùkù 8:17) Tá a bá ń sapá láti yẹra fún àwọn ohun tínú Jèhófà kò dùn sí, a ó ní ẹ̀rí ọkàn tó dára, inú wa yóò sì máa dùn nítorí mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá. Kò sí iyèméjì rárá pé Jèhófà máa ń mọrírì ẹni “tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Sáàmù 15:1, 2.

13 Àmọ́ o, báwo la ṣe lè dáàbò bo èrò inú àti ọkàn wa nínú ayé tó kún fún ìwà búburú yìí? (Òwe 4:23; Éfésù 2:2) Láfikún sí lílo gbogbo ohun tí Jèhófà ń pèsè kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára, a tún gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti yàgò fún ohun búburú ká sì máa ṣe ohun tó dára. A tún ní láti máa gbé ìgbésẹ̀ kíá kí àwọn èrò òdì má bàá di èyí tó gbilẹ̀ lọ́kàn wa, tí yóò sì wá bí ẹ̀ṣẹ̀. (Jákọ́bù 1:14, 15) Ronú nípa bínú rẹ ṣe máa dùn tó ká ní ìwọ ni Jésù sọ ohun tó sọ fún Nàtáníẹ́lì yẹn fún pé: “Wò ó, [ọkùnrin kan] nínú ẹni tí ẹ̀tàn kankan kò sí.” (Jòhánù 1:47) Nàtáníẹ́lì yìí, tó tún ń jẹ́ Bátólómíù, wá ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀, ó di ọkàn lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá tí Jésù ní.—Máàkù 3:16-19.

“Àlùfáà Àgbà Tí Ó Jẹ́ Aláàánú àti Olùṣòtítọ́”

14. Báwo ni ojú tí Jésù fi wo ẹ̀mí ọ̀làwọ́ Màríà ṣe yàtọ̀ sí ojú tàwọn yòókù fi wò ó?

14 Nítorí pé Jésù jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí,” gbogbo ìgbà ló máa ń fara wé Baba rẹ̀ nínú fífi ìmọrírì hàn fún àwọn tó ń fi ọkàn tó mọ́ tónítóní sin Ọlọ́run. (Kólósè 1:15) Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọjọ́ márùn-ún ṣáájú ọjọ́ tí Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀, Símónì ará Bẹ́tánì gba òun àti díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lálejò sílé rẹ̀. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Màríà, tó jẹ́ arábìnrin Lásárù àti Màtá, “mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì, olówó iyebíye gan-an” (tí iye rẹ̀ tó owó iṣẹ́ ọdún kan), ó sì dà á sí orí àti ẹsẹ̀ Jésù. (Jòhánù 12:3) Àwọn kan wá sọ pé: “Kí ní fa ìfiṣòfò yìí?” Àmọ́ ojú tí Jésù fi wo ẹ̀mí ọ̀làwọ́ Màríà yìí yàtọ̀ pátápátá. Ó kà á sí ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ga tó sì ṣe pàtàkì gan-an fún ikú òun àti ìsìnkú òun tó ti sún mọ́lé. Nítorí náà, dípò kí Jésù bá Màríà wí, ńṣe ló gbóríyìn fún un. Ó ní: “Ibikíbi tí a bá ti wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, ohun tí obìnrin yìí ṣe ni a ó sọ pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”—Mátíù 26:6-13.

15, 16. Àǹfààní wo la rí nínú gbígbé tí Jésù gbé lórí ilẹ̀ ayé tó sì tún sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí èèyàn?

15 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé irú ẹni tó lẹ́mìí ìmọrírì bẹ́ẹ̀ ni Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa! Ká sòótọ́, ìgbésí ayé Jésù gẹ́gẹ́ bí èèyàn múra rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ tí Jèhófà ní lọ́kàn fún un, ìyẹn ni iṣẹ́ Àlùfáà Àgbà àti jíjẹ́ tó máa jẹ́ Ọba lórí ìjọ àwọn ẹni àmì òróró lákọ̀ọ́kọ́, àti lẹ́yìn náà, lórí gbogbo ayé.—Kólósè 1:13; Hébérù 7:26; Ìṣípayá 11:15.

16 Kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé, ó ti ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ọmọ aráyé, ó sì fẹ́ràn wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. (Òwe 8:31) Gbígbé tó gbé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn túbọ̀ wá mú kó mọ̀ nípa àwọn àdánwò tá a ń fojú winá rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó di dandan fún [Jésù] láti dà bí ‘àwọn arákùnrin’ rẹ̀ lọ́nà gbogbo, kí ó lè di àlùfáà àgbà tí ó jẹ́ aláàánú àti olùṣòtítọ́ . . . Nítorí níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ ti jìyà nígbà tí a ń dán an wò, ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn tí a ń dán wò.” Ó ṣeé ṣe fún Jésù láti “báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa” nítorí pé ó jẹ́ ẹni tí “a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bí àwa fúnra wa, ṣùgbọ́n tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.”—Hébérù 2:17, 18; 4:15, 16.

17, 18. (a) Kí làwọn lẹ́tà Jésù sáwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré fi hàn nípa bí Jésù ti mọrírì àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó? (b) Kí lohun tá a múra àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró sílẹ̀ dè?

17 Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó wá túbọ̀ hàn pé ó mọrírì àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nítorí àwọn àdánwò tí wọ́n ń fojú winá rẹ̀. Ronú lórí lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ìjọ méje tó wà ní Éṣíà Kékeré, èyí tí àpọ́sítélì Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀. Ohun tí Jésù sọ fún ìjọ tó wà ní Símínà ni pé: “Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ.” Lẹ́nu kan, ohun tí Jésù ń sọ níbí yìí ni pé, ‘mo lóye àwọn ìṣòro rẹ dáadáa; mo mọ ohun tó ò ń fojú winá rẹ̀.’ Níwọ̀n bí òun fúnra rẹ̀ sì ti jìyà títí dojú ikú, ó láàánú. Pẹ̀lú ìdánilójú ló sì fi sọ pé: “Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.”—Ìṣípayá 2:8-10.

18 Àwọn lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ìjọ méjèèje náà kún fún àwọn ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé Jésù mọ gbogbo ìṣòro táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń dojú kọ, ó sì mọrírì ìdúróṣinṣin wọn gan-an. (Ìṣípayá 2:1–3:22) Rántí pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀, ìyẹn àwọn tó nírètí láti bá a ṣàkóso lókè ọ̀run. Bíi ti Olúwa wọn, a ti múra wọn sílẹ̀ láti kó ipa pàtàkì nínú fífi àánú ṣèrànwọ́ lọ́nà tó ga, láti mú kí àwọn àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ aráyé tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.—Ìṣípayá 5:9, 10; 22:1-5.

19, 20. Báwo làwọn tó máa di ogunlọ́gọ̀ ńlá ṣe ń fi ìmọrírì wọn hàn sí Jèhófà àti sí Ọmọ rẹ̀?

19 Láìsí àní-àní, ìfẹ́ tí Jésù ní sáwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tún nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn ti wà ní sẹpẹ́ báyìí láti di “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀ já. (Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 7:9, 14) Àwọn wọ̀nyí ń rọ́ wá sọ́dọ̀ Jésù nítorí pé wọ́n mọrírì ẹbọ ìràpadà rẹ̀ àti nítorí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n ní. Báwo ni wọ́n ṣe ń fi ìmọrírì wọn hàn? Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.”—Ìṣípayá 7:15-17.

20 Ìròyìn iṣẹ́ ìsìn ọdún 2006 jákèjádò ayé, èyí tó wà ní ojú ìwé 27 sí 30, fún wa ní ẹ̀rí tó dájú pé lóòótọ́ làwọn òjíṣẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyí ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Jèhófà] tọ̀sán-tòru.” Àní, láàárín ọdún kan yẹn, àwọn àgùntàn mìíràn wọ̀nyí àti díẹ̀ tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lo àpapọ̀ bílíọ̀nù kan, mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé mẹ́rìndínláàádọ́rin, àti igba ó dín ẹyọ kan [1,333,966,199] wákàtí lórí iṣẹ́ ìwàásù, iye wákàtí yẹn sì jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́jọ ó lé méjì, àti igba ó lé mẹ́tàlélọ́gọ́rin [152,283] ọdún!

Túbọ̀ Máa Fi Ìmọrírì Rẹ Hàn!

21, 22. (a) Lórí ọ̀ràn fífi ìmọrírì hàn, kí nìdí táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ wà lójúfò lóde òní? (b) Kí la ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

21 Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ti fi ìmọrírì tó ga gan-an hàn nínú àjọṣe àárín àwọn àtàwọn èèyàn aláìpé. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn èèyàn ni kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa Ọlọ́run, tó jẹ́ pé nǹkan ti ara wọn ni wọ́n ń gbájú mọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ irú ìwà táwọn èèyàn tó ń gbé ayé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí yóò máa hù, ó kọ̀wé pé: “Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn gan-an, wọ́n á ní ojúkòkòrò owó. . . Wọn ò ní í ní ẹ̀mí ìmoore rárá.” (2 Tímótì 3:1-5, Phillips) Ẹ ò rí i pé àwọn yẹn yàtọ̀ pátápátá sí àwọn Kristẹni tòótọ́, tí wọ́n ń tipasẹ̀ àdúrà àtọkànwá, ìgbọràn tinútinú, àti iṣẹ́ ìsìn tọkàntọkàn, fi hàn pé àwọn mọyì gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn!—Sáàmù 62:8; Máàkù 12:30; 1 Jòhánù 5:3.

22 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a ó ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ti fìfẹ́ nawọ́ rẹ̀ sí wa. Bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ‘ẹ̀bùn rere’ wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí ìmọrírì wa máa jinlẹ̀ sí i.—Jákọ́bù 1:17.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ Ọlọ́run tó ń mọrírì àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

• Nígbà tá a bá dá wà, báwo la ṣe lè múnú Jèhófà dùn?

• Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi ìmọrírì hàn?

• Báwo ni gbígbé tí Jésù gbé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn ṣe ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ alákòóso tó láàánú tó sì mọrírì àwọn olóòótọ́ èèyàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bíi ti òbí rere, Jèhófà máa ń mọrírì rẹ̀ gan-an nígbà tá a bá ṣe gbogbo ohun tágbára wa ká

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́