Melito Ará Sádísì Ṣé Ẹni Tó Gbèjà Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ni?
ỌDỌỌDÚN làwọn Kristẹni ń ṣe ìrántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́jọ́ tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà àwọn Hébérù. Àṣẹ Jésù ni wọ́n ń pa mọ́, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” Lẹ́yìn tí Jésù ṣàjọyọ̀ Ìrékọjá tán ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ọjọ́ yẹn kan náà ló fi ètò Ìrántí Ikú rẹ̀ tó fi ṣe ìrúbọ lọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn náà sì ni Jésù kú.—Lúùkù 22:19, 20; 1 Kọ́ríńtì 11:23-28.
Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í yí àkókò Ìrántí Ikú Kristi àti ọ̀nà tá a gbà ń ṣe é padà. Ọjọ́ tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọjọ́ tí Jésù kú làwọn ará Éṣíà Kékeré ń tẹ̀ lé. Ṣùgbọ́n, ìwé kan sọ pé, “àjíǹde Jésù tó wáyé lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé ọjọ́ tó kú làwọn ará Róòmù àtàwọn ará Alẹkisáńdíríà máa ń ṣe ìrántí rẹ̀ ní tiwọn,” wọ́n wá pè é ní Àjíǹde Ìrékọjá. Ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Quartodeciman, ìyẹn Àwọn Ọlọ́jọ́ Kẹrìnlá, jà fún Nísàn 14 pé ọjọ́ yẹn ló bá a mu láti máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù Kristi. Melito ará Sádísì fara mọ́ ẹ̀kọ́ wọn yìí. Ta ni Melito? Báwo ló ṣe gbèjà ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí àtàwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì mìíràn?
‘Ẹni Ńlá Tó La Àwọn Èèyàn Lóye’
Nínú ìwé ìtàn Ecclesiastical History tí Eusebius ará Kesaréà kọ, ó sọ pé ní apá ìparí ọ̀rúndún kejì, Polycrates ará Éfésù kọ lẹ́tà kan sí Róòmù láti fi gbèjà ṣíṣe ayẹyẹ “ọjọ́ kẹrìnlá Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Ìhìn Rere, pé kí wọ́n máa ṣe é gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni, kí wọ́n má yà kúrò nínú rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí lẹ́tà náà ṣe sọ, Melito tí í ṣe Bíṣọ́ọ̀bù ìlú Sádísì tó wà lórílẹ̀-èdè Lìdíà wà lára àwọn tí wọ́n sọ pé Nísàn 14 jẹ́ ọjọ́ tó yẹ kéèyàn máa rántí. Lẹ́tà náà sọ pé àwọn tí ń bẹ láyé nígbà ayé Melito sọ pé Melito wà lára ‘àwọn ẹni ńlá tó la àwọn èèyàn lóye àmọ́ tí wọ́n ti dolóògbé báyìí.’ Polycrates sọ pé Melito kò fẹ́yàwó àti pé “ohun tó bá ti jẹ mọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ló ń jẹ ẹ́ lógún, ìlú Sádísì ni wọ́n sin ín sí, ó sì ń retí ìpè látọ̀run nígbà àjíǹde.” Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí Melito wà lára àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ pé ìgbà tí Kristi bá padà wá ni àjíǹde máa tó bẹ̀rẹ̀.—Ìṣípayá 20:1-6.
Gbogbo èyí jẹ́ ká mọ̀ pé Melito ní láti jẹ́ ẹnì kan tó nígboyà tó sì máa ń dúró lórí ìpinnu rẹ̀. Àní, ó kọ ìwé kan tó pè ní Apology láti fi gbèjà àwọn Kristẹni, ẹni tó sì kọ ìwé ọ̀hún sí ni Olú Ọba Róòmù, ìyẹn Marcus Aurelius, tó wà lórí oyè láti ọdún 161 sí 180 Sànmánì Kristẹni. Melito jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí àkọsílẹ̀ fi hàn pé wọ́n kọ́kọ́ kọ irú ìwé bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rù ò bà á rárá láti gbèjà ẹ̀sìn Kristẹni àti láti sọ fáwọn èèyàn burúkú àtàwọn oníwọra pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dára. Onírúurú àṣẹ ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ti lọ gbà lọ́dọ̀ ọba kí wọ́n lè rí nǹkan fi kẹ́wọ́ láti fojú àwọn Kristẹni gbolẹ̀ àti láti fìyà jẹ wọ́n láìṣẹ nítorí àtilè jí wọn lẹ́rù kó.
Melito fi ìgboyà kọ̀wé sí olú ọba pé: “Kábíyèsí, a fẹ́ kẹ́ ẹ ṣe ohun kan fún wa, a fẹ́ kẹ́ ẹ fúnra yín wádìí àwọn táwọn èèyàn ń tìtorí wọn fa wàhálà yìí [ìyẹn àwọn Kristẹni], kẹ́ ẹ sì ṣèdájọ́ òdodo, bóyá wọ́n yẹ fún ikú àti ìyà lóòótọ́ tàbí wọ́n yẹ lẹ́ni tẹ́ ẹ máa dáàbò bò tẹ́ ẹ sì máa dá sí. Àmọ́, tí kì í bá ṣe ẹ̀yin lẹ pa àṣẹ yìí tí kì í sì í ṣe ẹ̀yin lẹ ṣe òfin tuntun yìí, èyí tó jẹ́ pé kò tiẹ̀ dáa kéèyàn ṣe nítorí tàwọn ọ̀tá tí wọ́n jẹ́ jàgídíjàgan pàápàá, a bẹ̀ yín gidigidi pé kẹ́ ẹ má ṣe gbàgbé wa bí àwọn èèyànkéèyàn wọ̀nyí ṣe ń ṣe ohun tí kò bófin mu, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń jí wa lẹ́rù kó.”
Melito Fi Ìwé Mímọ́ Gbèjà Ẹ̀sìn Kristẹni
Melito nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ gan-an ni. A ò mọ orúkọ gbogbo ìwé tó kọ, àmọ́ lára àwọn àkọlé ìwé tó kọ fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Lára àkọlé àwọn ìwé tó kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ni Lórí Ìgbésí Ayé Kristẹni Àtàwọn Wòlíì, Lórí Ìgbàgbọ́ Èèyàn, Lórí Ìṣẹ̀dá, Lórí Ìrìbọmi àti Òtítọ́ àti Ìgbàgbọ́ àti Ìbí Kristi, Lórí Bá A Ṣe Lè Lẹ́mìí Àlejò Ṣíṣe, Bá A Ṣe Lè Lóye Bíbélì, àti Lórí Èṣù àti Ìṣípayá Jòhánù.
Melito dìídì lọ sáwọn ilẹ̀ tí Bíbélì dárúkọ láti lọ ṣèwádìí kó lè mọ iye ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Melito sì kọ̀wé nípa ìwádìí rẹ̀, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí mo lọ sí Ìlà Oòrùn Ayé níbi tí wọ́n ti wàásù nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n sì ti fi ṣèwà hù, tí mo sì ti mọ àwọn ìwé tí ń bẹ nínú Májẹ̀mú Láéláé lámọ̀dunjú tí mo sì ti kọ ohun tó jẹ́ òótọ́ nípa wọn sílẹ̀, mo fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ.” Ìwé Nehemáyà àti ìwé Ẹ́sítérì ò sí lára àwọn ìwé Bíbélì tí Melito mẹ́nu kàn nínú ìwé rẹ̀, síbẹ̀ ìwé rẹ̀ yìí ló pẹ́ jù lọ lára ìwé táwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ kọ tó mẹ́nu kan àwọn ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù.
Nígbà ìwádìí yìí, Melito ṣe àkójọ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ìwé Melito tó pè ní Extracts sọ pé Jésù ni Mèsáyà táwọn èèyàn ń retí láti ọjọ́ pípẹ́, ó sì sọ pé Òfin Mósè àtàwọn Wòlíì tọ́ka sí Kristi.
Ó Ṣàlàyé Pé Ìràpadà Ṣe Pàtàkì
Àwọn Júù tó wà láwọn ìlú pàtàkì-pàtàkì ní Éṣíà Kékeré pọ̀ gan-an. Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn làwọn Júù tí ń bẹ nílùú Sádísì tí Melito ń gbé máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá àwọn Hébérù. Melito kọ ọ̀rọ̀ ìwàásù kan sínú ìwé tó pe àkọlé rẹ̀ ní The Passover (Ìrékọjá) káwọn èèyàn lè mọ̀ pé àjọyọ̀ Ìrékọjá tí Òfin Mósè là sílẹ̀ tọ̀nà, bẹ́ẹ̀ náà ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa táwọn Kristẹni ń ṣe lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn.
Lẹ́yìn tí Melito ti ṣàlàyé Ẹ́kísódù orí kejìlá tó sì ti fi hàn pé ńṣe ni àjọyọ̀ Ìrékọjá ṣàpẹẹrẹ ẹbọ Kristi, ó sọ ìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu fáwọn Kristẹni láti tún máa ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ìdí ni pé Ọlọ́run ti mú Òfin Mósè kúrò. Ó wá sọ ìdí tí ẹbọ Kristi fi ṣe pàtàkì. Ó ní Ọlọ́run fi Ádámù sínú Párádísè kó lè máa gbé ìgbésí ayé aláyọ̀. Àmọ́, ọkùnrin àkọ́kọ́ yìí rú òfin tí Ọlọ́run pa fún un pé kó má ṣe jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Bó ṣe di pé a nílò ìràpadà nìyẹn.
Melito tún ṣàlàyé pé Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé, ó sì kú sórí òpó igi kó bàa lè ra àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, nígbà tí Melito ń kọ̀wé nípa irú òpó tí Jésù kú sí, ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà xylon, tó túmọ̀ sí “igi.”—Ìṣe 5:30; 10:39; 13:29.
Kò síbi tí wọn ò ti mọ Melito ní Éṣíà Kékeré, àní wọ́n mọ̀ ọ́n kọjá ibẹ̀ pàápàá. Àwọn èèyàn bíi Tertullian, Clement ará Alẹkisáńdíríà àti Origen máa ń ka ìwé Melito. Síbẹ̀, òpìtàn kan tó ń jẹ́ Raniero Cantalamessa sọ pé: “Ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fojú wo ẹgbẹ́ Quartodeciman pé wọ́n jẹ́ aládàámọ̀ ló di pé Melito kò lókìkí mọ́, èyí sì mú káwọn ìwé rẹ̀ di àwátì ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn tó ń jà lórí ọ̀rọ̀ ṣíṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá Ọjọ́ Sunday borí.” Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo ìwé Melito fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì.
Ǹjẹ́ Melito Di Apẹ̀yìndà?
Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn apẹ̀yìndà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú nínú ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́. (Ìṣe 20:29, 30) Ó dájú pé èyí ṣàkóbá fún Melito. Téèyàn bá wo bí Melito ṣe máa ń kọ̀wé rẹ̀, èèyàn á rí i pé ìmọ̀ àwọn ọ̀mọ̀ràn Gíríìkì àti tí Róòmù fẹ́ máa hàn níbẹ̀. Bóyá ohun tó mú kí Melito sọ pé ẹ̀sìn Kristẹni jẹ́ “ìmọ̀ ọgbọ́n orí wa” nìyẹn. Ó tún ka àjọṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn tó pera wọn ní ẹlẹ́sìn Kristẹni àti Ilẹ̀ Ọba Róòmù sí “ẹ̀rí tó ga jù lọ . . . tó fi hàn pé nǹkan ń lọ dáadáa.”
Ó dájú pé Melito ò kọbi ara sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Melito gbèjà ẹ̀kọ́ Bíbélì dé ìwọ̀n àyè kan, èyí tí kò tẹ̀ lé nínú àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ló pọ̀ jù.— Kólósè 2:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jésù fi ìrántí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́lẹ̀ ní Nísàn 14