ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/15 ojú ìwé 14-16
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Ọmọ Mi Lè Jẹ́ Ẹni Tó Gbẹ̀kọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Ọmọ Mi Lè Jẹ́ Ẹni Tó Gbẹ̀kọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpìlẹ̀ Ẹ̀kọ́ Tó Ṣàǹfààní
  • Àwọn Ọmọ Rẹ Ń Wò Ẹ́ O!
  • Ṣe Ojúṣe Rẹ
  • Rí I Pé O Wáyè Láti Tọ́ Ọmọ Rẹ
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/15 ojú ìwé 14-16

Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí Ọmọ Mi Lè Jẹ́ Ẹni Tó Gbẹ̀kọ́?

KÍKỌ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ dà bí ìgbà téèyàn ń rìnrìn àjò kan tó ń múnú ẹni dùn àmọ́ tó ṣòroó rìn. Ńṣe ni ìwọ òbí àtọmọ rẹ jọ ń rin ìrìn àjò náà pa pọ̀. Ìdí ni pé bó o ṣe ń gbà á níyànjú ni wàá máa tọ́ ọ sọ́nà tìfẹ́tìfẹ́ kó lè túbọ̀ máa tẹ̀ síwájú nígbèésí ayé. Ohun tó yẹ kí ọmọ mọ̀ pọ̀ gan-an ni!

Káyé ọmọ tó lè dáa lóòótọ́ kó sì jẹ́ aláyọ̀, ó gbọ́dọ̀ jẹ ẹni tó níwà rere, àjọṣe tó dára ní láti wà láàárín òun àti Ọlọ́run, ó sì gbọ́dọ̀ lè dá ohun tó tọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́. Báwọn ọmọ bá mọ Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ yóò ṣe wọ́n láǹfààní, ìtọ́ni tí wọ́n gbà yóò sì wà lọ́kàn wọn títí ayé. Ipa kékeré kọ́ nìwọ òbí ń kó nínú irú ẹ̀kọ́ tí ọmọ rẹ ń gbà, bí ẹ̀kọ́ ṣe máa yé e sí àti ọwọ́ táá fi mú ohun tó ń kọ́.

Ọmọ kíkọ́ ò ṣàì ní ìṣòro tiẹ̀. Ọkàn ọmọdé tètè máa ń gba nǹkan mọ́ra, torí náà wọ́n lè kọ́ onírúurú ìkọ́kúkọ̀ọ́ láti ìta wa sílé. Inú ayé tí Sátánì Èṣù ń darí la wà yìí. (1 Jòhánù 5:19) Sátánì máa ń fẹ́ láti kọ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ nítorí kó lè sọ wọ́n dìdàkudà ni. Ọ̀jáfáfá olùkọ́ tó ti nírìírí ni Sátánì, ṣùgbọ́n olùkọ́ burúkú gbáà ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dọ́gbọ́n ṣe bí “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” ẹ̀tàn ni gbogbo ìlàlóye tó ń fúnni, ó sì tún lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:4; 11:14; Jeremáyà 8:9) Ọ̀gá ni Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù nídìí ìtànjẹ, wọ́n ń sọ àwọn èèyàn di onímọtara-ẹni-nìkan, aláìṣòótọ́ àti oníwà ìbàjẹ́.—1 Tímótì 4:1.

Kí lo lè ṣe kí wọ́n má bàa ṣi ọmọ rẹ lọ́nà? Báwo lo ṣe máa kọ́ wọn lọ́nà tó jẹ́ pé ohun tó tọ́ tó sì ṣàǹfààní ni wọ́n á máa fi sọ́kàn? Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó o máa ṣe ni pé kó o yẹ ara rẹ wò. O ní láti fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ó sì ṣe pàtàkì pé kó o gbà pé ojúṣe rẹ ni láti tọ́ ọmọ rẹ kó o sì rí i pé ò ń wáyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ká tó dẹ́nu lé àlàyé nípa èyí, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó jẹ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní.

Ìpìlẹ̀ Ẹ̀kọ́ Tó Ṣàǹfààní

A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lọ́dọ̀ Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó lọ́gbọ́n jù lọ láyé yìí. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi àti fífẹ̀ ọkàn-àyà, bí iyanrìn tí ó wà ní etíkun. Ọgbọ́n Sólómọ́nì sì pọ̀ jaburata ju ọgbọ́n gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn àti ju gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.” Sólómọ́nì “lè pa ẹgbẹ̀ẹ́dógún òwe, àwọn orin rẹ̀ sì wá jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún.” Ó ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa ewéko, ẹranko, ẹyẹ àti ẹja. (1 Àwọn Ọba 4:29-34) Abẹ́ àbójútó Sólómọ́nì Ọba ni wọ́n sì ti ṣe onírúurú iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Ísírẹ́lì, títí kan tẹ́ńpìlì ológo tí wọ́n kọ́ fún Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù.

Àwọn nǹkan tí Sólómọ́nì kọ, bí irú èyí tó wà nínú ìwé Oníwàásù, fi hàn pé ó ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa ẹ̀dá èèyàn. Ọlọ́run mí sí i láti sọ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní. Sólómọ́nì sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀.” Ọba ọlọgbọ́n yìí sì tún sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.”—Òwe 1:7; 9:10.

Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run, a ó máa bu ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un, a ó sì máa ṣọ́ra ká má ṣe ohun tí kò fẹ́. Àá gbà dájúdájú pé òun ni Atóbijù àti pé a wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀. Lójú àwọn èèyàn, àwọn tí kò ka ẹni tó ni ẹ̀mí wa sí lè jẹ́ ọlọgbọ́n, àmọ́ “òmùgọ̀” ni ọgbọ́n irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ “lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 3:19) Ẹ̀kọ́ tá a gbé ka “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” ni ẹ̀kọ́ tó dára fún ọmọ rẹ.—Jákọ́bù 3:15, 17.

Kẹ́nì kan tó lè máa bẹ̀rù pé kóun má ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́, onítọ̀hún ní láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun bẹ̀rù òun kí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ òun. Mósè sọ pé: “Ìwọ Ísírẹ́lì, kí sì ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, bí kò ṣe láti máa fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ; láti máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́ àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, fún ire rẹ?”—Diutarónómì 10:12, 13.

Tá a bá jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ wa, ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ògidì ọgbọ́n la fi lélẹ̀ yẹn. Bí wọ́n bá jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà máa jinlẹ̀ sí i lọ́kàn wọn, wọ́n á túbọ̀ mọyì Ẹlẹ́dàá wọn, Ẹni tó jẹ́ orísun ojúlówó ìmọ̀. Èyí á jẹ́ kí wọ́n ní òye tó yẹ nípa ohun tí wọ́n ń kọ́, wọn ò sì ní lò ó lọ́nà òdì. Wọ́n á dẹni tó mọ̀ bá a ṣe ń “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Irú ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò tún mú kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì máa yẹra fún ṣíṣe ohun tí kò dáa.—Òwe 8:13; 16:6.

Àwọn Ọmọ Rẹ Ń Wò Ẹ́ O!

Àmọ́ báwo la ṣe lè mú káwọn ọmọ wa fẹ́ràn Jèhófà kí wọ́n sì bẹ̀rù rẹ̀? A óò rí ìdáhùn nínú Òfin tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó sọ fáwọn tó jẹ́ òbí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:5-7.

Ẹsẹ Bíbélì yìí kọ́ àwọn òbí ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. Ọ̀kan rèé: Ìwọ òbí gbọ́dọ̀ fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Kó o tó lè kọ́ ọmọ rẹ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìwọ alára ní láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ní láti wà lọ́kàn rẹ. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì gan-an? Ìdí ni pé ìwọ gan-an ni olùkọ́ ọmọ rẹ ní pàtàkì. Ohun tí ọmọ rẹ bá kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ yóò nípa tó pọ̀ gan-an lórí rẹ̀, ó ṣe tán, òwú tí ìyá gbọ̀n lọmọ ń ran. Kò sí ohun tó ń nípa lórí ìgbésí ayé ọmọ bí àpẹẹrẹ òbí.

Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ nìkan kọ́ ló ń fi ohun tó wù ọ́, ohun tó o gbà pé ó tọ́, ohun tó o kà sí pàtàkì àtohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí hàn. Ìṣe rẹ pẹ̀lú ń fi hàn. (Róòmù 2:21, 22) Àti kékeré jòjòló làwọn ọmọ ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ṣíṣàkíyèsí gbogbo ohun táwọn òbí wọn ń ṣe. Àwọn ọmọ máa ń fòye mọ ohun tó jẹ àwọn òbí wọn lógún, nǹkan wọ̀nyẹn ló sì sábà máa ń jẹ àwọn náà lógún tó bá yá. Bó bá jẹ́ pé òótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ọmọ rẹ á mọ̀ bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣàkíyèsí rẹ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa rí i pé Bíbélì kíkà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ ọ́ lógún. Wọ́n yóò rí i pé àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run lò ń fi ṣáájú nígbèésí ayé rẹ. (Mátíù 6:33) Bó o bá ń lọ sípàdé déédéé tó o sì ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n á rí i pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló jẹ ọ́ lógún jù.—Mátíù 28:19, 20; Hébérù 10:24, 25.

Ṣe Ojúṣe Rẹ

Ẹ̀kọ́ tí ìwọ òbí tún lè kọ́ látinú Diutarónómì 6:5-7 ni pé: Ojúṣe rẹ ni láti tọ́ ọmọ rẹ. Nígbà ayé àwọn èèyàn Jèhófà látijọ́, àwọn òbí ló máa ń rí sí i pé ọmọ àwọn gbẹ̀kọ́. Bákan náà, láàárín àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn òbí kó ipa pàtàkì nínú kíkọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (2 Tímótì 1:5; 3:14, 15) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀, ó fi yé wọn pé àwọn bàbá ní pàtàkì, ní láti “máa bá a lọ ní títọ́ [ọmọ wọn] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.

Nítorí kòókòó jàn-án jàn-án ayé ìsinsìnyí, tó fi mọ́ iṣẹ́ àtàwọn nǹkan míì tó ń gba àkókò àwọn òbí, wọ́n lè fẹ́ yẹ ojúṣe wọn láti máa kọ́ ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, bóyá fún àwọn olùkọ́ ní iléèwé tàbí àwọn tó ń báni tọ́mọ wẹ́wẹ́. Àmọ́ kò sóhun tó dà bíi kí òbí fúnra rẹ̀ bójú tó ọmọ tìfẹ́tìfẹ́. Má ṣe fojú kékeré wo ipò rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí àti ipa tó ò ń ní lórí ọmọ. Tó bá wá di dandan káwọn ẹlòmíì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kọ́ ọmọ rẹ, fọgbọ́n wo irú ẹni tó o máa yàn, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kó o wá já ojúṣe tí Ọlọ́run ní kó o ṣe jù sílẹ̀ fún wọn o.

Rí I Pé O Wáyè Láti Tọ́ Ọmọ Rẹ

Ẹ̀kọ́ míì tí òbí tún lè rí kọ́ nínú Diutarónómì 6:5-7 ni pé: Ọmọ títọ́ gba àkókò àti ìsapá. Ní Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, àwọn òbí ní láti ‘fi ìtẹnumọ́ gbin’ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn ọmọ wọn. Nínú èdè Hébérù, ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “fi ìtẹnumọ́ gbìn” túmọ̀ sí “láti tún ọ̀rọ̀ sọ,” “láti sọ̀rọ̀ lásọtúnsọ.” Àtàárọ̀ ṣúlẹ̀ ni ẹsẹ Bíbélì yìí sì ní kí òbí máa ṣe é, àní “nínú ilé rẹ” àti “nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà.” Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá láti kọ́ ọmọdé àti láti tọ́ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi dẹni tí ìwà àti ìṣe wọn á máa múnú Ọlọ́run dùn.

Kí lo wá lè ṣe kí àwọn ọmọ rẹ lè jẹ́ ẹni tó gbẹ̀kọ́? Ohun tó o lè ṣe pọ̀ gan-an o. Kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n á sì máa bẹ̀rù rẹ̀. Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ṣe ojúṣe rẹ láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ kó o sì rí i pé o wáyè láti tọ́ wọn tó bó ṣe yẹ. Má rò pé o ò ní ṣàṣìṣe bó o ṣe ń kọ́ ọmọ rẹ o, torí aláìpé ni ọ́. Àmọ́, tó o bá ń gbìyànjú gidigidi láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, láìsí àní-àní, ọmọ rẹ yóò mọrírì ìsapá rẹ, yóò sì jàǹfààní rẹ̀. Ìwé Òwe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe rí fáwọn ọmọbìnrin.

Ẹ̀kọ́ kíkọ́ jẹ́ ìrìn àjò téèyàn ń rín jálẹ̀ ayé ẹni. Bí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ bá sì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, títí láé lẹ óò máa gbádùn ìrìn àjò náà. Ìdí ni pé kò ní yéé sí àwọn nǹkan tó yẹ ká mọ̀ nípa Jèhófà àti bá a ṣe lè wúlò fún un.—Oníwàásù 3:10, 11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ǹjẹ́ o máa ń ka Bíbélì sétí ọmọ rẹ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Rí i pé ò ń wáyè láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ nípa Ẹlẹ́dàá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́