ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Ìlànà tó wà fún onírúurú ọrẹ (1-31)

        • Ọrẹ ojoojúmọ́ (1-8)

        • Ọrẹ ọjọ́ Sábáàtì (9, 10)

        • Ọrẹ oṣooṣù (11-15)

        • Ẹbọ Ìrékọjá (16-25)

        • Ọrẹ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (26-31)

Nọ́ńbà 28:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 8:13; Ne 10:32, 33

Nọ́ńbà 28:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:38; Le 6:9; Isk 46:15

Nọ́ńbà 28:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:39

Nọ́ńbà 28:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.

  • *

    Òṣùwọ̀n hínì kan jẹ́ Lítà 3.67. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:40; Nọ 15:4

Nọ́ńbà 28:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:38, 42; 2Kr 2:4; Ẹsr 3:3

Nọ́ńbà 28:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:39, 40

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 6/2019, ojú ìwé 6

Nọ́ńbà 28:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láàárín ìrọ̀lẹ́ méjèèjì.”

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:41

Nọ́ńbà 28:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 16:29; 20:10; Isk 20:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 77

Nọ́ńbà 28:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 28:3, 7

Nọ́ńbà 28:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn oṣù yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:10; 1Kr 23:31; 2Kr 2:4; Ne 10:32, 33

Nọ́ńbà 28:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:11
  • +Le 1:10

Nọ́ńbà 28:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:10, 13

Nọ́ńbà 28:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 15:8, 10
  • +Nọ 15:6, 7
  • +Nọ 15:5

Nọ́ńbà 28:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:14; Le 23:5; Di 16:1; Isk 45:21; 1Kọ 5:7

Nọ́ńbà 28:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:15; Le 23:6; 1Kọ 5:8

Nọ́ńbà 28:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:20, 22; Di 15:21

Nọ́ńbà 28:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:1

Nọ́ńbà 28:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “búrẹ́dì.”

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Nọ́ńbà 28:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:6
  • +Ẹk 12:16; Le 23:8; Di 16:8

Nọ́ńbà 28:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:16
  • +Le 23:15, 16
  • +Ẹk 34:22; Di 16:10; Iṣe 2:1
  • +Le 23:16, 21

Nọ́ńbà 28:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:16, 18

Nọ́ńbà 28:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:16, 19

Nọ́ńbà 28:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:3

Àwọn míì

Nọ́ń. 28:22Kr 8:13; Ne 10:32, 33
Nọ́ń. 28:3Ẹk 29:38; Le 6:9; Isk 46:15
Nọ́ń. 28:4Ẹk 29:39
Nọ́ń. 28:5Ẹk 29:40; Nọ 15:4
Nọ́ń. 28:6Ẹk 29:38, 42; 2Kr 2:4; Ẹsr 3:3
Nọ́ń. 28:7Ẹk 29:39, 40
Nọ́ń. 28:8Ẹk 29:41
Nọ́ń. 28:9Ẹk 16:29; 20:10; Isk 20:12
Nọ́ń. 28:10Nọ 28:3, 7
Nọ́ń. 28:11Nọ 10:10; 1Kr 23:31; 2Kr 2:4; Ne 10:32, 33
Nọ́ń. 28:12Le 2:11
Nọ́ń. 28:12Le 1:10
Nọ́ń. 28:13Le 1:10, 13
Nọ́ń. 28:14Nọ 15:8, 10
Nọ́ń. 28:14Nọ 15:6, 7
Nọ́ń. 28:14Nọ 15:5
Nọ́ń. 28:16Ẹk 12:14; Le 23:5; Di 16:1; Isk 45:21; 1Kọ 5:7
Nọ́ń. 28:17Ẹk 12:15; Le 23:6; 1Kọ 5:8
Nọ́ń. 28:19Le 22:20, 22; Di 15:21
Nọ́ń. 28:20Le 2:1
Nọ́ń. 28:25Ẹk 13:6
Nọ́ń. 28:25Ẹk 12:16; Le 23:8; Di 16:8
Nọ́ń. 28:26Ẹk 23:16
Nọ́ń. 28:26Le 23:15, 16
Nọ́ń. 28:26Ẹk 34:22; Di 16:10; Iṣe 2:1
Nọ́ń. 28:26Le 23:16, 21
Nọ́ń. 28:27Le 23:16, 18
Nọ́ń. 28:30Le 23:16, 19
Nọ́ń. 28:31Le 1:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 28:1-31

Nọ́ńbà

28 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Kí ẹ rí i pé ẹ mú ọrẹ mi wá, oúnjẹ mi. Kí ẹ máa mú àwọn ọrẹ àfinásun mi tó máa mú òórùn dídùn* jáde fún mi wá ní àkókò rẹ̀.’+

3 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ọrẹ àfinásun tí ẹ máa mú wá fún Jèhófà nìyí: kí ẹ máa mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá wá lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ sísun nígbà gbogbo.+ 4 Kí o mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan wá ní àárọ̀, kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́,*+ 5 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí wọ́n pò mọ́ òróró tí wọ́n fún tó jẹ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* láti fi ṣe ọrẹ ọkà.+ 6 Ẹbọ sísun ìgbà gbogbo+ ni, èyí tí a fi lélẹ̀ ní Òkè Sínáì láti mú òórùn dídùn* jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, 7 pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀, ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kọ̀ọ̀kan. Da ohun mímu tó ní ọtí náà sínú ibi mímọ́ láti fi ṣe ọrẹ ohun mímu fún Jèhófà. 8 Kí o sì mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì wá ní ìrọ̀lẹ́.* Kí o fi ṣe ọrẹ àfinásun tó ń mú òórùn dídùn*+ jáde sí Jèhófà, pẹ̀lú ọrẹ ọkà kan náà tí o mú wá láàárọ̀ àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀.

9 “Àmọ́, ní ọjọ́ Sábáàtì,+ kí ọrẹ náà jẹ́ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá àti ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀. 10 Èyí ni ẹbọ sísun ti Sábáàtì, pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ+ ohun mímu rẹ̀.

11 “‘Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kọ̀ọ̀kan,* kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ara wọn dá ṣáṣá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ wá láti fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, 12 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà  + fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà fún àgbò+ náà, 13 pẹ̀lú ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan, láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn*+ jáde, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 14 Kí ọrẹ ohun mímu wọn jẹ́ wáìnì ìdajì òṣùwọ̀n hínì fún akọ màlúù+ kan àti ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì fún àgbò+ náà àti ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ kan. Èyí ni ẹbọ sísun oṣooṣù fún oṣù kọ̀ọ̀kan, jálẹ̀ ọdún. 15 Bákan náà, kí ẹ mú ọmọ ewúrẹ́ kan wá láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí Jèhófà, ní àfikún sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀.

16 “‘Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní ni kó jẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá+ sí Jèhófà. 17 Tó bá sì di ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù yìí, àjọyọ̀ máa wà. Ọjọ́ méje+ ni kí ẹ fi jẹ búrẹ́dì aláìwú. 18 Àpéjọ mímọ́ máa wà ní ọjọ́ kìíní. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19 Kí ẹ fi akọ ọmọ màlúù méjì, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan rú ẹbọ sísun, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. Àwọn ẹran tí ara wọn dá ṣáṣá+ ni kí ẹ mú wá. 20 Kí ẹ mú wọn wá pẹ̀lú ọrẹ ọkà wọn, ìyẹn ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró,+ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà. 21 Kí o mú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n wá fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà 22 àti ewúrẹ́ kan tí o máa fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún yín. 23 Kí ẹ mú ìwọ̀nyí wá yàtọ̀ sí ẹbọ sísun àárọ̀, èyí tó wà lára ẹbọ sísun ìgbà gbogbo. 24 Bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ ṣe máa mú nǹkan wọ̀nyí wá ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ méje láti fi ṣe oúnjẹ,* ọrẹ àfinásun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà. Kí ẹ fi rúbọ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ohun mímu rẹ̀. 25 Ní ọjọ́ keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára+ kankan.

26 “‘Ní ọjọ́ àkọ́pọ́n èso,+ tí ẹ bá mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Jèhófà,+ kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe àsè àwọn ọ̀sẹ̀.+ Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára+ kankan. 27 Kí ẹ mú akọ ọmọ màlúù méjì wá pẹ̀lú àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ láti fi rú ẹbọ sísun tó ń mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, 28 pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan, ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún àgbò náà, 29 ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà, 30 pẹ̀lú ọmọ ewúrẹ́ kan láti ṣe ètùtù fún yín.+ 31 Kí ẹ fi wọ́n rúbọ ní àfikún sí ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ọkà rẹ̀. Pẹ̀lú àwọn ọrẹ ohun mímu wọn, kí àwọn ẹran+ náà jẹ́ èyí tí ara wọn dá ṣáṣá.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́