Ìdí Tí Kò Fi Ní Pẹ́ Tí Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin
“Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.”—DIUTARÓNÓMÌ 32:4.
1, 2. (a) Kí nìdí tó o fi ka ìrètí wíwà láàyè títí láé sí iyebíye? (b) Kí nìdí tó fi ṣòro fáwọn kan láti gba Ọlọ́run tó ṣèlérí pé aráyé á gbádùn àwọn ohun àgbàyanu lọ́jọ́ iwájú gbọ́?
ǸJẸ́ ó máa ń dùn mọ́ ẹ láti fọkàn ro bí nǹkan ṣe máa rí ní Párádísè? Bóyá o máa ń fojú inú rí ara rẹ níbẹ̀ tó ò ń ṣèwádìí nípa ilẹ̀ ayé ẹlẹ́wà yìí, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa onírúurú àwọn ohun alààyè inú rẹ̀ tó pọ̀ lọ jàra. Tàbí kó jẹ́ pé o máa ń ronú nípa bí inú rẹ á ṣe máa dùn tó bí ìwọ àtàwọn míì ṣe ń ṣiṣẹ́ láti bójú tó ilẹ̀ ayé àti láti sọ ọ́ di Párádísè. Ó sì lè jẹ́ pé o máa ń ronú nípa onírúurú àrà tí wàá fẹ́ máa dá nídìí iṣẹ́ ọnà, ilé kíkọ́, orin kíkọ tàbí àwọn nǹkan míì tí kò sí àkókò fún ọ láti ṣe láyé bó-o-jí-o-jí-mi tọ́wọ́ máa ń dí gan-an yìí. Ohun tó wù kó o máa fọkàn rò nípa Párádísè, ó dájú pé o ka ìrètí rẹ láti ní “ìyè tòótọ́” tí Bíbélì sọ sí ohun iyebíye. Ìyè tòótọ́ yìí ni ìyè àìnípẹ̀kun tí Jèhófà ti pinnu láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí ìran èèyàn gbádùn.—1 Tímótì 6:19.
2 Àǹfààní ńlá la ní láti máa sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tá a rí nínú Bíbélì yìí fáwọn èèyàn. Ó sì ń dùn mọ́ wa láti máa sọ ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò gba ìrètí yìí gbọ́. Wọ́n ní àlá tí ò lè ṣẹ ni, pé àwọn tí kò gbọ́n ni wọ́n fi ń tàn jẹ. Ó tiẹ̀ lè ṣòro fún wọn láti gba Ọlọ́run tó ṣèlérí pé a óò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè gbọ́. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wọn? Ní tàwọn kan, ó lè jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ló fà á tó fi ṣòro fún wọn láti gba Ọlọ́run gbọ́. Èrò wọn ni pé tí Ọlọ́run bá wà, tó sì jẹ́ alágbára gíga jù lọ àti onífẹ̀ẹ́, kò sídìí tó fi yẹ kí ìwà ibi àti ìpọ́njú wà láyé. Wọn ronú pé kò sí Ọlọ́run tó lè fàyè gba ìwà ibi, pé tírú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ bá sì wà, ó ní láti jẹ́ pé òun kọ́ ni agbára rẹ̀ ga jù lọ tàbí kó jẹ́ pé kò bìkítà nípa ọmọ aráyé. Ẹ jẹ́ mọ̀ pé àwọn kan gbà pé èrò yìí tọ̀nà. Áà, Sátánì mà kúkú ń fọ́ àwọn èèyàn lójú o!—2 Kọ́ríńtì 4:4.
3. Ìbéèrè tó le wo la fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé àwa la lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
3 Níwọ̀n bá a ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwa la lè ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn tí Sátánì àtàwọn tó ń lo ọgbọ́n ayé yìí ń tàn jẹ. (1 Kọ́ríńtì 1:20; 3:19) A mọ ìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi gba àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì gbọ́. Ìdí náà sì ni pé wọn ò mọ Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n má mọ orúkọ rẹ̀ tàbí bí orúkọ náà ṣe ṣe pàtàkì tó. Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé díẹ̀ ni wọ́n mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ rárá, wọ́n sì lè má mọ̀ pé ó jẹ́ Ọlọ́run tó ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Àǹfààní ńlá ni pé àwa mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Lóòrèkóòrè, ó yẹ ká máa ṣàtúnyẹ̀wò bá a ṣe lè ran àwọn èèyàn tí wọ́n “wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí” lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìdáhùn sí ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó le jù lọ táwọn èèyàn máa ń béèrè. Ìbéèrè náà ni: “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi àti ìpọ́njú?” (Éfésù 4:18) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a máa kọ́kọ́ ṣe kí ìdáhùn wa lè múná dóko. Lẹ́yìn náà, a óò jíròrò bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀rọ̀ ìwà ibi ṣe fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn.
Ohun Tó Yẹ Ká Kọ́kọ́ Ṣe Kí Ìdáhùn Wa Lè Múná Dóko
4, 5. Kí ló lè dára pé ká kọ́kọ́ ṣe tẹ́nì kan bá béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìpọ́njú? Ṣàlàyé.
4 Tẹ́nì kan bá bi wá pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìpọ́njú, báwo la ṣe lè dáhùn? Ó lè ṣe wá bíi pé ká tú àlàyé palẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, látorí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́gbà Édẹ́nì. Nígbà míì, ó lè dára bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ṣá, ohun kan wà tó yẹ ká kíyè sí. Ó lè dáa ká kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan kan ká tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé. (Òwe 25:11; Kólósè 4:6) Ẹ jẹ́ ká wo ohun mẹ́ta tá a lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́ ká tó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.
5 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, tó bá jẹ́ pé ìwà ibi tó pọ̀ láyé ló ń dun ẹni tó béèrè ìbéèrè náà, ó ṣeé ṣe kó ti kan òun tàbí èèyàn rẹ̀ kan. Nítorí náà, ó máa dáa ká kọ́kọ́ bá a kẹ́dùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwa Kristẹni pé: “Ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Tá a bá fẹ̀mí ìbánikẹ́dùn hàn, ìyẹn “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì,” èyí lè wọ ẹni náà lọ́kàn. (1 Pétérù 3:8) Tó bá rí i pé ìṣòro òun dùn wá, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ fẹ́ láti gbọ́ ohun tá a bá sọ.
6, 7. Kí nìdí tó fi lè dára ká yin ẹni tó béèrè ìbéèrè pàtàkì tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn?
6 Ohun kejì tá a lè ṣe ni pé ká yin ẹni tó béèrè ìbéèrè tọkàntọkàn yìí. Èrò àwọn kan ni pé níwọ̀n bí irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ti ń jà gùdù lọ́kàn àwọn, àwọn ò nígbàgbọ́ nìyẹn tàbí pé àwọn ń yájú sí Ọlọ́run. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn olórí ìsìn wọn ti sọ bẹ́ẹ̀ fún wọn. Àmọ́, pé ẹnì kan béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ ò fi hàn pé ẹni náà ò nígbàgbọ́ tàbí pé ó ń yájú sí Ọlọ́run. Ó ṣe tán, àwọn kan tí wọ́n nígbàgbọ́ láyé ọjọ́un béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù náà Dáfídì béèrè pé: “Jèhófà, èé ṣe tí ìwọ fi dúró lókèèrè réré? Èé ṣe tí ìwọ fi ara rẹ pa mọ́ ní àwọn àkókò wàhálà?” (Sáàmù 10:1) Bákan náà, wòlíì Hábákúkù béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí èmi yóò fi kígbe fún ìrànlọ́wọ́, tí ìwọ kò sì gbọ́? Yóò ti pẹ́ tó tí èmi yóò fi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́ kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá, tí ìwọ kò sì gbà là? Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú? Èé sì ti ṣe tí ìfiṣèjẹ àti ìwà ipá fi wà ní iwájú mi, èé sì ti ṣe tí aáwọ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, èé sì ti ṣe tí gbọ́nmi-si omi-ò-to fi ń bẹ?”—Hábákúkù 1:2, 3.
7 Dáfídì àti Hábákúkù ní ìgbàgbọ́ wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run gan-an. Ǹjẹ́ Ọlọ́run bá wọn wí nítorí pé wọ́n béèrè ìbéèrè tó ń jà gùdù lọ́kàn wọn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà jẹ́ kí ìbéèrè tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn yẹn wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lóde òní, ebi tẹ̀mí lè máa pa ẹnì kan tí inú rẹ̀ bà jẹ́ nítorí ìwà ibi tó pọ̀ láyé, ìyẹn ni pé ó lè máa wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó jẹ́ pé Bíbélì nìkan ló lè dáhùn rẹ̀. Rántí pé Jésù yin àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa, ìyẹn àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ayọ̀ tí Jésù ṣèlérí!
8. Àwọn ẹ̀kọ́ tó ń ṣini lọ́nà wo ló mú káwọn èèyàn máa rò pé Ọlọ́run ló ń fa ìpọ́njú bá aráyé, báwo la sì ṣe lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?
8 Ohun kẹta ni pé, ó lè pọn dandan pé ká ran onítọ̀hún lọ́wọ́ kó lè mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìwà ibi tó pọ̀ láyé. Ohun tí wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé Ọlọ́run ló ń ṣàkóso ayé yìí, pé tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ séèyàn mọ́ ọn, àti pé ìdí kan tí ò yéèyàn wà tí Ọlọ́run fi ń fìyà jẹ ọmọ aráyé. Ẹ̀kọ́ èké làwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí o. Ńṣe làwọn ẹ̀kọ́ náà ń tàbùkù sí Ọlọ́run wọ́n sì ń mú káwọn èèyàn máa rò pé òun ló fa ìwà ibi àti ìpọ́njú. Nítorí náà, ó lè pọn dandan pé ká fi Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tó jóòótọ́. (2 Tímótì 3:16) Jèhófà kọ́ ló ń ṣàkóso ayé oníwà ìbàjẹ́ yìí, Sátánì Èṣù ni. (1 Jòhánù 5:19) Jèhófà kò kádàrá ohunkóhun mọ́ àwa ẹ̀dá rẹ̀; ńṣe ló fún kálukú wa ní òmìnira láti yan èyí tó bá wù ú nínú rere àti búburú, nínú ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. (Diutarónómì 30:19) Jèhófà sì kọ́ ló dá ìwà ibi sílẹ̀; ó kórìíra ìwà búburú ó sì bìkítà nípa àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí ìyà ń jẹ.—Jóòbù 34:10; Òwe 6:16-19; 1 Pétérù 5:7.
9. Àwọn ìwé wo ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè ká lè fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi fàyè gbà ìpọ́njú tó ń bá aráyé?
9 Tó o bá ti kọ́kọ́ ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, wàá rí i pé ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lè fẹ́ mọ ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìpọ́njú ṣì wà. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti pèsè àwọn ìwé tó máa jẹ́ kó o lè ṣe èyí. (Mátíù 24:45-47) Bí àpẹẹrẹ, ní Àpéjọ Àgbègbè “Ìgbọràn sí Ọlọ́run” tá a ṣe lọ́dún 2005 sí 2006, a mú ìwé àṣàrò kúkúrú kan jáde tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́! Tí ìwé àṣàrò kúkúrú yìí bá wà ní èdè rẹ, o ò ṣe gbìyànjú láti mọ ohun tó wà nínú rẹ̀? Bákan náà, odindi orí kan ni ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? fi jíròrò ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìwà ibi ṣì wà. A ti túmọ̀ ìwé náà sí èdè mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ [157] báyìí. Máa lo àwọn ìwé wọ̀nyí dáadáa. Àwọn ìwé náà ṣàlàyé yékéyéké látinú Bíbélì nípa bí ẹnì kan ṣe dá ọ̀ràn kan sílẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì nípa ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run, wọ́n sì tún ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi bójú tó ọ̀ràn náà lọ́nà tó gbà bójú tó o. Fi sọ́kàn pé tó o bá ń bá ẹnì kan jíròrò kókó yìí, ńṣe lò ń jẹ́ kẹ́ni náà ní ìmọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ìmọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ àtàtà.
Ṣàlàyé Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
10. Kí ló ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti lóye nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé, kí sì ni wọn ò mọ̀, tó jẹ́ pé tí wọ́n bá mọ̀ ọ́n, á ràn wọ́n lọ́wọ́?
10 Tó o bá ń ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí aráyé máa ṣàkóso ara wọn lábẹ́ ìdarí Sátánì fáwọn èèyàn, jẹ́ kí wọ́n lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára, wọ́n máa ń gbọ́ táwọn èèyàn máa ń pè é ní Ọlọ́run Olódùmarè. Àmọ́, ó lè ṣòro fún wọn láti lóye ìdí tí kò fi lo agbára ńlá rẹ̀ láti fòpin sí ìwà ibi àti ìpọ́njú ní gbàrà tó bẹ̀rẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọn ò mọ àwọn ànímọ́ mìíràn tí Jèhófà ní, irú bí ìjẹ́mímọ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti ìfẹ́. Jèhófà ń lo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí lọ́nà pípé, tí ìkan ò fi ní pa ìkejì lára. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé àwọn ànímọ́ wọ̀nyí nígbà tó o bá ń dáhùn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè lórí ọ̀rọ̀ tá à ń gbé yẹ̀ wò yìí? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
11, 12. (a) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà ò fi lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdáríjì nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀? (b) Kí nìdí tí Jèhófà ò fi ní jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa wà títí láé?
11 Ṣé Jèhófà ò kàn lè dárí ji Ádámù àti Éfà ni? Wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ìdáríjì rárá. Níwọ̀n bí Ádámù àti Éfà ti jẹ́ ẹni pípé, ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ wọn tí wọ́n sì gbà pé kí Sátánì máa darí àwọn. Abájọ táwọn ọlọ̀tẹ̀ náà ò fi ronú pìwà dà rárá. Àmọ́ táwọn èèyàn bá ń béèrè ìbéèrè nípa ìdí tí Jèhófà ò fi dárí jì wọ́n, ó lè jẹ́ pé ohun tí wọ́n fẹ́ mọ̀ gan-an ni ìdí tí Jèhófà ò fi gbójú fo ìlànà rẹ̀ kó sì fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣọ̀tẹ̀. Ṣó o rí i, ìdáhùn ìbéèrè yìí ní í ṣe pẹ̀lú ànímọ́ Jèhófà kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni mímọ́.—Ẹ́kísódù 28:36; 39:30.
12 Bíbélì mẹ́nu kan ìjẹ́mímọ́ Jèhófà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé nínú ayé tó ti bà jẹ́ yìí, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló mọ ohun tí ànímọ́ yìí jẹ́. Jèhófà jẹ́ ẹni mímọ́, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ò sì lè sí ní sàkáání rẹ̀. (Aísáyà 6:3; 59:2) Ó ti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ láti lè mú un kúrò, kò ní jẹ́ kó máa wà títí láé. Ká ní Jèhófà fẹ́ fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ títí láé ni, a kì bá má ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la. (Òwe 14:12) Tí àkókò tí Jèhófà yàn bá tó, ó máa mú kí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀ padà di mímọ́. Ó sì dájú pé èyí máa rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé Jèhófà tí í ṣe Ẹni Mímọ́ ló fẹ́ bẹ́ẹ̀.
13, 14. Kí nìdí tí Jèhófà kò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run ní Édẹ́nì?
13 Ǹjẹ́ kò ní dára ká ní Jèhófà wulẹ̀ ti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run ní Édẹ́nì kó sì dá àwọn mìíràn láti tún bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun? Dájúdájú, ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀; ó sì máa lo agbára yẹn láti fòpin sí gbogbo ìwà ibi láìpẹ́. Àmọ́ àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘kí nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀ lákòókò tí ẹlẹ́ṣẹ̀ tó wà ní gbogbo ayé àtọ̀run ò ju mẹ́ta lọ?’ Wọ́n ronú pé ká ló ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, kì bá má sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìpọ́njú tó ń bá aráyé báyìí. Àmọ́ kí nìdí tí Jèhófà ò fi ṣe bẹ́ẹ̀? Diutarónómì 32:4 sọ pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.” Jèhófà kì í fi ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òdodo ṣeré rárá. Bíbélì sọ pé “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà.” (Sáàmù 37:28) Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run ní Édẹ́nì. Kí nìdí?
14 Nígbà tí Sátánì ṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì, ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ńṣe ló máa dáhùn ẹ̀sùn Sátánì yìí lọ́nà tó bá òdodo mu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú tọ́ sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, ká ní ńṣe ni Jèhófà pa wọ́n lójú ẹsẹ̀ ni, ìyẹn ì bá má pèsè ìdáhùn sí ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà. Lóòótọ́ o, pípa tí Jèhófà bá pa wọn ì bá túbọ̀ fi hàn pé Jèhófà ló lágbára jù láyé lọ́run, àmọ́ ọ̀tọ̀ lẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án. Kì í ṣe pé ó ń jiyàn bóyá Jèhófà ní agbára tàbí kò ní. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti sọ ohun tó jẹ́ ìpinnu rẹ̀ fún Ádámù àti Éfà. Ìpinnu náà ni pé kí wọ́n bímọ kí irú ọmọ wọn sì kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n máa ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì máa jọba lórí gbogbo ohun mìíràn tí Ọlọ́run dá sórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ká ní Jèhófà pa Ádámù àti Éfà ni, ohun tó jẹ́ ìpinnu rẹ̀ fún èèyàn kì bá má nímùúṣẹ. Àmọ́, níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ onídàájọ́ òdodo, kò lè jẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, nítorí pé gbogbo ohun tó bá pinnu láti ṣe ló máa ń nímùúṣẹ.—Aísáyà 55:10, 11.
15, 16. Táwọn èèyàn bá ń sọ ọ̀nà táwọn rò pé ó yẹ kí Ọlọ́run gbà yanjú ọ̀ràn tó jẹ yọ ní Édẹ́nì, báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
15 Láyé àtọ̀run, ǹjẹ́ ẹlòmíràn tún wà tó lè fi ọgbọ́n tó ju ti Jèhófà lọ yanjú ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì? Àwọn kan lè máa sọ ọ̀nà tí wọ́n rò pé ó yẹ kí Ọlọ́run gbà yanjú ọ̀ràn ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì. Àmọ́ ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí wọ́n ń sọ ni pé àwọn mọ ọ̀nà tó dára jù láti gbà yanjú ọ̀ràn náà? Ó lè má jẹ́ pé ohun búburú ló wà lọ́kàn wọn tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀, kó kàn jẹ́ pé ńṣe ni wọn ò mọ Jèhófà àti ọgbọ́n rẹ̀ tí kò láfiwé. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù, ó ṣàlàyé tó jinlẹ̀ nípa ọgbọ́n Ọlọ́run, tó fi mọ́ “àṣírí ọlọ́wọ̀” nípa ètò tí Jèhófà ṣe láti tipasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà mú aráyé bọ̀ sípò àti láti tipasẹ̀ Ìjọba náà ya orúkọ mímọ́ rẹ̀ sí mímọ́. Kí ni èrò Pọ́ọ̀lù nípa ọgbọ́n tí Ọlọ́run tó ṣe irú ètò yìí ní? Ọ̀rọ̀ tó fi parí ìwé tó kọ ni pé: “Ọlọ́run, ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n, ni kí ògo wà fún nípasẹ̀ Jésù Kristi títí láé. Àmín.”—Róòmù 11:25; 16:25-27.
16 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Jèhófà ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n,” ìyẹn ni pé, ọgbọ́n rẹ̀ ló ga jù lọ láyé lọ́run. Ṣé ẹ̀dá èèyàn aláìpé kankan wá lè mọ bóun ṣe lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí lọ́nà tó dára ju ti Ọlọ́run lọ, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ẹ̀sùn Sátánì tó jẹ́ pé ó gba ọgbọ́n ńlá fún ọlọgbọ́n gíga jù lọ láyé lọ́run láti yanjú rẹ̀? Ẹ ò wá rí i pé a ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ káwọn náà lè ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tá a ní fún Ọlọ́run tó “jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ọkàn-àyà.” (Jóòbù 9:4) Bá a bá ṣe ń mọ̀ sí i nípa ọgbọ́n Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe túbọ̀ máa dá wa lójú pé ọ̀nà tó gbà ń bójú tó àwọn nǹkan ló dára jù lọ.—Òwe 3:5, 6.
Jẹ́ Kó Mọ Èyí Tó Ta Yọ Lára Àwọn Ànímọ́ Jèhófà
17. Bí àwọn tí inú wọn bà jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run fàyè gba ìpọ́njú bá ní ìmọ̀ sí i nípa ìfẹ́ Jèhófà, báwo lèyí á ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
17 “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn yìí ni Bíbélì fi sọ èyí tó ta yọ lára àwọn ànímọ́ Jèhófà. Ànímọ́ náà ló fani mọ́ra jù lọ lára àwọn ànímọ́ rẹ̀, òun ló sì ń tu àwọn tí ìwà ibi tó pọ̀ láyé ń kó ìbànújẹ́ bá nínú. Jèhófà ń lo ìfẹ́ nínú gbogbo ohun tó ń ṣe láti fòpin sí àwọn ohun búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ fà bá àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní ló fi jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ọmọ Ádámù àti Éfà nírètí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n lè máa gbàdúrà sóun, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú òun. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní yìí ló mú kó pèsè ìràpadà tó jẹ́ kí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ṣeé ṣe, tó tún máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún aráyé láti padà ní ìwàláàyè pípé, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Ìfẹ́ tó ní tún jẹ́ kó máa mú sùúrù fún aráyé, èyí tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láǹfààní láti kọ Sátánì sílẹ̀ kí wọ́n sì yan Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ wọn.—2 Pétérù 3:9.
18. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ wo la ní, kí la sì máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Nígbà tí pásítọ̀ kan ń wàásù níbì kan tí wọ́n ti ń ṣe àyájọ́ ọjọ́ táwọn apániláyà ṣọṣẹ́ tó burú jáì, ó ní: “A ò mọ ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìwà ibi àti ìpọ́njú ṣì máa bá a nìṣó.” Àbẹ́ ẹ̀ máa gbọ́ pásítọ̀, ó mà ṣe o! Ǹjẹ́ kì í ṣe àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ pé àwa ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìwà ibi ṣì wà? (Diutarónómì 29:29) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ọlọgbọ́n ni Jèhófà, tó jẹ́ onídàájọ́ òdodo tó sì tún nífẹ̀ẹ́, a mọ̀ pé kò ní pẹ́ fòpin sí gbogbo ìpọ́njú. Ó tiẹ̀ ti ṣèlérí pé òun máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìṣípayá 21:3, 4) Àmọ́, àwọn tí ikú ti ń pa láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ńkọ́? Ṣé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bójú tó ọ̀ràn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án ní Édẹ́nì yọ wọ́n sílẹ̀ tí wọn ò fi ní nírètí kankan ni? Rárá o. Ìfẹ́ mú kí Jèhófà ṣe ìpèsè kan fáwọn náà, ìyẹn àjíǹde. Èyí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí la lè sọ fún ẹni tó bá béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìpọ́njú tó ń bá aráyé?
• Báwo ni ìjẹ́mímọ́ Jèhófà àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣe hàn nínú ọwọ́ tó fi mú àwọn tó ṣọ̀tẹ̀ ní Édẹ́nì?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ sí i nípa ìfẹ́ Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Wọ́nà láti ṣèrànwọ́ fáwọn tínú wọn bà jẹ́ nítorí ìpọ́njú tó ń bá aráyé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Dáfídì àti Hábákúkù tí wọ́n nígbàgbọ́ bi Ọlọ́run ní ìbéèrè tó jẹ wọ́n lọ́kàn