Báwo Lo Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bá Ìfẹ́ Ọlọ́run Mu?
LỌ́JỌ́ kan, ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà mú ṣẹ́ẹ̀kì tí iye tí wọ́n kọ sórí rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n dọ́là [$25,000] lọ sí báńkì. Ó fẹ́ fi owó náà pa mọ́ síbẹ̀ di àkókò kan pàtó kí èlé jaburata lè gorí ẹ̀. Àmọ́, akọ̀wé tó ń gbowó wọlé ní báńkì gbà á nímọ̀ràn pé kó lọ gbé owó náà fún àjọ tó máa ń fi owó dókòwò, pé bó ti wù kó rí okòwò náà kò ní jẹ́ kówó náà bà jẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́. Ló bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ akọ̀wé yìí. Àmọ́ láìpẹ́ sígbà yẹn, okòwò tí àjọ náà fowó ọ̀hún ṣe ba owó ọ̀hún jẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin yìí fi hàn pé kò rọrùn láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Onírúurú ìpinnu míì tá a máa ń ṣe tí kò jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ òwò ńkọ́? Ọ̀pọ̀ ìpinnu téèyàn ń ṣe lè yọrí sí rere tàbí kó má yọrí sí rere, ó sì lè yọrí sí ìyè tàbí ikú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, kí ló lè mú kó dá wa lójú pé ìpinnu ọlọgbọ́n là ń ṣe?
“Èyí Ni Ọ̀nà”
Ojoojúmọ́ là ń ṣe ìpinnu lórí irú oúnjẹ tá a máa jẹ, aṣọ tá a máa wọ̀, ibi tá a máa lọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó lè dà bíi pé àwọn ìpinnu kan ò ṣe pàtàkì, síbẹ̀ àbájáde rẹ̀ lè burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá pinnu láti dán sìgá wò fúngbà àkọ́kọ́, ó lè wá di bárakú sí i lára kó má lè fi í sílẹ̀ mọ́. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kékeré wo ipa tí àwọn ìpinnu kan tá a rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì lè ní lórí wa.
Ta lẹni tó lè tọ́ wa sọ́nà nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu, títí kan ìpinnu tá a rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì? Á mà dára gan-an o tá a bá rí ẹni tó ṣeé gbára lé tó lè máa fún wa nímọ̀ràn tá a bá fẹ́ ṣèpinnu tó ta kókó! Irú agbaninímọ̀ràn bẹ́ẹ̀ wà. Ìwé àtayébáyé kan tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ wúlò fún wa lónìí sọ pé: “Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” (Aísáyà 30:21) Ta lẹni tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn? Báwo ló sì ṣe lè dá ọ lójú pé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ṣeé gbára lé?
Inú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ ìdánilójú tá a fà yọ lókè yìí wà. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì ti rí i pé ó ní ìmísí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa. (2 Tímótì 3:16, 17) Kò sí nǹkan tí Jèhófà ò mọ̀ nípa àwa ẹ̀dá èèyàn, nítorí náà òun lẹni tó lè tọ́ wa sọ́nà lọ́nà tó dára jù lọ. Ó tún mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí pé òun ni “ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe; Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró.’” (Aísáyà 46:10) Onísáàmù kan gbẹ́kẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìyẹn ló mú kó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Síbẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà kó lè ṣeé ṣe fún wa láti gúnlẹ̀ sébùúté ayọ̀ nínú agbami ayé tí ìṣòro kúnnú rẹ̀ yìí? Báwo la ṣe lè ṣe ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu?
Máa Tẹ̀ Lé Ìlànà Bíbélì
Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni ní ìlànà kí wọ́n lè máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Kíkọ́ àwọn ìlànà Bíbélì àti fífi wọ́n sílò dà bí ìgbà téèyàn bá ń kọ́ èdè tó sì ń lo èdè ọ̀hún. Téèyàn bá ti gbọ́ èdè náà dáadáa, kì í ṣòro láti mọ ìgbà tẹ́nì kan ò bá sọ èdè náà bó ṣe yẹ. Ó ṣeé ṣe kó o má lè sọ òfin èdè tí ẹni náà kò tẹ̀ lé ní pàtó, àmọ́ wàá ṣáà mọ̀ pé kò sọ ọ́ dáadáa. Tó o bá ti kọ́ àwọn ìlànà Bíbélì débi pé o ti mọ bó ṣe yẹ kó o máa lò wọ́n, ó máa ń rọrùn láti mọ ìgbà tí ìpinnu kan ò bá tọ̀nà tí kò sì bá ìlànà Ọlọ́run mu.
Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin kan fẹ́ pinnu irú irun tóun fẹ́ gẹ̀. Òótọ́ ni pé kò síbi tí Bíbélì ti ṣòfin pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ gẹ irú irun kan. Síbẹ̀, ronú nípa ìlànà Bíbélì yìí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” (1 Tímótì 2:9, 10) Àwọn obìnrin ni Pọ́ọ̀lù ń bá sọ̀rọ̀ níbí, àmọ́ ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan tọkùnrin tobìnrin. Kí ni ìlànà yìí? Òun ni pé ìrísí wa ní láti fi hàn pé a jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà àtẹni tó yè kooro ní èrò inú. Torí náà ọ̀dọ́kùnrin yẹn lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé irun tí mo fẹ́ gẹ̀ á fi mí hàn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tó jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà?’
Ọmọlẹ́yìn náà Jákọ́bù sọ pé: “Ẹ̀yin panṣágà obìnrin, ẹ kò ha mọ̀ pé ìṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ayé jẹ́ ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọ́run? Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Ìlànà tó wúlò wo ni ọ̀dọ́ kan lè fà yọ látinú ọ̀rọ̀ Jákọ́bù yẹn? Ó dájú pé àwọn Kristẹni ò ní fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé lọ́nàkọnà nítorí pé ayé jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. Ǹjẹ́ tí ọ̀dọ́kùnrin yìí bá lọ gẹ irú irun táwọn ojúgbà rẹ̀ fẹ́ràn láti máa gẹ̀, ṣé ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ló máa jọ ni tàbí ọ̀rẹ́ ayé? Ọ̀dọ́kùnrin yìí tó ń ronú nípa irú irun tó fẹ́ gẹ̀ lè lo irú àwọn ìlànà tá a gbé ka Bíbélì wọ̀nyí láti ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Bẹ́ẹ̀ ni, ìlànà Bíbélì ń ràn wá lọ́wọ́ nínú ìpinnu ṣíṣe. Tó bá sì ti mọ́ wa lára láti máa lo ìlànà Bíbélì tá a bá ń ṣèpinnu, á rọrùn fún wa láti máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tí kò ní kó wa sí wàhálà tó bá yá.
Ọ̀pọ̀ ìlànà ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lóòótọ́ o, a lè má rí ẹsẹ Bíbélì tó sọ ohun tó yẹ ká ṣe lórí ọ̀rọ̀ kan ní pàtó. Àmọ́ a lè rí ìtàn àwọn tí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run àti tàwọn tí wọn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7, 13-16; Diutarónómì 30:15-20; 1 Kọ́ríńtì 10:11) Tá a bá ka àwọn ìtàn wọ̀nyẹn tá a sì ronú lórí àbájáde ìpinnu tí wọ́n ṣe, a óò róye àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó máa múnú Ọlọ́run dùn.
Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ kúkúrú tó wáyé láàárín Jésù Kristi àti Pétérù àpọ́sítélì rẹ̀. Àwọn tó ń gba dírákímà méjì gẹ́gẹ́ bí owó orí bi Pétérù pé: “Ṣé olùkọ́ yín kì í san dírákímà méjì owó orí ni?” Pétérù ti fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Jésù wá bi Pétérù pé: “Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?” Nígbà tí Pétérù sọ pé: “Lọ́wọ́ àwọn àjèjì,” Jésù wí fún un pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, àwọn ọmọ bọ́ lọ́wọ́ owó orí. Ṣùgbọ́n kí a má bàa mú wọn kọsẹ̀, ìwọ lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, sì mú ẹja tí ó kọ́kọ́ jáde wá, nígbà tí o bá sì la ẹnu rẹ̀, ìwọ yóò rí ẹyọ owó sítátà kan. Mú ìyẹn, kí o sì fi í fún wọn fún èmi àti ìwọ.” (Mátíù 17:24-27) Ìlànà wo la lè rí fà yọ látinú ìtàn yìí?
Jésù bi Pétérù láwọn ìbéèrè kan kó lè mọ̀ pé òun ò sí lábẹ́ òfin láti máa sanwó orí nítorí pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. Pétérù ò mọ ìyẹn tẹ́lẹ̀, àmọ́ Jésù jẹ́ kó mọ̀ láìkanra mọ́ ọn. Nítorí náà, nígbà tẹ́nì kan bá ṣe àṣìṣe kan, á dára ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ká fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ sọ àṣìṣe rẹ̀ fún un dípò tí a óò fi kanra mọ́ ọn tàbí tí a óò fi láálí rẹ̀.
Pétérù wá rí ìdí tó fi san owó orí yẹn, ìyẹn ni pé kò fẹ́ mú àwọn ẹlòmíràn kọsẹ̀. Ìlànà mìíràn tún nìyẹn tá a lè rí fà yọ látinú ìtàn yìí. Gbígba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò ṣe pàtàkì ju ká máa rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wa lọ.
Kí ló máa mú ká lè ṣe ìpinnu táá fi hàn pé a gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò? Ìfẹ́ tá a ní sí ọmọnìkejì wa ni. Jésù Kristi kọ́ni pé yàtọ̀ sí òfin tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ní ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, òfin tó tún tẹ̀ lé e ni èyí tó ní ká fẹ́ràn ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bí ara wa. (Mátíù 22:39) Àmọ́, ayé onímọtara-ẹni-nìkan là ń gbé yìí, ńṣe ni ẹ̀ṣẹ̀ tá a sì ti jogún ń mú ká fẹ́ máa hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Nítorí náà, bí ẹnì kan yóò bá fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀, onítọ̀hún ní láti yí èrò inú rẹ̀ padà.—Róòmù 12:2.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe irú ìyípadà yẹn, tí wọ́n sì ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò tí wọ́n bá fẹ́ ṣèpinnu, ì báà jẹ́ ìpinnu lórí nǹkan ńlá tàbí kékeré. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú, òmìnira ni a pè yín fún, ẹ̀yin ará; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe fún ẹran ara, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìfẹ́, ẹ máa sìnrú fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gálátíà 5:13) Báwo la ṣe lè ṣe ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí? Wo àpẹẹrẹ omidan kan tó lọ ń sìn lábúlé kan kó lè ran àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó ṣe ń wàásù fáwọn ará ibẹ̀, ó ṣàkíyèsí pé wọn kì í sọ̀rọ̀ tó dáa nípa aṣọ tóun máa ń wọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ wọ̀nyẹn ò burú tá a bá fojú àwọn tó ń gbé nígboro wò ó. Aṣọ àti ìmúra rẹ̀ bójú mu o, àmọ́ ó pinnu pé òun yóò máa wọ aṣọ tó bá àdúgbò ibẹ̀ mu “kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run má bàa di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—Títù 2:5.
Ká ní ìwọ ni omidan yìí, kí lò bá ṣe tó bá di pé ìwọ náà fẹ́ ṣèpinnu lórí ìmúra rẹ tàbí lórí àwọn nǹkan míì tó jẹ́ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́? Kí ó dá ọ lójú pé inú Jèhófà yóò dùn bí ìpinnu rẹ bá fi hàn pé ò ń gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò.
Ronú Ọjọ́ Iwájú
Yàtọ̀ sí pé ká ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, ká sì gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò, àwọn nǹkan mìíràn wo ló tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò nígbà tá a bá fẹ́ ṣèpinnu? Kò rọrùn rárá láti jẹ́ Kristẹni, ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn bá ń rin ọ̀nà híhá tó rí págunpàgun. Àmọ́ Ọlọ́run fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá tá ò bá ṣáà ti ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà rẹ̀. (Mátíù 7:13, 14) A ní láti ronú lórí ipa tí ìpinnu tá a bá ṣe máa ní lórí ìjọsìn wa sí Ọlọ́run àti bí kò ṣe ní ṣèpalára kankan fún wa lọ́jọ́ iwájú.
Ká ní iṣẹ́ kan yọjú, o wá ń rò ó bóyá kó o ṣe é tàbí kó o má ṣe é. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè má tiẹ̀ burú lọ́nàkọnà fún Kristẹni láti ṣe. Kò ní dí ọ lọ́wọ́ àtilọ sípàdé ìjọ, ìpàdé àyíká àti ti àgbègbè. Owó tí wàá máa gbà ju iye tó o rò lọ. Ẹni tó ni ilé iṣẹ́ náà mọyì rẹ torí pé o mọṣẹ́ ọ̀hún gan-an, ó sì fẹ́ kó o ṣiṣẹ́ yẹn fóun gidi gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ìwọ náà fẹ́ràn irú iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ gbà ọ́ fún. Ǹjẹ́ ohunkóhun tún wà tó lè má jẹ́ kó o siṣẹ́ ọ̀hún? Tó o bá rí i pé lọ́jọ́ iwájú, iṣẹ́ yẹn á ti gbà ọ́ lọ́kàn jù ńkọ́? Ẹni tó fẹ́ gbà ọ́ síṣẹ́ ti sọ fún ọ pé òun ò ní ní kó o ṣe àfikún iṣẹ́ lọ́ranyàn. Àmọ́, ǹjẹ́ o ṣe tán láti máa ṣe àfikún iṣẹ́ kó o lè rí i pé o parí iṣẹ́ tó o dáwọ́ lé? Ṣé kì í ṣe ìgbà gbogbo ni irú àfikún iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò máa wáyé? Ṣé ìyẹn ò ní mú kó o máa fi aya àtọmọ rẹ sílẹ̀? Tó bá sì yá, ṣé kò ní mú kó o máa pa àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni lára, èyí tó jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe?
Wo bí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jim ṣe ṣèpinnu pàtàkì kan nípa iṣẹ́ rẹ̀. Ó ṣiṣẹ́ kára, ó sì dépò ńlá níbi iṣẹ́. Níkẹyìn, ó di ọ̀gá àgbà níbi iṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní Ìlà Oòrùn Ayé, òun tún ni ọ̀gá pátápátá ní ẹ̀ka ibi iṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní Amẹ́ríkà, ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí ẹ̀ka ibi iṣẹ́ rẹ̀ tó wà nílẹ̀ Yúróòpù. Àmọ́ nígbà tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Japan, ó wá rí i pé asán ni kéèyàn máa lépa owó òun agbára. Ìṣẹ́jú akàn ni gbogbo owó tó ti ṣiṣẹ́ kára láti kó jọ fò lọ. Gbogbo nǹkan wá tojú sú u, kò tiẹ̀ mọ ibi táyé rẹ̀ dorí kọ. Ó bi ara rẹ̀ pé: ‘Kí ni màá máa ṣe lọ́dún mẹ́wàá sí ìsinsìnyí?’ Ìgbà yẹn ló wá rí i pé ohun tí ìyàwó òun àtàwọn ọmọ òun ń fi ìgbésí ayé wọn ṣe dára ju tòun lọ. Ó ti pẹ́ tí ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ ti ń lọ sí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jim náà fẹ́ kí òun ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn bíi ti ìyàwó àtàwọn ọmọ òun. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.
Kò pẹ́ tí Jim fi rí i pé irú ayé tóun ń gbé ni kò jẹ́ kóun lè di Kristẹni tó ń gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀. Orí ìrìn ni Jim máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà. Bó ṣe ń lọ sí Éṣíà náà ló ń lọ sí Amẹ́ríkà, tó tún ń lọ sílẹ̀ Yúróòpù. Gbogbo ìrìn àjò wọ̀nyí ò jẹ́ kó ráyè tó láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀. Ó wá bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé kí n máa gbé ìgbésí ayé mi lọ bí mo ṣe ń gbé e bọ̀ láti àádọ́ta ọdún ni, àbí kí n bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun?’ Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí ọ̀rọ̀ yìí, lẹ́yìn náà ó ronú lórí ipa tí ìpinnu òun máa ní lórí ìgbésí ayé òun lọ́jọ́ iwájú, ó wá pinnu láti fi gbogbo iṣẹ́ náà sílẹ̀ àfi ọ̀kan tó máa jẹ́ kó ráyè fún ìjọsìn Ọlọ́run. (1 Tímótì 6:6-8) Ìpinnu tó ṣe yìí mú kí ayọ̀ rẹ̀ pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì jẹ́ kó lè máa kópa púpọ̀ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni.
Ìpinnu rẹ ṣe pàtàkì, ì báà jẹ́ lórí ohun kékeré tàbí ńlá. Ìpinnu tó o bá ṣe lónìí lè yọrí sí rere tàbí kó má yọrí sí rere, àní ó lè yọrí sí ikú tàbí ìyè lọ́jọ́ iwájú. Tó o bá ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì, tó ò ń gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò, tó o sì ń ronú ọjọ́ iwájú, wàá lè máa ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Ìpinnu tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu ni kó o máa ṣe o.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ó lè dà bíi pé àwọn ìpinnu kan ò ṣe pàtàkì, síbẹ̀ àbájáde rẹ̀ lè burú jáì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Báwo ni ìlànà Bíbélì ṣe lè ran ọmọbìnrin yìí lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jésù fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá Pétérù sọ̀rọ̀, kò kanra mọ́ ọn