ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/1 ojú ìwé 14-18
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tọ́ Ìṣísẹ̀ Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tọ́ Ìṣísẹ̀ Rẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Fìtílà fún Ẹsẹ̀ Mi”
  • “Ìmọ́lẹ̀ sí Òpópónà Mi”
  • Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìtọ́sọ́nà Jèhófà
  • Báwo Lo Ṣe Máa Ń Ṣèpinnu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tànmọ́lẹ̀ Sí Òpópónà Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bá Ìfẹ́ Ọlọ́run Mu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Bá A Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dáa
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/1 ojú ìwé 14-18

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tọ́ Ìṣísẹ̀ Rẹ

“Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—SÁÀMÙ 119:105.

1, 2. Kí nìdí tí kò fi ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láti rí ojúlówó àlàáfíà àti ayọ̀?

ǸJẸ́ o rántí ìgbà kan tó di dandan kó o béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹnì kan? Ó ṣeé ṣe kó o ti máa sún mọ́ ibi tó ò ń lọ àmọ́ ibi tó o máa yà sí kò dá ọ lójú. Ó sì lè jẹ́ pé o tiẹ̀ ti ṣìnà pátápátá tó o sì ní láti padà síbi tó o ti ń bọ̀. Èyí tó wù kó jẹ́, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu kó o tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ẹnì kan tó mọ àgbègbè náà dáadáa? Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti débi tó ò ń lọ.

2 Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn lọmọ aráyé ti ń gbìyànjú láti tọ́ ara wọn sọ́nà láìwá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Àmọ́ àwọn ẹ̀dá èèyàn tí wọ́n jẹ́ aláìpé ti ṣìnà pátápátá nítorí pé wọn ò fi ti Ọlọ́run ṣe. Kò ṣeé ṣe fún wọn rárá láti mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà rí ojúlówó àlááfíà àti ayọ̀. Kí nìdí tí kò fi ṣeé ṣe? Lóhun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì àtààbọ̀ [2,500] sẹ́yìn, wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti tọ́ ara rẹ̀ sọ́nà láìgba ìrànlọ́wọ́ ẹni tó mọ̀ jù ú lọ yóò dá ara rẹ̀ lẹ́bi ṣáá ni. Ká sòótọ́, ọmọ aráyé nílò ìtọ́sọ́nà!

3. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó kúnjú ìwọ̀n jù lọ láti fún ọmọ aráyé ní ìtọ́sọ́nà, ìlérí wo ló sì ṣe?

3 Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó kúnjú ìwọ̀n jù lọ láti fún wa nírú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ ẹ̀dá èèyàn dáadáa ju ẹnikẹ́ni lọ. Ó sì tún mọ ohun tó mú kí ọmọ aráyé ṣìnà tí wọ́n sì sọnù pátápátá. Bákan náà ló tún mọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè padà sójú ọ̀nà tó tọ́. Kì í ṣèyẹn nìkan, nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, gbogbo ìgbà ló mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní. (Aísáyà 48:17) Ìdí nìyí tó fi yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa gba ìlérí tó wà nínú Sáàmù 32:8 gbọ́, èyí tó sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Ó dájú pé Jèhófà ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó dára jù lọ. Àmọ́ báwo gan-an ló ṣe ń tọ́ wa sọ́nà?

4, 5. Báwo làwọn ohun tí Ọlọ́run sọ ṣe lè tọ́ wa sọ́nà?

4 Ọ̀kan lára àwọn tó kọ sáàmù sọ nínú àdúrà rẹ̀ sí Jèhófà pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Àwọn ohun tí Ọlọ́run sọ àtàwọn ìránnilétí rẹ̀ wà nínú Bíbélì wọ́n sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tá a lè bá pàdé nígbèésí ayé wa. Ká sòótọ́, nígbà tá a bá ka Bíbélì tá a sì jẹ́ kóhun tó wà nínú rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, ohun tó wà nínú ìwé Aísáyà 30:21 ló ń ṣẹ sí wa lára yẹn. Ó ní: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.’”

5 Àmọ́ kíyè sí i pé, ohun méjì tó tan mọ́ra wọn ni Sáàmù 119:105 sọ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ṣe. Èkíní, ó jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa. Nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ìṣòro tó ń yọjú lójoojúmọ́, ó yẹ káwọn ìlànà inú Bíbélì darí ìṣísẹ̀ wa ká bàa lè ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání ká sì lè yàgò fáwọn ewu inú ayé yìí. Èkejì, àwọn ìránnilétí Ọlọ́run ń tànmọ́lẹ̀ sójú ọ̀nà wa, ó ń jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìrètí wa mu, ìyẹn ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Tí ọ̀nà tá à ń tọ̀ bá mọ́lẹ̀ kedere, á ṣeé ṣe fún wa láti mọ ibi tí ohun kan tá a fẹ́ dáwọ́ lé yóò yọrí sí, yálà sí rere tàbí sí búburú. (Róòmù 14:21; 1 Tímótì 6:9; Ìṣípayá 22:12) Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ ṣàyẹ̀wò bí ohun tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì ṣe lè jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa àti ìmọ́lẹ̀ sójú ọ̀nà wa.

“Fìtílà fún Ẹsẹ̀ Mi”

6. Inú àwọn ipò wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lè jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa?

6 Ojoojúmọ́ là ń ṣèpinnu. Àwọn ìpinnu kan lè dà bí èyí tí kò tó nǹkan. Àmọ́ ìgbà míì wà tá a lè bára wa nípò tó lè mú ká fẹ́ lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, ká hùwà àìṣòótọ́, tàbí ká lọ́wọ́ sí ìṣèlú. Ká tó lè borí irú àwọn ìdánwò bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ “kọ́ agbára ìwòye [wa] láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Tá a bá ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì lóye àwọn ìlànà inú rẹ̀, ńṣe là ń kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa ká lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn.—Òwe 3:21.

7. Sọ ohun kan tó lè mú kí Kristẹni kan fẹ́ bá àwọn ará ibi iṣẹ́ rẹ̀ tí wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ kẹ́gbẹ́.

7 Wo àpẹẹrẹ kan. Ṣé àgbàlagbà ni ọ́ tó ò ń sa gbogbo ipá rẹ láti múnú Jèhófà dùn? (Òwe 27:11) Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká gbóríyìn fún ọ. Àmọ́ ká sọ pé àwọn kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pè ọ́ síbi ayẹyẹ kan ńkọ́? Inú wọn máa ń dùn nígbà tẹ́ ẹ bá jọ wa níbi iṣẹ́, wọ́n sì tún fẹ́ kẹ́ ẹ jọ wà pa pọ̀ nígbà tẹ́ ò sí níbi iṣẹ́. Nínú ọkàn rẹ, o lè gbà pé àwọn ẹni yìí kì í ṣe èèyànkéèyàn. Kódà, wọ́n lè ní àwọn ìwà kan tó dára. Kí ni wàá ṣe? Tó o bá gbà láti lọ, ǹjẹ́ ó lè ṣàkóbá fún ọ? Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́ nínú ọ̀ràn yìí?

8. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti ronú lórí ọ̀ràn bíbá àwọn èèyàn kẹ́gbẹ́?

8 Wo àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ kan. Èyí tó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ wá síni lọ́kàn ni èyí tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:33 tó sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” Ṣé títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí túmọ̀ sí pé kó o pa àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tì pátápátá ni? Ìwé Mímọ́ dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó ṣe tán, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ fìfẹ́ hàn sí “ènìyàn gbogbo,” títí kan àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 9:22) Ìsìn Kristẹni fúnra rẹ̀ sì pà á láṣẹ pé ká fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, títí kan àwọn tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí tiwa. (Róòmù 10:13-15) Ká sòótọ́, báwo la ṣe máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ pé ká “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn” tá a bá ń yẹra fáwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ wa?—Gálátíà 6:10.

9. Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Bíbélì tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́?

9 Àmọ́ ṣá o, ìyàtọ̀ díẹ̀ kọ́ ló wà láàárín ṣíṣe dáadáa sẹ́nì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àti ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Apá ibí yìí gan-an ni ìlànà Ìwé Mímọ́ mìíràn ti jẹ mọ́ ọ̀ràn náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 6:14) Kí ni ìtúmọ̀ gbólóhùn náà, “má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́”? Ọ̀nà táwọn Bíbélì mìíràn gbà tú gbólóhùn yìí ni: “má ṣe dára rẹ pọ̀ mọ́,” “má ṣe gbìyànjú láti bá kẹ́gbẹ́,” tàbí “jáwọ́ nínú bíbá ẹni tí kò yẹ ṣọ̀rẹ́.” Ìgbà wo gan-an ni bíbá ẹnì kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ṣọ̀rẹ́ lè di ohun tí kò bójú mu? Ìgbà wo gan-an ló di ohun tí kò bá Bíbélì mu tó sì di fífi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú wọn? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn Bíbélì, lè tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ lórí kókó yìí.

10. (a) Báwo ni Jésù ṣe yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọ irú àwọn tó yẹ kó bá kẹ́gbẹ́?

10 Wo àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látìgbà tí Ọlọ́run ti dá wọn. (Òwe 8:31) Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sún mọ́ra gan-an. (Jòhánù 13:1) Kódà, ó “ní ìfẹ́ fún” ọkùnrin kan tó rò pé ọ̀nà tóun ń gbà sin Ọlọ́run tọ̀nà. (Máàkù 10:17-22) Àmọ́ Jésù mọ àwọn tó yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́. Kò ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí kò fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Nígbà kan, Jésù sọ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín.” (Jòhánù 15:14) Lóòótọ́, ìwọ àtẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lè mọwọ́ ara yín. Àmọ́ bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ẹni yìí múra tán láti ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ? Ǹjẹ́ ó fẹ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà, ẹni tí Jésù kọ́ wa pé ká máa sìn? Ǹjẹ́ ó ń tẹ̀ lé irú àwọn ìlànà tí èmi tí mo jẹ́ Kristẹni ń tẹ̀ lé ní ti irú ìwà tó yẹ ká máa hù?’ (Mátíù 4:10) Bó o ti ń bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ tó o sì ń jẹ́ kó mọ̀ pé o ò lè yà kúrò lórí àwọn ìlànà Bíbélì, wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

11. Sọ àwọn ipò tó ti yẹ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ ìṣísẹ̀ wa.

11 Ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn ló tún máa ń ṣẹlẹ̀ tó lè mú kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bíi fìtílà sí ẹsẹ̀ wa. Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan tó ti ń wáṣẹ́ gan-an lè wá rí iṣẹ́ kan. Àmọ́ iṣẹ́ ọ̀hún yóò máa gba àkókò àti okun rẹ̀, bó bá sì gbà láti ṣe é, kò ní lè máa wá sípàdé déédéé, bẹ́ẹ̀ ni kò ní lè máa kópa nínú àwọn nǹkan mìíràn tó jẹ mọ́ ìjọsìn tòótọ́. (Sáàmù 37:25) Ó sì lè máa wu Kristẹni mìíràn gan-an láti wo eré tó mọ̀ dájú pé kò bá ìlànà Bíbélì mu. (Éfésù 4:17-19) Bẹ́ẹ̀ ni Kristẹni mìíràn sì lè jẹ́ ẹni tó tètè máa ń bínú nítorí kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀. (Kólósè 3:13) Nínú gbogbo àwọn ipò yìí, ó yẹ ká jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa. Ó dájú pé bá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, yóò ṣeé ṣe fún wa láti lè kojú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú nígbèésí ayé wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.”—2 Tímótì 3:16.

“Ìmọ́lẹ̀ sí Òpópónà Mi”

12. Lọ́nà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí ojú ọ̀nà wa?

12 Sáàmù 119:105 tún sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè tànmọ́lẹ̀ sí ojú ọ̀nà wa, yóò jẹ́ kí ọ̀nà tó wà níwájú wa mọ́lẹ̀ kedere. Àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kò ṣókùnkùn sí wa, nítorí pé Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí táwọn nǹkan ìbànújẹ́ tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi ń ṣẹlẹ̀ àtohun tó máa gbẹ̀yìn wọn. Dájúdájú, a mọ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú yìí la wà báyìí. (2 Tímótì 3:1-5) Ó yẹ kí mímọ̀ tá a mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú nípa lórí ọ̀nà tá à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa báyìí. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!”—2 Pétérù 3:11, 12.

13. Báwo ló ṣe yẹ kí mímọ̀ tá a mọ̀ pé òpin kò ní pẹ́ dé nípa lórí bá a ṣe ń ronú àti bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa?

13 Ó yẹ kí ìrònú wa àti ọ̀nà tá à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé a gbà lóòótọ́ pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (1 Jòhánù 2:17) Fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò á jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu nípa àwọn ohun tá a fẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jésù yìí nípa fífi iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún ṣe ohun tí wọ́n ń lépa! Àwọn mìíràn, títí kan odindi ìdílé, ti yọ̀ọ̀da ara wọn tinútinú wọ́n sì ti kó lọ sáwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run.

14. Báwo ni ìdílé kan ṣe túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?

14 Wo ìdílé kan tí wọ́n lọ́mọ méjì tí wọ́n sì ṣí kúrò nílẹ̀ Amẹ́ríkà lọ sórílẹ̀-èdè Dominican Republic láti lọ ran ìjọ kan lọ́wọ́. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] èèyàn ló ń gbé nílùú tí ìjọ náà wà. Nǹkan bí àádóje [130] akéde Ìjọba Ọlọ́run ló sì wà nínú ìjọ náà. Síbẹ̀, lọ́jọ́ kejìlá oṣù April ọdún 2006, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún dín légbèje [1,300] èèyàn ló wà níbi Ìrántí ikú Kristi! Pápá àgbègbè náà “funfun fún kíkórè” débi pé, lẹ́yìn oṣù márùn-ún péré, bàbá yìí, màmá yìí, àti ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin ti ń darí ọgbọ̀n ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Jòhánù 4:35) Bàbá náà ṣàlàyé pe: “Ọgbọ̀n arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ṣí wá láti ibòmíràn láti ṣèrànwọ́ ló wà nínú ìjọ wa. Nǹkan bí ogún lára wọn wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn yòókù sì wá láti orílẹ̀-èdè Bahamas, Kánádà, Ítálì, New Zealand, àti ilẹ̀ Sípéènì. Bí wọ́n ṣe ń dé, ara wọn ti wà lọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù, èyí sì jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ wu àwọn arákùnrin tó wà nínú ìjọ yìí.”

15. Àwọn ìbùkún wo lo ti rí nítorí pé o fi Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé rẹ?

15 A mọ̀ pé kò ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ lára wa láti ṣí lọ sórílẹ̀-èdè mìíràn ká sì lọ sìn níbi tá a ti nílò ọ̀pọ̀ oníwàásù. Àmọ́, ó dájú pé àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn tó lè yí ipò wọn padà láti ṣe bẹ́ẹ̀, yóò rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà bí wọ́n ti ń kópa nínú ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn yìí. Ibikíbi tó sì wù kó o ti máa sìn, má ṣe jẹ́ kí ayọ̀ tó yẹ kó o ní tó o bá fi gbogbo agbára rẹ sin Jèhófà bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́. Bó o bá fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé rẹ, Jèhófà ṣèlérí pé òun á ‘tú ìbùkún dà sórí rẹ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’—Málákì 3:10.

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Ìtọ́sọ́nà Jèhófà

16. Ọ̀nà wo la ó gbà jàǹfààní tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ wa sọ́nà?

16 Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i, ọ̀nà méjì tó bára wọn tan làwọn ọ̀rọ̀ tó tẹnu Jèhófà jáde ń gbà tọ́ wa sọ́nà. Wọ́n dà bíi fìtílà sí ẹsẹ̀ wa, nítorí pé wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà tó tọ́, wọ́n sì ń tọ́ wa sọ́nà tá a bá fẹ ṣèpinnu. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún ń tànmọ́lẹ̀ sójú ọ̀nà wa, nítorí pé ó ń jẹ́ ká rí ohun tó wà níwájú kedere. Èyí sì ń jẹ́ ká lè máa fi ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Pétérù sọ sílò, ó ní: “Ẹ mú èrò inú yín gbára dì fún ìgbòkègbodò, ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré; ẹ gbé ìrètí yín ka inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a óò mú wá fún yín nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.”—1 Pétérù 1:13.

17. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?

17 Kò sí iyèméjì rárá pé Jèhófà ń tọ́ wa sọ́nà. Àmọ́ ìbéèrè tó wà níbẹ̀ ni pé, Ṣé wàá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀? Tó o bá fẹ́ lóye ìtọ́sọ́nà tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, pinnu láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Ṣàṣàrò lórí ohun tó o bá kà, gbìyànjú láti mọ ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lórí àwọn nǹkan, kó o sì ronú lórí oríṣiríṣi ọ̀nà tó o lè gbà fi ohun tó o bá kà sílò nígbèésí ayé rẹ. (1 Tímótì 4:15) Lẹ́yìn náà, lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ nígbà tó o bá ń ṣèpinnu.—Róòmù 12:1.

18. Tá a bá ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí wa, àwọn ìbùkún wo la máa rí?

18 Tá a bá jẹ́ káwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa darí wa, wọ́n á máa jẹ́ ká ní òye, wọ́n á sì máa fún wa ní ìtọ́sọ́nà tá a nílò nígbà tá a bá ń ṣe ìpinnu nípa ọ̀nà tó dára tó yẹ ká tọ̀. Ó yẹ ká fọkàn balẹ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì máa ń mú kí “aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sáàmù 19:7) Tá a bá ń jẹ́ kí Bíbélì tọ́ wa sọ́nà, a óò ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ a ó sì máa láyọ̀ nítorí pé à ń múnú Jèhófà dùn. (1 Tímótì 1:18, 19) Tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ ìṣísẹ̀ wa lójoojúmọ́, Jèhófà yóò fún wa ní ìbùkún tó ga jù lọ, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run máa darí ìṣísẹ̀ wa?

• Ọ̀nà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè gbà jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ wa?

• Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè jẹ́ ìmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa?

• Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìgbà wo ni bíbá ẹni tí kì í ṣe onígbàgbọ́ kẹ́gbẹ́ jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn tó ń ṣèfẹ́ Jèhófà ni Jésù fi ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ǹjẹ́ bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa fi hàn pé à ń fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́