ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 4/1 ojú ìwé 17-20
  • Bá A Ṣe Lè Máa Rú Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Máa Rú Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọrẹ Ẹbọ Àtàwọn Ẹbọ Nínú Ìjọsìn Tòótọ́
  • “Ohun Tí Èmi Kò Pa Láṣẹ”
  • Ẹbọ Ìràpadà Tí Kristi Jésù Fi Ara Rẹ̀ Rú
  • Àwọn Ẹbọ àti Ọrẹ Ẹbọ Tẹ̀mí
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú ‘Kókó Òtítọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àwọn Ẹbọ Ìyìn Tí Inú Jèhófà Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ṣé Wàá Yááfì Àwọn Nǹkan Torí Ìjọba Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 4/1 ojú ìwé 17-20

Bá A Ṣe Lè Máa Rú Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí

“INÚ ikú ni ìwàláàyè ti máa ń wá. Èyí ni ìgbàgbọ́ àwọn kan tí wọ́n ń pè ní Aztec tí wọ́n máa ń fi èèyàn rúbọ gan-an lọ́nà tá ò rí irú rẹ̀ rí nílẹ̀ Mesoamerica ayé ọjọ́un.” Ìwé kan tó ń jẹ́ The Mighty Aztecs ló sọ bẹ́ẹ̀. Ìwé náà tún sọ pé: “Bí ilẹ̀ táwọn Aztec ń ṣàkóso lé lórí ti ń gbòòrò sí i, fífi èèyàn rúbọ ló ń fi àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ́kàn balẹ̀.” Ìwé mìíràn sọ pé, iye èèyàn táwọn Aztecs fi ń rúbọ lọ́dún tó ọ̀kẹ́ kan [20,000].

Látìgbà táwọn èèyàn ti wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n ti ń rú onírúurú ẹbọ sáwọn òrìṣà wọn. Ìbẹ̀rù àti àìníbàlẹ̀ ọkàn tàbí ẹ̀rí ọkàn wọn tó ń dá wọ́n lẹ́bi ló ń mú kí wọ́n máa rú àwọn ẹbọ náà. Bíbélì sọ pé àwọn ẹbọ kan wà tí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè ní ká máa rú. Nítorí náà, ó yẹ́ ká béèrè pé: Irú àwọn ẹbọ wo ni inú Ọlọ́run dùn sí? Ṣé ó yẹ kí ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ jẹ́ apá kan ìjọsìn wa lónìí?

Àwọn Ọrẹ Ẹbọ Àtàwọn Ẹbọ Nínú Ìjọsìn Tòótọ́

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì di orílẹ̀-èdè, Jèhófà fún wọn nítọ̀ọ́ni tó ṣe kedere nípa ọ̀nà tó fẹ́ kí wọ́n máa gbà jọ́sìn òun, ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ sì wà lára ìjọsìn náà. (Númérì, orí 28 àti 29) Àwọn nǹkan ọ̀gbìn wà lára àwọn ọrẹ ẹbọ tí wọ́n máa ń mú wá; àwọn yòókù jẹ́ ẹran, irú bí akọ màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, ẹyẹlé, àti oriri. (Léfítíkù 1:3, 5, 10, 14; 23:10-18; Númérì 15:1-7; 28:7) Àwọn ọrẹ ẹbọ kan wà tó jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ ni wọ́n máa ń fi iná sun pátápátá. (Ẹ́kísódù 29:38-42) Àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ tún wà, èyí tó jẹ́ pé àwọn tó rú u máa ń jẹ lára ohun tí wọ́n fi rúbọ sí Ọlọ́run.—Léfítíkù 19:5-8.

Lábẹ́ òfin Mósè, gbogbo àwọn ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ tí wọ́n máa ń rú sí Ọlọ́run jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn rẹ̀ tí wọ́n sì ń fi hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ńṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oore rẹ̀ àti ààbò rẹ̀ lórí wọn, wọ́n sì tún ń rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Tí wọ́n bá ti ń ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà là sílẹ̀ yìí tọkàntọkàn nínú ìjọsìn wọn, ó máa ń bù kún wọn lọ́pọ̀lọpọ̀.—Òwe 3:9, 10.

Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà ni ìwà àwọn tó ń rú àwọn ẹbọ náà. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Hóséà sọ pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni mo ní inú dídùn sí, kì í sì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun.” (Hóséà 6:6) Nítorí ìdí yìí, nígbà táwọn èèyàn náà kẹ̀yìn sí ìjọsìn tòótọ́ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla tí wọ́n sì ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Jèhófà di èyí tí kò wúlò. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi ní kí Aísáyà sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Àǹfààní kí ni ògìdìgbó àwọn ẹbọ yín jẹ́ fún mi? . . . Odindi ọrẹ ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa ti tó mi gẹ́ẹ́; èmi kò sì ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti òbúkọ.”—Aísáyà 1:11.

“Ohun Tí Èmi Kò Pa Láṣẹ”

Ohun táwọn ará Kénáánì ṣe burú ju tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Ní ti àwọn ará Kénáánì, ọmọ wọn ni wọ́n fi máa ń rúbọ sáwọn òrìṣà wọn, títí kan òrìṣà Ámónì tó ń jẹ́ Mólékì. (1 Àwọn Ọba 11:5, 7, 33; Ìṣe 7:43) Ìwé kan tó ń jẹ́ Halley’s Bible Handbook sọ pé: “Lílọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ ni àwọn ará Kénáánì fi máa ń ṣe ìjọsìn, wọ́n máa ń fi ṣe ààtò ìsìn níwájú òrìṣà wọn; wọ́n sì tún máa ń pa àkọ́bí wọn fi rúbọ sí àwọn òrìṣà yẹn.”

Ǹjẹ́ inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sáwọn nǹkan wọ̀nyẹn? Rárá o. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ wọ ilẹ̀ Kénáánì, Jèhófà pàṣẹ fún wọn nínú Léfítíkù 20:2, 3 pé: “Ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ọkùnrin èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti àtìpó èyíkéyìí tí ń ṣe àtìpó ní Ísírẹ́lì, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Mólékì, kí a fi ikú pa á láìkùnà. Kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. Ní tèmi, èmi yóò dojú mi kọ ọkùnrin yẹn, èmi yóò sì ké e kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó ti fi àwọn kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ fún Mólékì fún ète sísọ ibi mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin àti láti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.’”

Ẹ ò rí i pé ó yani lẹ́nu púpọ̀ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan tí wọ́n yapa kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù yìí, tí wọ́n ń fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sáwọn ọlọ́run èké. Sáàmù 106:35-38 sọ nípa èyí pé: “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ń kọ́ àwọn iṣẹ́ wọn. Wọ́n sì ń sin òrìṣà wọn, ìwọ̀nyí sì wá jẹ́ ìdẹkùn fún wọn. Wọn a sì máa fi àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù. Tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ṣáá, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn àti ti àwọn ọmọbìnrin wọn, àwọn tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì; ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì wá sọ ilẹ̀ náà di eléèérí.”

Nígbà tí Jèhófà ń sọ bí ohun tí wọ́n ṣe yìí ti kó òun nírìíra tó, ó lo wòlíì rẹ̀ Jeremáyà láti sọ nípa àwọn ọmọ Júdà pé: “Wọ́n ti gbé àwọn ohun ìríra wọn kalẹ̀ sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Wọ́n sì ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hínómù, láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná, ohun tí èmi kò pa láṣẹ tí kò sì wá sínú ọkàn-àyà mi.”—Jeremáyà 7:30, 31.

Nítorí pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe irú àwọn nǹkan burúkú bẹ́ẹ̀, wọ́n pàdánù ojú rere Ọlọ́run. Àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Ísírẹ́lì run níkẹyìn, wọ́n sì kó àwọn èèyàn náà lọ sígbèkùn ní Bábílónì. (Jeremáyà 7:32-34) A rí i kedere pé fífi èèyàn rúbọ kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ, kì í sì í ṣe apá kan ìjọsìn mímọ́. Àwọn ẹ̀mí èṣù ló ń mú kí àwọn èèyàn máa fi èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn rúbọ, àwọn olùjọsìn Ọlọ́run kì í lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó jẹ́ mọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Ẹbọ Ìràpadà Tí Kristi Jésù Fi Ara Rẹ̀ Rú

Àmọ́, àwọn kan lè béèrè pé, ‘Kí wá nìdí tí Òfin Jèhófà fi ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ẹran rúbọ?’ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ronú lórí ìbéèrè yìí, ó sì fún wa ní ìdáhùn yìí pé: “Ti Òfin ti wá jẹ́? A fi kún un láti mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere, títí irú-ọmọ tí a ṣe ìlérí fún yóò fi dé . . . Nítorí náà, Òfin ti di akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi.” (Gálátíà 3:19-24) Fífi ẹran rúbọ, èyí tí Òfin Mósè pa láṣẹ, ṣàpẹẹrẹ ẹbọ tó tóbi jù lọ tí Jèhófà Ọlọ́run yóò fi Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi rú nítorí ọmọ aráyé. Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn yìí nígbà tó sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Nítorí pé Jésù tó jẹ́ ẹni pípe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aráyé, ó fínnú-fíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti ra àwọn ọmọ Ádámù padà. (Róòmù 5:12, 15) Jésù sọ pé: “Ọmọ ènìyàn . . . wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan lórí ilẹ̀ ayé tó lè ra aráyé padà nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí Ádámù tà wá sí. (Sáàmù 49:7, 8) Nípa bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Jésù “wọlé sínú ibi mímọ́, rárá, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé, ó sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa.” (Hébérù 9:12) Nígbà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹ̀jẹ̀ Jésù yìí, Ọlọ́run “pa ìwé àfọwọ́kọ tí ó lòdì sí wa rẹ́.” Ìyẹn ni pé Jèhófà kò nílo májẹ̀mú Òfin àtàwọn ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ mọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ‘ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun.’—Kólósè 2:14; Róòmù 6:23.

Àwọn Ẹbọ àti Ọrẹ Ẹbọ Tẹ̀mí

Níwọ̀n bí ọrẹ ẹbọ àti ẹbọ tá à ń fi ẹran rú kò ti jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́ mọ́, ǹjẹ́ ẹbọ èyíkéyìí tiẹ̀ wà tí a ní láti máa rú lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. Jésù Kristi yọ̀ǹda ara rẹ̀ pátápátá fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run, ó sì wá fi ara rẹ̀ rúbọ fún aráyé níkẹyìn. Ìdí rèé tó fi sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Èyí túmọ̀ sí pé ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ fi àwọn nǹkan kan rúbọ. Kí ni àwọn nǹkan náà?

Ọ̀kan lára wọn ni pé ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ kò wà láàyè fún ìfẹ́ ti ara rẹ̀ mọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run ló gbọ́dọ̀ máa ṣe nígbèésí ayé rẹ̀. Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló máa ń fi sípò àkọ́kọ́ kì í ṣe ìfẹ́ ti ara rẹ̀. Wo bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, ó ní: “Mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run pàrọwà fún yín, ẹ̀yin ará, pé kí ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín. Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”—Róòmù 12:1, 2.

Láfikún sí i, Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ ìyìn látẹnu wa jẹ́ ẹbọ́ kan tá à ń rú sí Jèhófà. Wòlíì Hóséà lo gbólóhùn náà “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa,” tó ń fi hàn pé Ọlọ́run ka ìyìn tó ń tẹnu wa jáde sí ọ̀kan lára àwọn ẹbọ tó dára jù lọ. (Hóséà 14:2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Hébérù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Lóde òní, ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n ń rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run tọ̀sán tòru jákèjádò ayé.—Ìṣípayá 7:15.

Láfikún sí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe, ṣíṣe ohun rere fáwọn èèyàn tún wà lára àwọn ẹbọ tí inú Ọlọ́run dùn sí. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé, “Ẹ má gbàgbé rere ṣíṣe àti ṣíṣe àjọpín àwọn nǹkan pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀ ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.” (Hébérù 13:16) Lóòótọ́, kí inú Ọlọ́run tó lè dùn sí àwọn ẹbọ ìyìn tí à ń rú, àwọn tó ń rú ẹbọ náà gbọ́dọ̀ máa hùwà tó dára. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa hùwà lọ́nà tí ó yẹ ìhìn rere nípa Kristi.”—Fílípì 1:27; Aísáyà 52:11.

Bíi ti ìgbà àtijọ́, gbogbo ẹbọ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi ń ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́ lónìí máa ń fún wọn láyọ̀ gan-an, yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti máa rú àwọn ẹbọ tí inú Ọlọ́run dùn sí gan-an!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

‘Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn àtàwọn ọmọbìnrin wọn rúbọ sí àwọn òrìṣà Kénáánì’

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń rú àwọn ẹbọ tí inú Ọlọ́run dùn sí nípa wíwàásù ìhìn rere àti nípa ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́