18 Kí ẹ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá àti ọmọ akọ màlúù kan àti àgbò+ méjì, kí ẹ mú wọn wá pẹ̀lú àwọn búrẹ́dì náà. Kí ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí Jèhófà pẹ̀lú ọrẹ ọkà wọn àti ọrẹ ohun mímu wọn, kó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà tó ń mú òórùn dídùn jáde.